Kí Ni Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí Ń Béèrè?
Ṣé wàá fẹ́ bẹ́ jùà sínú odò kan láìkọ́kọ́ kọ́ báa ṣe ń lúwẹ̀ẹ́? Irú ìwà òpònú bẹ́ẹ̀ mà lè ṣeni léṣe—ó tilẹ̀ lè gbẹ̀mí ẹni pàápàá. Ṣùgbọ́n, wá ronú nípa ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń kù gìrì wọnú ìgbéyàwó láìmọ bí wọn yóò ṣe gbé àwọn ẹrù iṣẹ́ tó wé mọ́ ọn.
JÉSÙ wí pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) Bí ọ̀ràn ti rí nínú kíkọ́ ilé gogoro bẹ́ẹ̀ náà ló rí nínú gbígbé ìdílé kalẹ̀. Ó yẹ kí àwọn tó bá ń gbèrò àtiṣègbéyàwó fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó wé mọ́ ìgbéyàwó, kí wọ́n rí i dájú pé wọ́n kúnjú ìwọ̀n ohun tó ń béèrè.
Ẹ Jẹ́ Ká Gbé Ìgbéyàwó Yẹ̀ Wò
Lóòótọ́, ìbùkún ńlá gbáà ló jẹ́ láti ní ọkọ tàbí aya tí a lè jọ ṣàjọpín ayọ̀ àti ìbànújẹ́ inú ìgbésí ayé. Ìgbéyàwó lè dí àlàfo tí ìdánìkanwà tàbí àìnírètí ń dá sílẹ̀. Ó lè tẹ́ ìyánhànhàn tí a bí mọ́ wa lọ́rùn, ìyẹn ni ti níní ẹnì kan táa nífẹ̀ẹ́, ẹnì kan táa lè jọ máa ṣe wọléwọ̀de, àti níní ẹnì kan táa lè jọ máa fara rora. Abájọ nígbà náà tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó wí pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:18; 24:67; 1 Kọ́ríńtì 7:9.
Ká sòótọ́, ṣíṣègbéyàwó lè yanjú àwọn ìṣòro kan. Ṣùgbọ́n, yóò dá àwọn ìṣòro tuntun sílẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé ìgbéyàwó jẹ́ síso ẹ̀dá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ méjì papọ̀, àwọn tó jẹ́ pé ìwà wọn lè bára mu, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé wọn kò ní ànímọ́ kan náà. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé èdèkòyedè kì í ṣàìwáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kódà láàárín àwọn tọkọtaya tó mọwọ́ ara wọn gan-an. Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, àwọn tó bá ṣègbéyàwó yóò ní “ìpọ́njú nínú ẹran ara”—tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ The New English Bible ṣe sọ ọ́, wọn yóò ní “ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn nínú ẹran ara ní ayé yìí.”—1 Kọ́ríńtì 7:28.
Ṣé Pọ́ọ̀lù ń gbèrò ibi ni? Rárá o! Ó kàn ń rọ àwọn tó ń ronú àtiṣègbéyàwó pé kí wọ́n ronú jinlẹ̀ dáadáa ni. Ìdùnnú tí ẹnì kan lè ní nítorí pé ẹnì kan ń gba tiẹ̀ kì í ṣe ìdiwọ̀n tó péye tí a fi lè mọ bí ìgbésí ayé ìdílé yóò ti rí lẹ́yìn oṣù àti ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ ìgbéyàwó. Ìpèníjà àti ìṣòro tí ìgbéyàwó kọ̀ọ̀kan ní yàtọ̀ síra wọn. Ọ̀ràn yìí kì í ṣe pé bóyá ìṣòro àti ìpèníjà wọ̀nyí yóò yọjú, àmọ́ kókó ibẹ̀ ni bí a ó ṣe yanjú wọn nígbà tí wọ́n bá dé.
Ṣe ni ìṣòro máa ń fún tọkọtaya láǹfààní láti fi hàn bí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ara wọn ti jẹ́ ojúlówó tó. Bí àpẹẹrẹ: Ọkọ̀ òkun kan lè rí jìmọ̀wò-jimọwo bó ti ń mì lẹ̀ǹgbẹ̀ létíkun, níbi táa dè é mọ́, tí kò lọ síwá sẹ́yìn. Àmọ́, ó dìgbà tó bá dé ojú agbami kí a tó lè mọ bó ṣe lágbára tó—ó tilẹ̀ lè dìgbà tó bá lè la ìgbì tó lè fọ́ ọkọ̀ yángá kọjá pàápàá. Bákan náà ló jẹ́ pé àkókò tí gbogbo nǹkan ń gún régé, tí ọ̀ràn ìfẹ́ ń dùn yùngbà nìkan kò tó láti mọ bí ìdè ìgbéyàwó ti lágbára tó. Nígbà mìíràn, ìgbà tí àdánwò bá dé, tí tọkọtaya náà dojú kọ ìṣòro tó lékenkà ni a tó lè mọ bí ìdè ìgbéyàwó náà ti lágbára tó.
Láti lè ṣe bẹ́ẹ̀, tọkọtaya gbọ́dọ̀ dúró ti àdéhùn wọn, nítorí Ọlọ́run pète pé kí ọkùnrin “fà mọ́ aya rẹ̀” àti pé àwọn méjèèjì yóò “di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Èrò nípa dídúró ti àdéhùn ń ba ọ̀pọ̀ ènìyàn lẹ́rù lónìí. Síbẹ̀, ó sáà bọ́gbọ́n mu pé ẹni méjì tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú yóò fẹ́ láti ṣàdéhùn tọkàntọkàn pé àwọn yóò jọ máa gbé pọ̀. Dídúró ti àdéhùn ń buyì kún ìgbéyàwó. Ó ń fúnni ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pé, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ọkọ àti aya náà yóò máa ran ara wọn lọ́wọ́.a Bí o kò bá tíì ṣe tán láti wọnú irú àdéhùn bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o kò tíì ṣe tán láti ṣègbéyàwó nìyẹn. (Fi wé Oníwàásù 5:4, 5.) Àní àwọn tí wọ́n ti ṣègbéyàwó pàápàá tún lè ní láti fi kún ìmọrírì wọn fún bí dídúró ti àdéhùn ti ṣe pàtàkì tó nínú ìgbéyàwó tó wà pẹ́ títí.
Yẹ Ara Rẹ Wò
Kò sí àní-àní pé o lè ka àwọn ànímọ́ tí ìwọ yóò fẹ́ kí ẹni tóo fẹ́ẹ́ fẹ́ ní. Ṣùgbọ́n, ìṣòro ńlá ló jẹ́ fún ìwọ alára láti yẹ ara rẹ wò, kí o sì pinnu bí o ṣe lè mú kí ìgbéyàwó náà tura. Yíyẹ ara ẹni wò fínnífínní ṣe kókó, ṣáájú jíjẹ́jẹ̀ẹ́ ìgbéyàwó àti lẹ́yìn tí a ti jẹ́jẹ̀ẹ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, béèrè àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí lọ́wọ́ ara rẹ.
• Ǹjẹ́ mo ti ṣe tán láti wọnú àdéhùn títí ayérayé pẹ̀lú ẹni tí mo fẹ́ẹ́ fẹ́?—Mátíù 19:6.
Ní ìgbà ayé wòlíì inú Bíbélì náà, Málákì, ọ̀pọ̀ ọkọ fi aya wọn sílẹ̀, bóyá láti lọ fẹ́ àwọn ìṣẹ́ǹṣẹ́rẹ́ obìnrin. Jèhófà wí pé omijé àwọn aya tí àwọn ọkọ wọn ti pa tì bo pẹpẹ òun mọ́lẹ̀, ó sì bẹnu àtẹ́ lu àwọn ọkùnrin tí wọ́n “ṣe àdàkàdekè sí” aya wọn.—Málákì 2:13-16.
• Bí mo bá ń ronú àtiṣègbéyàwó, ṣé mo ti kọjá ìgbà ọ̀dọ́, nígbà tí ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an, tó sì lè nípa lórí ìpinnu mi?—1 Kọ́ríńtì 7:36.
Nikki, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún nígbà tó wọlé ọkọ sọ pé: “Ó léwu gidigidi láti ṣègbéyàwó nígbà tí ẹnì kan ṣì kéré.” Ó kìlọ̀ pé: “Ìmọ̀lára rẹ, góńgó rẹ, àti àwọn ohun tó wù ẹ́ yóò máa yí padà látìgbàdégbà bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí o bá ti ń sún mọ́ ọmọ ogún ọdún, títí wàá fi lé ní ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.” Àmọ́ ṣá o, ọjọ́ orí nìkan kọ́ la fi ń mọ̀ pé ẹnì kan ti tóó ṣègbéyàwó. Síbẹ̀síbẹ̀, ṣíṣègbéyàwó nígbà tí ẹnì kan kò tíì kọjá ìgbà ọ̀dọ́, nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń nímọ̀lára ìfẹ́ tó lágbára gan-an fún ìbálòpọ̀, lè gbé ìrònú rẹ̀ gbòdì, ó sì lè máà jẹ́ kí ẹnì kan rí àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó yọjú.
• Àwọn ànímọ́ wo ni mo ní tí yóò ràn mí lọ́wọ́ láti mú kí ìgbéyàwó náà jẹ́ aláṣeyọrí?—Gálátíà 5:22, 23.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Kólósè pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” (Kólósè 3:12) Ìmọ̀ràn yìí bá a mu wẹ́kú fún àwọn tí ń gbèrò àtiṣègbéyàwó àti àwọn tí wọ́n ti ṣègbéyàwó.
• Mo ha ní ànímọ́ adàgbàdénú tí mo nílò, kí n bàa lè ran aya tàbí ọkọ mi lọ́wọ́ nígbà ìṣòro?—Gálátíà 6:2.
Dókítà kan sọ pé: “Nígbà tí ìṣòro bá dé, a sábà máa ń fẹ́ láti dá aya tàbí ọkọ tọ́ràn kàn lẹ́bi. Ẹni tó lẹ̀bi kọ́ ló ṣe pàtàkì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣe pàtàkì ni bí tọkọtaya náà yóò ṣe fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti mú kí ìbátan lọ́kọláya wọn sunwọ̀n sí i.” Ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì Ọba ṣeé lò fún àwọn tọkọtaya. Ó kọ̀wé pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, . . . nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde. Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe rí fún ẹnì kan ṣoṣo tí ó ṣubú nígbà tí kò sí ẹlòmíràn láti gbé e dìde?”—Oníwàásù 4:9, 10.
• Ṣé ọlọ́yàyà, tó lẹ́mìí pé nǹkan yóò dára ni mí, àbí ṣe ni ojú mi sábà máa ń dá gùdẹ̀, tí mo sì máa ń lérò òdì?—Òwe 15:15.
Elérò òdì kì í gbà pé nǹkan yóò dára lọ́jọ́ kan. Ìgbéyàwó kò lè yí ìwà yìí padà ní ọ̀sán kan òru kan! Bí àpọ́n kan—yálà ọkùnrin tàbí obìnrin—tó jẹ́ pé ó sábà máa ń ṣàríwísí tàbí tó jẹ́ elérò òdì bá ṣègbéyàwó, alárìíwísí tàbí elérò òdì náà ni yóò jẹ́. Irú èrò òdì bẹ́ẹ̀ lè kó ìṣòro ńlá bá ìgbéyàwó.—Fi wé Òwe 21:9.
• Bí ìṣòro kan bá yọjú, ṣé mo máa ń ní sùúrù, àbí ṣe ni mò ń fara ya?—Gálátíà 5:19, 20.
A pàṣẹ fún àwọn Kristẹni láti “lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Kí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ṣègbéyàwó àti lẹ́yìn tí ó bá ti ṣègbéyàwó, ó yẹ kí ó mú agbára láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò dàgbà, ìmọ̀ràn náà ni pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.”—Éfésù 4:26.
Wo Ẹni Tóo Fẹ́ẹ́ Fẹ́
Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Lóòótọ́, bó ṣe yẹ kí ó rí nìyẹn nígbà tí ẹnì kan bá fẹ́ yan ẹni tó fẹ́ẹ́ fẹ́. Yíyan ẹni tí a fẹ́ẹ́ fẹ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ tí ọkùnrin tàbí obìnrin kan lè ṣe. Síbẹ̀, a ti ṣàkíyèsí pé àkókò tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lò láti pinnu irú ọkọ̀ tí wọn yóò rà tàbí irú ilé ẹ̀kọ́ tí wọn yóò lọ ju èyí tí wọ́n ń lò láti fi pinnu irú ẹni tí wọn yóò fẹ́.
Nínú ìjọ Kristẹni, àwọn tí a fa ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ ni ‘a kọ́kọ́ máa ń dán wò láti mọ bí wọ́n ti yẹ sí.’ (1 Tímótì 3:10) Bóo bá ń ronú pé o fẹ́ ṣègbéyàwó, ó yẹ kí o kọ́kọ́ mọ̀ ní àmọ̀dájú bí ẹni tóo fẹ́ẹ́ fẹ́ “ti yẹ sí.” Bí àpẹẹrẹ, gbé àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí yẹ̀ wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbé ìbéèrè náà kalẹ̀ bí ẹni pé obìnrin ló gbé e dìde, àwọn ìlànà náà kan ọkùnrin pẹ̀lú. Àwọn tí wọ́n ti ṣègbéyàwó pàápàá sì lè gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò, kí wọ́n sì jàǹfààní nínú rẹ̀.
• Irú èèyàn wo ni ọkùnrin náà jẹ́?—Fílípì 2:19-22.
Òwe 31:23 ṣàpèjúwe ọkọ kan tí ó jẹ́ “ẹni mímọ̀ . . . ní àwọn ẹnubodè, nígbà tí ó bá jókòó pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin ilẹ̀ náà.” Àwọn àgbà ọkùnrin ìlú máa ń jókòó sí ẹnubodè láti ṣèdájọ́. Nítorí náà, ó hàn gbangba pé, ó di ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán mú láàárín ìlú. Ojú tí àwọn èèyàn fi ń wo ọkùnrin kan ń sọ ohun kan nípa irú ẹni tó jẹ́. Bó bá wà ní ipò kan, ronú nípa ojú tí àwọn tí ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ rẹ̀ fi ń wò ó. Èyí lè jẹ́ kí o mọ ojú tí ìwọ yóò máa fi wò ó nígbà tí o bá di aya rẹ̀.—Fi wé 1 Sámúẹ́lì 25:3, 23-25.
• Irú àwọn ìwà wo ní onítọ̀hún ní?
Ọgbọ́n tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa á “kọ́kọ́ mọ́ níwà.” (Jákọ́bù 3:17) Ṣé títẹ́ ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ tirẹ̀ lọ́rùn ló ṣe pàtàkì jù lójú tirẹ̀ ni, àbí ìdúró rẹ̀ àti tìrẹ níwájú Ọlọ́run? Bó bá jẹ́ pé kì í sapá láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù ti Ọlọ́run nísinsìnyí, ẹ̀rí wo ló wà pé yóò ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣègbéyàwó?—Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12.
• Báwo ló ṣe ń ṣe sí mi?—Éfésù 5:28, 29.
Ìwé Òwe nínú Bíbélì sọ nípa ọkọ kan tí ó “gbẹ́kẹ̀ lé” aya rẹ̀. Ní àfikún sí i, “ó . . . yìn ín.” (Òwe 31:11, 28) Kì í jowú láìnídìí, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í retí ohun tí kò ṣeé ṣe. Jákọ́bù kọ̀wé pé ọgbọ́n tí ó ti òkè wá “lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, . . . ó kún fún àánú àti àwọn èso rere.”—Jákọ́bù 3:17.
• Báwo ló ṣe ń ṣe sí àwọn mẹ́ńbà ìdílé tirẹ̀?—Ẹ́kísódù 20:12.
Bíbọ̀wọ̀ fún òbí ẹni kì í kàn ṣe ohun tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ. Bíbélì sọ pé: “Fetí sí baba rẹ tí ó bí ọ, má sì tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.” (Òwe 23:22) Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, Dókítà W. Hugh Missildine, kọ̀wé pé: “A lè yẹra fún ọ̀pọ̀ ìṣòro ìgbéyàwó àti àìbáramu—tàbí ó kéré tán kí a ti rí wọn tẹ́lẹ̀—bí àwọn tí ń fẹ́ra sọ́nà bá ń ṣèbẹ̀wò sí ilé ara wọn láìsọtẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣàkíyèsí àjọṣe tó wà láàárín ‘àfẹ́sọ́nà’ wọn àti àwọn òbí rẹ̀. Ojú tí ó fi ń wo àwọn òbí rẹ̀ yóò nípa lórí ojú tí yóò fi wo ọkọ tàbí aya rẹ̀. O ní láti béèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mo fẹ́ kó máa ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bó ti ń ṣe sí àwọn òbí rẹ̀?’ Bí àwọn òbí rẹ̀ pẹ̀lú ṣe ń ṣe sí i yóò fi hàn bí òun alára yóò ṣe máa ṣe síra rẹ̀ àti bí yóò ṣe fẹ́ kí o máa ṣe sí òun—lẹ́yìn ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì ẹ̀yìn ìgbéyàwó.”
• Ṣé onínúfùfù ni àbí ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú?
Bíbélì gbani nímọ̀ràn pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.” (Éfésù 4:31) Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún Tímótì nípa àwọn Kristẹni kan tí wọn yóò “jẹ́ olókùnrùn ní èrò orí lórí bíbéèrè ìbéèrè àti fífa ọ̀rọ̀,” tí wọn yóò sì máa lọ́wọ́ nínú “ìlara, . . . gbọ́nmi-si omi-ò-to, ọ̀rọ̀ èébú, ìfura burúkú, awuyewuye lílenípá lórí àwọn ohun tí kò tó nǹkan.”—1 Tímótì 6:4, 5.
Ní àfikún sí i, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ẹni tó bá tóótun fún àwọn àǹfààní àkànṣe nínú ìjọ kò yẹ kó jẹ́ “aluni”—gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, “kò yẹ kó máa kanni lẹ́ṣẹ̀ẹ́.” (1 Tímótì 3:3, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References) Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ń bá àwọn èèyàn jà, yálà ìjà àfẹ̀ṣẹ́jà tàbí ìjà àfẹnujà. Ẹni tó lè hu ìwà ipá bí inú bá ń bí i, kì í ṣe ẹni tó dára láti fẹ́.
• Kí ni àwọn góńgó onítọ̀hún?
Àwọn kan ń lépa ọrọ̀, wọ́n sì ń rí àwọn àbájáde rẹ̀ tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. (1 Tímótì 6:9, 10) Àwọn mìíràn kàn ń fi ìgbésí ayé wọn ṣe ìranù kiri, láìní góńgó kan pàtó tí wọ́n ń lé. (Òwe 6:6-11) Ṣùgbọ́n, ọkùnrin kan tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, yóò ṣe irú ìpinnu tí Jóṣúà ṣe, ẹni tó wí pé: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”—Jóṣúà 24:15.
Èrè Rẹ̀ àti Ẹrù Iṣẹ́ Tó Wé Mọ́ Ọn
Ìgbéyàwò jẹ́ ìṣètò Ọlọ́run. Jèhófà Ọlọ́run ni ó fàṣẹ sí i, òun ló sì dá a sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:22-24) Ó ṣètò ipò lọ́kọláya lọ́nà tí ìdè pípẹ́ títí yóò fi lè wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin kí àwọn méjèèjì bàa lè máa ran ara wọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n bá fi ìlànà Bíbélì sílò, ọkọ àti aya kan lè retí pé kí ìgbésí ayé àwọn jẹ́ aláyọ̀.—Oníwàásù 9:7-9.
Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé a ń gbé ní “àwọn àkókò tí ó nira láti bá lò.” Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àkókò yìí, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, . . . aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, . . . afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.” (2 Tímótì 3:1-4) Àwọn ìwà wọ̀nyí lè ní ipa búburú lórí ìgbéyàwó ẹni. Nítorí náà, ó yẹ kí àwọn tí ń gbèrò àtiṣègbéyàwó ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó wé mọ́ ọn. Ó sì yẹ kí àwọn tí wọ́n ti ṣègbéyàwó máa bá a nìṣó láti mú kí àjọṣe wọn sunwọ̀n sí i nípa kíkọ́ àwọn ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run tí ó wà nínú Bíbélì, kí wọ́n sì máa fi í sílò.
Bẹ́ẹ̀ ni, yóò dára bí àwọn tí ń gbèrò àtiṣègbéyàwó bá jẹ́ kí ìrònú wọn kọjá ọjọ́ ìgbéyàwó. Ó sì yẹ kí gbogbo wa ronú jinlẹ̀ nípa ìgbésí ayé lọ́kọláya kì í kàn-án ṣe ṣíṣègbéyàwó nìkan. Yíjú sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà kí o bàa lè ronú lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu dípò gbígbé ìrònú rẹ ka òòfà ìfẹ́ nìkan. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ìwọ yóò gbádùn ìgbéyàwó aláṣeyọrí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìdí kan ṣoṣo ni Bíbélì sọ pé ó lè fa ìkọ̀sílẹ̀, tí ó sì lè mú kí ó ṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn, ìdí náà sì ni “àgbèrè”—ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó.—Mátíù 19:9.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
“Àpèjúwe Dídára Jù Lọ Tí Mo Tí ì Kà Rí Nípa Ìfẹ́”
Ọ̀mọ̀wé afìṣemọ̀rònú, Kevin Leman kọ̀wé pé: “Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá o ti kó sínú ìfẹ́ ní tòótọ́? Ìwé àtayébáyé kan wà tó ní àpèjúwe ìfẹ́ nínú. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá ọdún báyìí tí ìwé náà ti wà, ṣùgbọ́n àpèjúwe ìfẹ́ tó wà nínú rẹ̀ ṣì ni àpèjúwe dídára jù lọ tí mo tí ì kà rí nípa ìfẹ́.”
Àwọn ọ̀rọ̀ Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí a rí nínú Bíbélì nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4-8 ni Ọ̀mọ̀wé afìṣemọ̀rònú, Leman, ń tọ́ka sí, níbi tó ti sọ pé:
“Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìmọ̀lára Lè Tanni Jẹ
Ó hàn gbangba pé ọmọbìnrin Ṣúlámáítì ti ìgbà tí a kọ Bíbélì mọ agbára ìtannijẹ tí ìfẹ́ tí a gbé ka ìmọ̀lára ní. Nígbà tí Sólómọ́nì, Ọba tí ń gba ìdọ̀bálẹ̀ ọba sọ pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ, ọmọbìnrin náà sọ fún àwọn obìnrin alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pé ‘kí wọ́n má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú òun, títí òun yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru ú sókè.’ (Orin Sólómọ́nì 2:7) Ọlọ́mọge tí orí rẹ̀ pé yìí kò fẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ òun sún òun débi tí òun kò ti ní lè ṣàkóso ìmọ̀lára òun mọ́. Èyí ṣeé mú lò fún àwọn tí ń gbèrò àtiṣègbéyàwó lónìí pẹ̀lú. Ṣàkóso ìmọ̀lára rẹ dáadáa. Bóo bá ṣègbéyàwó, jẹ́ kí ó jẹ́ nítorí pé o nífẹ̀ẹ́ onítọ̀hún, kì í ṣe nítorí èrò pé o kàn fẹ́ ṣègbéyàwó.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn tí wọ́n ti ṣègbéyàwó fún ìgbà pípẹ́ pàápàá lè fún ìdè ìgbéyàwó wọn lókun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Báwo ló ṣe ń ṣe sí àwọn òbí rẹ̀?