Ǹjẹ́ Kérésìmesì Kò Ti Jẹ́ Ká Gbàgbé Kristi?
“Kò tí ì ṣeé ṣe fún mi láti fara mọ́ gbogbo pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ìgbà Kérésìmesì. Lójú tèmi o, wọn kò bá ìgbésí ayé àti ẹ̀kọ́ Jésù mu.”—Mohandas K. Gandhi.
Ọ̀PỌ̀ ènìyàn ni kò ní fara mọ́ ohun tí Gandhi sọ yìí rárá. Wọ́n lè sọ pé, ‘Kí tilẹ̀ ni òṣèlú ẹlẹ́sìn Híńdù yìí mọ̀ nípa ọdún àwọn Kristẹni?’ Àmọ́, ká má wulẹ̀ déènà pẹnu, Kérésìmesì ti tàn ká gbogbo ayé, ó ti nípa lórí gbogbo àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀. Ní gbogbo oṣù December, àfi bí pé kò sí àwùjọ tí wọn kì í ti í ṣọdún náà.
Bí àpẹẹrẹ, nǹkan bí mílíọ̀nù márùnlélógóje àwọn ará Éṣíà ló ń ṣe Kérésìmesì, èyí fi ogójì mílíọ̀nù ju iye àwọn tó ń ṣe é ní nǹkan tó lé ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. Bó bá sì jẹ́ àṣà ayé tí ó wà nínú Kérésìmesì òde òní, ti sísáré ra nǹkan ọdún, tí gbogbo wa ń fojú rí ni Gandhi pè ní “pọ̀pọ̀ṣìnṣìn,” a jẹ́ pé òótọ́ pọ́ńbélé ni pé apá yìí nínú ayẹyẹ náà ló sábà máa ń gbapò iwájú. Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Ní pàtàkì, Kérésìmesì ní Éṣíà—látorí iná ọdún ní Hong Kong tó fi dórí òdòdó Kérésì tó wà lórí òtẹ́ẹ̀lì Yuletide tó jẹ́ àwòṣífìlà ní Beijing, títí dórí àwòrán ìbí Jésù tó wà ní àgbègbè ìṣòwò ìlú Singapore—kì í ṣe ọ̀ràn ẹ̀sìn mọ́, (òwò ni).”
Ǹjẹ́ ayẹyẹ Kérésìmesì lóde òní kò ti jẹ́ ká gbàgbé Kristi? Ní èyí tó hàn sí gbogbo ayé, láti ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa ni àwọn èèyàn ti ń ṣọdún ní December 25, nígbà tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì pa á láṣẹ fún wọn láti máa ṣàjọ̀dún ọjọ́ ìbí Jésù ní ọjọ́ yẹn. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a ṣe ní ilẹ̀ United States láìpẹ́ yìí ti fi hàn, ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún péré nínú àwọn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, ló gbà pé, ọjọ́ ìbí Kristi ni apá pàtàkì jù lọ nínú Kérésìmesì.
Kí lèrò tìrẹ? Nígbà mìíràn, o ha ń rò ó lọ́kàn pé, pẹ̀lú gbogbo pípariwo ọdún náà láìdábọ̀, dídààmú láti ra ẹ̀bùn, fífi òdòdó ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́, ṣíṣètò àríyá àti lílọ ságbo àríyá, fífi káàdì ẹ-kú-ọdún ránṣẹ́ síni—lọ́nà kan ṣáá, a ti gbàgbé Jésù nínú ọ̀ràn náà?
Ó dà bí pé ọ̀pọ̀ rò pé ọ̀nà kan tí Kristi fi lè di ẹni àìgbàgbé nígbà Kérésìmesì ni nípa pípàtẹ Àwòrán ìgbà ìbí rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ pẹ̀lú ti rí irú àwọn iṣẹ́ ọnà bẹ́ẹ̀, tí ó fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọwọ́ tí ó wà ní ibùjẹ ẹran, tí ó tún ṣàfihàn Màríà, Jósẹ́fù, àti àwọn olùṣọ́ àgùntàn mélòó kan, “àwọn amòye mẹ́ta,” tàbí “àwọn ọba mẹ́ta,” àwọn ẹran tí wọ́n wà nínú ọgbà àti àwọn èèyàn díẹ̀ tí wọ́n rọ̀gbà yí ọmọ náà ká. Ọ̀pọ̀ ló gbàgbọ́ pé ṣe ni àwọn Àwòrán wọ̀nyí ń ránni létí ohun tí Kérésìmesì jẹ́ gan-an. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà, U.S. Catholic ti sọ, “Àwòrán Ìbí Jésù mú kí a ní òye tí ó ju èyí ti ìwé ìhìn rere èyíkéyìí fúnni, àmọ́ ṣá o, ó tún ń fi hàn bí ìtàn tí Àwòrán náà ń sọ kò ṣe jóòótọ́ tó.”
Ṣùgbọ́n, báwo ni Àwòrán Ìbí Jésù ṣe wá lè fi hàn pé ìtàn tó wà nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì kì í ṣòótọ́? Ó dáa, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbà pé àwọn iṣẹ́ ọnà kékeré rèǹtè-rente kan ló mú ìtàn àtẹnudẹ́nu tàbí ìtàn àròsọ wọnú ìtàn nípa ìbí Kristi. Tẹ́lẹ̀ rí, Àwòrán Ìbí Jésù kì í ṣe ohun bàbàrà rárá, àfi ìgbà tó di ọ̀rúndún kẹtàlá tí ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kan wá sọ ọ́ di ohun tí a ń gbé gẹ̀gẹ̀. Lónìí, bí ti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn tí a ti wá so mọ́ ọdún yìí, Àwòrán Ìbí Jésù ti di òwò ńlá. Ní Naples, Ítálì, títí ọdún fi máa yípo ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ilé ìtajà máa ń ta Àwòrán Ìbí Jésù, tàbí presepi bí wọ́n ti máa ń pè é. Díẹ̀ nínú àwòrán tí ó gbajúmọ̀ gan-an wọ̀nyí ni kì í ṣe àwòrán àwọn tí a sọ ọ̀rọ̀ wọn nínú àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ àwòrán àwọn gbajúgbajà òde òní, àwọn ẹni bí Ọmọbabìnrin Diana, Màmá Teresa, àti ìlú-mọ̀ọ́ká aránṣọ nì, Gianni Versace. Níbòmíràn, wọ́n máa ń fi ṣokoléètì, oúnjẹ alápòpọ̀, àní ìkarawun inú òkun ṣe presepi náà. O lè wá rí ìdí tó fi ṣòro láti tipasẹ̀ irú àwọn àwòrán tí a pàtẹ bẹ́ẹ̀ lóye ìtàn náà.
Báwo wá ni irú Àwòrán yìí ṣe lè jẹ́ “kí a ní òye tó ju èyí tí ìwé ìhìn rere èyíkéyìí fúnni”? Ṣé kì í ṣe ìtàn tòótọ́ ló wà nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere ni? Kódà àwọn oníyèméjì paraku pàápàá gbọ́dọ̀ gbà pé Jésù jẹ́ ẹni gidi, ẹni tí ìtàn rẹ̀ jóòótọ́. Nítorí náà, ìgbà kan wà tó wà ní ọmọ ọwọ́ lóòótọ́, tí a sì bí i síbì kan lóòótọ́. Ó yẹ kí ọ̀nà mìíràn tí ó dára wà tí a fi lè mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó yí bí a ṣe bí i ká dípò wíwulẹ̀ wo Àwòrán lásán tí ń ṣàpèjúwe bí a ṣe bí i!
Lóòótọ́, ọ̀nà wà. Àwọn òpìtàn méjì kọ àkọsílẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ìbí Jésù. Nígbà mìíràn, tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ń rò ó lọ́kàn pé a máa ń gbàgbé Kristi pátápátá nígbà Kérésìmesì, èé ṣe tí o ko fi ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí fúnra rẹ? Nínú wọn, wàá rí ìtàn tó gbádùn mọ́ni, kì í ṣe ìtàn àtẹnudẹ́nu tàbí àlọ́ lásán—òkodoro ìtàn ìbí Kristi.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Iṣẹ́ ọnà tó wà létí ojú ìwé 3 sí 6, 8, àti 9: Fifty Years of Soviet Art