Wíwu Jèhófà Ni Olórí Àníyàn Mi
GẸ́GẸ́ BÍ THEODOROS NEROS ṢE SỌ Ọ́
Ilẹ̀kùn galagálá tí mo wà ṣí gbayawu, sójà kan sì fọhùn pé: “Ta ní ń jẹ́ Neros?” Nígbà tì mo sọ pé èmi ni, ó pàṣẹ pé: “Dìde. A fẹ́ lọ pa ọ́.” Àgọ́ àwọn ológun ni ìyẹn ti ṣẹlẹ̀ ní Kọ́ríńtì, ní ilẹ̀ Gíríìsì, ní ọdún 1952. Èé ṣe tí ẹ̀mí mi fi ń mì báyìí? Kí n tó ṣàlàyé, ẹ jẹ́ kí ń sọ díẹ̀ fún yín nípa irú ẹni tí mo jẹ́.
ÀWỌN Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (gẹ́gẹ́ bí a ti mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì nígbà yẹn) kàn sí baba mi ní nǹkan bí ọdún 1925. Kò sì pẹ́ tí òun náà fi di ara wọn, tí ó sì gbin ìgbàgbọ́ rẹ̀ sínú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àti àwọn àbúrò rẹ̀ tí gbogbo wọn jẹ́ mẹ́jọ, gbogbo wọn sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì. Àwọn òbí rẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, ó ṣègbéyàwó, a sì bí mi ní ọdún 1929 ní Agrinio, Gíríìsì.
Ọdún burúkú gbáà mà ni àwọn ọdún wọ̀nyẹn jẹ́ fún Gíríìsì o! Àkọ́kọ́ ni ìṣàkóso òǹrorò ti bóofẹ́ bóokọ̀ lábẹ́ Ọ̀gágun Metaxas. Lẹ́yìn náà, ní 1939, Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí ìjọba Nazi fi gba orílẹ̀-èdè náà. Àrùn àti ebi sì gbalé gbòde. Ọmọlanke kéékèèké ni wọ́n fi ń ru àwọn okú tí ó ti wu. Bìlísì tí ó wà nínú ayé nígbà náà kò fara sin rárá, bí nínílò Ìjọba Ọlọ́run nígbà náà kò ti fara sin.
Ìgbésí Ayé Iṣẹ́ Ìsìn Àfọkànṣe
Ní August 20, 1942, bí àwa díẹ̀ tí pé jọ fún ìpàdé lẹ́yìn odi ìlú Tẹsalóníkà, alábòójútó olùṣalága wa tọ́ka sí àwọn ọkọ̀ ogun òfuurufú ti ilẹ̀ Britain tí ń ju bọ́ǹbù sórí ìlú náà, ó sì tẹnu mọ́ bí ṣíṣègbọràn sí ìṣílétí náà ‘láti máà máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀,’ ṣe dáàbò bò wa. (Hébérù 10:25) Nígbà yẹn, etíkun ni a ti pàdé, mo sì wà lára àwọn tí ó fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Nígbà tí a ti inú omi jáde, a tò sórí ìlà kan, àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa sì kọrin kan fún wa, tí wọ́n fi gbóríyìn fún wa fún ìpinnu tí a ṣe. N kò lè gbàgbé ọjọ́ yẹn láé!
Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, nígbà tí èmi àti ọmọdékùnrin kan ń wàásù fún àwọn ènìyàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé, ọlọ́pàá mú wa, ó di àgọ́ wọn. Láti lè fi hàn pé wọ́n kà wá sí àwọn Kọ́múníìsì àti pé wọ́n ti fòfin de isẹ́ ìwàásù wa, wọ́n lù wá, wọ́n sì wí fún wa pé: “Ẹ̀yin olórí burúkú wọ̀nyí, Stalin náà ní ń jẹ́ Jèhófà!”
Ogun abẹ́lé gbóná ní Gíríìsì nígbà yẹn, ẹ̀mí ìlòdì sí ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì sì ń ga sí i. Ní ọjọ́ kejì, a mú wa gba iwájú ilé wa kọjá pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lọ́wọ́, bí ẹni pé ọ̀daràn ni wá. Ṣùgbọ́n ìyẹn nìkan kọ́ ni àwọn ìdánwò tí mo dojú kọ.
Ìdánwò Ìgbàgbọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1944, mo ṣì jẹ́ ọmọ ilé ìwé, ìjọba Nazi ṣì gba Tẹsalóníkà síbẹ̀. Lọ́jọ́ kan, ní ilé ẹ̀kọ́, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Gíríìkì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan, tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n wa nínú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn, sọ pé a ó yẹ̀ mí wò lórí ẹ̀kọ́ ọjọ́ náà. Àwọn ọmọ yòókù wí pé: “Kì í màá ṣe Kristẹni ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì.”
Ọ̀jọ̀gbọ́n náà béèrè “Ẹ̀sin wo ni tirẹ̀?”
Mo fèsì pé: “Mo jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Ó gbá mi mú, ó sì di ìgbájú rù mí, bẹ́ẹ̀ ni ó kígbe pé: “Ìkookò láàárín àgùntàn nìyí.”
Mo wá ronú ara mi pé, ‘Báwo ni ó ṣe wá tọ́ kí àgùntàn máa lu ìkookò?’
Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, nǹkan bí 350 nínú wa jókòó láti jẹ oúnjẹ ọ̀sán. Ọ̀gá náà sọ pé: “Neros ni yóò gbàdúrà.” Mo ka ‘Baba wa Tí Ń Bẹ Lọ́run,’ gẹ́gẹ́ bí a ṣe máa ń pe àdúrà tí Jèsù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tí ó wà nínú Mátíù 6:9-13. Èyí kì í ṣe ohun tí ọ̀gá náà fẹ́, nítorí náà, ó fi ìbínú béèrè lọ́wọ́ mí láti àyè rẹ̀ pé: “Èé ṣe tí o fi gbàdúrà bẹ́ẹ̀ yẹn?”
Mo wí pé: “Nítorí pé mo jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.” Òun náà gbá mi mú gírígírí, ó sì fọ́ mi lẹ́nu. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan náà yẹn, olùkọ́ kan pè mí sí ọ́fíìsì rẹ̀, ó sì wí pé: “Neros, o káre, di ohun tí ó gbà gbọ́ mú ṣinṣin, má sì ṣe juwọ́ sílẹ̀.” Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, baba mi fún mi níṣìírí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wọ̀nyí: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.”—2 Tímótì 3:12.
Nígbà tí mo jáde ilé ẹ̀kọ́ giga, mo ní láti yan iṣẹ́ ìgbésí ayé tí n óò ṣe. Nítorí rúkèrúdò tí ó wà ní Gíríìsì, mo tún ní láti dojú kọ ọ̀ràn àìdásí-tọ̀túntòsì Kristẹni. (Aísáyà 2:4; Mátíù 26:52) Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ní ìbẹ̀rẹ̀ 1952, a rán mi lọ sí ẹ̀wọ̀n 20 ọdún nítorí pé mo kọ̀ láti gbé ìbọn láàárín àkókò tí kò fara rọ yẹn nínú ìtàn Gíríìkì.
A Dán Àìdásí-Tọ́tùntòsì Kristẹni Mi Wò
Nígbà tí a fi mi sí galagálá ní ibùdó àwọn ológun ní Mesolóngion àti Kọ́ríńtì, mo láǹfààní láti ṣàlàyé fún olórí àwọn ọmọ ogun náà pé ẹ̀rí-ọkàn mi tí a ti fi Bíbélì kọ́ kò ní yọ̀ǹda fún mi láti di ọmọ ogun tí yóò máa ṣètìlẹ́yìn fún ọ̀ràn ìṣèlú. Mo ṣàlàyé pé: “Ọmọ ogun Jésù ni mi,” ní títọ́ka sí 2 Tímótì 2:3. Nígbà tí wọ́n rọ̀ mí láti rò ó dáadáa, mo sọ pé n kò kánjú ṣe ìpinnu tí mo ṣe, ṣùgbọ́n, mo ṣe é lẹ́yìn tí mo ti rò ó jinlẹ̀ dáradára, tí mo sì ti ronú nípa ìyàsìmímọ́ mi sí Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, mo ní láti ṣe iṣẹ́ kàn-ń-pá, kí n máa jẹun lọ́jọ́ kẹtakẹta fún 20 ọjọ́, kí n sì máa sun ilẹ̀ẹ́lẹ̀ inú sẹ́ẹ̀lì tí kò fẹ̀ tó mítà kan níbùú àti mítà méjì lóròó. Èmi àti àwọn mèjí mìíràn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ni a sì jọ wà nínú galagálá yìí! Ní àkókò yìí tí mo fi wà nínú àgọ́ ní Kọ́ríńtì, ni wọ́n pè mí láti inú sẹ́ẹ̀lì mi, pé wọ́n fẹ́ lọ pa mí.
Bí a ti ń lọ sí ibi tí wọn yóò ti pa mi, sójà náà sọ pé, “Ṣe o kò ní sọ nǹkankan ni?”
Mo dáhùn pé: “Rárá.”
“Ṣé o kò ní kọ̀wé sí ìdílé rẹ̀ ni?”
Mo tún dáhùn pé: “Rárá. Wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ẹ pa mí síhìn-ín.”
A dé àgbàlá náà, ó sì pàṣẹ pé kí ń fara ti ògiri. Lẹ́yìn náà, dípò kí ọ̀gá náà pàṣẹ fún àwọn sójà náà láti yìnbọn, ó pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé lọ.” Fífi ikú halẹ̀ lásán ni, ṣe ni wọ́n pète rẹ̀ láti fi dán ìpinnu mi wò.
Lẹ́yìn náà, a rán mi lọ sí erékùṣù Makrónisos, níbi tí wọn kò ti yọ̀ǹda kí n ní ìwé èyíkéyìí lọ́wọ́ àfi Bíbélì nìkan. Yàtọ̀ sí àwọn 500 ọ̀daràn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n fi àwọn Ẹlẹ́rìí 13 pa mọ́ sínú ilé kékeré kan tí ó wà lọ́tọ̀. Síbẹ̀, a ṣì ń fọgbọ́n mú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọnú ilé wá. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan, a fi páálí loukoúmia (midin-mí-ìndìn kan tí ó gbajúmọ̀) ránṣẹ́ sí mi. Àwọn ọ̀gá fi ìháragàgà ṣàyẹ̀wò loukoúmia náà tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi ṣe nǹkan kan nípa ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí a fi pa mọ́ sísàlẹ̀ rẹ̀. Ẹlẹ́rìí kan sọ pé: “Àwọn sójà ni wọ́n jẹ loukoúmia, ṣùgbọ́n àwa ni a ‘jẹ’ Ilé Ìṣọ́!”
Ẹ̀dà ìwé What Has Religion Done for Mankind? tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde nígbà náà tẹ̀ wá lọ́wọ́, Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n tí ó gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì sì tú u sí èdè tí a gbọ́. A tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ pa pọ̀, a ń yọ́ ìpàdé wa ṣe. A ka ọgbà ẹ̀wọ̀n sí ilé ẹ̀kọ́, àǹfààní kan láti fún ipò tẹ̀mí wa lókun. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, inú wa dùn nítorí pé a mọ̀ pé ọ̀nà ìwà títọ́ wa dùn mọ́ Jèhófà.
Ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi mí sí kẹ́yìn ni ti Týrintha ní ìlà oòrùn Pelopónnisos. Níbẹ̀, mo ṣàkíyèsí ẹ̀ṣọ́ kan tí ń fara balẹ̀ wò mí bí mo ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ mi kan. Ìyàlẹ́nu ńláǹlà ni ó jẹ́ fún mi láti pàdé ẹ̀ṣọ́ yẹn lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà ní Tẹsalóníkà! Nígbà yẹn, ó ti di Ẹlẹ́rìí. Lẹ́yìn náà, wọ́n rán ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, kì í ṣe láti lọ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣọ́ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n. A jù ú sẹ́wọ̀n nítorí ohun kan náà tí a fi jù mí sẹ́wọ̀n níjelòó.
Ìgbòkègbodò Tí A Mú Sọjí Lẹ́yìn Ìtúsílẹ̀
Ọdún mẹ́ta péré ni mo lò lẹ́wọ̀n 20 ọdún tí wọ́n ràn mí. Lẹ́yìn tí wọ́n tú mi sílẹ̀, mo pinnu láti máa gbé ní Áténì. Ṣùgbọ́n, kò pẹ́ tí àrùn pleura fi kì mí, ó wá pọndandan fún mi láti padà sí Tẹsalóníkà. Oṣù méjì ni ń kò fi lè jáde nílé. Lẹ́yìn náà, mo pàdé ọmọbìnrin òrékelẹ́wà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Koula, a sì ṣègbéyàwó ní December 1959. Ní ọdún 1962, ó bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó ṣeé ṣe fún mi láti dara pọ̀ mọ́ ọn nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí ó ń ṣe.
Ní January 1965, a yàn wá sí iṣẹ́ àyíká, kí a máa bẹ àwọn ìjọ wò láti fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, a tún láǹfààní láti lọ sí àpéjọ àgbègbè fún ìgbà àkọ́kọ́, ní Vienna, Austria. Kò dà bí àwọn ìpàdé tí a ṣe ní Gíríìsì, tí a ní láti yọ́ ṣe nínú igbó nítorí pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa. Nígbà tí ọdún 1965 fi máa parí, a pè wá láti wá ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Áténì. Ṣùgbọ́n, nítorí ìṣòro ìlera tí àwọn ẹbí mi kan ní, a ní láti padà sí Tẹsalóníkà ní ọdún 1967.
Bí a ti ń bójú tó ẹrù iṣẹ́ ìdílé, a tún ń bá a nìṣó láti jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ ajíhìnrere. Nígbà kan, tí mo ń bá ìbátan mi kan, Kostas, sọ̀rọ̀, mo ṣàpèjúwe bí ètò àjọ Ọlọ́run ti dára tó fún un, mo sọ fún un nípa ìfẹ́, ìṣọ̀kan, àti ìgbọràn sí Ọlọ́run tí ó wà níbẹ̀. Ó wí pé: “Ká ní Ọlọ́run wà ni, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ì bá dára.” Ó gbà pẹ̀lú mi láti ṣàyẹ̀wò bóyá Ọlọ́run wà tàbí kò sí. Mo sọ fún un pé a óò lọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nuremberg, Germany, ní August 1969. Ó béèrè bí òun bá lè wá síbẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀, Alekos, tí òun náà ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wa, fẹ́ wá pẹ̀lú.
Ohun àfiṣerànwò àrà ọ̀tọ̀ gbáà ni àpéjọpọ̀ ti Nuremberg jẹ́! Pápá eré ìdárayá ńlá tí Hitler ti ṣayẹyẹ ìṣẹ́gun rẹ̀ ni a ti ṣe àpéjọpọ̀ ọ̀hún. Àwa tí a pésẹ̀ síbẹ̀ lé ní 150,000, ẹ̀mí Jèhófà sì hàn gbangba nínú gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, Kostas àti Alekos ṣèrìbọmi. Àwọn méjèèjì ń sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí Kristẹni alàgbà, àwọn ìdílé wọn pẹ̀lú sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí.
Mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú obìnrin kan tí ó fi ìfẹ́ hàn sí òtítọ́. Ọkọ rẹ̀ sọ pé òun fẹ́ yẹ ohun tí a gbà gbọ́ wò, láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé òun ti pe Ọ̀gbẹ́ni Sakkos, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Gíríìkì, fún ìjiyàn kan. Ọkọ obìnrin yìí fẹ́ béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ àwa méjèèjì. Ọ̀gbẹ́ni Sakkos wá, àlùfáà kan sì tẹ̀ lé e. Ọkùnrin tí a ti ń bẹ̀ wò bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Lákọ̀ọ́kọ́, n óò fẹ́ kí Ọ̀gbẹ́ni Sakkos dáhùn ìbéèrè mẹ́ta.”
Ọkùnrin náà na ìtumọ̀ Bíbélì tí a ti ń lò nínú ìjíròrò wa sókè, ó ní, “Ìbéèrè àkọ́kọ́ ni pé: Ṣé Bíbélì gidi nìyí, àbí Bíbélì Àwọn Ajẹ́rìí?” Ọ̀gbẹ́ni Sakkos dáhùn pé ìtumọ̀ tí a fàṣẹ tì lẹ́yìn ni, ó sì ṣàpèjúwe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Bíbélì.”
Bí ó ti ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ọkùnrin náà béèrè pé, “Ìbéèrè kejì: Ṣé èèyàn dáadáa ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” Dájúdájú, ó fẹ́ mọ irú àwọn ènìyàn tí aya rẹ̀ ti ń bá rìn. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà fèsì pé èèyàn dáadáa ni wọ́n.
Ọkùnrin náà tún ni: “Ìbéèrè kẹta nìyí: Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbowó oṣù?” Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà dáhùn pé: “Rárá o.”
Ọkùnrin náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo ti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi, mo sì ti ṣe ìpinnu mi.” Lẹ́yìn náà, ó ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ lọ, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí ó ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ìgbésí Ayé Gidi Tí Ó Ṣàǹfààní
Lẹ́yìn náà, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká ní January 1976. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, mo ní àǹfààní láti ṣagbátẹrù oríṣi ọ̀nà ìwàásù tuntun kan ní Gíríìsì—ìjẹ́rìí ní òpópónà. Nígbà tí ó yá, ní October 1991, èmi àti aya mi bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n ní láti ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn-àyà tí ó nílò òpójẹ̀ àtọwọ́dá mẹ́rin fún mi, èyí tí ó sì kẹ́sẹ járí. Nísinsìnyí, koko lára mi le, ó sì ti ṣeé ṣe fún mi láti padà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún. Mo tún ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà kan ní ọ̀kan nínú àwọn ìjọ tí ó wà ní Tẹsalóníkà, mo sì ń bá àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tí ó wà ládùúgbò ṣiṣẹ́ láti lè ran àwọn tí ó nílò ìtọ́jú ìṣègùn lọ́wọ́.
Bí mo bá bojú wẹ̀yìn wo ìgbésí ayé mi, mo máa ń rí bí ó ti ṣe dùn tó láti ṣe ohun tí ó wu Baba wa ọ̀run. Inú mi dùn pé nígbà pípẹ́ sẹ́yìn mo gba ìkésíni pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Nítòótọ́, ó mú inú mi dùn láti rí ìbísí kárí ayé nínú iye àwọn olóòótọ́ ọkàn tí ń wá sínú ètò àjọ Jèhófà. Láti lọ́wọ́ nínú gbígba àwọn ènìyàn sílẹ̀ ní oko ẹrú nípasẹ̀ òtítọ́ Bíbélì, kí a sì ṣí ìrètí ìyè ayérayé nínú ayé tuntun òdodo sílẹ̀ fún wọn jẹ́ àǹfààní ńlá kan!—Jòhánù 8:32; 2 Pétérù 3:13.
Ìgbà gbogbo ni a máa ń gbìyànjú láti fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà níṣìírí láti fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ṣe góńgó wọn, kí wọ́n lo àkókò àti okun wọn láti sìn ín. Ní tòótọ́, gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà àti rírí inú dídùn kíkọyọyọ nínú mímú inú rẹ̀ dùn ni ìgbésí ayé tí ó láyọ̀ jù lọ tí ẹnì kan lè ní!—Òwe 3:5; Oníwàásù 12:1.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
(Láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún)
Mo ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìgbọ́únjẹ ní Bẹ́tẹ́lì ní 1965
Mo ń sọ àwíyé ní 1970 nígbà tí wọ́n ṣì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa
Èmi àti ìyàwó mi ní 1959
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Èmi àti ìyàwó mi, Koula