Gbádùn Ayé Rẹ
BABA wà lórí ibùsùn, nínú ìyẹ̀wù, àrùn jẹjẹrẹ ń pá a kú lọ. Ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní ṣọ́ọ̀bù, ó ń tọ́jú àwọn irinṣẹ́ baba rẹ̀. Bí ó ti mú irinṣẹ́ náà lọ́wọ́, ó ronú nípa àrà tí baba rẹ̀ ti fi wọ́n dá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ ilé wọn ní ṣọ́ọ̀bù náà wà, ó mọ̀ pé baba òun kò tún lè wọbẹ̀ mọ́ láé, kò ní lo irinṣẹ́ tí ó ti ń lò lọ́nà jíjáfáfá mọ́ láé. Ìyẹn ti di ohun àtijọ́.
Ọmọ náà ronú lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ inú Oníwàásù 9:10, tí ó sọ pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [isà òkú], ibi tí ìwọ ń lọ.” Ó mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí bí ẹní mowó. Ó ti lò ó lọ́pọ̀ ìgbà nígbà tí ó ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́ Bíbélì pé, ikú jẹ́ ipò àìmọ-nǹkan-kan. Wàyí o, kókó ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì gbún ọkàn rẹ̀ ní kẹ́ṣẹ́—ó yẹ kí a lo ìgbésí ayé wa dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, kí a sì gbádùn ayé wa nígbà tí àǹfààní rẹ̀ ṣì wà, nítorí ọjọ́ ń bọ̀ tí a kò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Gbádùn Ìgbésí Ayé
Jálẹ̀ ìwé Oníwàásù, Sólómọ́nì, ọlọ́gbọ́n Ọba gba àwọn òǹkàwé rẹ̀ níyànjú láti gbádùn ayé wọn. Bí àpẹẹrẹ, orí 3 sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ pé kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí [ènìyàn] máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ìgbésí ayé [wọn]; pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 3:12, 13.
Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti tún èrò yìí sọ pé: “Wò ó! Ohun tí ó dára jù lọ tí èmi alára ti rí, èyí tí ó ṣe rèterète, ni pé kí ènìyàn máa jẹ kí ó sì máa mu kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀, èyí tí ó fi ń ṣiṣẹ́ kárakára lábẹ́ oòrùn ní iye ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ fi fún un, nítorí ìyẹn ni ìpín rẹ̀.”—Oníwàásù 5:18.
Bákan náà, ó rọ àwọn ọ̀dọ́ pé: “Máa yọ̀, ọ̀dọ́kùnrin, ní ìgbà èwe rẹ, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ọ́ ní ire ní àwọn ọjọ́ ìgbà ọ̀dọ́kùnrin rẹ [tàbí ọ̀dọ́bìnrin rẹ], kí o sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà ọkàn-àyà rẹ àti nínú àwọn ohun tí ojú rẹ bá rí.” (Oníwàásù 11:9a) Ó mà dára láti gbádùn okun àti agbára ìgbà ọ̀dọ́ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ o!—Òwe 20:29.
“Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ”
Àmọ́ ṣá o, Sólómọ́nì kò ní in lọ́kàn pé ó bọ́gbọ́n mu láti máa lépa ohun gbogbo tí ó bá sáà ti wù wá. (Fi wé 1 Jòhánù 2:16.) Èyí ṣe kedere láti inú ohun tí ó kọ tẹ̀ lé e pé: “Ṣùgbọ́n mọ̀ pé ní tìtorí gbogbo ìwọ̀nyí [ìlépa tí ó lè tẹ́ ìfẹ́ rẹ lọ́rùn] ni Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe mú ọ wá sínú ìdájọ́.” (Oníwàásù 11:9b) Bí ó ti wù kí a kéré tó tàbí kí a dàgbà tó, ó yẹ kí a rántí pé Ọlọ́run ń ṣàkíyèsí ohun tí a ń fi ìgbésí ayé wa ṣe, yóò sì ṣèdájọ́ wa bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ gbáà tó láti rò pé a lè gbé ìgbésí ayé anìkànjọpọ́n, kí a sì máa sún fífọkànsin Ọlọ́run síwájú títí di ìgbà tí a bá darúgbó! Ìgbàkígbà ni ìwàláàyè wa lè dópin. Ká tilẹ̀ wá ní kò dópin, kò rọrùn rárá láti sin Ọlọ́run nígbà tí a ti darúgbó. Mímọ̀ tí Sólómọ́nì mọ òtítọ́ yìí mú kí ó kọ̀wé pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin, kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé, tàbí tí àwọn ọdún náà yóò dé nígbà tí ìwọ yóò wí pé: ‘Èmi kò ní inú dídùn sí wọn.’”—Oníwàásù 12:1.
Ọjọ́ ogbó máa ń nípa lórí ẹni. Sólómọ́nì lo àkàwé láti ṣàpèjúwe ipa tí ọjọ́ ogbó ń ní lórí ẹni. Ọwọ́ àti apá á máa gbọ̀n, ẹsẹ̀ á ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, ìwọ̀nba eyín díẹ̀ ni yóò kù sẹ́nu. Gbogbo irun á ti funfun, á sì ti re jẹ. Oorun kò ní wọra mọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìró ẹyẹ lásán á fi jíni kalẹ̀. Àwọn ẹ̀yà ìmọ̀lára—ìríran, ìgbọ́ròó, ìfọwọ́bà, ìgbóòórùn, àti ìtọ́wò—á ti kú. Ara tí ó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ á bẹ̀rẹ̀ sí múni bẹ̀rù ṣíṣubú, “ìpayà” àwọn ohun mìíràn tí ó lè ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà tí gbogbo ayé ń gbà á sì múni. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ikú á mú olúwarẹ̀ lọ.—Oníwàásù 12:2-7.
Àjálù ńláǹlà ni ọjọ́ ogbó jẹ́, pàápàá jù lọ fún àwọn tí kò ‘rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá’ nígbà èwe wọn. Nítorí fífi àkókò rẹ̀ ṣòfò, irú ẹni bẹ́ẹ̀ “kò ní inú dídùn” nínú ọjọ́ ogbó. Ìgbésí ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lè tún fi kún àwọn ìṣòro àti làásìgbò ọjọ́ ogbó. (Òwe 5:3-11) Ó ṣeni láàánú pé, nígbà tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá wo ọjọ́ iwájú, kì í sí ìrètí ọjọ́ ọ̀la kankan fún wọn ju sàréè lọ.
Yíyọ̀ ní Ọjọ́ Ogbó
Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn àgbàlagbà kò lè gbádùn ìgbésí ayé wọn. Nínú Bíbélì, “ọjọ́ gígùn àti ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè” jẹ́ àbájáde ìbùkún Ọlọ́run. (Òwe 3:1, 2) Jèhófà sọ fún Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Ní tìrẹ, . . . a ó sin ọ́ ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:15) Láìka àìfararọ tí ọjọ́ ogbó ń mú wá sí, Ábúráhámù ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀-ọkàn ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí ó bojú wẹ̀yìn wo ìgbésí ayé tí ó fi fọkàn sin Jèhófà. Ó tún ń fi ojú ìgbàgbọ́ wo “ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́,” èyíinì ni Ìjọba Ọlọ́run. (Hébérù 11:10) Lẹ́yìn náà, ó kú, “ó darúgbó, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn.”—Jẹ́nẹ́sísì 25:8.
Nítorí náà, Sólómọ́nì rọni pé: “Bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ wà láàyè fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí ó máa fi gbogbo rẹ̀ yọ̀.” (Oníwàásù 11:8) Yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, ayọ̀ tòótọ́ ní í ṣe pẹ̀lú ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọ́run.
Bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà nínú ṣọ́ọ̀bù náà ti fi èyí tí ó kẹ́yìn nínú àwọn irinṣẹ́ baba rẹ̀ tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ lélẹ̀, ó ronú nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ó ronú nípa gbogbo àwọn ẹni tí ó mọ̀ tí àwọn náà gbìyànjú láti gbádùn ayé wọn ṣùgbọ́n tí wọn kò láyọ̀ nítorí pé wọn kò ní ìbátan pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn. Ẹ wo bí ó ti bá a mu tó pé lẹ́yìn fífúnni ní ìṣírí láti yọ̀ nígbà ọ̀dọ́ ẹni, Sólómọ́nì ṣàkópọ̀ ọ̀ràn náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn”!—Oníwàásù 12:13.