ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 5/15 ojú ìwé 29-31
  • Sọ́ọ̀lù—Ààyò Ohun Èlò Olúwa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sọ́ọ̀lù—Ààyò Ohun Èlò Olúwa
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Irú Ilé Tí Sọ́ọ̀lù Ti Wá
  • Bí Sọ́ọ̀lù Ṣe Kàwé
  • Ó Lo Ìmọ̀ Rẹ̀ Lọ́nà Rere
  • Jésù Yan Sọ́ọ̀lù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ìjọ “Wọnú Àkókò Àlàáfíà”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Onínúnibíni Rí Ìmọ́lẹ̀ Ńlá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • ‘Ìgbọràn Sàn Ju Ẹbọ Lọ’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 5/15 ojú ìwé 29-31

Sọ́ọ̀lù—Ààyò Ohun Èlò Olúwa

SỌ́Ọ̀LÙ ará Tásù jẹ́ alátakò tí kò kọ̀ láti fikú pa àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni nǹkan tí Olúwa fẹ́ kó fi ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ ṣe. Sọ́ọ̀lù yóò di alágbàwí aláìlẹ́gbẹ́ fún iṣẹ́ tó ti kọ́kọ́ gbéjà kò gidigidi. Jésù sọ pé: “Ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí [Sọ́ọ̀lù] jẹ́ fún mi láti gbé orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”—Ìṣe 9:15.

Ìgbésí ayé Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí “aláfojúdi” yí padà pátápátá nígbà tó rí àánú gbà, tó sì di ‘ààyò ohun èlò’ Jésù Kristi Olúwa. (1 Tímótì 1:12, 13) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù di Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, agbára tó lò tẹ́lẹ̀ nídìí lílọ́wọ́ sí sísọ Sítéfánù lókùúta pa àti àwọn wàhálà mìíràn tó bá àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fà, ló wá bẹ̀rẹ̀ sí lò fún ète ọ̀tọ̀ gbáà. Kò sí àní-àní pé Jésù rí àwọn ànímọ́ rere nínú Sọ́ọ̀lù. Àwọn ànímọ́ wo? Ta ni Sọ́ọ̀lù? Báwo ni ipò rẹ̀ àtẹ̀yìnwá ṣe sọ ọ́ di ohun èlò yíyẹ fún ìtẹ̀síwájú ìjọsìn tòótọ́? Ṣé a lè rí nǹkan kọ́ nínú ìrírí rẹ̀?

Irú Ilé Tí Sọ́ọ̀lù Ti Wá

“Ọ̀dọ́kùnrin” ni Sọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n sọ Sítéfánù lókùúta pa, gẹ́rẹ́ lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Àmọ́, ó ti di “àgbàlagbà” nígbà tó ń kọ̀wé sí Fílémónì ní nǹkan bí ọdún 60 sí 61 Sànmánì Tiwa. (Ìṣe 7:58; Fílémónì 9) Àwọn ọ̀mọ̀wé dá a lábàá pé, bó bá ṣe bí wọ́n ti ń ṣírò ọjọ́ orí láyé àtijọ́ ni, ó ṣeé ṣe kí ọjọ́ orí ẹni tí wọ́n pè ní “ọ̀dọ́kùnrin” wà láàárín ọdún mẹ́rìnlélógún sí ogójì ọdún, kí ọjọ́ orí ẹni tí wọ́n pè ní “àgbàlagbà” sì jẹ́ láti àádọ́ta ọdún sí ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta. Fún ìdí yìí, ó jọ pé ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìbí Jésù ni wọ́n bí Sọ́ọ̀lù.

Igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé làwọn Júù ìgbà yẹn ń gbé. Ṣíṣẹ́gun táa ń ṣẹ́gun wọn, kíkó wọn lẹ́rú, kíkó wọn lọ sígbèkùn, iṣẹ́ ajé, àti fífúnra ẹni ṣí lọ síbòmíràn, wà lára ohun tó fà á tí wọ́n fi tú ká kúrò ní Jùdíà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé Sọ́ọ̀lù wà lára àwọn èyí tó ṣí lọ sí ilẹ̀ àjèjì, Sọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ bí àwọn ṣe rọ̀ mọ́ Òfin tó, ó sọ pé òun “dádọ̀dọ́ ní ọjọ́ kẹjọ, láti inú ìlà ìran ìdílé Ísírẹ́lì, láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Hébérù tí a bí láti inú àwọn Hébérù; ní ti òfin, Farisí.” Orúkọ Hébérù kan náà ni Sọ́ọ̀lù ń jẹ́ bíi ti ògúnnágbòǹgbò kan nínú ẹ̀yà rẹ̀—èyíinì ni ọba àkọ́kọ́ tó jẹ ní Ísírẹ́lì. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù, Sọ́ọ̀lù ará Tásù tún ní orúkọ Látìn náà, Pọ́lọ́sì.—Fílípì 3:5; Ìṣe 13:21; 22:25-29.

Bíbí tí a bí Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ará Róòmù túmọ̀ sí pé ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ̀ ti rí ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ará Róòmù gbà. Lọ́nà wo? Ó ṣeé ṣe lóríṣiríṣi ọ̀nà. Yàtọ̀ sí pé èèyàn lè jogún ẹ̀tọ́ jíjẹ́ aráàlú, a lè fi dá àwọn kan tàbí àwọn àwùjọ kan lọ́lá, yálà nítorí àwọn ìwà ọmọlúwàbí kan, tàbí fún ète òṣèlú, tàbí kí wọ́n fi dáni lọ́lá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san iṣẹ́ takuntakun tí onítọ̀hún ṣe fún Orílẹ̀-Èdè náà. Ẹrú tó bá ra òmìnira ara rẹ̀ padà lọ́wọ́ ará Róòmù, tàbí ẹni tí ọlọ̀tọ̀ Róòmù bá dá sílẹ̀ lóko òǹdè, òun alára yóò di ará Róòmù. Tí a bá sì sọ àbọ̀dé sọ́jà, tó ti wà lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù tẹ́lẹ̀ rí di ajagunfẹ̀yìntì, òun náà di ọmọ onílẹ̀ nìyẹn. Àwọn tí ń gbé inú àwọn ìlú òkèèrè tí Róòmù ń ṣàkóso pẹ̀lú lè di ará Róòmù nígbà tó bá yá. A tún gbọ́ pé ní àwọn sáà kan, àwọn kan ń fi owó gọbọi ra ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ará Róòmù. Kò sẹ́ni tó mọ bí ẹ̀tọ́ yìí ṣe wọnú ìdílé Sọ́ọ̀lù.

Ohun táa mọ̀ ni pé Sọ́ọ̀lù wá láti Tásù, ìlú tó lóókọ jù lọ, tó sì tún jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Róòmù táa ń pè ní Sìlíṣíà (ó wà ní gúúsù ilẹ̀ Turkey báyìí). Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù tó pọ̀ díẹ̀ ń gbé lágbègbè yẹn, gbígbé níbẹ̀ yóò jẹ́ kí Sọ́ọ̀lù dojúlùmọ̀ àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Kèfèrí. Tásù jẹ́ ìlú ńlá aláásìkí, táwọn èèyàn mọ̀ sí ojúkò ẹ̀kọ́ àwọn Hélénì, tàbí ti ilẹ̀ Gíríìsì. Àwọn kan fojú bù ú pé á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] sí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] tí ń gbé inú ìlú yìí ní ọ̀rúndún kìíní. Ó jẹ́ ìlú kátàkárà, torí pé ó wà lójú òpópónà tààrà tó wà láàárín Éṣíà Kékeré, Síríà, àti Mesopotámíà. Ohun tó jẹ́ kí Tásù jẹ́ ìlú aásìkí ni òwò ṣíṣe àti ilẹ̀ ọlọ́ràá tó wà lágbègbè rẹ̀, lájorí àwọn ohun tí ilẹ̀ ọ̀hún sì ń mú jáde ni ọkà, wáìnì, àti aṣọ ọ̀gbọ̀. Àwọn ilé iṣẹ́ ìhunṣọ rẹ̀ tí ń gbèrú gan-an nígbà yẹn ló ń pèsè àwọn aṣọ táa fi irun ewúrẹ́ ṣe, aṣọ wọ̀nyí sì ni a fi ń ṣe aṣọ àgọ́.

Bí Sọ́ọ̀lù Ṣe Kàwé

Sọ́ọ̀lù, tàbí Pọ́ọ̀lù, ló ń bọ́ ara rẹ̀ láìrẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ, ó ń pa àwọn àgọ́ láti fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀. (Ìṣe 18:2, 3; 20:34) Iṣẹ́ pàgọ́pàgọ́ lọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe ní Tásù, ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé láti kékeré ni Sọ́ọ̀lù ti kọ́ṣẹ́ àgọ́ pípa lọ́dọ̀ baba rẹ̀.

Àwọn èdè tí Sọ́ọ̀lù gbọ́—pàápàá jù lọ gbígbọ́ tó gbọ́ ìjìnlẹ̀ Gíríìkì, tí í ṣe èdè tí wọ́n ń sọ ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù—tún wúlò gidigidi nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀. (Ìṣe 21:37–22:2) Àwọn tó ti ṣàtúpalẹ̀ àwọn ìwé rẹ̀ sọ pé ó gbọ́ èdè Gíríìkì débi téèyàn lè gbọ́ ọ dé. Àwọn ọ̀rọ̀ tó lò kì í kúkú ṣe àdììtú tàbí àwọn ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ó lo irú àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì táa lò nínú Septuagint, tí í ṣe Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, táa tú sí èdè Gíríìkì, èyí tó sábà máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú rẹ̀, tàbí tó ń ṣàyọlò ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. Ní ti ẹ̀rí yìí, ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló gbà pé ó kéré tán Sọ́ọ̀lù gba ìmọ̀ ìpìlẹ̀ tó pegedé nínú èdè Gíríìkì, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ iléèwé àwọn Júù ló ti gba ìmọ̀ ọ̀hún. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, Martin Hengel, sọ pé: “Láyé ijọ́un, ẹ̀kọ́ tó dáńgájíá—pàápàá jù lọ ẹ̀kọ́ àwọn Gíríìkì—kì í ṣe ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́; èèyàn ò lè rí i gbà láìsanwó fún un.” Nípa báyìí, ẹ̀kọ́ tí Sọ́ọ̀lù rí gbà fi hàn pé ó ti ní láti wá láti inú ìdílé ọlọ́là.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nígbà tí Sọ́ọ̀lù kò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́tàlá ló ti wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, èyí jẹ́ nǹkan bí òjìlélẹ́gbẹ̀rin [840] kìlómítà sílé. Ó kàwé lọ́dọ̀ Gàmálíẹ́lì, tí í ṣe gbajúgbajà olùkọ́ tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Farisí. (Ìṣe 22:3; 23:6) Ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn, tó jẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹ̀kọ́ yunifásítì lóde òní, ṣílẹ̀kùn àǹfààní dídi gbajúmọ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù.a

Ó Lo Ìmọ̀ Rẹ̀ Lọ́nà Rere

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ìdílé Júù tí ń gbé láàárín àwọn Hélénì ní ìlú Róòmù la bí Sọ́ọ̀lù sí, Sọ́ọ̀lù jẹ́ mẹ́ńbà àwùjọ mẹ́ta. Ó dájú pé àgbègbè tí Pọ́ọ̀lù ti dàgbà, tó jẹ́ àgbègbè tí onírúurú ẹ̀yà jọ ń gbé pọ̀, táa ti ń sọ onírúurú èdè, ràn án lọ́wọ́ láti di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 9:19-23) Ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ló wá fún un láǹfààní láti gbèjà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lábẹ́ òfin, ẹ̀tọ́ yìí ló sì lò tó fi mú ìhìn rere náà lọ bá aláṣẹ gíga jù lọ ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù. (Ìṣe 16:37-40; 25:11, 12) Láìṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ, ó dájú pé Jésù tí a ti jí dìde mọ irú ilé tí Sọ́ọ̀lù ti wá, ó mọ bó ti kàwé tó, ó sì mọ irú èèyàn tó jẹ́, ìyẹn ló fi sọ fún Ananíà pé: “Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, nítorí ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi láti gbé orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nítorí èmi yóò fi hàn án ní kedere bí ohun tí yóò jìyà nítorí orúkọ mi ti pọ̀ tó.” (Ìṣe 9:13-16) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù lo ìtara rẹ̀ lọ́nà rere, ìtara ọ̀hún wúlò gan-an fún títan ìhìn Ìjọba náà dé àwọn ìpínlẹ̀ tó jìnnà.

Yíyàn tí Jésù yan Sọ́ọ̀lù fún iṣẹ́ àkànṣe jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ nínú ìtàn Kristẹni. Síbẹ̀, olúkúlùkù àwọn Kristẹni lóde òní ló ní àwọn ẹ̀bùn àti ànímọ́ tí wọ́n lè lò lọ́nà tó gbéṣẹ́ ní títan ìhìn rere kálẹ̀. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù mọ ohun tí Jésù fẹ́ kóun ṣe, kò fà sẹ́yìn rárá. Ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti gbé ire Ìjọba Ọlọ́run lárugẹ. Ṣé bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ ń ṣe?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nípa irú ẹ̀kọ́ tó ṣeé ṣe kí Sọ́ọ̀lù kọ́ lọ́dọ̀ Gàmálíẹ́lì, wo Ilé Ìṣọ́, July 15, 1996, ojú ìwé 26 sí 29.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Fíforúkọsílẹ̀ fún Ẹ̀tọ́ Jíjẹ́ Ará Róòmù àti Rírí Ìwé Ẹ̀rí Rẹ̀ Gbà

Ọ̀gọ́sítọ́sì ló ṣètò pé ká máa forúkọ àwọn ojúlówó ọmọ àwọn ará Róòmù sílẹ̀, ètò yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òfin méjì tó ṣe lọ́dún kẹrin àti ìkẹsàn-án Sànmánì Tiwa. A gbọ́dọ̀ forúkọ ọmọ náà sílẹ̀ láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ táa bí i. Bó bá ṣe pé ìgbèríko la bí ọmọ náà sí, ìdílé náà gbọ́dọ̀ lọ búra níwájú adájọ́ ní ọ́fíìsì tí ń bójú tó àkọsílẹ̀ ìlú, wọn yóò sì sọ nínú ìbúra náà pé ọmọ náà kì í ṣe àtọ̀húnrìnwá àti pé ọmọ bíbí Róòmù ni. Orúkọ àwọn òbí ọmọ náà, bóyá akọ tàbí abo ni ọmọ náà, àti orúkọ ọmọ náà, àti ọjọ́ táa bí i pẹ̀lú, yóò wà nínú àkọọ́lẹ̀ náà. Kódà, kí òfin wọ̀nyí tó dóde, ni ìforúkọsílẹ̀ àwọn ará Róòmù ní gbogbo ẹkùn ilẹ̀, àti àwọn ìlú àtòkèèrè ṣàkóso, àti àwọn ìpínlẹ̀, ti ń wáyé lẹ́ẹ̀kan lọ́dún márùn-ún márùn-ún nípasẹ̀ ìkànìyàn.

Nípa báyìí wọ́n lè mọ ẹni tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ nípa lílọ ṣàyẹ̀wò àkójọ ìwé wọnnì táa tò lẹ́sẹẹsẹ. Wọ́n lè ṣe àdàkọ irú àwọn àkọọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sínú wàláà kóńkóló aláwẹ́ méjì táa figi ṣe (àwọn wàláà tó ṣeé pa dé), wọn á sì lù ú lóǹtẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí èrò àwọn ọ̀mọ̀wé kan, nígbà tí Pọ́ọ̀lù fọwọ́ sọ̀yà pé ọmọ bíbí Róòmù lòun, wọ́n ní ó ṣeé ṣe kó ní ìwé ẹ̀rí lọ́wọ́ tó ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn. (Ìṣe 16:37; 22:25-29; 25:11) Níwọ̀n bí àwọn èèyàn ti ka ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ará Róòmù sóhun táa lè fẹ́rẹ̀ẹ́ pè ní “ohun mímọ́,” tó sì fún èèyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní, ṣíṣe ayédèrú irú ìwé bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà ọ̀daràn tó burú jáì. Wọ́n lè dájọ́ ikú fẹ́ni tó bá purọ́ pé ọmọ ìbílẹ̀ lòun nígbà tí kì í ṣe bẹ́ẹ̀.

[Credit Line]

Historic Costume in Pictures/Dover Publications, Inc., New York

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Orúkọ Àwọn Ará Róòmù Tí Sọ́ọ̀lù Ń Jẹ́

Gbogbo ọmọkùnrin tó jẹ́ ará Róòmù ló jẹ́ pé, ó kéré tán, ó ní orúkọ mẹ́ta. Wọ́n máa ń ní orúkọ àkọ́kọ́, ti ìdílé (tó jẹ mọ́ ẹ̀yà wọn, tàbí gens), àti orúkọ àpèlé. Àpẹẹrẹ táa mọ̀ dunjú ni ti Gaius Julius Caesar. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í sọ gbogbo orúkọ àwọn ará Róòmù, ṣùgbọ́n àwọn ìwé ayé sọ fún wa pé orúkọ Àgírípà ni Marcus Júlíọ́sì Ágírípà. Orúkọ Gálíò ni Lúkíọ́sì Junius Gálíò. (Ìṣe 18:12; 25:13) Àwọn àpẹẹrẹ ibi tí Ìwé Mímọ́ ti mẹ́nu kan méjì lára orúkọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta táwọn èèyàn ń jẹ́ ni àpẹẹrẹ Pọ́ńtíù Pílátù (wo ohun gbígbẹ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí), Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, Kíláúdíù Lísíà, àti Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì.—Ìṣe 4:27; 13:7; 23:26; 24:27.

Kò ṣeé ṣe láti sọ ní pàtó bóyá Pọ́lọ́sì ni orúkọ àkọ́kọ́ tàbí orúkọ ìdílé Sọ́ọ̀lù. Ó wọ́pọ̀ láti tún fi orúkọ mìíràn kún un nílé, èyí tí àwọn aráalé àti ọ̀rẹ́ lè máa fi pèèyàn. Tàbí kẹ̀, wọ́n lè tún máa lo orúkọ tí kì í ṣe tàwọn ará Róòmù, irú bíi Sọ́ọ̀lù. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Pípè é ní [Sọ́ọ̀lù] nìkan kì í ṣe orúkọ tó kún rẹ́rẹ́ ní Róòmù, ṣùgbọ́n bó bá jẹ́ pé orúkọ ìbílẹ̀ ni, tó kàn jẹ́ signum, ìyẹn, ìnagijẹ, táa sọ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù, á jẹ́ pé ó kún rẹ́rẹ́.” Láwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń sọ onírúurú èdè, ó jọ pé ipò àwọn nǹkan ló máa ń pinnu orúkọ tẹ́nì kan fẹ́ kí wọ́n máa pe òun.

[Credit Line]

Fọ́tò láti Israel Museum, ©Israel Antiquities Authority

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́