ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 4/1 ojú ìwé 3-7
  • Ìwé Àkàkọ́gbọ́n Tí Ìmọ̀ràn Rẹ̀ Wúlò Lóde Ìwòyí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé Àkàkọ́gbọ́n Tí Ìmọ̀ràn Rẹ̀ Wúlò Lóde Ìwòyí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Ha Sorí Kọ́ Bí?
  • Ṣé Ìṣòro Abẹ́lé Ni Tìẹ?
  • Ṣé O Fẹ́ Kí Ìgbésí Ayé Rẹ Yọrí Sí Rere?
  • Ṣé Wàá Tú Àpò Náà?
  • “Aláyọ̀ Ni Ènìyàn Tí Ó Ti Wá Ọgbọ́n Rí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Jèhófà Fẹ́ Kó O Ní Ọgbọ́n Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • “Gbogbo Ìṣúra Ọgbọ́n”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
  • Ṣé Ò Ń Jẹ́ Kí “Ọgbọ́n Tó Wá Láti Òkè” Darí Rẹ?
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 4/1 ojú ìwé 3-7

Ìwé Àkàkọ́gbọ́n Tí Ìmọ̀ràn Rẹ̀ Wúlò Lóde Ìwòyí

JÓÒBÙ, baba ńlá ìgbàanì, tó dájú pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó lọ́rọ̀ jù lọ nígbà ayé rẹ̀, sọ pé: “Ẹ̀kún àpò ọgbọ́n níye lórí ju èyí tí ó kún fún péálì.” (Jóòbù 1:3; 28:18; 42:12) Òdodo ọ̀rọ̀, nítorí pé ọgbọ́n níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn nǹkan ìní ti ara, tó bá dọ̀ràn pé ká ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba sọ pé: “Ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.”—Oníwàásù 7:12.

Ṣùgbọ́n, níbo la ti lè rí irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ lónìí? Àwọn èèyàn máa ń fi ìṣòro wọn lọ àwọn elétíi-gbáròyé inú ìwé ìròyìn, àwọn afìṣemọ̀rònú, oníṣègùn ọpọlọ, kódà wọ́n tilẹ̀ máa ń fi lọ àwọn aṣerunlọ́ṣọ̀ọ́ àti àwọn onítakisí. Mélòó sì la fẹ́ kà lára àìmọye àwọn ògbógi tí wọ́n ti wà ní sẹpẹ́ láti pèsè ìmọ̀ràn lórí ìṣòro èyíkéyìí—lówó pọ́ọ́kú sì ni. Àmọ́ ṣá o, irú àwọn ọ̀rọ̀ “ọgbọ́n” bẹ́ẹ̀ ti yọrí sí ìjákulẹ̀ gbáà, àní ó tilẹ̀ ti yọrí sí àgbákò. Báwo wá ni a ṣe lè rí ọgbọ́n tòótọ́?

Jésù Kristi, tó ní òye jíjinlẹ̀ nípa ìgbòkègbodò ọmọ aráyé, sọ nígbà kan rí pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣòro kan tó wọ́pọ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn, ká sì rí àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó ti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní tòótọ́, tó sì níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ‘ẹ̀kún àpò péálì.’ Ìwọ náà lè rí “ẹ̀kún àpò ọgbọ́n” yẹn, kí o sì jàǹfààní láti inú rẹ̀.

O Ha Sorí Kọ́ Bí?

Ìwé ìròyìn náà, International Herald Tribune ti London, sọ pé: “Bó bá jẹ́ pé ọ̀rúndún ogún yìí ni Sànmánì Híhàhílo wọlé dé, a jẹ́ pé bí ọ̀rúndún ogún yìí ti ń kógbá sílé ni Sànmánì Másùnmáwo ń wọlé dé.” Ó fi kún un pé “ìwádìí àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe kárí ayé lórí ìsoríkọ́ lílékenkà, fi hàn pé ṣe ni ìsoríkọ́ kàn ń pọ̀ sí i ṣáá. Nínú àwọn ọ̀kan-kò-jọ̀kan orílẹ̀-èdè bíi Taiwan, Lẹ́bánónì àti New Zealand, ṣe ni àrùn yìí túbọ̀ ń jàrábà ìran kan tẹ̀ lé òmíràn.” Wọ́n sọ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn táa bí lẹ́yìn ọdún 1955 dojú kọ akọ ìsoríkọ́ tó fi ìlọ́po mẹ́ta ga ju èyí tó yọ àwọn òbí wọn àgbà lẹ́nu.

Bọ́ràn ṣe rí nìyí fún Tomoe, tí akọ ìsoríkọ́ dé bá, tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń wà lórí bẹ́ẹ̀dì. Nítorí àìlè tọ́jú ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún méjì, ó kó padà sílé àwọn òbí ẹ̀. Kò pẹ́ tí aládùúgbò kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ pẹ̀lú ọmọkùnrin Tomoe jọ jẹ́ ẹgbẹ́, dọ̀rẹ́ Tomoe. Nígbà tí Tomoe sọ fún un pé òun ò rò pé òun wúlò rárá, aládùúgbò náà fi ọ̀rọ̀ kan hàn án nínú ìwé kan. Ọ̀rọ̀ náà kà pé: “Ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé: ‘Èmi kò nílò rẹ’; tàbí, ẹ̀wẹ̀, orí kò lè sọ fún ẹsẹ̀ pé: ‘Èmi kò nílò rẹ.’ Ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, bí ọ̀ràn ti rí ni pé àwọn ẹ̀yà ara tí ó dà bí ẹni pé ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera jẹ́ kò-ṣeé-má-nìí.”a Omi fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ lójú Tomoe bó ti wá mọ̀ pé kò sẹ́ni tó wà láyé yìí tí kò wúlò láyè tirẹ̀.

Aládùúgbò náà dámọ̀ràn pé kó ṣàyẹ̀wò ìwé tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn wà nínú rẹ̀. Tomoe gbà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kó tó dìgbà yẹn, kò lè ṣe nǹkan kan, kì í tilẹ̀ gbà láti wọnú àdéhùn kankan, bó ti wù kó kéré mọ. Aládùúgbò náà tún ń bá a lọ ra nǹkan lọ́jà, òun àti Tomoe sì jọ ń gbọ́ oúnjẹ lójoojúmọ́. Lóṣù kan lẹ́yìn náà, Tomoe ń jí láràárọ̀, ó ń fọṣọ, ó ń gbálẹ̀ ilé, ó ń lọ sọ́jà, ó ń gbọ́ oúnjẹ, àní ó ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tí ìyàwó ilé ń ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro púpọ̀ ń bẹ láti borí, ó sọ pé, “Ó dá mi lójú pé bí mo bá sáà lè tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́, ayé mi yóò dáa.”

Nítorí pé Tomoe lo ọgbọ́n tó rí kọ́, ó ṣẹ́pá àwọn ọjọ́ ìdààmú tí ìsoríkọ́ rẹ̀ fà. Ní báyìí o, iṣẹ́ alákòókò kíkún ni Tomoe ń ṣe lọ ràì, ó ń fi ìyẹn ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, kí àwọn náà lè lo àwọn ọ̀rọ̀ kan náà tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti rí ojútùú sí àwọn ìṣòro rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n wọnnì wà nínú ìwé àtayébáyé kan tí ìmọ̀ràn rẹ̀ wúlò fún gbogbo èèyàn òde ìwòyí.

Ṣé Ìṣòro Abẹ́lé Ni Tìẹ?

Kárí ayé, ṣe ni iye ìkọ̀sílẹ̀ kàn ń bú rẹ́kẹ́. Àwọn ìṣòro abẹ́lé ń pọ̀ sí i, kódà ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn, níbi tí okùn ọmọ ìyá ti yi, tí ìṣọ̀kan ìdílé sì jẹ́ ohun àmúyangàn láyé ijọ́un. Níbo la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó mọ́gbọ́n dání tí yóò gbéṣẹ́ nínú ìgbéyàwó?

Gbé ọ̀ràn Shugo àti Mihoko yẹ̀ wò, tọkọtaya tó ní ìṣòro jáǹrẹrẹ nínú ìgbéyàwó wọn. Gbogbo nǹkan ló máa ń díjà sílẹ̀ láàárín wọn. Oníbìínú èèyàn ni Shugo, Mihoko aya rẹ̀ sì máa ń fìbínú dáhùn padà ní gbogbo ìgbà tí ọkọ rẹ̀ bá ń di ẹ̀bi rù ú. Mihoko tilẹ̀ ronú pé, ‘Ẹnu wa kò lè kò láé.’

Lọ́jọ́ kan, obìnrin kan bẹ Mihoko wò, ó ṣí ìwé kan, ó sì ka ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí sétígbọ̀ọ́ rẹ̀: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkàn Mihoko kò sí nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn, ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé tí wọ́n ti ka ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn jáde. Ohun tó jẹ obìnrin yìí lógún ni bí àlàáfíà ṣe lè jọba nínú ìdílé rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n ké sí i pé kó ká lọ sí ìpàdé tí wọn yóò ti jíròrò ìwé náà, Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ, tayọ̀tayọ̀ ni Mihoko—àti ọkọ rẹ̀—fi lọ.c

Níbi ìpàdé náà, Shugo ṣàkíyèsí pé àwọn tó wà níbẹ̀ ń lo ohun tí wọ́n ń kọ́ ní tòótọ́, ó sì jọ pé wọ́n láyọ̀ gan-an. Ó pinnu pé òun náà yóò wá àyè ka ìwé tí ìyàwó òun ń kẹ́kọ̀ọ́. Kò pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí kà á tó fi rí gbólóhùn kan tó wọ̀ ọ́ lára, gbólóhùn náà ni: “Ẹni tí ó bá lọ́ra láti bínú pọ̀ yanturu ní ìfòyemọ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́ aláìnísùúrù ń gbé ìwà òmùgọ̀ ga.”d Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbà á lákòókò láti fi ìlànà yìí sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ó ń ṣe ìyípadà ní wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, èyí sì hàn sí àwọn tó wà láyìíká rẹ̀, títí kan ìyàwó rẹ̀.

Nígbà tí Mihoko rí àwọn ìyípadà tí ọkọ rẹ̀ ṣe, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí fi ohun tó ń kọ́ sílò. Ìlànà kan tó ṣèrànwọ́ gan-an nìyí: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́.”e Nítorí náà, Mihoko àti ọkọ rẹ̀ pinnu pé àwọn yóò máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ibi táwọn ti ń ṣe dáadáa, àti bí àwọn ṣe lè ṣàtúnṣe ní àwọn ibi yòókù, dípò kí àwọn máa di ẹ̀bi ru ẹnì kìíní kejì. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Mihoko rántí pé: “Ó fún mi láyọ̀ ní ti gidi. A ti ń ṣe èyí nídìí oúnjẹ ní alaalẹ́. Kódà, ọmọkùnrin wa ọlọ́dún mẹ́ta máa ń dá sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ náà. Ó tù wá lára gan-an!”

Nígbà tí ìdílé yìí lo ìmọ̀ràn rere tí wọ́n rí gbà, wọ́n ṣẹ́pá àwọn ìṣòro tó fẹ́ já ìdè ìdílé wọn. Ìmọ̀ràn yẹn kò ha sàn ju ẹ̀kún àpò péálì bí?

Ṣé O Fẹ́ Kí Ìgbésí Ayé Rẹ Yọrí Sí Rere?

Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé kíkó ọrọ̀ jọ ni góńgó tí wọ́n ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lé kiri. Bẹ́ẹ̀, oníṣòwò kan tó lówó bí ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tó ti fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù owó dọ́là ṣètọrẹ àánú, sọ nígbà kan rí pé: “Àwọn kan ń wá owó kiri lójú méjèèjì, ṣùgbọ́n kò sẹ́ni tó lè wọ bàtà méjì pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà.” Díẹ̀ làwọn èèyàn tó gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, síbẹ̀ àwọn tí iye wọ́n kéré jọjọ, ló lè ṣíwọ́ lílépa ọrọ̀.

Ìdílé tálákà la bí Hitoshi sí, nítorí náà, bó ṣe máa di ọlọ́rọ̀ ló wà ní góńgó ẹ̀mí ẹ̀. Lẹ́yìn tó rí bí àwọn ayánilówó ti ń fá àwọn èèyàn lórí tí wọ́n sì ń fọ̀dà kùn ún, ó sọ pé: “Olówó ló ṣohun gbogbo tán.” Níbi tí ọ̀ràn owó ká Hitoshi lára dé, ó gbà pé ó lè ra ẹ̀mí èèyàn. Kí ó lè rí towó ṣe, ó tẹpá mọ́ṣẹ́ ẹ̀rọ omi tó ń ṣe, ó ń fi ojoojúmọ́ ayé ṣiṣẹ́ bí agogo, láìsí ìsinmi. Bí Hitoshi ti ń fi torí tọrùn ṣe tó, kò pẹ́ tó fi wá mọ̀ pé, òun tóun jẹ́ agbaṣẹ́ṣe lọ́wọ́ kọngílá, tí òun sì fẹ́ máa ṣe gbogbo ohun tí kọngílá ń ṣe, bí ọ̀ràn labalábá tó ń fira rẹ̀ wé ẹyẹ lọ̀ràn náà rí. Ojoojúmọ́ ló wá ń rí i pé òmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀, ó tilẹ̀ tún wá ń bẹ̀rù pé òun lè wọko gbèsè.

Nígbà náà ni ẹnì kan wá sẹ́nu ọ̀nà Hitoshi, ó sì bi í bóyá ó mọ̀ pé Jésù Kristi kú fóun. Níwọ̀n bí Hitoshi ti nímọ̀lára pé kò sẹ́ni tó lè kú fún irú èèyàn bíi tòun, ó fẹ́ tọpinpin ọ̀rọ̀ náà, ó sì gbà pé kí àwọn jọ jíròrò síwájú sí i. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó lọ síbi àsọyé kan, ó sì yà á lẹ́nu nígbà tó gbọ́ ìmọ̀ràn náà pé kí ‘ojú èèyàn mú ọ̀nà kan.’ Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé ojú tó “mú ọ̀nà kan” jẹ́ èyí tó lè rí nǹkan tó jìnnà réré, tó sì gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí; lódìkejì ẹ̀wẹ̀, kìkì àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ni ojú tó bá “burú,” tàbí tí “ń ṣe ìlara,” máa ń gbájú mọ́, irú ojú bẹ́ẹ̀ kì í sì í rí ọ̀ọ́kán. Ìmọ̀ràn náà, “Ibi tí ìṣúra rẹ bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú,” wọ̀ ọ́ lákínyẹmí ara.f Ohun kan wà tó tún ṣe pàtàkì ju kíkó ọrọ̀ jọ! Kò gbọ́ irú rẹ̀ rí.

Nítorí pé ọ̀rọ̀ yìí wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi nǹkan tó ń kọ́ sílò. Dípò tí ì bá fi máa ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó nítorí àtilà, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó tún ṣètò àkókò fún bíbójútó ire tẹ̀mí ìdílé rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, èyí dín àkókò iṣẹ́ kù, síbẹ̀ ṣe ni owó túbọ̀ ń wọlé fún un. Èé ṣe?

Bí ó ti ń gba ìmọ̀ràn tí wọ́n ń fún un, gbogbo jàgídíjàgan rẹ̀ rọlẹ̀ wọ̀ọ̀, ó sì wá di oníwà tútù àti èèyàn jẹ́jẹ́. Ìmọ̀ràn tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn púpọ̀púpọ̀ ni: “Ní ti gidi, ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín. Ẹ má ṣe máa purọ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a.”g Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí kò sọ ọ́ dọlọ́rọ̀, ṣùgbọ́n “àkópọ̀ ìwà tuntun” rẹ̀ jẹ́ kí àwọn oníbàárà rẹ̀ máa fojú rere wò ó, wọ́n wá gbẹ́kẹ̀ lé e, wọ́n sì fọkàn tán an. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó gbọ́ jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ̀ yọrí sí rere. Ní tirẹ̀ o, lóòótọ́ ni ìmọ̀ràn yẹn níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju ẹ̀kún àpò péálì tàbí ẹ̀kún àpò owó.

Ṣé Wàá Tú Àpò Náà?

Ǹjẹ́ o lè dá ẹ̀kún àpò ọgbọ́n mọ̀, èyí tó ti wúlò gan-an fún àwọn èèyàn táa mẹ́nu kàn lókè yìí? Èyí ni ọgbọ́n tí a rí nínú Bíbélì, ìwé tí a pín kiri jù lọ, tó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Àfàìmọ̀ kí o máà ní ẹ̀dà kan lọ́wọ́, bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, àtirí ọ̀kan rà kò lè nira. Ṣùgbọ́n o, gan-an gẹ́gẹ́ bí níní ẹ̀kún àpò péálì tó ṣeyebíye, ká má sì lò ó lọ́nà tó yẹ, kò ti lè ṣe ẹni tó ni ín láǹfààní, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwulẹ̀ ní Bíbélì níkàáwọ́ láìlò ó kò ní ṣàǹfààní. O ò ṣe kúkú tú àpò náà, ká sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀, kí o sì fi ìmọ̀ràn àti ìṣílétí Bíbélì tó bọ́gbọ́n mu, tó bákòókò mu sílò, kí o wá rí i bí yóò ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé.

Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan fún ẹ ní ẹ̀kún àpò péálì, ǹjẹ́ o ò ní fi ìmọrírì hàn, ǹjẹ́ o ò ní gbìyànjú láti mọ ẹni tí olóore náà jẹ́, kí o lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀? Nínú ọ̀ràn ti Bíbélì, ǹjẹ́ o mọ Ẹni tó fún wa?

Bíbélì fi Orísun ọgbọ́n tó wà nínú rẹ̀ hàn nígbà tó sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.” (2 Tímótì 3:16) Ó tún sọ fún wa pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì fi bọ́ sákòókò, tó sì wúlò fún wa lóde ìwòyí. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, Ọlọ́run Oníbú Ọrẹ yìí, kí ó bàa lè ṣeé ṣe fún ẹ láti jàǹfààní láti inú “ẹ̀kún àpò ọgbọ́n” tó wà nínú Bíbélì—ìwé àkàkọ́gbọ́n tí ìmọ̀ràn rẹ̀ wúlò fún àwọn èèyàn òde ìwòyí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Inú 1 Kọ́ríńtì 12:21, 22 lọ̀rọ̀ yẹn ti wá.

b Mátíù 7:12.

c Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ ìwé yìí jáde.

d Òwe 14:29.

e Mátíù 7:1, 2.

f Mátíù 6:21-23; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References.

g Kólósè 3:8-10.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tí Ń Fini Lọ́kàn Balẹ̀

“Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.”—Sáàmù 130:3, 4.

“Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú máa ń ní ipa rere lórí ìrísí, ṣùgbọ́n nítorí ìrora ọkàn-àyà, ìdààmú máa ń bá ẹ̀mí.”—Òwe 15:13.

“Má di olódodo àṣelékè, tàbí kí o fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó gbọ́n ní àgbọ́njù. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi fa ìsọdahoro wá bá ara rẹ?”—Oníwàásù 7:16.

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

“Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.”—Éfésù 4:26.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tó Lè Mú Kí Ìdílé Jẹ́ Aláyọ̀

“Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.”—Òwe 15:22.

“Ọkàn-àyà olóye ń jèrè ìmọ̀, etí àwọn ọlọ́gbọ́n sì ń wá ọ̀nà láti rí ìmọ̀.”—Òwe 18:15.

“Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.”—Òwe 25:11.

“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:13, 14.

“Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n. Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.”—Jákọ́bù 1:19.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tó Lè Mú Kí Ìgbésí Ayé Ẹni Yọrí Sí Rere

“Òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì tí a fi ń rẹ́ni jẹ jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n òkúta àfiwọn-ìwúwo tí ó pé pérépéré jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.”—Òwe 11:1.

“Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.”—Òwe 16:18.

“Bí ìlú ńlá tí a ya wọ̀, láìní ògiri, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí kò kó ẹ̀mí rẹ̀ níjàánu.”—Òwe 25:28.

“Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya, nítorí pé fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn.”—Oníwàásù 7:9.

“Fọ́n oúnjẹ rẹ sí ojú omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò tún rí i.”—Oníwàásù 11:1.

“Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.”—Éfésù 4:29.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ síhà jíjàǹfààní láti inú “ẹ̀kún àpò ọgbọ́n”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́