ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 12/8 ojú ìwé 13-14
  • Ìfẹ́ fún Áńgẹ́lì Ti Gba Àwọn Èèyàn Lọ́kàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfẹ́ fún Áńgẹ́lì Ti Gba Àwọn Èèyàn Lọ́kàn
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Gbajúmọ̀ Tó
  • Ọgọ́rọ̀ọ̀rún Ìwé
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Wíwádìí Ìròyìn náà Wò
    Jí!—1999
  • Ìwọ Ha Ní Áńgẹ́lì Kan Tí Ń dáàbò Bò Ọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Áńgẹ́lì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 12/8 ojú ìwé 13-14

Ìfẹ́ fún Áńgẹ́lì Ti Gba Àwọn Èèyàn Lọ́kàn

“‘Gbogbo’ wa la ní áńgẹ́lì tó ń tọ́ wa sọ́nà, tó ń dáàbò bò wá . . . Bí a kò bá yọ wọ́n lẹ́nu tí a fi ara wa sábẹ́ àbójútó wọn, bí ọmọdé, tí a fọkàn tán wọn pátápátá, tí a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, tí a sì fìmoore hàn sí wọn dáadáa, nígbà náà ni wọn yóò bù kún wa lọ́pọ̀ yanturu. Wọ́n ń bá wa ṣeré. Wọ́n ń tọ́jú wa. Wọ́n ń wò wá sàn, wọ́n ń fọwọ́ kàn wá, wọ́n ń fọwọ́ wọn tí a kò lè rí gbá wa mọ́ra, ìgbà gbogbo ni wọ́n sì máa ń gbìyànjú láti fún wa ní ohun tí a ń fẹ́.”—Láti inú ìwé “Angel Letters.”

WÀÁ gbà pé èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa àwọn áńgẹ́lì yìí ń runi lọ́kàn sókè. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn kan ń pè ní “ipò tẹ̀mí tuntun,” ti sọ, olúkúlùkù wa la ti yan áńgẹ́lì kan fún, iṣẹ́ áńgẹ́lì náà sì ni láti máa tù wá nínú, kó sì máa dáàbò bò wá kí nǹkan má bàa ṣe wá. Wọ́n máa ń sọ pé àwọn áńgẹ́lì wa náà lágbára, wọ́n sì jẹ́ onífẹ̀ẹ́. Kò béèrè pé ká gbọ́ràn sóun lẹ́nu tàbí kí a máa jọ́sìn òun, kò sì ní dá wa lẹ́bi tàbí kó bá wa wí. Kì í kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, ọ̀ràn tó bá kàn ẹ́ ló jẹ ẹ́ lógún, ó sì máa ń fẹ́ kí gbogbo ohun tí o ń fẹ́ di ṣíṣe. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gba àwọn nǹkan wọ̀nyí gbọ́ tọkàntọkàn lónìí.

Lóòótọ́, gbígbàgbọ́ nínú áńgẹ́lì kì í ṣe nǹkan tuntun. Àtayébáyé ni wọ́n ti ń kó ipa pàtàkì nínú ohun tí àwọn èèyàn gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn wọn. Àwọn àwòrán tí àwọn èèyàn ń yà ń fi èyí hàn. Oríṣi àwọn áńgẹ́lì kan tó ń jẹ́ kérúbù ni àwọn Júù fi ṣe àwọn àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì wọn ìgbàanì lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ fi àwòrán àwọn áńgẹ́lì ṣe àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti ilé ìjọsìn ńláńlá wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí kún fún àwòrán àti ère àwọn áńgẹ́lì.

Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Gbajúmọ̀ Tó

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn áńgẹ́lì ti wá gbajúmọ̀ gan-an ní àwọn ilẹ̀ kan. Nínú sinimá, wọ́n sábà máa ń fi àwọn áńgẹ́lì hàn bí ẹ̀dá èèyàn tó ti kú, àmọ́ tó tún padà wá sáyé láti máa ṣe nǹkan rere. Nínú fíìmù kan, àwọn áńgẹ́lì ló ran ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfigigbá kan lọ́wọ́ tí wọn ò fi fìdí rẹmi. Nínú òmíràn, áńgẹ́lì kan tó ń dáàbò bo ọ̀dọ́mọkùnrin kan ló ràn án lọ́wọ́ láti gbẹ̀san lára àwọn tó pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀. Wọ́n tún ń gbé ọ̀ràn nípa áńgẹ́lì arannilọ́wọ́ yìí lárugẹ nínú eré kan tó gbajúmọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.

Àwọn orin nípa áńgẹ́lì pọ̀ jaburata. Ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ọ̀kan lára orin mẹ́wàá tó gbajúmọ̀ ló ń mẹ́nu kan áńgẹ́lì. Nígbà tó fi máa di àárín àwọn ọdún 1990, ó ti lé ní ọgọ́fà “àwọn ilé ìtajà áńgẹ́lì” tí àwọn èèyàn ti ṣí ní Amẹ́ríkà. Àwọn ilé ìtajà wọ̀nyí ń ta ère áńgẹ́lì, ohun ọ̀ṣọ́ tó ní àwòrán áńgẹ́lì, àti àwọn ohun ìkọ̀wé tó ní àwòrán áńgẹ́lì lára—wọ́n tilẹ̀ ń ta woroworo ọmọdé tí wọ́n ya àwòrán áńgẹ́lì sí. Wọ́n ń ṣe àwọn àpérò àti ìwé tí wọ́n sọ pé ó ń kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè máa bá àwọn ẹ̀dá ọ̀run wọ̀nyí sọ̀rọ̀. Àwọn ìwé ìròyìn àti ìjíròrò lórí tẹlifíṣọ̀n ń sọ nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ṣalábàápàdé àwọn áńgẹ́lì.

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún Ìwé

Bákan náà ni àwọn ìwé wà tó ń sọ nípa àwọn áńgẹ́lì. Ilé ìtàwé ńlá kan ní Ìlú New York kó oríṣiríṣi ìwé tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta tó ń sọ nípa àwọn áńgẹ́lì, ní pàtàkì àwọn áńgẹ́lì tí ń dáàbò boni, sórí àtẹ. Àwọn ìwé wọ̀nyẹn ṣèlérí pé àwọn tó bá kà á yóò mọ bí wọ́n ṣe lè kàn sí àwọn áńgẹ́lì adáàbòboni, kí wọ́n mọ orúkọ wọn, kí wọ́n máa bá wọn sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì máa rí ìrànlọ́wọ́ wọn. Àwọn ìwé wọ̀nyí ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtàn nípa bí àwọn áńgẹ́lì ṣe ń yọ síni láìròtẹ́lẹ̀ nígbà tí a nílò ìrànlọ́wọ́, bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn èèyàn kúrò lójú títì nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ń bọ̀, bí wọ́n ṣe ń wo àwọn àìsàn tó ń ṣekú pani sàn, bí wọ́n ṣe ń tu àwọn tí ìdààmú bá nínú, àti bí wọ́n ṣe ń dáàbò bo àwọn sójà lójú ogun. Irú àwọn áńgẹ́lì bẹ́ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún èèyàn “láìbéèrè ẹ̀rí ìrònúpìwàdà, ìyíléròpadà, tàbí ṣíṣe ẹ̀sìn kan rárá.” Ṣùgbọ́n irú “àwọn ìbápàdé” bẹ́ẹ̀ lóde òní kì í fi bẹ́ẹ̀ mú kí àwọn èèyàn ṣe àwọn ìyípadà nínú ayé wọn. Àwọn tó sọ pé àwọn rí irú nǹkan báwọ̀nyẹn kàn ń dá ara wọn nínú dùn ni.

Nínú ayé tí àìfararọ àti rògbòdìyàn pọ̀ yìí, irú ìròyìn wọ̀nyí lè dà bí ìròyìn rere tó jẹ́ àgbàyanu. Ṣùgbọ́n ṣé a lè gbà wọ́n gbọ́? Ṣé ó tilẹ̀ já mọ́ nǹkan kan?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Àwọn kan ń rò pé àwọn ti bá àwọn áńgẹ́lì pàdé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́