Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Wíwàásù ‘ní Àsìkò Tí Ó Rọgbọ àti ní Àsìkò Tí Ó Kún fún Ìdààmú’
NÍGBÀ tí ogun jà jákèjádò orílẹ̀-èdè Bosnia àti Herzegovina, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló bẹ̀rẹ̀ sí ráágó. Nígbà ìpọ́njú yẹn, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sa gbogbo ipá wọn láti fún àwọn èèyàn ibẹ̀ ní ìṣírí àti ìrètí. Ẹlẹ́rìí kan tó sìn ní Sarajevo fúngbà díẹ̀ ló kọ lẹ́tà táa ṣàyọkà rẹ̀ nísàlẹ̀ yìí.
“Ìyà ń jẹ pásapàsa sáwọn èèyàn lára níbí o, ṣùgbọ́n wọ́n ń fi tọkàntọkàn tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì. Mo gbédìí fún Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń gbé lágbègbè yìí nítorí ìfaradà wọn. Nípa tara, wọn ò ní gá, wọn ò ní go, ṣùgbọ́n wọ́n ní ẹ̀mí rere. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wà nínú ìjọ ni wọ́n wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ìtara yìí ń fún àwọn akéde tuntun níṣìírí, ọ̀pọ̀ lára wọn tilẹ̀ máa ń lo ọgọ́ta wákàtí tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láàárín oṣù kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, àní lóṣù tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí jáde nínú iṣẹ́ ìsìn.
“Ní àfikún sí wíwàásù láti ilé dé ilé, a ti gbìyànjú onírúurú ọ̀nà táa lè gbà rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀. Fún àpẹẹrẹ, pípín àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì ní ọ̀pọ̀ itẹ́ òkú tó wà ní ìlú náà ti kẹ́sẹ járí.
“A tún ń jẹ́rìí nínú àwọn ilé ìwòsàn. Ní Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Nípa Ọkàn-Àyà ní ilé ìwòsàn kan ní Sarajevo, oníṣègùn àgbà tó wà níbẹ̀ gba Jí! [lédè Gẹ̀ẹ́sì] ti December 8, 1996, tí àkọlé ẹ̀yìn rẹ̀ kà pé ‘Ìkọlù Àrùn Ọkàn-Àyà—Kí Ni A Lè Ṣe?’ Ó béèrè fún ẹ̀dà púpọ̀ sí i, kí ó bàa lè pín wọn fún àwọn dókítà yòókù. Ó wá gba àwọn Ẹlẹ́rìí láyè láti bẹ gbogbo àwọn aláìsàn tó wà ní ẹ̀ka iṣẹ́ rẹ̀ wò. Nítorí náà, ní èyí tó fi díẹ̀ lé ní wákàtí kan, ìwé ìròyìn táa pín láti orí bẹ́ẹ̀dì kan dé orí bẹ́ẹ̀dì mìíràn lé ní ọgọ́rùn-ún. Ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ló sọ pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ẹnikẹ́ni tíì bẹ̀ wọ́n wò ní ilé ìwòsàn láti fún wọn níṣìírí àti ìrètí.
“Ní àkókò mìíràn a bẹ Ẹ̀ka Tí Ń Tọ́jú Àwọn Ọmọdé wò, a sì kó àwọn àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn wa dání tó bá àwọn ọmọdé mu. Oníṣègùn àgbà tó wà níbẹ̀ tún gba ẹ̀dá mélòó kan ìwé náà, Iwe Itan Bibeli Mi, láti fi sínú yàrá ìkàwé. Ní báyìí o, àwọn ìyá tó bá wá bẹ ọmọ wọn wò ní ilé ìwòsàn máa ń ka àwọn ìtàn Bíbélì sí wọn létí lójoojúmọ́. A tún ṣètò láti bẹ dókítà yìí wò ní ilé rẹ̀.
“Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn sójà NATO [Ẹgbẹ́ Alájọṣe ti Àríwá Òkun Àtìláńtíìkì] tí wọ́n ti onírúurú orílẹ̀-èdè wá ló wà ní Sarajevo. A ti jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú. Nígbà mìíràn, a máa ń lọ láti ìdí ọkọ̀ afọ́nta kan dé ìdí ọkọ̀ afọ́nta mìíràn, tí a ó máa lo ìwé pẹlẹbẹ náà, Good News for All Nations àti ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní onírúurú èdè. Ìwé ìròyìn táa pín nínú àwọn bárékè àwọn ọmọ ogun Ítálì lé ní igba. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wa nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun Ítálì sọ pé àwọn kò tíì bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ rí. Tóò, a kàn wọ́n lára ní ìlú Sarajevo.
“Lọ́jọ́ kan, ọkọ̀ afọ́nta dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Mo fi agbòjò mi kan ọkọ̀ náà ko-ko-ko, sójà kan sì jáde wá. Mo fi Ilé Ìṣọ́ kan lọ̀ ọ́ tí àkọlé ẹ̀yìn rẹ̀ kà pé ‘Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà—Ta Ni Wọ́n?’ Sójà náà wò mí lójú, ó sì béèrè pé, ‘Ṣé ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́?’ Lẹ́yìn tó mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni mí, ó fèsì pé, ‘Ó ga o; ìyẹn ni pé ẹ tún máa ń débí! Ǹjẹ́ ibì kankan wà láyé tí Àwọn Ẹlẹ́rìí kò sí?’”
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.” (2 Tímótì 4:2) Gẹ́gẹ́ bí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn jákèjádò ayé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Sarajevo ń ṣe bẹ́ẹ̀, kódà láti orí bẹ́ẹ̀dì dé orí bẹ́ẹ̀dì àti láti ìdí ọkọ̀ afọ́nta kan dé ìdí ọkọ̀ afọ́nta mìíràn!