ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 10/15 ojú ìwé 30-31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Kí Nìdí Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fí Ṣe Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ǹjẹ́ Gbogbo Àpèjẹ Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Àwọn Ayẹyẹ Tí Inú Ọlọ́run Ò Dùn Sí
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 10/15 ojú ìwé 30-31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ọ̀pọ̀ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣàyájọ́ ìgbéyàwó wọn. Ọjọ́ ìbí jẹ́ àyájọ́ ọjọ́ tí wọ́n bí ọ. Nítorí náà, èé ṣe tí a fi ń ṣàyájọ́ ìgbéyàwó, tí a kì í sì í ṣe àyájọ́ ọjọ́ ìbí?

Ká sọ tòótọ́, kò sí ìdí tí Kristẹni kan fi ní láti ṣayẹyẹ èyíkéyìí nínú wọn. Síbẹ̀, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé bákan náà ni ìjẹ́pàtàkì méjèèjì rí tàbí pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ wo àyájọ́ ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń wo àyẹyẹ ọjọ́ ìbí.

Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ, a lè sọ pé àyájọ́ ni àwọn méjèèjì nítorí pé “àyájọ́” jẹ́ ‘ọjọ́ kan tí ń fara hàn lọ́dọọdún, tí ń sàmì sí ìṣẹ̀lẹ̀ kan.’ Ó lè jẹ́ àyájọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí—ọjọ́ tí ìjàǹbá ọkọ̀ ṣẹlẹ̀ sí ọ, ọjọ́ tí o rí ìpàdé oòrùn òun òṣùpá, ọjọ́ tí ìwọ àti ìdílé rẹ lọ lúwẹ̀ẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni kì í sọ gbogbo “àyájọ́” di ọjọ́ pàtàkì kan tàbí kí wọ́n ṣayẹyẹ wọn. Ó yẹ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn apá ìṣẹ̀lẹ̀ kan kí a sì pinnu ohun tí a rò pé ó tọ́.

Fún àpẹẹrẹ, Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítọ̀ọ́ni ní pàtó pé lọ́dọọdún ni kí wọ́n máa ṣayẹyẹ ọjọ́ tí áńgẹ́lì rẹ̀ ré ilé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọjá ní Íjíbítì àti jíjáde tí àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde lọ ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa. (Ẹ́kísódù 12:14) Nígbà tí àwọn Júù, títí kan Jésù, wá ń ṣèrántí àyájọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn lẹ́yìn náà, wọ́n ń ṣègbọràn sí ìtọ́ni Ọlọ́run ni, wọn kò sì ṣe é gẹ́gẹ́ bí àríyá tàbí nípa fífúnni lẹ́bùn. Àwọn Júù tún wo títún tẹ́ńpìlì yà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àyájọ́ pàtàkì kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣe ayẹyẹ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí, Jòhánù 10:22, 23 fi hàn pé Jésù kò ta kò ó. Níkẹyìn, àwọn Kristẹni ní ìpàdé pàtàkì kan tí wọ́n máa ń ṣe ní àyájọ́ ikú Jésù. Dájúdájú, wọ́n ń ṣe ìyẹn ní ìgbọràn sí àṣẹ tí ó ṣe kedere tí wọ́n rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni.—Lúùkù 22:19-20.

Àyájọ́ ìgbéyàwó ńkọ́? Ní àwọn ilẹ̀ kan, ó wọ́pọ̀ fún ọkọ àti aya láti pa àyájọ́ ìgbà tí wọ́n di tọkọtaya mọ́, ètò kan tí Ọlọ́run pilẹ̀ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24; Mátíù 19:4-6) Dájúdájú, Bíbélì kò fojú burúkú wo ìgbéyàwó. Jésù lọ sí ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó, ó sì kópa nínú mímú kí àkókò ayẹyẹ náà gbádùn mọ́ àwọn ènìyàn.—Jòhánù 2:1-11.

Nítorí náà, kò ní ṣàjèjì pé tọkọtaya kan lè yàn láti lo àkókò ní àyájọ́ ìgbéyàwó wọn láti ronú lórí ìdùnnú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kí wọ́n sì fún ìpinnu wọn láti ṣiṣẹ́ fún àṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya lókun. Bóyá ní kọ̀rọ̀ iyàrá wọn ni wọ́n ti fún àkókò aláyọ̀ yí ní àfiyèsí, gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya, tàbí bóyá àwọn ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mélòó kan wà pẹ̀lú wọn, ìpinnu tiwọn nìyẹn. A kò gbọ́dọ̀ sọ àkókò náà di àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà rẹpẹtẹ. Ní àkókò ayẹyẹ yìí, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ìlànà tí wọ́n ń fi sílò ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé wọ́n tọ́ wọn sọ́nà. Nítorí náà, bóyá a pa àyájọ́ ìgbéyàwó mọ́ tàbí a kò pa á mọ́ jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni.—Róòmù 13:13, 14.

Ṣùgbọ́n, kíkíyèsí ọjọ́ ìbí lọ́nà pàtàkì ńkọ́? Ǹjẹ́ a ní irú àyájọ́ bẹ́ẹ̀ tí a lè tọ́ka sí nínú Bíbélì?

Ó dára, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ti mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà, máa ń kíyè sí ọjọ́ ìbí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí. Ọ̀pọ̀ lára wọn tọ́jú ìwé kékeré tí a ń pè ní Daily Heavenly Manna. Èyí ní ẹsẹ Bíbélì kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni sì máa ń fi fọ́tò pélébé kan sí àwọn ojú ìwé tí ó ní ọjọ́ ìbí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹlẹgbẹ́ wọn nínú. Síwájú sí i, Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) February 15, 1909, ròyìn pé ní àpéjọpọ̀ kan ní Jacksonville, Florida, U.S.A., a ṣètò àwọn tí wọ́n bá Arákùnrin Russell, ààrẹ Society nígbà náà, kẹ́sẹ̀ rìn lọ sórí pèpéle. Èé ṣe? Wọ́n ṣe ohun ìyàlẹ́nu fún un nípa fífún un ní àpótí èso àjàrà, ọ̀pẹ̀ òyìnbó, àti ọsàn mélòó kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọjọ́ ìbí rẹ̀. Ìyẹn jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Láti wo ipò tí ó yí ọ̀ràn náà ká, rántí pé ní àkókò yẹn, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú máa ń ṣayẹyẹ December 25 gẹ́gẹ́ bí àyẹyẹ ìbí Jésù, tàbí ọjọ́ ìbí rẹ̀. Ó tilẹ̀ tún jẹ́ àṣà wọn láti máa jẹ oúnjẹ Kérésìmesì ní Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn pàápàá.

Àmọ́ ṣá o, ní ọ̀nà púpọ̀ ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run ti ń dàgbà nípa tẹ̀mí láti ìgbà náà wá. Ní àwọn ọdún 1920, ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tí ń pọ̀ sí i jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí:

Kì í ṣe December 25, ọjọ́ kan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn kèfèrí, ni a bí Jésù. Bíbélì pàṣẹ pé kí a ṣèrántí ọjọ́ ikú Jésù, kì í ṣe àyájọ́ ọjọ́ ìbí rẹ̀ tàbí ti ẹnikẹ́ni mìíràn. Ṣíṣèrántí bẹ́ẹ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú Oníwàásù 7:1, àti òtítọ́ náà pé ìgbẹ̀yìn olóòótọ́ ènìyàn kan ṣe pàtàkì ju ọjọ́ tí a bí i lọ. Bíbélì kò ṣàkọsílẹ̀ olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ èyíkéyìí tí ó ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀. Ó ṣàkọsílẹ̀ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àwọn kèfèrí, ní síso àkókò wọ̀nyí pọ̀ mọ́ ìwà òǹrorò. Ẹ jẹ́ kí a ka àlàyé tí ó rọ̀ mọ́ àwọn ayẹyẹ ọjọ́ ìbí wọ̀nyẹn.

Àkọ́kọ́ ni ọjọ́ ìbí Fáráò ní ìgbà ayé Jósẹ́fù. (Jẹ́nẹ́sísì 40:20-23) Lójú ìwòye èyí, àpilẹ̀kọ tí ń sọ nípa àwọn ọjọ́ ìbí nínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia of Religion and Ethics tí Hastings ṣe bẹ̀rẹ̀ ní sísọ̀ pé: “Ọ̀nà tí a ń gbà ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí kan ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣírò àkókò, abẹ́ ipò tí a ti ṣe é, ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìlànà ìsìn ìpilẹ̀ṣẹ̀ kan.” Lẹ́yìn náà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà fa ọ̀rọ̀ tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun ìṣẹ̀ǹbáyé Íjíbítì náà, Alàgbà J. Gardner Wilkinson, kọ yọ pé: “Olúkúlùkù ará Íjíbítì ló ka ọjọ́, àti wákàtí tí a bí i pàápàá, sí pàtàkì gan-an; ó ṣì ṣeé ṣe pé, inú olúkúlùkù máa ń dùn gan-an lọ́jọ́ tó ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀, tí ó ń kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ káàbọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ńlá láàárín àwùjọ, pẹ̀lú oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn tí ó pọ̀ yamùrá lórí tábìlì, bí wọ́n ṣe ń ṣe ní Páṣíà.”

Ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mìíràn tí a mẹ́nu kan nínú Bíbélì ni ti Hẹ́rọ́dù, níbi tí wọ́n ti gé orí Jòhánù Oníbatisí. (Mátíù 14:6-10) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia (ẹ̀dà ti 1979) ṣe àlàyé pé: “Àwọn Hélénì àtètèkọ́ṣe ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àwọn òrìṣà àti àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn. Lédè Gí[ríì]kì genéthlia ni àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí túmọ̀ sí, nígbà tí genésia sì túmọ̀ sí ayẹyẹ ìrántí ọjọ́ ìbí èèyàn pàtàkì kan tó ti kú. Nínú 2 Macc[abees] 6:7, a rí ìtọ́ka sí genéthlia olóṣooṣù ti Antiochus Kẹrin, tí a ti ń fipá mú àwọn Júù láti ‘jẹ lára àwọn ohun ìrúbọ.’ . . . Nígbà tí Hẹ́rọ́dù ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀, ó ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àwọn Héléní ni; kò sí ẹ̀rí pé a ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ní Ísírẹ́lì kí àwọn Hélénì tó dé.”

Ní tòótọ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ òde òní kì í jẹ́ kí orírun àti àwọn ohun tí ó lè so pọ̀ mọ́ ìsìn ìjímìjí nínú àṣà èyíkéyìí, tàbí gbogbo àṣà, gbà wọ́n lọ́kàn, àmọ́ wọn kì í dágunlá sí àwọn àmì tí ó bá jẹ mọ́ ọn tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí kan pé ìwọ̀nba àwọn ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tí a mẹ́nu kan nínú Bíbélì jẹ́ ti àwọn abọ̀rìṣà, ó sì so pọ̀ mọ́ ìwà òǹrorò. Nítorí náà, Ìwé Mímọ́ kò sọ ohun tí ó dára nípa ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, èyí jẹ́ òtítọ́ kan tí àwọn Kristẹni tòótọ́ kò fojú kéré.

Lójú ìwòye èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni pátápátá ni bí àwọn Kristẹni bá yàn láti ṣe àyájọ́ ìgbéyàwó wọn, àwọn ìdí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà tí àwọn Kristẹni tí wọ́n dàgbà dénú fi ń ta kété sí ṣíṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́