ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 11/15 ojú ìwé 3-4
  • Ìwọ Ha Ní Áńgẹ́lì Kan Tí Ń dáàbò Bò Ọ́ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Ní Áńgẹ́lì Kan Tí Ń dáàbò Bò Ọ́ Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nínífẹ̀ẹ́ sí Àwọn Áńgẹ́lì
  • Ìfẹ́ fún Áńgẹ́lì Ti Gba Àwọn Èèyàn Lọ́kàn
    Jí!—1999
  • Ṣé O Ní Áńgẹ́lì Tó Ń Dáàbò Bò Ẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Áńgẹ́lì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 11/15 ojú ìwé 3-4

Ìwọ Ha Ní Áńgẹ́lì Kan Tí Ń dáàbò Bò Ọ́ Bí?

ÌWỌ ha gbà pé o ní áńgẹ́lì kan tí ń dáàbò bò ọ́ bí? Ọ̀pọ̀ ènìyàn rò bẹ́ẹ̀. Ìdí abájọ nìyẹn tí wọ́n fi ròyìn pé obìnrin kan wà ní ìwọ̀ oòrùn Kánádà tí ó ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì. Bí o bá fún un ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ orúkọ rẹ pẹ̀lú 200 dọ́là, obìnrin náà sọ pé òun yóò jẹ́ kí o bá áńgẹ́lì tí ń dáàbò bò ọ́ pàdé. Lákọ̀ọ́kọ́, yóò ṣàṣàrò nípa títẹjúmọ́ iná àbẹ́là roro. Lẹ́yìn náà, yóò lọ nínú ìran, níbi tí áńgẹ́lì rẹ yóò ti rán an níṣẹ́ sí ọ. Àjẹmọ́nú kan ni pé, obìnrin náà yóò ya àwòrán bí áńgẹ́lì rẹ ṣe rí fún ọ.

Lójú àwọn kan, èyí lè dà bí ohun kan náà pẹ̀lú ìtàn Louis Kẹsàn-án, Ọba Faransé. A gbọ́ pé ó ra àwọn ìyẹ́ olówó iyebíye, tí àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé apá Máíkẹ́lì, Olú-Áńgẹ́lì, ni ó ti bọ́ sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ń ṣiyèméjì nípa ìtàn yẹn, kíá ni wọ́n ń gba ohun tí obìnrin ará Kánádà yẹn sọ gbọ́.

Nínífẹ̀ẹ́ sí Àwọn Áńgẹ́lì

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ìfẹ́ sí àwọn áńgẹ́lì túbọ̀ ń ga sí i. Lórí tẹlifíṣọ̀n àti simimá, nínú ìwé, ìwé ìròyìn, àti lẹ́tà ìròyìn, a ń gbọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì tí ń tu àwọn tí ń ṣàìsàn lílekoko àti àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú, tí ń fúnni lọ́gbọ́n, tí wọ́n sì ń gbani lọ́wọ́ ikú. Ní United States, nǹkan bí 20 mílíọ̀nù ènìyàn ní ń wo ètò orí tẹlifísọ̀n tí ń ṣàfihàn bí àwọn áńgẹ́lì ṣe ń lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ìgbésí ayé àwọn ènìyàn. Ilé ìtàwé kan ní àkọsílẹ̀ ìwé tí ó lé ní 400 tí ó dá lórí àwọn áńgẹ́lì.

Ìwé kan láìpẹ́ yìí sọ nípa bí àwọn áńgẹ́lì tí ń dáàbò boni ṣe gba ẹ̀mí àwọn sójà là lójú ìjà. Àwọn àkọlé tí ó wà lára ọkọ̀ ń sọ fúnni pé àwọn áńgẹ́lì ń dáàbò bo àwọn awakọ̀. Àwọn àjọ, ìpàdé àpérò, àti sẹminá ń gbé ẹ̀kọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì lárugẹ, a tilẹ̀ gbọ́ pé wọ́n ń ranni lọ́wọ́ láti mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì ṣeé ṣe.

Eileen Freeman ni ó kọ ìwé mẹ́ta tí ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì, òun sì ni òǹṣèwé ìwé ìròyìn tí a pilẹ̀ ṣe fún wọn. Obìnrin náà kéde pé: “Mo gbà pé bí áńgẹ́lì ti pọ̀ tó ní ọ̀run, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn áńgẹ́lì tí ń dáàbò boni lọ súà lórí Ilẹ̀ Ayé, àwọn ẹ̀dá tí a kò fi iṣẹ́ wọn mọ sí yíyin Ọlọ́run ní òkè ọ̀run nìkan, ṣùgbọ́n, tí iṣẹ́ wọn tún kan bíbójútó àwọn ẹ̀dá ènìyàn àti onírúurú ẹ̀mí mìíràn lórí Ilẹ̀ Ayé. Olúkúlùkù wa ni a ti yan áńgẹ́lì tí ń dáàbò boni fún nígbà tí a ti wà nínú oyún, tí ó sì ṣọ́ wa jálẹ̀ ìgbà tí a fi dàgbà nínú ọlẹ̀, tí a fi bí wa, tí a fi wà nínú ayé, títí tí áńgẹ́lì náà yóò fi darí wa láti inú àhámọ́ ayé yìí wọnú ògo ti ọ̀run.” Èyí ṣàpèjúwe ojú ìwòye lílókìkí náà pé àwọn áńgẹ́lì adáàbòboni ń bẹ.

Ní àwọn àkókò hílàhílo, tí nǹkan kò sì fara rọ yìí, ó ń tuni nínú láti gbà pé a ní áńgẹ́lì tiwa tí ń dáàbò bò wá, tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ láti máa ṣọ́ wa. Kí wá ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, sọ nípa èyí? Ǹjẹ́ ó yẹ kí a gbìyànjú láti kàn sí àwọn áńgẹ́lì? Ǹjẹ́ wọ́n bìkítà nípa ìlànà ìwà rere àti ìgbàgbọ́ wa ní ti ẹ̀sìn? Ìrànlọ́wọ́ wo ni a lè retí láti ọ̀dọ̀ wọn? Àpilẹ̀kọ tí ó kàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́