ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 6/15 ojú ìwé 17-21
  • Ètò Àjọ Jèhófà Ń ti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Lẹ́yìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ètò Àjọ Jèhófà Ń ti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Lẹ́yìn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílà Á Já Láìka Inúnibíni Kárí Ayé Sí
  • Jèhófà Ń Bù Kún Ìwàásù Onítara
  • Mímú Ara Wa Bá Àìní Àwọn Ènìyàn Mu
  • Kí Ní Ń Sún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣiṣẹ́?
  • Ìtara Wa Láti Parí Ìjẹ́rìí Náà
  • Jíjẹ́rìí Fún “Gbogbo Awọn Orílẹ̀-Èdè”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • A Níláti Kọ́kọ́ Wàásù Ìhìnrere Yìí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Báwo La Ṣe Ń Wàásù Ìhìn Rere?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 6/15 ojú ìwé 17-21

Ètò Àjọ Jèhófà Ń ti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Lẹ́yìn

“Mo . . . rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀.”—ÌṢÍPAYÁ 14:6.

1. Báwo ni a ṣe dán Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò, èé sì ti ṣe tí wọ́n fi là á já?

ÈÉ ṢE tí ó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ pé kí a mọ ipa tí ètò àjọ Jèhófà ti òkè ọ̀run ń kó nínú ṣíṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni? Tóò, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ha ti lè kẹ́sẹ járí nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé oníkanra yìí láìní ìtìlẹ́yìn àwọn ogun ọ̀run ti Jèhófà bí? Àwọn Ẹlẹ́rìí ti ṣe irú ìwàásù bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rúndún kan tí ó kún fún ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lọ́nà bíbùáyà, ètò ìṣèlú aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀, àwọn ogun àgbáyé, àti onírúurú ìdààmú. Láìsí ìrànwọ́ Jèhófà Àwọn Ẹlẹ́rìí ha lè la ìdènà kárí ayé ti ẹ̀tanú, ìkórìíra, àti nígbà mìíràn inúnibíni gbígbóná janjan tí a ń ṣe sí wọn já bí?—Sáàmù 34:7.

Lílà Á Já Láìka Inúnibíni Kárí Ayé Sí

2. Ìjọra wo ni ó wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ ti ọ̀rúndún kìíní àti ti òde òní?

2 Ní ọ̀rúndún ogún yìí, àwọn ọ̀tá, ti ìsìn àti ti ìṣèlú, ti gbé gbogbo ìdènà tí ó ṣeé ṣe fún wọn dìde, ní ti òfin àti lọ́nà mìíràn, láti gbìyànjú láti dènà iṣẹ́ Jèhófà tàbí láti dá a dúró. A ti ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin, a ti parọ́ mọ́ wọn, a ti kọ ọ̀rọ̀ burúkú nípa wọn, a ti bà wọ́n lórúkọ jẹ́—a tilẹ̀ ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀—lọ́pọ̀ ìgbà nígbà tí àwọn àlùfáà Bábílónì Ńlá súnná sí i. A lè sọ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nípa àwọn Kristẹni ìjímìjí, pé, “lóòótọ́, ní ti ẹ̀ya ìsìn yìí, a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà ìsìn Júù ti ọjọ́ Kristi ṣe jà fitafita láti dá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ dúró, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn apẹ̀yìndà, tí wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn àlè wọn olóṣèlú, ti gbìyànjú láti bomi paná iṣẹ́ ìjẹ́rìí ńláǹlà tí a fi ń dáni lẹ́kọ̀ọ́, èyí tí àwọn ènìyàn Jèhófà ń ṣe.—Ìṣe 28:22; Mátíù 26:59, 65-67.

3. Kí ni a lè rí kọ́ láti inú ìwà títọ́ Henryka Żur?

3 Gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Poland ní March 1, 1946 yẹ̀ wò. Henryka Żur, ọ̀dọ́mọbìnrin ọlọ́dún 15 kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, tí ó wá láti itòsí Chełm, bá Ẹlẹ́rìí mìíràn, tí ó jẹ́ arákùnrin lọ bẹ àwọn olùfìfẹ́hàn tí ń gbé ní abúlé itòsí wò. Àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ jagunjagun ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tí a ń pè ní, Narodowe Siły Zbrojne (Agbo Ọmọ Ogun Jákèjádò Orílẹ̀-Èdè), mú wọn. Wọ́n lu arákùnrin náà bíi-kíkú-bíi-yíyè, ṣùgbọ́n, ó sá mọ́ wọn lọ́wọ́. Àmọ́ ti Henryka kò rí bẹ́ẹ̀. Wọ́n dá a lóró gidigidi fún ọ̀pọ̀ wákàtí bí wọ́n ti ń gbìyànjú láti fipá mú un láti fọwọ́ ṣe àmì àgbélébùú ti ẹ̀sìn Kátólíìkì. Ọ̀kan lára àwọn tí ń dá a lóró wí pé: “Ìwọ lo mọ ohun tí o lè gbà gbọ́, sáà ti fọwọ́ ṣe àmì àgbélébùú ti ẹ̀sìn Kátólíìkì ni tèmi. Àìjẹ́bẹ́ẹ̀, ìbọn yóò dún lára rẹ!” Èyí ha dín ìwà títọ́ rẹ̀ kù bí? Rárá o. Àwọn ẹlẹ́sìn tí wọ́n ń sá kíjokíjo náà wọ́ ọ tuuru lọ sínú igbó, wọ́n sì yìnbọn pa á. Síbẹ̀, ó jàjàṣẹ́gun! Kò ṣeé ṣe fún wọn láti ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́.a—Róòmù 8:35-39.

4. Báwo ni àwọn ètò òṣèlú àti ti ìsìn ti gbìyànjú tó láti tẹ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà rì?

4 Fún ohun tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, a ti hùwà ìkà sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti òde òní, a sì ti tẹ́ńbẹ́lú wọn. Nítorí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe apá kan ìsìn olókìkí ti Sátánì, tí wọn kò sì fẹ́ láti jẹ́ apá kan rẹ̀, a ti kà wọ́n sí ẹran ọdẹ yíyẹ wẹ́kú fún ẹnikẹ́ni tí ń fi ẹ̀tanú ṣe lámèyítọ́ tàbí agbawèrèmẹ́sìn, tí ń ṣàtakò. Ètò òṣèlú ti ta kò wọ́n lọ́nà rírorò. A ti pa ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Àní ètò ìjọba tí a fẹnu lásán pè ní tiwa-n-tiwa pàápàá ti gbìyànjú láti dènà wíwàásù ìhìn rere náà. Láti ọdún 1917 ní Kánádà àti United States, àwọn àlùfáà ti súnná sí fífẹ̀sùn kan Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ti ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí nígbà náà, fún fífẹ́ láti dojú ìjọba bolẹ̀. A fi àwọn òṣìṣẹ́ Watch Tower Society sẹ́wọ̀n lọ́nà tí kò tọ́, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ṣe ni a tún dá wọn sílẹ̀.—Ìṣípayá 11:7-9; 12:17.

5. Ọ̀rọ̀ wo ni ó ti jẹ́ ìṣírí fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà?

5 Sátánì ti lo gbogbo agbára rẹ̀ láti gbìyànjú láti dá iṣẹ́ ìjẹ́rìí àwọn arákùnrin Kristi àti àwọn adúróṣinṣin alábàákẹ́gbẹ́ wọn dúró. Síbẹ̀, bí ọ̀pọ̀ ìrírí ti fi hàn, ìhalẹ̀mọ́ni, ìkójìnnìjìnnìbáni, ìwà ipá ojúkoojú, ìfisẹ́wọ̀n, ìfiságọ̀ọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àní ikú pàápàá kò lè pa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu mọ́. Bí ọ̀ràn sì ti rí nìyẹn jálẹ̀ ìtàn. Léraléra, ọ̀rọ̀ Èlíṣà ti jẹ́ ìṣírí: “Má fòyà, nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” Ìdí kan ni pé, àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ pọ̀ ju àwọn ọmọ ogun Èṣù lọ!—2 Àwọn Ọba 6:16; Ìṣe 5:27-32, 41, 42.

Jèhófà Ń Bù Kún Ìwàásù Onítara

6, 7. (a) Àwọn ìsapá àkọ́kọ́ wo ni a ṣe láti wàásù ìhìn rere náà? (b) Ìyípadà wo tí ó mú àǹfààní wa ni ó wáyé bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1943?

6 Bí ọ̀rúndún ogún ṣe ń lọ, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lo ọ̀pọ̀ ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ láti mú kí iṣẹ́ ńlá ti jíjẹ́rìí kí òpin tó dé gbòòrò sí i, kí ó sì yá kánkán sí i. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ní ọdún 1914, Pásítọ̀ Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Bible and Tract Society, ṣonígbọ̀wọ́ kíkọ́kọ́ lo àwòrán sinimá gbagidi àti èyí tí ń rìn, tí a gba àlàyé rẹ̀ tí a gbé ka Bíbélì sínú rẹ́kọ́ọ̀dù ohun èlò agbóhùnjáde, tí ó ń sọ̀rọ̀ bí àwòrán ti ń jáde, nínú ìmújáde sinimá oníwákàtí mẹ́jọ tí a gbé ka Bíbélì, tí a pè ní, “The Photo-Drama of Creation.” Ẹnu ya ọ̀pọ̀ àwọn tí ó wo sinimá náà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nígbà náà lọ́hùn-ún. Lẹ́yìn náà, ní àwọn ọdún 1930 àti 1940, a mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí bí ẹní mowó nítorí iṣẹ́ ìwàásù wọn láti ilé dé ilé pẹ̀lú ohun èlò agbóhùnjáde tí ó mọ níwọ̀n, ní lílo àwọn àsọyé Bíbélì tí a ti gbà sílẹ̀, tí J. F. Rutherford, ààrẹ kejì ti Society, sọ.

7 Ní ọdún 1943, lábẹ́ ìdarí Nathan H. Knorr, ààrẹ kẹta ti Society, a gbé ìgbésẹ̀ onígboyà kan, nígbà tí a pinnu láti dá ilé ẹ̀kọ́ kan sílẹ̀ fún àwọn òjíṣẹ́ ní gbogbo ìjọ. A óò dá Àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́kọ̀ọ́ láti máa wàásù àti láti máa kọ́ni láti ilé dé ilé láìlo àwọn ohun èlò agbóhùnjáde. Láti ìgbà náà, a ti ṣètò àwọn ilé ẹ̀kọ́ mìíràn láti dá àwọn míṣọ́nnárì, àwọn òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún, àwọn alàgbà ìjọ, àti àwọn alábòójútó tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ ní àwọn ẹ̀ka Watch Tower Society, lẹ́kọ̀ọ́. Kí ni èyí ti yọrí sí?

8. Báwo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe fi ìgbàgbọ́ ńláǹlà hàn ní ọdún 1943?

8 Nígbà náà lọ́hùn-ún ní ọdún 1943, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì gbóná janjan, ìwọ̀nba 129,000 ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí péré ni ó wà ní ilẹ̀ 54. Síbẹ̀, wọ́n ní ìgbàgbọ́ àti ìpinnu tí ó lágbára pé Mátíù 24:14 yóò ní ìmúṣẹ kí òpin tó dé. Ó dá wọn lójú gbangba pé Jèhófà yóò mú kí a pòkìkí ìhìn iṣẹ́ ìkìlọ̀ pàtàkì náà ṣáájú kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò tẹ̀ lé e, tí yóò mú òpin dé bá ètò àwọn nǹkan yìí tí ó ti díbàjẹ́ tó dé. (Mátíù 24:21; Ìṣípayá 16:16; 19:11-16, 19-21; 20:1-3) A ha ti san èrè fún ìsapá wọn bí?

9. Àwọn kókó wo ni ó fi hàn pé iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà tẹ̀ síwájú?

9 Nísinsìnyí, ó kéré tán, orílẹ̀-èdè 13 ni ó wà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ògbóṣáṣá wọn lé ní 100,000. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì jọba lé. Síbẹ̀, ẹ wo bí nǹkan ti rí. Brazil ní nǹkan bí 450,000 akéde ìhìn rere náà, iye tí ó lé ní 1,200,000 sì wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ní ọdún 1997. Àpẹẹrẹ mìíràn ni Mexico, tí ó ní nǹkan bí 500,000 Ẹlẹ́rìí, àwọn tí ó sì wá sí ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí níbẹ̀ lé ní 1,600,000. Àwọn orílẹ̀-èdè Kátólíìkì mìíràn ni Ítálì (nǹkan bí 225,000 Ẹlẹ́rìí), ilẹ̀ Faransé (nǹkan bí 125,000), Sípéènì (wọ́n lé ní 105,000), àti Argentina (wọ́n lé ní 115,000). Ní United States, níbi tí ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, Kátólíìkì, àti àwọn ẹ̀sìn Júù mìíràn ti gbalẹ̀ kan, nǹkan bí 975,000 Ẹlẹ́rìí wà níbẹ̀, iye tí ó lé ní 2,000,000 sì wá sí Ìṣe Ìrántí. Dájúdájú, ogunlọ́gọ̀ ńlá ń wọ́ jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ àdììtú rẹ̀, wọ́n sì ń yíjú sí àwọn ìlérí Ọlọ́run tí kò díjú, tí ó sì dájú ti “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.”—2 Pétérù 3:13; Aísáyà 2:3, 4; 65:17; Ìṣípayá 18:4, 5; 21:1-4.

Mímú Ara Wa Bá Àìní Àwọn Ènìyàn Mu

10. Báwo ni ipò àwọn nǹkan ti ṣe yí padà ní àwọn àgbègbè kan?

10 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí wọ́n ti yíjú sí Jèhófà nípasẹ̀ Kristi Jésù ni ó jẹ́ pé lẹ́nu iṣẹ́ ilé dé ilé ni a ti bá wọn pàdé. (Jòhánù 3:16; Ìṣe 20:20) Ṣùgbọ́n a ti lo àwọn ọ̀nà mìíràn pẹ̀lú. Ìgbà ti yí padà, ipò ọrọ̀ ajé sì ti dàrú débi pé ọ̀pọ̀ obìnrin ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí lẹ́yìn òde ìdílé. Lọ́pọ̀ ìgbà, láàárín ọ̀sẹ̀, ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ni a lè bá nílé. Nípa báyìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú ara wọn bá ipò náà mu. Gẹ́gẹ́ bí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn ìjímìjí, wọ́n ń lọ síbi tí wọ́n ti lè rí àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń lọ ní àkókò tí wọ́n lè bá wọn níbẹ̀.—Mátíù 5:1, 2; 9:35; Máàkù 6:34; 10:1; Ìṣe 2:14; 17:16, 17.

11. Níbo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù lónìí, kí sì ni ó ti yọrí sí?

11 Lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí ń lo ìdánúṣe, wọ́n sì ń fi ọgbọ́n inú wàásù fún àwọn ènìyàn ní àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí ńláńlá, ilé ìrajà, ilé iṣẹ́, ọ́fíìsì àti ibi iṣẹ́ ajé, ilé ẹ̀kọ́, àgọ́ ọlọ́pàá, ilé epo, hòtẹ́ẹ̀lì àti ilé àrójẹ, àti lójú pópó. Ní tòótọ́, wọ́n ń wàásù níbikíbi tí wọ́n bá ti lè bá ènìyàn pàdé. Bí àwọn ènìyàn bá sì wà nílé, nígbà náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí kò ní dẹ́kun láti máa kàn sí wọn níbẹ̀. Mímú ara wọn bá ipò mu àti mímú kí ọwọ́ wọn dí fún iṣẹ́ yìí ń yọrí sí pípín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó pọ̀ sí i kiri. A ń rí àwọn ẹni bí àgùntàn. A ń bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun. Àwọn òjíṣẹ́ onítara tí ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ààbọ̀ ti ṣe iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó lágbára jù lọ tí a tí ì ṣe nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn! Ìwọ ha ní àǹfààní jíjẹ́ ọ̀kan lára wọn bí?—2 Kọ́ríńtì 2:14-17; 3:5, 6.

Kí Ní Ń Sún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣiṣẹ́?

12. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀? (b) Ipa wo ni ẹ̀kọ́ yìí ń ní?

12 Ipa wo ni ètò àjọ ti òkè ọ̀run ń kó nínú ọ̀ràn yìí? Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Gbogbo ọmọ rẹ yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀ yanturu.” (Aísáyà 54:13) Jèhófà ń tipasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé tí a lè fojú rí kọ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé yìí tí ó wà ní ìṣọ̀kan—ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, ní àwọn àpéjọpọ̀ àti ní àpéjọ. Ó ti yọrí sí ìṣọ̀kan àti àlàáfíà. Ẹ̀kọ́ Jèhófà ti mú àwọn ènìyàn tí wọ́n yàtọ̀ gédégbé jáde, àwọn tí a kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ẹnì kíní kejì àti àwọn aládùúgbò wọn gẹ́gẹ́ bí ara wọn, àwọn tí a ti kọ́ láti má ṣe kórìíra aládùúgbò wọn, láìka ibikíbi tí wọ́n lè gbé nínú ayé tí ó ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí sí.—Mátíù 22:36-40.

13. Báwo ni a ṣe lè ní ìdánilójú pé àwọn áńgẹ́lì ń darí iṣẹ́ ìwàásù náà?

13 Ìfẹ́ ni ó ń sún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa bá wíwàásù lọ láìka ẹ̀mí ìdágunlá tàbí inúnibíni sí. (1 Kọ́ríńtì 13:1-8) Wọ́n mọ̀ pé gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 14:6 ti sọ, ọ̀run ni a ti ń darí iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà tí wọ́n ti ń ṣe. Kí ni ìhìn iṣẹ́ náà tí a ń pòkìkí lábẹ́ ìdarí àwọn áńgẹ́lì? “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.” Wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà ń gbé orúkọ Jèhófà ga. A ń ké sí àwọn ènìyàn láti fi ògo fún Ẹlẹ́dàá náà, Ọlọ́run, kì í ṣe fún ẹ̀dá àti ẹfolúṣọ̀n tí kò lágbára láti darí nǹkan. Èé sì ti ṣe tí iṣẹ́ ìwàásù náà fi jẹ́ kánjúkánjú tó bẹ́ẹ̀? Nítorí wákàtí ìdájọ́ náà ti dé—ìdájọ́ lòdì sí Bábílónì Ńlá àti gbogbo apá ètò àwọn nǹkan Sátánì tí a lè fojú rí.—Ìṣípayá 14:7; 18:8-10.

14. Àwọn wo ni ó ń lọ́wọ́ nínú ìgbétásì ìkọ́ni ńláǹlà yìí?

14 Iṣẹ́ ìwàásù yìí kò yọ Kristẹni kankan tí ó ti ṣèyàsímímọ́ sílẹ̀. Àwọn alàgbà nípa tẹ̀mí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ. Ọwọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ dí fọ́fọ́ fún iṣẹ́ náà. Àwọn akéde onítara fún ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ń sọ ìhìn iṣẹ́ náà jákèjádò ayé, bóyá ìwọ̀nba wákàtí díẹ̀ nínú oṣù tàbí ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n lè fi wàásù.—Mátíù 28:19, 20; Hébérù 13:7, 17.

15. Ẹ̀rí wo ni ó fi ipa tí ìwàásù Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní hàn?

15 Gbogbo ìsapá yìí ha ti ní ipa kankan lórí ayé bí? Ẹ̀rí kan tí ó fi hàn pé ó ti ṣe bẹ́ẹ̀ ni ti iye ìgbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti hàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n àti àwọn abala ìwé ìròyìn. Ìwọ̀nyí sábà ń tẹnu mọ́ ìforítì àti ìmúratán wa láti dé ọ̀dọ̀ ènìyàn gbogbo. Ní tòótọ́, ìtara wa àti wíwá wa lemọ́lemọ́ ń gbin nǹkan sí àwọn ènìyàn lọ́kàn, àní bí ọ̀pọ̀ jù lọ bá tilẹ̀ kọ ìhìn iṣẹ́ àti àwọn ońṣẹ́ náà!

Ìtara Wa Láti Parí Ìjẹ́rìí Náà

16. Ìṣarasíhùwà wo ni ó yẹ kí a fi hàn ní àkókò tí ó ṣẹ́kù yìí?

16 A kò mọ bí àkókò tí ó kù fún ètò àwọn nǹkan yìí ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ sì ni kò pọndandan fún wa láti mọ̀ ọ́n, níwọ̀n bí ète wa láti sin Jèhófà bá ti mọ́ gaara. (Mátíù 24:36; Kọ́ríńtì 13:1-3) Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé kí ìfẹ́, agbára, àti ìdájọ́ òdodo Jèhófà lè hàn, a gbọ́dọ̀ “kọ́kọ́” wàásù ìhìn rere náà. (Máàkù 13:10) Nítorí náà, láìka iye ọdún tí a ti fi ìháragàgà dúró de òpin ayé oníwà burúkú, onímàgòmágó, àti oníwà ipá yìí, a gbọ́dọ̀ fi ìtara gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa gẹ́gẹ́ bí àyíká ipò wa bá ti yọ̀ǹda. A ti lè dàgbà tàbí kí a máa ṣàìsàn, ṣùgbọ́n a ṣì lè fi ìtara tí a ní nígbà tí a ṣì wà ní ọ̀dọ́ tàbí tí ara wa ṣì le dáadáa sin Jèhófà. Bóyá kò ṣeé ṣe fún wa láti lo àkókò gígùn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n a lè rí i dájú pé ẹbọ ìyìn tí a ń rú sí Jèhófà ń bá a nìṣó láìyingin.—Hébérù 13:15.

17. Sọ ìrírí agbéniró kan tí ó lè ran gbogbo wa lọ́wọ́?

17 Nítorí náà, yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, ẹ jẹ́ kí a fi ìtara hàn, kí a sì máa ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ wa nípa ayé tuntun fún gbogbo àwọn tí a bá bá pàdé. Ẹ jẹ́ kí a dà bí ọmọdébìnrin ọlọ́dún méje tí ó jẹ́ onítìjú tí ń gbé ní Australia ẹni tí ó bá ìyá rẹ̀ lọ sí ilé ìtajà. Ó ti gbọ́ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti wàásù, nítorí náà ó fi ìwé pẹlẹbẹ Bíbélì méjì sínú àpò rẹ̀. Nígbà tí ọwọ́ ìyá rẹ̀ ṣì dí nídìí káńtà, a kò rí ọmọdébìnrin náà mọ́. Níbi tí ìyá rẹ̀ ti ń wá a, ni ó ti rí i tí ó ń fi ìwé pẹlẹbẹ lọ ọ̀dọ́mọbìnrin kan! Ìyá rẹ̀ lọ tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọ̀dọ́mọbìnrin náà fún yíyọ tí ọmọbìnrin òun wá yọ ọ́ lẹ́nu. Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọbìnrin náà ti fi ayọ̀ gba ìwé pẹlẹbẹ náà. Nígbà tí ìyá náà dá wà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, ó béèrè lọ́wọ̀ rẹ̀ bí ó ṣe nígboyà láti bá ẹni tí kò mọ̀ rí sọ̀rọ̀. Ó fèsì pé: “Mo kàn sọ pé, Ó yá, Gbéra ńlẹ̀! Bí mo ṣe lọ nìyẹn!”

18. Báwo ni a ṣe lè fi ẹ̀mí títayọlọ́lá hàn?

18 Gbogbo wa nílò ẹ̀mí bí ti ọmọdébìnrin Australia yẹn, ní pàtàkì láti lè bá àwọn àjòjì tàbí àwọn lọ́gàálọ́gàá sọ̀rọ̀ ìhìn rere náà. A lè máa bẹ̀rù pé wọn kò ní fẹ́ẹ́ gbọ́. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gbàgbé ohun tí Jésù wí pé: “Ẹ má ṣàníyàn nípa báwo tàbí kí ni ẹ ó sọ ní ìgbèjà tàbí ohun tí ẹ óò wí; nítorí ẹ̀mí mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí yẹn gan-an àwọn ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”—Lúùkù 12:11, 12.

19. Kí ni èrò rẹ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?

19 Nítorí náà, gbẹ́kẹ̀ lé ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run bí o ṣe ń fi inú rere mú ìhìn rere náà tọ àwọn ènìyàn lọ. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó wà lónìí, tó sì lè kú lọ́la, tí kò yẹ kí èèyàn gbẹ́kẹ̀ lé, ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ gbẹ́kẹ̀ lé. Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ ti òkè ọ̀run—Kristi Jésù, àwọn áńgẹ́lì mímọ́, àti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí a ti jí dìde—tí wọ́n wà láàyè títí láé ni àwa gbẹ́kẹ̀ lé! Nítorí náà, ẹ rántí pé: “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ”!— Àwọn Ọba 6:16.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àpẹẹrẹ síwájú sí i, wo ìwé náà, 1994 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 217 sí 220.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Ipa wo ni ètò àjọ Ọlọ́run ní òkè ọ̀run kó nínú lílàájá àwọn ènìyàn Jèhófà?

◻ Àwọn ètò òṣèlú àti ti ẹ̀sìn wo ni ó ti gbéjà ko Àwọn Ẹlẹ́rìí ní ọ̀rúndún ogún yìí?

◻ Báwo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn bá àìní àkókò mu?

◻ Kí ní ń sún ọ láti wàásù?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Henryka Żur

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Japan

Martinique

United States

Kenya

United States

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù nígbàkígbà àti níbikíbi tí àwọn ènìyàn bá wà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, a lo ohun èlò agbóhùnjáde láti tan ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kálẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́