Jíjẹ́rìí Fún “Gbogbo Awọn Orílẹ̀-Èdè”
“A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.”—MATTEU 24:14, NW.
1. Èéṣe tí àwọn ọ̀rọ̀ Jesu tí a kọsílẹ̀ ní Matteu 24:14 fi níláti jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
ẸWO ìyàlẹ́nu tí àwọn ọ̀rọ̀ Jesu tí ó wà lókè yìí ti gbọ́dọ̀ jẹ́ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Ju! Èrò náà pé kí àwọn Ju tí a ti yàsímímọ́ máa lọ bá àwọn Kèfèrí “aláìmọ́,” “awọn ènìyàn awọn orílẹ̀-èdè” sọ̀rọ̀, ṣàjèjì sí ẹnìkan tí ó jẹ́ Ju, ó tilẹ̀ ń rínilára.a Họ́wù, Ju olùfọkànsìn kan kì yóò fẹ́ láti wọnú ilé Kèfèrí! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí wọ́n jẹ́ Ju wọ̀nyẹn ṣì ní púpọ̀ síi láti kọ́ nípa Jesu, ìfẹ́ rẹ̀, àti iṣẹ́ tí a fi rán an. Wọ́n sì tún ní púpọ̀ síi láti kọ́ nípa àìṣojúṣàájú Jehofa.—Iṣe 10:28, 34, 35, 45.
2. (a) Báwo ni iṣẹ́-òjíṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ti gbòòrò tó? (b) Àwọn kókó abájọ mẹ́ta pàtàkì wo ni ó ti fikún ìtẹ̀síwájú àwọn Ẹlẹ́rìí?
2 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wàásù ìhìnrere láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, títíkan ilẹ̀ Israeli ti òde-òní, wọ́n sì tún ń polongo rẹ̀ nísinsìnyí ní àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ síi ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Ní 1994 iye àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ju million mẹ́rin àti ààbọ̀ ń wàásù ní àwọn ilẹ̀ 230. Wọ́n ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bíi million mẹ́rin àti ààbọ̀ pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn. Èyí ni a ń ṣe lójú ẹ̀tanú kárí-ayé, tí a sábà máa ń gbékarí àìmọ̀kan nípa àwọn ẹ̀kọ́ àti ète ìsúnniṣe àwọn Ẹlẹ́rìí. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nípa àwọn Kristian ìjímìjí, bẹ́ẹ̀ ni a lè sọ nípa wọn pé: “Nítorí bí ó ṣe ti ìsìn ìyapa yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdìsí i.” (Iṣe 28:22) Nígbà náà kí ni a lè sọ pé ó jẹ́ orísun iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn tí ń yọrísírere? Ó kérétán a ní àwọn kókó abájọ mẹ́ta tí ń fikún ìtẹ̀síwájú wọn—títẹ̀lé ìdarí ẹ̀mí Jehofa, ṣíṣàfarawé àwọn ọ̀nà ìgbà ṣe nǹkan gbígbéṣẹ́ ti Kristi, àti lílo àwọn irin-iṣẹ́ títọ̀nà fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ gbígbéṣẹ́.
Ẹ̀mí Jehofa àti Ìhìnrere
3. Èéṣe tí a kò fi lè ṣògo nípa ohun tí a ti ṣàṣeparí rẹ̀?
3 Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ha ń ṣògo nípa àṣeyọrí wọn, bí ẹni pé ó jẹ́ nítorí àkànṣe agbára èyíkéyìí tí wọ́n lè ní bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, nítorí pé àwọn ọ̀rọ̀ Jesu bá wọn mu: “Nígbà tí ẹ bá ti ṣe gbogbo awọn ohun tí a yàn lé yín lọ́wọ́ tán, ẹ wí pé, ‘Awa jẹ́ ẹrú aláìdára fún ohunkóhun. Ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe.’” Gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristian olùṣèyàsímímọ́, tí a ti baptisi, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fínnú-fíndọ̀ tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun, láìka ohun yòówù kí àwọn àyíká ipò ara-ẹni wọn jẹ́ sí. Fún àwọn kan, ìyẹn túmọ̀sí iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì tàbí gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda ara-ẹni ní àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka àti ní àwọn ilé lílò fún títẹ àwọn ìtẹ̀jáde Kristian. Fún àwọn ẹlòmíràn irú ìmúratán Kristian bẹ́ẹ̀ ń ṣamọ̀nà wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ilé ìsìn, sẹ́nu ìwàásù alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, tàbí sẹ́nu ìwàásù aláàbọ̀ àkókò gẹ́gẹ́ bí akéde ìhìnrere ní àwọn ìjọ àdúgbò. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí ó lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ yangàn nípa ṣíṣe iṣẹ́ wa, “ohun tí ó yẹ kí a ṣe.”—Luku 17:10, NW; 1 Korinti 9:16.
4. Báwo ni a ṣe ṣẹ́pá àtakò kárí-ayé sí iṣẹ́-òjíṣẹ́ àwọn Kristian?
4 Àṣeyọrí èyíkéyìí tí a bá ṣe ni a lè gbà pé ó wá nípasẹ̀ ẹ̀mí Jehofa, tàbí ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀. Ó tọ̀nà gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní àwọn ọjọ́ wòlíì Sekariah láti sọ pé: “Èyí ni ọ̀rọ̀ Oluwa sí Serubbabeli wí pé, Kìí ṣe nípa ipá, kìí ṣe nípa agbára, bíkòṣe nípa Ẹ̀mí mi, ni Oluwa àwọn ọmọ-ogun wí.” Nípa báyìí, a ti ṣẹ́gun àtakò sí iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí kárí-ayé, kìí ṣe nípasẹ̀ ìsapá ènìyàn, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìdarí àti ààbò Jehofa.—Sekariah 4:6.
5. Ipa wo ni Jehofa kó nínú mímú kí ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà tànkálẹ̀?
5 Níti àwọn wọnnì tí wọ́n dáhùnpadà sí ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà, Jesu wí pé: “A sá ti kọ̀ ọ́ nínú àwọn wòlíì pé, A ó sì kọ́ gbogbo wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́, tí a sì ti ọ̀dọ̀ Baba kọ́, òun ni ó ń tọ́ mí wá. . . . Kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ mí wá, bíkòṣe pé a fifún un láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá.” (Johannu 6:45, 65) Jehofa lè mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn-àyà àti iyè-inú, ó sì mọ àwọn wọnnì tí ó ṣeéṣe kí wọ́n dáhùnpadà sí ìfẹ́ rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè má tíì mọ̀ ọ́n. Ó tún ń lo àwọn angẹli rẹ̀ láti darí iṣẹ́-òjíṣẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ yìí. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé nínú ìran, Johannu rí bí àwọn angẹli ṣe ń kópa ó sì kọ̀wé pé: “Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ti òun ti ìhìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀-ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn.”—Ìfihàn 14:6.
Àìní Nípa Tẹ̀mí Ń Jẹ Wọ́n Lọ́kàn
6. Ìṣarasíhùwà ṣíṣekókó wo ni a nílò kí ẹnìkan tó lè dáhùnpadà sí ìhìnrere?
6 Kókó abájọ mìíràn tí ń mú kí Jehofa fún ẹnìkan ní àǹfààní láti tẹ́wọ́gba ìhìnrere ni èyí tí Jesu sọ jáde pé: “Aláyọ̀ ni awọn wọnnì tí àìní wọn nipa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba awọn ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Matteu 5:3, NW) Ẹnìkan tí ó ní ìtẹ́lọ́rùn lójú araarẹ̀ tàbí ẹnìkan tí kò wá òtítọ́ ni àìní tẹ̀mí kì yóò jẹ lọ́kàn. Òun yóò máa ronú kìkì lọ́nà ti ara, tí kìí ṣe tẹ̀mí. Ìtẹ́lọ́rùn àìbìkítà yóò di ìdènà fún un. Nítorí náà, nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn tí a ń bá pàdé bí a ti ń lọ láti ilé-dé-ilé ti ń kọ ìhìn-iṣẹ́ náà, a níláti ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo àwọn ìdí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àwọn ènìyàn lè ní fún ìhùwàpadà wọn.
7. Èéṣe tí àwọn púpọ̀ kò fi dáhùnpadà sí òtítọ́?
7 Ọ̀pọ̀ kọ̀ láti fetísílẹ̀ nítorí pé wọ́n fi agídí rọ̀ mọ́ ìsìn àjogúnbá wọn tí wọn kò sì múratán láti wọnú ìjíròrò. Àwọn mìíràn ni ìsìn kan tí ó bá àkópọ̀ ànímọ́ wọn mu ti fàmọ́ra—àwọn kan fẹ́ ìsìn awo, àwọn mìíràn ń dáhùnpadà sí èrò ìmọ̀lára, síbẹ̀ àwọn mìíràn ń wá àwùjọ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ní ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Ọ̀pọ̀ lónìí ti yan ọ̀nà ìgbésí-ayé kan tí ó forígbárí pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n Ọlọrun. Bóyá wọ́n ń gbé ìgbésí-ayé oníwà pálapàla, èyí tí ó fà á tí wọ́n fi ń sọ pé: “Èmi kò fẹ́ gbọ́.” Síbẹ̀, àwọn mìíràn tí wọ́n lè jẹ́wọ́ pé àwọn ní ìmọ̀-ẹ̀kọ́ tí wọ́n sì jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀, kọ Bibeli tì gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ti rọrùn jù.—1 Korinti 6:9-11; 2 Korinti 4:3, 4.
8. Èéṣe tí ìkọ̀jálẹ̀ kò fi níláti dín ìtara wa kù? (Johannu 15:18-20)
8 Kíkọ̀jálẹ̀ tí ọ̀pọ̀ jùlọ kọ̀ láti gbọ́ ha níláti dín ìgbàgbọ́ àti ìtara wa kù nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà bí? A lè rí ìtùnú fàyọ láti inú ọ̀rọ̀ Paulu sí àwọn ará Romu pé: “Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọrun di asán bí? Kí a má ri: kí Ọlọrun jẹ́ olóòótọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, Ki a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ lè ṣẹ́gun nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”—Romu 3:3, 4.
9, 10. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé a ti ṣẹ́pá àtakò ní àwọn ilẹ̀ púpọ̀?
9 A lè rí ìṣírí gbà láti inú ọ̀pọ̀ àwọn àpẹẹrẹ tí ó wà yíká ayé nípa àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti dàbí ẹni pé wọn kìí dáhùnpadà síbẹ̀, tí wọ́n ti jásí òdìkejì nígbà tí ó yá. Jehofa àti àwọn angẹli ti mọ̀ pé àwọn tí wọ́n lọ́kàn-àyà rere wà láti wá rí—ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbọ́dọ̀ máa ṣeé lemọ́lemọ́ kí wọ́n sì lo ìfaradà nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn orílẹ̀-èdè kan níbi tí ó ti dàbí ẹni pé ìsìn Katoliki ń gbé àwọn ìdènà tí kò ṣeé borí kalẹ̀ ní 50 ọdún sẹ́yìn—Argentina, Brazil, Colombia, Ireland, Italy, Mexico, Portugal, àti Spain. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà kéréníye nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1943, kìkì 126,000 kárí-ayé, tí 72,000 nínú àwọn wọ̀nyí sì wà ní United States. Àìmọ̀kan àti ẹ̀tanú tí ń dojúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí náà dàbí ògiri oníbíríkì tí a kò lè là kọjá. Síbẹ̀, díẹ̀ lára àwọn ìyọrísí ìwàásù tí ó yọrísírere jùlọ lónìí ti jẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí. Ohun kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Kọmunist àtijọ́. Ní 1993 ìrìbọmi 7,402 ní àpéjọpọ̀ ní Kiev, Ukraine, fúnni ní ẹ̀rí èyí.
10 Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí ti lò láti bá àwọn aládùúgbò wọn sọ̀rọ̀ nípa ìhìnrere? Wọ́n ha ti lo ìfi ohun ti ara fanilójúmọ́ra láti jèrè àwọn tí a yí lọ́kàn padà, èyí tí àwọn kan ti fẹ̀sùn rẹ̀ kàn wọ́n? Wọ́n ha ti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn òtòṣì àti púrúǹtù nìkan, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn ti jẹ́wọ́ bí?
Àwọn Ọ̀nà Yíyọrísírere fún Títàtaré Ìhìnrere
11. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Jesu fi lélẹ̀ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀? (Wo Johannu 4:6-26.)
11 Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni wọ́n fi àpẹẹrẹ àwòkọ́ṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń tẹ̀lé lélẹ̀ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn tí wọ́n ń ṣe títí dí òní yìí. Jesu lọ sí ibikíbi tí àwọn ènìyàn bá ti wà, yálà wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí òtòṣì—ó lọ sí àwọn ilé, àwọn ibi tí àwọn ènìyàn wà, ẹ̀bá adágún, ẹ̀bá àwọn òkè-ńlá, àti àwọn sínágọ́gù pàápàá.—Matteu 5:1, 2; 8:14; Marku 1:16; Luku 4:15.
12, 13. (a) Báwo ni Paulu ṣe pèsè àpẹẹrẹ àwòkọ́ṣe fún àwọn Kristian? (b) Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe tẹ̀lé àpẹẹrẹ Paulu?
12 Nípa iṣẹ́-òjíṣẹ́ tirẹ̀, aposteli Paulu lè sọ lọ́nà títọ́ pé: “Ẹ̀yin tìkáraayín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo ti dé Asia, bí èmi ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà, bí mo ti . . . sin Oluwa, bí èmi kò ti fà sẹ́yìn láti sọ ohunkóhun tí ó ṣàǹfààní fún yín, àti láti máa kọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.”—Iṣe 20:18-20.
13 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a mọ̀ jákèjádò orí ilẹ̀-ayé fún títẹ̀lé àpẹẹrẹ ti àwọn aposteli, iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé. Dípò pípa àfiyèsí pọ̀ sórí iṣẹ́-òjíṣẹ́ orí tẹlifíṣọ̀n gbígbówólórí tí wọn kò darí rẹ̀ sí ẹnìkan pàtó, tí ó sì jẹ́ oréfèé, àwọn Ẹlẹ́rìí ń tọ àwọn ènìyàn, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, lọ ní ojúkorojú. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti jùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nípa Ọlọrun àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀.b Wọn kìí gbìyànjú láti sọ àwọn ènìyàn di Kristian onírẹsì, ní fífi àwọn nǹkan ti ara fúnni. Fún àwọn wọnnì tí wọ́n múratán láti báni ronú pọ̀, wọ́n ń ṣàlàyé pé ojútùú kanṣoṣo tí ó wà fún àwọn ìṣòro aráyé ní ìṣàkóso nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọrun, èyí tí yóò yí àwọn ipò lórí ilẹ̀-ayé wa padà sí èyí tí ó dára jù.—Isaiah 65:17, 21-25; 2 Peteru 3:13; Ìfihàn 21:1-4.
14. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣe fi ìpìlẹ̀ lílágbára lélẹ̀? (b) Kí ni a kọ́ láti inú ìrírí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Japan?
14 Láti ṣàṣeparí iṣẹ́ náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó, àwọn míṣọ́nnárì àti aṣáájú-ọ̀nà ti lànàsílẹ̀ fún ìtẹ̀síwájú ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò sì ti mú ipò iwájú lẹ́yìn náà. Nípa báyìí, kò béèrè fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Ẹlẹ́rìí àjòjì láti máa bá ìwàásù náà lọ àti láti mú kí ó wà létòlétò. Àpẹẹrẹ àrà-ọ̀tọ̀ kan ni ti Japan jẹ́. Nígbà náà lọ́hùn-ún ní apá ìparí àwọn ọdún 1940, kìkì àwọn ará Australasia àti àwọn míṣọ́nnárì ilẹ̀ Britain ni wọ́n lọ síbẹ̀, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ èdè náà, wọ́n mú araawọn bá àwọn ipò tí ó dàbí ti àtijọ́ ti ẹ̀yìn sànmánì ogun yẹn mu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí láti ilé-dé-ilé. Nígbà Ogún Àgbáyé II, àwọn Ẹlẹ́rìí náà ni a ti fòfindè tí a sì ṣenúnibíni sí ní Japan. Nítorí náà àwọn míṣọ́nnárì dé láti rí ìwọ̀nba kéréje àwọn Ẹlẹ́rìí ògbóṣáṣá ará Japan. Ṣùgbọ́n lónìí iye wọn ti ga ju 187,000 ní àwọn ìjọ tí ó ju 3,000 lọ! Kí ni àṣírí àṣeyọrí wọn ní àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀? Míṣọ́nnárì kan tí ọdún iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ níbẹ̀ ti lé ní ọdún 25 wí pé: “Ó ṣe pàtàkì jùlọ láti kọ́ láti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀pọ̀. Nípa mímọ èdè wọn, ó ṣeéṣe fún wa láti fí ara wa sí ipò wọn, láti lóye kí a sì mọrírì ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn. A níláti fihàn pé a fẹ́ràn àwọn ará Japan. A fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn gbìyànjú láti dí apákan àwùjọ ènìyàn náà, àmọ́ ṣáá, ìyẹn jẹ́ láìfi àwọn ìlànà ìwàrere Kristian wa bánidọ́rẹ̀ẹ́.”
Ìwà Kristian Pẹ̀lú Jẹ́ Ẹ̀rí
15. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe fi ìwà Kristian hàn?
15 Bí ó ti wù kí ó rí, kìí ṣe ìhìn-iṣẹ́ Bibeli nìkan ni àwọn ènìyàn dáhùnpadà sí. Wọ́n tún ti rí bí a ṣe ń fi ìsìn Kristian ṣèwàhù. Wọ́n ti ṣàkíyèsí ìfẹ́, ìṣọ̀kan, àti ìrẹ́pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí àní lábẹ́ àwọn ipò ọ̀ràn tí ń dánniwò jùlọ pàápàá, bíi ogun abẹ́lé, ìjà láàárín àwọn ẹ̀yà, àti ìbáṣọ̀tá ẹ̀yà ìran. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ti pa ìdúró ṣíṣe kedere níti àìdásí tọ̀tún-tòsì Kristian mọ́ nínú gbogbo ìforígbárí wọ́n sì ti mú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu ṣẹ: “Òfin titun kan ni mo fifún yín, Kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ ọmọnìkejì yín; gẹ́gẹ́ bí èmi ti fẹ́ràn yín, kí ẹ̀yin kí ó sì lè fẹ́ràn ọmọnìkejì yín. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin íṣe, nígbà tí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ sí ọmọnìkejì yín.”—Johannu 13:34, 35.
16. Ìrírí wo ni ó ṣàkàwé ìfẹ́ Kristian gbígbéṣẹ́?
16 Ìfẹ́ aládùúgbò ni a ṣàkàwé rẹ̀ nínú ọ̀ràn ti ọkùnrin àgbàlagbà kan tí ó kọ̀wé sí ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn àdúgbò kan nípa “Ọ̀gbẹ́ni àti Ìyáàfin Adáraníwà.” Ó ṣàlàyé pé àwọn aládùúgbò òun ti ṣenúrere sí òun nígbà tí aya òun ń kú lọ́. Ó kọ̀wé pé, “Láti ìgbà tí ó ti jáláìsí . . . wọ́n ti lọ wà jù. Láti ìgbà náà wá wọ́n ti ‘sọ’ mi ‘di òbí wọn’ . . . , ní ṣíṣe onírúurú àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro ẹni ọdún 74 tí a ti fẹ̀yìn rẹ̀ tì lẹ́nu iṣẹ́. Ohun tí ó túbọ̀ mú kí gbogbo èyí jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ ni pé aláwọ̀ dúdú ni wọ́n, èmi sì jẹ́ aláwọ̀ funfun. Wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa, èmi sì jẹ́ ẹni tí ó ti fi ìsìn Katoliki sílẹ̀.”
17. Ipa-ọ̀nà wo ni a níláti yẹra fún?
17 Ìrírí yìí ṣàkàwé rẹ̀ pé a lè jẹ́rìí fúnni ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, títíkan ìwà wa ojoojúmọ́. Ní tòótọ́, bíkòṣe pé ìwà wa bá dàbí ti Kristi, iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa yóò dàbí ti àwọn Farisi, láìní ìyọrísí kankan. Àwa kò fẹ́ láti dàbí àwọn wọnnì tí Jesu ṣàpèjúwe pé: “Ohunkóhun gbogbo tí wọ́n bá wí pé kí ẹ kíyèsí, ẹ máa kíyèsí wọn kí ẹ sì máa ṣe wọ́n; ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn: nítorí tí wọn a máa wí, ṣùgbọ́n wọn kìí ṣe.”—Matteu 22:37-39; 23:3.
Ẹgbẹ́ Ẹrú náà Ń Pèsè Àwọn Irin-Iṣẹ́ Yíyẹ
18. Báwo ni ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣe mú wa gbaradì láti ran àwọn olótìítọ́ ọkàn lọ́wọ́?
18 Kókó abájọ ṣíṣekókó mìíràn nínú wíwàásù ìhìnrere fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti jẹ́ ìwàlárọ̀ọ́wọ́tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí a mújáde láti ọwọ́ Watch Tower Bible and Tract Society. A ní àwọn ìwé, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé àṣàrò kúkúrú, àti àwọn ìwé-ìròyìn tí wọ́n lè tẹ́ èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo olùfòtítọ́-inú béèrè ọ̀rọ̀ lọ́rùn. Bí a bá bá Musulumi, onísìn Hindu, Buddha, Tao, tàbí Ju kan pàdé, a lè lo ìwé náà Mankind’s Search for God tàbí ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé kékeré láti bẹ̀rẹ̀ ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ àti bóyá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan. Bí onígbàgbọ́ ẹfolúṣọ̀n kan bá béèrè nípa ìṣẹ̀dá, a lè lo ìwé náà Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? Bí ọ̀dọ́ kan bá béèrè pé, ‘Kí ni ète ìgbésí-ayé?’ a lè darí rẹ̀ sínú ìwé náà Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ. Bí àwọn ìṣòro ti ara-ẹni—ìsoríkọ́, àárẹ̀, ìfipábánilòpọ̀, ìkọ̀sílẹ̀ bá nípa lórí ẹnìkan lọ́nà jíjinlẹ̀—a ní àwọn ìwé ìròyìn tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ lórí irú àwọn kókó ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́. Nítòótọ́, ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ tí Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé yóò máa pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu’ ń mú ipa-iṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ.—Matteu 24:45-47, NW.
19, 20. Báwo ni iṣẹ́ Ìjọba náà ṣe túbọ̀ yárakánkán síi ní Albania?
19 Ṣùgbọ́n láti dé ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, ó ti pọndandan láti pèsè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ní oríṣiríṣi èdè. Báwo ni ó ti ṣeéṣe láti túmọ̀ Bibeli àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a gbékarí Ìwé Mímọ́ sí èdè tí ó ju 200 lọ? Àgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ kan ní ṣókí, Albania, ṣàkàwé bí ó ti ṣeéṣe fún ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà láti gbé ìhìnrere náà lárugẹ lójú àwọn ìṣòro ńlá àti láìsí Pentekosti òde-òní kan láti mú kí èdè púpọ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó lójú-ẹsẹ̀.—Iṣe 2:1-11.
20 Ní ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, Albania ni a ṣì ń wò gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kanṣoṣo náà tí ó jẹ́ oníjọba Kọmunist aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun. Ìwé ìròyìn National Geographic sọ ní 1980 pé: “Albania ka [ìsìn] léèwọ̀, ní kíkéde araarẹ̀ ní 1967 gẹ́gẹ́ bí ‘orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ lágbàáyé tí kò gbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun.’ . . . Ohun kanṣoṣo tí ìran Albania titun mọ ni àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun.” Nísinsìnyí tí ìjọba Kọmunist ti jórẹ̀yìn, àwọn ará Albania tí wọ́n mọyì àwọn àìní wọn nípa tẹ̀mí ń dáhùnpadà sí ìwàásù tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe. Àwùjọ kékeré ti àwọn atúmọ̀ èdè tí ó ní nínú àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ní ìmọ̀ èdè Italian àti Gẹ̀ẹ́sì ni a kójọ ní Tiranë ní 1992. Àwọn arákùnrin tí wọ́n tóótun tí wọ́n ń ṣèbẹ̀wò láti àwọn ilẹ̀ mìíràn kọ́ wọn bí a ti ń lo àwọn kọ̀m̀pútà kékeré láti tẹ àwọn ọ̀rọ̀ ní èdè Albania. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú títúmọ̀ àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà. Bí wọ́n ti ń jèrè ìrírí, wọ́n ṣiṣẹ́ lórí títúmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde Bibeli ṣíṣeyebíye mìíràn. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí àwọn ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí bíi 200 ni wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè kékeré yẹn (iye àwọn olùgbé jẹ́ 3,262,000), àwọn 1,984 ni wọ́n sì pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí ní 1994.
Gbogbo Wa Ní Ẹrù-Iṣẹ́
21. Irú sáà wo ni a ń gbé inú rẹ̀?
21 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé ti ń dé òtéńté. Pẹ̀lú ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá, ìpànìyàn àti ìfipábánilòpọ̀ nínú àwọn ogun àdúgbò, ìfọwọ́dẹngbẹrẹ mú ìwàrere àti àwọn ìṣùpọ̀ èso rẹ̀ ti àwọn òkùnrùn tí ìbálòpọ̀ takọtabo ń ta látaré, àìlọ́wọ̀ fún ọlá-àṣẹ tí ó bófinmu tí ń gbèrú síi, ó dàbí ẹni pé ayé ń di onírúgúdù; aláìṣeéṣàkóso. A wà nínú sáà kan tí ó dọ́gba pẹ̀lú àwọn àkókò tí ó wà ṣáájú Ìkún-omi tí a ṣàpèjúwe nínú Genesisi pé: “Ọlọrun sì rí i pé ìwà búburú ènìyàn di pípọ̀ ní ayé, àti pé gbogbo ìrò ọkàn rẹ̀ kìkì ibi ni lójoojúmọ́. Inú OLUWA sì bàjẹ́ nítorí tí ó dá ènìyàn sí ayé, ó sì dùn ún dé ọkàn rẹ̀.”—Genesisi 6:5, 6; Matteu 24:37-39.
22. Ẹrù-iṣẹ́ Kristian wo ni gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní?
22 Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ Noa, Jehofa yóò gbé ìgbésẹ̀. Ṣùgbọ́n nínú ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ rẹ̀, ó fẹ́ kí a kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere àti ìhìn-iṣẹ́ ìkìlọ̀ fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. (Marku 13:10) Ní ọ̀nà yìí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ẹrù-iṣẹ́ kan—láti wá àwọn wọnnì tí wọ́n yẹ fún àlàáfíà Ọlọrun àti láti kọ́ wọn ní àwọn ọ̀nà àlàáfíà rẹ̀. Láìpẹ́, ní àkókò yíyẹ lójú Ọlọrun, iṣẹ́ ìwàásù tí a fi ránwa náà ní a óò parí lọ́nà yíyọrísírere. “Nígbà náà ni opin yóò sì dé.”—Matteu 10:12, 13; 24:14; 28:19, 20.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú síi lórí àwọn Kèfèrí, wo àkòrí náà “Nations” (Awọn Orílẹ́-Èdè) nínú Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ II, ojú-ìwé 472 sí 474, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b Fún àwọn ìdámọ̀ràn gbígbéṣẹ́ lórí iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian, wo Ilé-Ìṣọ́nà ti February 15, 1985, ojú-ìwé 15, “Bi A Ṣe Le Di Awọn Ojiṣẹ tí Ó Gbeṣẹ,” àti ojú-ìwé 21 “Iṣẹ-ojiṣẹ tí Ó Gbeṣẹ Nṣamọna si Awọn Ọmọ-ẹhin Pupọ si I.”
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Àṣeyọrísírere wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí òde ìwòyí ní nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn?
◻ Èéṣe tí ọ̀pọ̀ fi kọ ìhìn-iṣẹ́ Kristian?
◻ Ọ̀nà ìgbà wàásù bíi ti àwọn aposteli wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí ń lò?
◻ Àwọn irin-iṣẹ́ wo ni a ní fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ gbígbéṣẹ́?
◻ Kí ni gbogbo wa gbọ́dọ̀ ṣe ní ìbámu pẹ̀lú Marku 13:10?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
ORÍLẸ̀-ÈDÈ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ TÍ WỌ́N GBÓṢÁṢÁ NÍ 1943 NÍ 1993
Argentina 374 102,043
Brazil 430 366,297
Chile 72 44,668
Colombia ?? 60,854
France Ogun Àgbáyé II—kò sí àkọsílẹ̀ 122,254
Ireland 150? 4,224
Italy Ogun Àgbáyé II—kò sí àkọsílẹ̀ 201,440
Mexico 1,565 380,201
Peru Kò sí àkọsílẹ̀ ìgbòkègbodò 45,363
Philippines Ogun Àgbáyé II—kò sí àkọsílẹ̀ 116,576
Poland Ogun Àgbáyé II—kò sí àkọsílẹ̀ 113,551
Portugal Kò sí àkọsílẹ̀ ìgbòkègbodò 41,842
Spain Kò sí àkọsílẹ̀ ìgbòkègbodò 97,595
Uruguay 22 9,144
Venezuela Kò sí àkọsílẹ̀ ìgbòkègbodò 64,081
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń pọ̀ síi ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè onísìn Katoliki, bíi Spain
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fi ìtara ṣiṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé