Ayẹyẹ Tí Ó Mìrìngìndìn—Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kíláàsì Kẹrìnlélọ́gọ́rùn-ún ti Gilead
“ỌJỌ́ ayọ̀ ní ọjọ́ òní jẹ́, gbogbo wa sì ni inú wa ń dùn.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ni Carey Barber, ọ̀kan lára mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, fi ṣí ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì kẹrìnlélọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead ní March 14, 1998. Ó ké sí 4,945 èèyàn tí ó wà láwùjọ náà láti bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ náà pẹ̀lú kíkọ orin Ìjọba nọnba 208, tí ó ní àkọlé náà, “Orin Ayọ̀-Inúdídùn.”
Ìmọ̀ràn Gbígbéṣẹ́ Láti Jẹ́ Aláyọ̀
Apá àkọ́kọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ọ̀wọ́ àsọyé kúkúrú márùn-ún tí a gbé ka Bíbélì, pèsè ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ lórí bí a ṣe lè jẹ́ kí ayọ̀ tí ó gbalẹ̀ kan ní ọjọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà máa bá a nìṣó.
Joseph Eames ti Ẹ̀ka Ìkọ̀wé ni ó sọ àsọyé àkọ́kọ́. Ó sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Fara Wé Ẹ̀mí Àwọn Adúróṣinṣin,” tí a gbé ka àkọsílẹ̀ Bíbélì ti 2 Sámúẹ́lì orí 15 àti 17, níbi tí Ábúsálómù, ọmọ Dáfídì, ti gbìmọ̀ láti gba ìjọba tí Ọlọ́run fún baba rẹ̀, nípa dídáná ọ̀tẹ̀. Ṣùgbọ́n, nígbà náà, àwọn kan wà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin ti ẹni àmì òróró Jèhófà, Dáfídì Ọba. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn míṣọ́nnárì tuntun lè rí kọ́ nínú èyí? Arákùnrin Eames parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní sísọ pé: “Ibikíbi tí o bá lọ nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ, máa fi ìdúróṣinṣin gbé ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ ti ìṣàkóso Ọlọ́run lárugẹ. Ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun kan náà.”
David Sinclair ni olùbánisọ̀rọ̀ kejì lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ó la ohun àbéèrèfún mẹ́wàá, tí a mẹ́nu kàn nínú Sáàmù 15 lẹ́sẹẹsẹ, láti lè jẹ́ àlejò nínú ‘àgọ́ Jèhófà.’ Àsọyé rẹ̀, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Máa Bá A Nìṣó Gẹ́gẹ́ Bí Àlejò Nínú Àgọ́ Míṣọ́nnárì Rẹ,” fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà níṣìírí láti fi sáàmú yìí sílò nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn, níbi tí wọn yóò ti jẹ́ àlejò. Arákùnrin Sinclair tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà. Kí ni yóò yọrí sí? Sáàmù 15:5 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, a kì yóò mú un ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”
John Barr, ọ̀kan lára mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ni ó sọ̀rọ̀ tẹ̀ lé e, ó sì pe àfiyèsí sí ipa tí ń tani jí tí orin kíkọ ń kó nínú àwọn ìpàdé Kristẹni. Ṣùgbọ́n orin wo ni ó ń múnú ẹni dùn jù lọ nínú gbogbo orin tí a ń kọ kárí ayé lónìí? Ìhìn rere Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run ni. Kí sì ni orin kíkọ yìí tàbí ìwàásù nípa Ìjọba náà ń yọrí sí? Ìlà kejì nínú orin nọnba 208 sọ ọ́ láìfibọpobọyọ̀ pé: “Ọpọlọpọ nwá sọdọ Jehofah nipa ’waasu ati ìkọ́ni. Awọn naa pẹlu nkọrin ajọyọ sétí ìgbọ́ gbogbo araye!” Bẹ́ẹ̀ ni, lójúmọ́ kọ̀ọ̀kan nǹkan bí 1,000 ọmọ ẹ̀yìn tuntun ni a ń batisí wọn. Arákùnrin Barr parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ará, kì í ha ṣe ohun àgbàyanu pé, a ń rán yín lọ sí àwọn àgbègbè tí ẹ óò ti pàdé àwọn ènìyàn tí wọn yóò ti máa retí yín láti gbọ́ orin tí ẹ fẹ́ kọ?”
“Ẹ Gbọ́rọ̀ Láti Ẹnu Àwọn Onírìírí” ni àkọlé àsọyé tí James Mantz ti Ẹ̀ka Ìkọ̀wé sọ tẹ̀ lé e. Ó tọ́ka sí i pé àwọn ohun kan wà tí ó jẹ́ pé inú ìrírí nìkan ni a ti lè kọ́ ọ. (Hébérù 5:8) Síbẹ̀síbẹ̀, Òwe 22:17 rọ̀ wá láti ‘dẹ etí wa sílẹ̀ kí a sì gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,’ tàbí àwọn onírìírí. Àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege lè kọ́ ohun púpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó ṣáájú wọn. Arákùnrin Mantz wí pé: “Wọ́n mọ bí a ti ń bá àwọn òǹtajà àdúgbò dúnàádúrà. Wọ́n mọ àgbègbè tí ó yẹ kí àwọn yẹra fún nínú ìlú nítorí ewu nípa ti ara tàbí ti ìwà híhù. Wọ́n mọ bí àwọn ará àdúgbò náà ṣe rára gba nǹkan sí. Àwọn míṣọ́nnárì ọlọ́jọ́ pípẹ́ mọ ohun tí o lè ṣe láti jẹ́ aláyọ̀, kí o sì kẹ́sẹ járí níbi iṣẹ́ àyànfúnni rẹ.”
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Mọyì Iṣẹ́ ti Ìṣàkóso Ọlọ́run Tí A Yàn Fún Ọ,” Wallace Liverance, akọ̀wé Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead, ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míṣọ́nnárì kan, bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, Tímótì, àti Bánábà, gba iṣẹ́ àyànfúnni wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ tàbí àwọn ìfihàn iṣẹ́ ìyanu kan, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni ó ń yan àwọn míṣọ́nnárì tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead sí ibì kan ní pápá àgbáyé. (Mátíù 24:45-47) Ó fi ibi tí a bá yan àwọn míṣọ́nnárì sí wé àwọn ibi tí Gídéónì yan àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n fẹ́ bá àwọn ará Mídíánì jagun sí. (Àwọn Onídàájọ́ 7:16-21) Arákùnrin Liverance rọni pé: “Mọyì ibi iṣẹ́ míṣọ́nnárì ti ìṣàkóso Ọlọ́run tí a yàn ọ́ sí. Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ogun Gídéónì ‘ṣe dúró ní àyè wọn,’ ka ibi tí a yàn ọ́ sí gẹ́gẹ́ bí ibi tí ó yẹ kí o dúró sí. Ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà lè lò ọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti lo àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin Gídéónì.”
Jíjẹ́ Ẹni Tí Ó Kóni Mọ́ra Ń Mú Ayọ̀ Wá
Ilé Ìṣọ́ sọ nígbà kan pé: “Kàkà tí a óò fi gbé gbogbo ìfẹ́ ọkàn wa àti ìgbésí ayé wa ka àwọn ohun tí a ń ṣe jáde àti àwọn ohun èlò ti ètò nǹkan ìsinsìnyí, àwọn ohun tí kò dájú pé yóò máa wà títí lọ, ẹ wo bí ó ti sàn jù, tí ó sì bọ́gbọ́n mu jù lọ láti gbé ìfẹ́ ọkàn wa gan-an ka àwọn ènìyàn, kí a sì kọ́ bí a ṣe lè rí ayọ̀ nínú ṣíṣe nǹkan fún wọn.” Ní ìbámu pẹ̀lú ìyẹn, Arákùnrin Mark Noumair, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead, jíròrò ìrírí wọn nínú iṣẹ́ ìsìn pápá pẹ̀lú àwùjọ àkẹ́kọ̀ọ́ kan, ó sì sọ pé: “Fífi ìfẹ́-ọkàn ara ẹni hàn nínú àwọn ẹlòmíràn ni ohun tí yóò jẹ́ kí ẹ jẹ́ míṣọ́nnárì rere.”
Àṣírí sí Ayọ̀ Nínú Pápá Ilẹ̀ Òkèèrè
Kí ni díẹ̀ lára àwọn àṣírí ṣíṣàṣeyọrí àti níní ayọ̀ nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì? Arákùnrin Charles Woody ti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn àti Harold Jackson, míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀ rí ní Látìn Amẹ́ríkà tí ó sì jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, fọ̀rọ̀ wá àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n wá sí kíláàsì kẹsàn-án ti ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka lẹ́nu wò. Ìwọ̀nyí ní díẹ̀ lára ìmọ̀ràn tí wọ́n ní:
Albert Musonda láti Zambia sọ pé: “Nígbà tí àwọn míṣọ́nnárì bá lo àtinúdá wọn láti lọ kí àwọn ará, ó máa ń mú ẹ̀mí rere dàgbà nítorí pé àwọn ará yóò lè sún mọ́ àwọn míṣọ́nnárì, àwọn míṣọ́nnárì pẹ̀lú yóò sì lè sún mọ́ wọn.”
Rolado Morales ti Guatemala dábàá pé nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó yá mọ́ni bá fún àwọn míṣọ́nnárì tuntun ní nǹkan mímu, wọ́n lè fi inú rere àti ọgbọ́n fèsì pé: “Ẹni tuntun ni mí ní orílẹ̀-èdè yìí. Ó wù mí kí n lè mu ún, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ohun tí ó bá yín lára mu ni ó lè yọ mí lẹ́nu. Mo nírètí pé lọ́jọ́ kan n óò lè mu ún, inú mi yóò sì dùn bí mo bá lè ṣe bẹ́ẹ̀.” Kí ni àǹfààní irú èsì bẹ́ẹ̀? “A kò ní mú inú bí àwọn ènìyàn, àwọn míṣọ́nnárì yóò sì jẹ́ onínúure sí àwọn ènìyàn.”
Kí ni ó lè ran àwọn míṣọ́nnárì lọ́wọ́ láti ní ìfaradà nínú iṣẹ́ àyànfúnni wọn? Arákùnrin Paul Crudass, akẹ́kọ̀ọ́yege ní kíláàsì kọkàndínlọ́gọ́rin ti Gilead, tí ó ti ń sìn ní Liberia fún ọdún 12 tí ó ti kọjá, ṣàkíyèsí pé: “Mo mọ̀ pé lóòótọ́ ni pé àárò àwọn ọmọ máa ń sọ àwọn òbí wọn. Ṣùgbọ́n nígbà mìíràn àwọn míṣọ́nnárì máa ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ara wọn mọ orílẹ̀-èdè, àyíká náà àti àṣà ìbílẹ̀ dáadáa, kí wọ́n sì di ojúlùmọ̀ àwọn ènìyàn. Ó lè fẹ́ láti fi ibẹ̀ sílẹ̀. Bí ó bá rí lẹ́tà gbà láti ilé tí ó sọ pé, ‘Àárò rẹ sọ wá púpọ̀; àìsí ọ nítòsí jẹ́ kí gbogbo nǹkan sú wa pátápátá,’ ìyẹn nìkan ti tó láti mú kí ó palẹ̀ ẹrù rẹ̀ mọ́, kí ó sì padà sílé. Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn mọ̀lẹ́bí tí ó wà níhìn-ín lónìí rántí ìyẹn.”
Lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà, Theodore Jaracz, ọ̀kan lára mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ni ó sọ ọ̀rọ̀ àsọparí. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni: “Fi Ìjọba Náà Sí Ipò Àkọ́kọ́ Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ.” Báwo ni àwọn míṣọ́nnárì ṣe lè jẹ́ kí ojú wọn mú ọ̀nà kan, tí wọn kò sì ní jẹ́ kí ọkàn wọn pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ó rọ̀ wọ́n láti ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi ire Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Ó sọ ìránnilétí tí ó bọ́ sákòókò yìí: “Àwọn míṣọ́nnárì kan ti pa ìdákẹ́kọ̀ọ́ tì nítorí pé àwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́, ètò ìfìsọfúnníránṣẹ́ E-mail, àti ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ti lè gbà wọ́n lọ́kàn. Ó yẹ kí a mọ bí a ṣe lè wà déédéé nínú lílo ohun èlò èyíkéyìí, kí a má sì ṣe lo àkókò tí ó pọ̀ jù lórí ohun kan tí yóò nípa lórí ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”
A fún wọn ní ìwé ẹ̀rí dípúlómà wọn lẹ́yìn tí Arákùnrin Jaracz parí àsọyé rẹ̀, tí ẹnì kan sì ka lẹ́tà ìmọrírì tí kíláàsì náà kọ. Aṣojú kíláàsì náà sọ ìmọ̀lára gbogbo wọn jáde lọ́nà yìí pé: “A rí ẹ̀rí tí ó tó nípa ìfẹ́ tí Jésù wí pé a óò fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun mọ̀, èyí sì ti jẹ́ kí a túbọ̀ ní ìfọkànbalẹ̀ pé ibi yòówù tí a lè wà, ọ̀yàyà, àti ìfẹ́ ètò àjọ tí ó dà bí ìyá wa ń bẹ lẹ́yìn wa. Pẹ̀lú irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀, a ṣe tán láti lọ sí òpin ilẹ̀ ayé.” Ọ̀rọ̀ ìkádìí tí ó mórí ẹni wú ni èyí jẹ́ fún ọjọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́yege tí ó mìrìngìndìn, ti kíláàsì kẹrìnlélọ́gọ́rùn-ún ti Gilead.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìsọfúnni Oníṣirò Nípa Kíláàsì
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 9
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yanni sí: 16
Iye akẹ́kọ̀ọ́: 48
Iye tọkọtaya: 24
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 33
Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 16
Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Kíláàsì kẹrìnlélọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege
Ní ìlà tí ó wà nísàlẹ̀ yìí, a fi nọ́ńbà sí ìlà láti iwájú lọ sí ẹ̀yìn, a sì kọ orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún ní ìlà kọ̀ọ̀kan
(1) Romero, M.; Howarth, J.; Blackburne-Kane, D.; Hohengasser, E.; West, S.; Thom, S. (2) Colon, W.; Glancy, J.; Kono, Y.; Drews, P.; Tam, S.; Kono, T. (3) Tam, D.; Zechmeister, S.; Gerdel, S.; Elwell, J.; Dunec, P.; Tibaudo, H. (4) Taylor, E.; Hildred, L.; Sanches, M.; Anderson, C.; Bucknor, T.; Hohengasser, E. (5) Howarth, D.; Ward, C.; Hinch, P.; McDonald, Y.; Sanches, T.; Thom, O. (6) Drews, T.; Tibaudo, E.; Elwell, D.; Dunec, W.; Blackburne-Kane, D.; Ward, W. (7) Anderson, M.; Zechmeister, R.; McDonald, R.; Bucknor, R.; Glancy, S.; Gerdel, G. (8) Romero, D.; Hinch, R.; Hildred, S.; Taylor, J.; Colon, A.; West, W.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn arákùnrin tí wọ́n kópa nínú dídá kíláàsì kẹrìnlélọ́gọ́rùn-ún náà lẹ́kọ̀ọ́: (láti ọwọ́ òsì) W. Liverance, U. Glass, K. Adams, M. Noumair