ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 4/1 ojú ìwé 23-27
  • Mò Ń wá Párádísè Kiri

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mò Ń wá Párádísè Kiri
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Padà Sóko
  • Ìgbàgbọ́ Mi Nínú Ọlọ́run Sọ Jí
  • Ìdáhùn sí Àwọn Àdúrà Mi
  • Títẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí
  • Ìrànwọ́ Nígbà Hílàhílo
  • Nínàgà fún Ohun Mìíràn Tí Ó Sàn Jù
  • Bẹ́tẹ́lì—Arabaríbí Párádísè Tẹ̀mí
  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Gbogbo Ìgbà Ni Mò Ń Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Gbogbo Èèyàn La Pè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 4/1 ojú ìwé 23-27

Mò Ń wá Párádísè Kiri

GẸ́GẸ́ BÍ PASCAL STISI ṢE SỌ Ọ́

Ààjìn ti jìn, gbogbo ìgboro ìlú Béziers, ní gúúsù ilẹ̀ Faransé, sì ti dá kése. Rírí tí èmi pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi rí ilé ìtàwé ẹ̀sìn kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kùn, ni àwa náà bá fi ọ̀dà dúdú kọ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n èrò orí ọmọ ilẹ̀ Germany náà, Nietzsche, sí i lára gàdàgbà pé: ‘Àwọn ọlọ́run ti kú. Kí àjíǹde ara máa jẹ́ ọ, ìwọ Akọni Ọkùnrin!’ Ẹ gbọ́ ná, kí ló sún mi dé gbogbo èyí tí mò ń ṣe yìí?

A BÍ mi nílẹ̀ Faransé, lọ́dún 1951, sínú ìdílé ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tí ó wá láti ilẹ̀ Ítálì. Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, a máa ń lọ lo ìsinmi ní gúúsù ilẹ̀ Ítálì. Níbẹ̀, ìdílé kọ̀ọ̀kan ló ní ère Màríà Wúńdíá tirẹ̀. Mo máa ń tẹ̀ lé baba mi àgbà, nígbà tí a bá ń bá àwọn èrò kọ́wọ̀ọ́ rìn tẹ̀ lé àwọn ère ńlá tí a wọ̀ láṣọ, bí a ti ń rìn gba àwọn orí òkè lọ—àmọ́ n kò nígbàgbọ́ eléépìnnì nínú wọn. Ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn kan tí àwọn onísìn Jesuit dá sílẹ̀ ni mo ti parí ìwé àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ mi. Ṣùgbọ́n, n kò rántí pé mo gbọ́ ohunkóhun tó gbé ìgbàgbọ́ mi ró nínú Ọlọ́run.

Ìgbà tí mo wọlé sí yunifásítì ní Montpellier láti kẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn ni mo tó bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí ète ìgbésí ayé. Baba mi ti fara gbọgbẹ́ nígbà ogun, ìgbà gbogbo sì ni àwọn dókítà máa ń wà lẹ́bàá ibùsùn rẹ̀. Kò ha ní sàn jù láti fòpin sí ogun dípò tí a óò fi máa lo àkókò púpọ̀, tí a óò sì máa sá sókè sódò láti wo àwọn tí ogun ṣe léṣe sàn bí? Síbẹ̀, Ogun Vietnam gbóná janjan. Fún àpẹẹrẹ, ní èrò tèmi, ọ̀nà kan ṣoṣo tó bọ́gbọ́n mu tí a lè gbà tọ́jú jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró ni láti yẹra fún ohun tó ń fa àrùn náà gan-an—ìyẹn ni tábà. Àìsàn tó ń jẹyọ láti inú àìjẹunre-kánú ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà àti àrùn tí àjẹjù oúnjẹ ń fà ní àwọn ilẹ̀ tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù ńkọ́? Kò ha ní sàn jù láti mú ohun tó ń fa àwọn àìsàn yìí kúrò dípò gbígbìyànjú láti ṣàtúnṣe sí àwọn àbájáde rẹ̀ tí ń bani nínú jẹ́? Kí ló fà á tí ìjìyà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? Mo gbà pé aburú kan ti ṣẹlẹ̀ sí àwùjọ oníkúpani yìí, èrò mi sì ni pé ìjọba ló jẹ̀bi.

Adájọ̀ngbọ̀n-sílẹ̀ ni ọ̀gbẹ́ni tó kọ ìwé tí mo fẹ́ràn jù lọ, mo sì máa ń ṣàdàkọ àwọn gbólóhùn kan nínú rẹ̀ sára ògiri. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, èmi pẹ̀lú di adájọ̀ngbọ̀n-sílẹ̀, n kò nígbàgbọ́ nínú ohunkóhun mọ́, kò sì sí òfin ìwà rere kan tí mo jẹ́ kó darí mi, n kò fẹ́ Ọlọ́run kankan, n kò sì fẹ́ ọ̀gá kankan. Lójú tèmi, àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn èèyàn sàràkí-sàràkí ló hùmọ̀ èrò pé Ọlọ́run kan ń bẹ, àwọn náà ló sì dá ẹ̀sìn sílẹ̀ kí wọn bàa lè jẹ gàba lé àwa yòókù lórí, kí wọ́n sì lè rẹ́ wa jẹ́. Ohun tó jọ pé wọ́n sábà máa ń sọ ni pé: ‘Ẹ ṣiṣẹ́ kára nítorí tiwa lórí ilẹ̀ ayé, èrè yin yóò sì pọ̀ ní párádísè ni ọ̀run.’ Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́run ti lògbà tiwọn kọjá. Ó yẹ kí a jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀. Kíkọ ìkọkúkọ sígboro sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí a fi lè sọ fún wọn.

Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, n kò fọwọ́ dan-in dan-in mú ẹ̀kọ́ mi mọ́. Láàárín àkókò yìí, mo ti forúkọ sílẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ nípa ilẹ̀ ayé, ìwàláàyè inú rẹ̀ àti àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn ní yunifásítì mìíràn tó wà ní Montpellier, níbi tí ètò ìdìtẹ̀mọ́jọba ti gbalé gbòde. Bí mo ti ń lọ jìnnà sí i nínú ẹ̀kọ́ nípa àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn, bẹ́ẹ̀ ni rírí i pé a ń ba pílánẹ́ẹ̀tì wa ẹlẹ́wà jẹ́ túbọ̀ ń bí mi nínú.

Lọ́dọọdún, nígbà ìsinmi ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, mo máa ń wọ sọọ́lẹ̀ kiri, mò ń kárí ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà jákèjádò Yúróòpù. Bí mo ti ń rìnrìn àjò kiri, tí mo sì ń bá ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn awakọ̀ sọ̀rọ̀, mo fojú ara mi rí ìwà ibi àti ìwà ìbàjẹ́ tí ń pọ́n àwùjọ ènìyàn lójú. Nígbà kan, níbi tí mo ti ń wá párádísè kiri, mo dé àwọn etíkun kíkọyọyọ ní erékùṣù ẹlẹ́wà tó wà ní Kírétè, mo sì rí i pé epo ti dà sí gbogbo ojú rẹ̀. Ọkàn mi gbọgbẹ́. Ibì kan ha tún wà tí a lè pè ní párádísè lórí ilẹ̀ ayé yìí bí?

Mo Padà Sóko

Ní ilẹ̀ Faransé, àwọn onímọ̀ nípa àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn ń ṣalágbàwí pípadà sóko gẹ́gẹ́ bí ojútùú sí wàhálà tó dé bá àwùjọ náà. Mo fẹ́ máa fi ọwọ́ ara mi ṣiṣẹ́. Nítorí náà, mo ra ilé àtijọ́ kan tí a fi òkúta kọ́ nínú ìletò kan nísàlẹ̀ àwọn òkè tó wà ní Òkè Cévennes, ní gúúsù ilẹ̀ Faransé. Ohun tí mo kọ sẹ́nu ilẹ̀kùn mi nìyí: “Párádísè Ìsinsìnyí,” ọ̀rọ̀ amóríwú tó wọ́pọ̀ lẹ́nu àwọn abẹ́gbẹ́yodì ará Amẹ́ríkà. Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Germany kan tó ń kọjá lọ lágbègbè wa di alábàágbé mi. Kò sí ohun tó lè mú kí n ṣègbéyàwó níwájú olórí ìlú láé, ẹni tó jẹ́ pé aṣojú ìjọba ní í ṣe. Ìgbéyàwó ṣọ́ọ̀ṣì ńkọ́? Gbàgbé ẹ̀!

Nígbà tó pọ̀ jù lọ, ẹsẹ̀ lásán la fi máa ń rìn kiri, mo dá irun mi sí, irùngbọ̀n mi pẹ̀lú sì ṣe yàwìrì-yàwìrì. Dídọ́gbìn èso àti ewébẹ̀ fà mí mọ́ra. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ojú ọ̀run máa ń dúdú bí aró, àwọn ẹ̀dá kan bí ìrẹ̀ a sì máa han gooro. Òórùn dídùn àwọn òdòdó igi á gba gbogbo igbó kan, àwọn èso Mẹditaréníà tí a ń gbìn—èso àjàrà àti ti ọ̀pọ̀tọ́—sì máa ń níṣu mùkẹ̀mukẹ! Àfi bíi pé a ti rí ibi tí ohun gbogbo tí a nílò láti gbé ìgbésí ayé ti lè tẹ̀ wá lọ́wọ́ nínú párádísè.

Ìgbàgbọ́ Mi Nínú Ọlọ́run Sọ Jí

Ní yunifásítì, mo ti kọ́ nípa ohun alààyè onísẹ́ẹ̀lì, ọlẹ̀, àti ẹ̀yà ara, bí àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí ṣe díjú tó, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ wú mi lórí gidigidi. Nísinsìnyí tó jẹ́ pé ojúmọ́ kan kò ní mọ́ kí n má ronú nípa ìṣẹ̀dá ní tààràtà, tí mo sì lè wò ó láwòfín, kàyéfì ńlá ni ẹwà rẹ̀ àti àwọn ohun tí ó lè ṣe jẹ́ fún mi. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, bẹ́ẹ̀ ni mo túbọ̀ ń rí ọ̀pọ̀ ohun tí Ọlọ́run dá. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mo ti rìn rìn ní àgbègbè olókè kan, tí mo sì ti ronú jinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé, mo dé orí ìparí èrò náà pé Ẹlẹ́dàá kan gbọ́dọ̀ wà. Mo pinnu lọ́kàn mi láti gba Ọlọ́run gbọ́. Ṣáájú àkókò yìí, gbogbo nǹkan sú mi látọkànwá, ọkàn mí dà rú torí pé mo dá wà. Ọjọ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, mo sọ fún ara mi pé, ‘Pascal, o ò ní dá nìkan wà mọ́.’ Ìmọ̀lára àrà ọ̀tọ̀ gbáà lèyí jẹ́.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, alábàágbé mi bí ọmọbìnrin kékeré kan fún mi—Amandine lórúkọ ẹ̀. Mo fẹ́ràn ọmọdébìnrin náà bí ẹyinjú mi. Nísinsìnyí tí mo ti wá gba Ọlọ́run gbọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀wọ̀ fún àwọn òfin ìwà rere díẹ̀ tí mo mọ̀. Mo jáwọ́ nínú olè jíjà àti irọ́ pípa, kò sì pẹ́ tí mo fi mọ̀ pé èyí ràn mí lọ́wọ́ láti yẹra fún ọ̀pọ̀ ìṣòro tó lè da àárín èmi àtàwọn tó yí mi ká rú. Bẹ́ẹ̀ ni, a ní ìṣòro tiwa, kì í sì í ṣe irú párádísè ti mo retí ni mo bá ara mi yìí. Àwọn tí ń gbin èso àjàrà ládùúgbò ń lo oògùn apakòkòrò àti pagipagi, tó jẹ́ pé ó máa ń ba nǹkan ọ̀gbìn mi jẹ́. Síbẹ̀, n kò tí ì rí ìdáhùn sí ìbéèrè mi nípa ìwà ibi. Ìyẹn nìkan kọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ka ọ̀pọ̀ ìsọfúnni nípa ìgbésí ayé ìdílé, èyí kò dín ìjiyàn gbígbóná janjan tó máa ń wáyé láàárín èmi àti alábàágbé mi kù. A láwọn ọ̀rẹ́ bí mélòó kan, àmọ́ ọ̀rẹ́ èké ni gbogbo wọn; àwọn kan tilẹ̀ gbìyànjú láti mú kí alábàágbé mi máa bá àwọn dálè. Párádísè mí-ìn, tó sàn ju èyí lọ, gbọ́dọ̀ wà.

Ìdáhùn sí Àwọn Àdúrà Mi

Lọ́nà tèmi, mo sábà máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run láti máa darí ìgbésí ayé mi. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday kan, obìnrin kan tó yá mọ́ni, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́, Irène Lopez, àti ọmọdékùnrin rẹ̀ wá sẹ́nu ọ̀nà wa. Ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóbìnrin yìí. Mo tẹ́tí sí ohun tó fẹ́ sọ, mo sì gbà á láyè láti máa padà wá. Àwọn ọkùnrin méjì ló padà wá rí mi. Nínú ìjíròrò wa, ohun méjì ni mo fi sọ́kàn—Párádísè àti Ìjọba Ọlọ́run. Mo fi àwọn nǹkan wọ̀nyẹn sọ́kàn dáradára, bí ọjọ́ sì ti ń gorí ọjọ́, mo mọ̀ pé lọ́jọ́ kan ṣá, bí mo bá fẹ́ ní ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́, tí mo sì fẹ́ ní ayọ̀ tòótọ́, màá mú ìgbésí ayé mi bá ìlànà Ọlọ́run mu.

Láti lè mú ìgbésí ayé wa bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu, alábàágbé mi ti kọ́kọ́ gbà pé òun á fẹ́ mi. Ẹ̀yìn ìgbà náà ló wá kó wọnú ẹgbẹ́ burúkú, àwọn èèyàn tí wọn kò ka Ọlọ́run àti òfin rẹ̀ sí. Mo padà délé ní ìgbà ìrúwé lálẹ́ ọjọ́ kan, ẹ̀rù bà mí. Ilé wa ti ṣófo. Alábàágbé mi ti lọ, ó sì gbé ọmọbìnrin wa, ọmọ ọdún mẹ́ta, lọ. Fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, mò ń retí pé wọ́n máa tó padà—àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀. Dípò tí màá fi dá Ọlọ́run lẹ́bi, mo gbàdúrà sí i pé kó jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́.

Kété lẹ́yìn náà, mo mú Bíbélì, mo jókòó sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á. Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀ mí lákínyẹmí ara. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ka onírúurú ìwé tí àwọn afìrírí-ayé-ẹni-wonisàn àti afìṣemọ̀rònú ṣe jáde, n kò tí ì bá irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ pàdé rí. Kò sí iyè méjì pé Ọlọ́run ló mí sí ìwé yìí. Ẹ̀kọ́ Jésù àti òye rẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn mú mi ṣe háà. Sáàmù tù mí nínú, ọgbọ́n ṣíṣeémúlò tó wà nínú ìwé Òwe sì ṣe mí ní kàyéfì. Kíá ni mo mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣẹ̀dá jẹ́ ọ̀nà dídára láti mú kí ẹnì kan sún mọ́ Ọlọ́run, kìkì “bèbè àwọn ọ̀nà rẹ̀” ló lè ṣí payá.—Jóòbù 26:14.

Mo tún ti gba ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye àti Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí.a Kíkà wọ́n là mí lójú. Ìwé Otitọ ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí ènìyàn fi dojú kọ ìṣòro bíba àyíká jẹ́ tó kárí ayé, ogun, ìwà ipá tí ń peléke sí i, àti ìṣòro kíkóni láyà sókè pé a óò fi bọ́ǹbù pa gbogbo ẹ̀dá run. Gẹ́gẹ́ bí ojú ọ̀run pípọ́n dẹ̀dẹ̀ tí mo rí nínú ọgbà mi ṣe ń sọ pé ojú ọjọ́ yóò dáa lọ́la, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ń fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé. Ní ti ìwé Igbesi Ayé Idile, ó wù mí pé kí n lè fi han alábàágbé mi, kí n sì sọ fún un pé a lè jẹ́ aláyọ̀ báa bá fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. Ṣùgbọ́n ẹ̀pa kò bóró mọ́.

Títẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí

Mo fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, nítorí náà mo sọ fún Robert, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí, pé kó máa wá sọ́dọ̀ mi. Ẹnú yà á púpọ̀ nígbà tí mo sọ fún un pé, mo fẹ́ ṣèrìbọmi, nítorí náà, kíá la bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lójú ẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mò ń kọ́, tí mo sì ń pín àwọn ìtẹ̀jáde tí mo gbà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Kí n lè gbọ́ bùkátà ara mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ṣẹ́ bíríkìlà. Nígbà tí mo mọ àǹfààní tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣe fúnni, mo lo gbogbo àǹfààní ti mo ní láti wàásù láìjẹ́ bí àṣà fún àwọn tí a jọ ń kọ́ṣẹ́ àti àwọn ọ̀gá wa. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, mo pàdé Serge ní ọ̀ọ̀dẹ̀ kan. Ó kó àwọn ìwé ìròyìn díẹ̀ dání. Mo sọ fún un pé: “Ó dà bí ẹni pé ó fẹ́ràn ìwé kíkà gan-an.” Ó fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ tọwọ́ mi yìí ti sú mi jàre.” Mo wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé wàá fẹ́ ka ohun kan tí yóò gbádùn mọ́ ọ?” Ìjíròrò wa nípa Ìjọba Ọlọ́run mọ́yán lórí gan-an, lẹ́yìn náà, ó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì díẹ̀. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó tẹ̀ lé mi wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Lọ́jọ́ kan, mo béèrè lọ́wọ́ Robert bí mo bá lè wàásù láti ilé dé ilé. Ó wọnú ibi tó ń kẹ́rù sí, ó sì gbé ẹ̀wù tòkètilẹ̀ kan fún mi. Ní Sunday tó tẹ̀ lé e, mo bá a jáde fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ìgbà àkọ́kọ́. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ní March 7, 1981, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà Ọlọ́run hàn, nípa ṣíṣe ìrìbọmi.

Ìrànwọ́ Nígbà Hílàhílo

Láàárín àkókò yìí, mo ti mọ ibi tí Amandine àti ìyá rẹ̀ ń gbé lókè òkun. Págà, màmá rẹ̀—nítorí àǹfààní òfin orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé—fòfin dè mí pé n kò gbọ́dọ̀ wá fojú kan ọmọ mi. Ara mi bù máṣọ. Ìyá Amandine ti lọ fẹ́ ọkọ mìíràn, ọkàn mi tún wá dà rú nígbà tí mo rí ìwé àṣẹ kan gbà, tó fi tó mi létí pé, ọkọ rẹ̀ ti sọ ọmọ mi di tirẹ̀—láìjẹ́ kí n gbọ́ rárá. N kò tún lẹ́tọ̀ọ́ lórí ọmọ mi mọ́. Yàtọ̀ sí ìgbésẹ̀ òfin yìí, Wọn kò tún gbà mí láyè láti lọ rí ọmọ náà. Ṣe ni ìrora yìí dà bí ẹni pé wọ́n gbé àpò sìmẹ́ńtì lé mi lẹ́yìn.

Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Jèhófà mú mi dúró ní onírúurú ọ̀nà. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí wàhálà bá mi pátápátá, mo tún ọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe 24:10 sọ lọ́pọ̀ ìgbà pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Ẹsẹ yìí ni kò jẹ́ kí ayé sú mi. Ní àkókò mìíràn, lẹ́yìn ìṣòro àìlèfojú kan ọmọ mi, mo lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, mo sì gbá ọwọ́ àpò ìjẹ́rìí mi mú gírígírí bó ti ṣeé ṣe tó fún mi. Nírú àwọn àkókò ìṣòro bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún mi láti rí bí ọ̀rọ̀ Sáàmù 126:6 ti jẹ́ òtítọ́ tó, nígbà tó sọ pé: “Láìkùnà, ẹni tí ń jáde lọ, àní tí ó ń sunkún, bí ó ti gbé irúgbìn ẹ̀kún àpò dání, láìkùnà, yóò fi igbe ìdùnnú wọlé wá, bí ó ti gbé àwọn ìtí rẹ̀ dání.” Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tí mo kọ́ ni pé nígbà tí o bá dojú kọ àwọn àdánwò ńlá, tí o bá ṣáà ti ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe láti yanjú wọn, ṣe ni kí o gbé wọn kúrò lọ́kàn, kí o sì máa tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìpinnu nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ọ̀nà kan ṣoṣo tí o fi lè máa láyọ̀ nìyẹn.

Nínàgà fún Ohun Mìíràn Tí Ó Sàn Jù

Nígbà tí àwọn òbí mi ọ̀wọ́n rí ìyípadà tí mo ti ṣe, wọ́n ṣe tán láti ràn mí lọ́wọ́ láti máa bá ẹ̀kọ́ mi lọ ní yunifásítì. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, ṣùgbọ́n góńgó mi ti yí padà báyìí. Òtítọ́ ti gbà mí lọ́wọ́ ọgbọ́n èrò orí ènìyàn, iṣẹ́ awo, àti ìwòràwọ̀. Mo ti wá ní àwọn ojúlówó ọ̀rẹ́ nísinsìnyí, àwọn tí kò ní pa ẹnì kìíní kejì bí ogun bá dé. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi nípa ìdí tí ìjìyà fi pọ̀ tó báyìí lórí ilẹ̀ ayé. Pẹ̀lú ẹ̀mí ìmoore, mo fẹ́ fi gbogbo okun mi sin Ọlọ́run. Jésù ti fi gbogbo ara rẹ̀ jìn pátápátá fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, mo sì fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

Lọ́dún 1983, mo fi iṣẹ́ bíríkìlà mi sílẹ̀, mo sì di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ní ìdáhùn sí àdúrà mi, níbi ìgbafẹ́ kan, mo rí iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ tí mo lè máa fi gbọ́ bùkátà ara mi. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó nígbà tí èmi pẹ̀lú Serge, ọ̀dọ́mọkùnrin tí mo wàásù fún ní ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ bíríkìlà, jọ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà! Lẹ́yìn tí mo ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ọdún mẹ́ta, mo tún fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nípa báyìí, ní ọdún 1986, a yàn mí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní ìlú rírẹwà nì, Provins, tí kò jìnnà sí Paris. Lọ́pọ̀ ìgbà, bí mo bá padà sílé ní alẹ́, màá kúnlẹ̀ àdúrà sí Jèhófà, màá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ àgbàyanu náà tí mo ti lò nínú bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ní tòótọ́, ohun méjì tó mú inú mi dùn jù lọ nínú ìgbésí ayé ni bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ àti bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run.

Ohun mìíràn tó tún mú inú mi dùn jọjọ ni ìrìbọmi ìyá mí, ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rin, tó ń gbé ní Cébazan, ìletò kan ní gúúsù ilẹ̀ Faransé. Nígbà tí màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì, mo bá a ṣètò àsansílẹ̀ Ilé Ìsọ́ àti Jí!, a sì ń fi ránṣẹ́ sí i. Ó jẹ́ onílàákàyè, kò sì pẹ́ tó fi rí òtítọ́ tó wà nínú ohun tó ń kà.

Bẹ́tẹ́lì—Arabaríbí Párádísè Tẹ̀mí

Nígbà tí Watch Tower Society pinnu láti dín iye àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kù, mo forúkọ sílẹ̀ fún àtilọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, mo tún gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì, ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ilẹ̀ Faransé. Mo fẹ́ fi í sílẹ̀ fún Jèhófà kó bá mi yan ibi tí mo ti lè wúlò jù lọ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ní December 1989, wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì ní Louviers, ìwọ̀ oòrùn àríwá ilẹ̀ Faransé. Èyí jẹ́ àbájáde tó dára jù lọ, níwọ̀n bí ibi tí Bẹ́tẹ́lì wà ti ràn mí lọ́wọ́ láti ṣèrànwọ́ fún àbúrò mi ọkùnrin àti aya rẹ̀ láti lè bójú tó àwọn òbí mi nígbà tí ara wọn kò dá. Ì bá ti ṣòro fún mi láti ṣe èyí bó bá jẹ́ pé ẹnu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà ni mo wà.

Màmá mi wá bẹ̀ mí wò lọ́pọ̀ ìgbà ní Bẹ́tẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lo ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ní ti gbígbé tí kò lè gbé lọ́dọ̀ mi, ó sábà máa ń sọ fún mi pé: “Ọmọ mi, máà kúrò ní Bẹ́tẹ́lì o. Ṣe ni inú mi ń dùn ṣáá pé o ń sin Jèhófà lọ́nà yìí.” Ó dùn mí pé, àwọn òbí mi méjèèjì ti dolóògbé báyìí. Ẹ wo bí mo ti ń fojú sọ́nà tó láti rí wọn lórí ilẹ̀ ayé kan tí a ti sọ di párádísè ní ti gidi!

Mo gbà gbọ́ pé bí ilé èyíkéyìí bá wà tí a lè pè ní “Párádísè Ìsinsìnyí,” Bẹ́tẹ́lì ni ilé náà—“Ilé Ọlọ́run”—ju gbogbo rẹ̀ lọ, párádísè tòótọ́ jẹ́ tẹ̀mí, ipò tẹ̀mí ló sì jọba ní Bẹ́tẹ́lì. A láǹfààní láti mú èso tẹ̀mí dàgbà. (Gálátíà 5:22, 23) Oúnjẹ tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ tí à ń jẹ nígbà tí a bá ń ṣàyẹ̀wò Bíbélì wa lójoojúmọ́ àti nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé láti inú Ilé Ìṣọ́ ń fún mi lókun láti máa bá iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì lọ. Síwájú sí i, kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí nǹkan tẹ̀mí jẹ lọ́kàn, tí wọ́n ti ń sin Jèhófà tọkàntọkàn fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ń mú kí Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ibi àrà ọ̀tọ̀ tí ẹnì kan ti lè dàgbà nípa tẹ̀mí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò fojú rí ọmọ mi láti ọdún mẹ́tàdínlógún sẹ́yìn, mo ti rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ onítara ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn tí mo mú bí ọmọ, tí ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí sì ń mú inú mi dùn. Ní ọdún mẹ́jọ tó ti kọjá, a ti yan iṣẹ́ méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìyípadà wọ̀nyí kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń ṣàǹfààní lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Tẹ́lẹ̀ rí, mo máa ń gbin ẹ̀wà kan tó ń so èso ọgọ́rọ̀ọ̀rún. Bákan náà, mo ti wá rí i pé, bóo bá gbin ẹyọ èbù ìkà kan ṣoṣo, ẹ̀ta tó burú ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún ni yóò fi ta fún ẹ—kò sì ní fi títa rẹ̀ mọ sí ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. Bí ìgbà tí èèyàn bá lọ sílé ẹ̀kọ́ ni ìrírí ìgbésí ayé ṣe rí. Ká ní ó ṣeé ṣe fún mi ni, n kì bá fẹ́ láti lọ sí irú ilé ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, ǹ bá ti yàn láti jẹ́ kí a tọ́ mi dàgbà lọ́nà Jèhófà. Àǹfààní ńláǹlà mà ni àwọn ọ̀dọ́ tí àwọn òbí Kristẹni tọ́ dàgbà ní o! Láìsí iyè méjì, ó sàn láti gbin ohun tí ó dára nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kí a sì ká àlàáfíà àti ìtẹ́lọ́rùn nígbà ọgọ́rùn-ún.—Gálátíà 6:7, 8.

Nígbà tí mo ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, mo sábà máa ń gba ilé ìtàwé ẹ̀sìn náà kọjá, tó jẹ́ pé àwa la kọ ìkọkúkọ àwọn adájọ̀ngbọ̀n-sílẹ̀ sára rẹ̀ láyé ọjọ́sí. Mo tilẹ̀ ti wọnú rẹ̀ rí, tí mo sì bá ọ̀gá ibẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run alààyè àti ète rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ń bẹ! Yàtọ̀ sí ìyẹn, Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo jẹ́ Baba olóòótọ́ tí kì í gbà gbé àwọn ọmọ rẹ̀. (Ìṣípayá 15:4) Ǹjẹ́ kí àwọn ògìdìgbó mìíràn láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè rí párádísè tẹ̀mí nísinsìnyí—àti Párádísè tí ń bọ̀ tí a óò mú padà bọ̀ sípò—nípa sísin Ọlọ́run alààyè, Jèhófà, àti yíyìn ín lógo!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ ẹ́ jáde

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn àgbàyanu ìṣẹ̀dá wú mi lórí, mo sì pinnu nínú ọkàn mi láti nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run (Ọwọ́ ọ̀tún) Lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́