“Fi Ìbùkún fún Jèhófà, Ìwọ Ọkàn Mi”
NANCY sọ pé: “Ní àwọn oṣù àìpẹ́ yìí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi kò já geere mọ́.a Ọdún kẹwàá rèé tó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà, olùpòkìkí ìhìn rere náà lákòókò kíkún. Síbẹ̀, ó fi kún un pé: “Inú mi ò dùn sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ sí mi. Ó dà bí ẹni pé n kò lè fi ìtara gbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀ mọ́ àti pé n kò fi gbogbo ọkàn ṣe é mọ́. Kí ni kí n ṣe?”
Bákan náà, tún gbé ọ̀ràn Keith, alàgbà kan nínú ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹ̀ wò. Ẹ wo bó ti yà á lẹ́nu tó láti gbọ́ tí aya rẹ̀ ń sọ pé: “Ó dà bí ẹni pé ò ń ronú. Nínú àdúrà tóo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà tán, o dúpẹ́ fún oúnjẹ, nígbà tó sì jẹ́ pé kì í ṣàkókò oúnjẹ la wà!” Keith kò jiyàn, ó ní: “Mo gbà pé àdúrà mi ti di àkọ́sórí.”
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n pé, o kò ní fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìyìn rẹ sí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ èyí tí kò fi ìmọ̀lára hàn tàbí kó jẹ́ àkọ́sórí. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, wàá fẹ́ kó jẹ́ àtọkànwá, kó wá láti inú ẹ̀mí ìmoore. Ṣùgbọ́n, a kò lè wulẹ̀ gbé ìmọ̀lára wọ̀ tàbí kí a bọ́ ọ sílẹ̀ bí ẹni bọ aṣọ. Ó gbọ́dọ̀ tinú ẹni wá. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè kún fún ìmoore láti inú ọkàn-àyà rẹ̀? Sáàmù kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye nípa èyí.
Ọba Dáfídì ti Ísírẹ́lì ìgbàanì ló fi Sáàmù kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún ṣorin kọ. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ló fi bẹ̀rẹ̀ rẹ̀: “Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi, Àní ohun gbogbo tí ń bẹ nínú mi, fi ìbùkún fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 103:1) Ìwé ìtọ́kasí kan sọ pé: “Gbólóhùn náà fi ìbùkún fún, nígbà táa bá lò ó fún Ọlọ́run, túmọ̀ sí láti fi ìyìn fún un, ó sábà máa ń túmọ̀ sí níní ìfẹ́ lílágbára àti ẹ̀mí ìmoore sí i.” Nítorí tí ó fẹ́ láti yin Jèhófà pẹ̀lú ọkàn-àyà tó kún fún ìfẹ́ àti ìmọrírì, Dáfídì rọ ọkàn rẹ̀—ìyẹn ni òun alára—pé kí ó “fi ìbùkún fún Jèhófà.” Àmọ́, kí ló ru ìmọ̀lára onífẹ̀ẹ́ yìí sókè nínú ọkàn-àyà Dáfídì sí Ọlọ́run tí ó ń jọ́sìn?
Dáfídì ń bá a nìṣó pé: “Má . . . gbàgbé gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ rẹ̀ [Jèhófà].” (Sáàmù 103:2) Ó ṣe kedere pé ohun tí ń mú kéèyàn fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí Jèhófà ní ṣíṣàṣàrò lọ́nà tó fi ìmọrírì hàn lórí àwọn “iṣẹ́ rẹ̀.” Ní pàtó, àwọn iṣẹ́ Jèhófà wo ni Dáfídì ní lọ́kàn? Wíwo àwọn ohun tí Jèhófà Ọlọ́run dá, irú bí sánmà tó kún fún ìràwọ̀ rẹpẹtẹ ní alẹ́ kan tójú ọ̀run mọ́ rekete, lè mú kí ọkàn-àyà kún fún ìmoore sí Ẹlẹ́dàá. Ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀ wú Dáfídì lórí gidigidi. (Sáàmù 8:3, 4; 19:1) Àmọ́ ṣá o, nínú Sáàmù kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún kan náà yìí, Dáfídì rántí ìgbòkègbodò Jèhófà mìíràn.
Jèhófà “Ń Dárí Gbogbo Ìṣìnà Rẹ Jì”
Nínú sáàmù yìí, Dáfídì rántí àwọn ìṣe inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ti ṣe. Nígbà tó ń tọ́ka sí àkọ́kọ́ àti èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìwọ̀nyí, ó kọrin pé: ‘Jèhófà ń dárí gbogbo ìṣìnà rẹ jì.’ (Sáàmù 103:3) Ó dájú pé Dáfídì mọ ipò ẹ̀ṣẹ̀ tí òun wà. Lẹ́yìn tí Nátánì wòlíì kò ó lójú nípa ìṣekúṣe tó bá Bátí-ṣébà ṣe, Dáfídì jẹ́wọ́, ó ní: “Ìwọ [Jèhófà], ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí, mo sì ti ṣe ohun tí ó burú ní ojú rẹ.” (Sáàmù 51:4) Pẹ̀lú ọkàn-àyà tó gbọgbẹ́, ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Fi ojú rere hàn sí mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́. Nu àwọn ìrélànàkọjá mi kúrò gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ. Wẹ̀ mí mọ́ tónítóní kúrò nínú ìṣìnà mi, kí o sì wẹ̀ mí mọ́ àní kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.” (Sáàmù 51:1, 2) Ẹ wo bí Dáfídì yóò ti kún fún ìmoore tó nígbà táa dárí jì í! Nítorí tó jẹ́ èèyàn aláìpé, ó dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn nígbà ayé ẹ̀, ṣùgbọ́n kò ṣàìtọrọ àforíjì, kò ṣàìtẹ́wọ́gba ìbáwí, kò sì ṣàìtún ìwà rẹ̀ ṣe. Ríronú lórí inú rere àgbàyanu tí Ọlọ́run fi hàn sí i sún Dáfídì láti fi ìbùkún fún Jèhófà.
Ṣé ẹlẹ́ṣẹ̀ bí tìrẹ kọ́ làwa náà ni? (Róòmù 5:12) Àní àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá kédàárò pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi. Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?” (Róòmù 7:22-24.) Ó mà yẹ ká kún fún ọpẹ́ o, pé Jèhófà kì í ṣàkọsílẹ̀ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wa! Tayọ̀tayọ̀ ló máa ń pa wọ́n rẹ́ nígbà táa bá ronú pìwà dà, táa sì tọrọ ìdáríjì.
Dáfídì rán ara rẹ̀ létí pé: “[Jèhófà] ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn.” (Sáàmù 103:3) Níwọ̀n bí ìmúláradá ti jẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò, ohun tó wé mọ́ ọn ju dídárí jini fún ìwà àìtọ́. Ó wé mọ́ mímú “àrùn” kúrò—ìyẹn ni àbájáde ìṣìnà wa. Nínú ayé tuntun rẹ̀ tó ń ṣètò lọ́wọ́, Jèhófà yóò mú àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ táa lè fojú rí kúrò pátápátá, irú bí àìsàn àti ikú. (Aísáyà 25:8; Ìṣípayá 21:1-4) Bó ti wù kí ó rí, lónìí pàápàá, Ọlọ́run ń wo àwọn àrùn wa nípa tẹ̀mí sàn. Fún àwọn kan, ìwọ̀nyí ní ẹ̀rí-ọkàn tí ń dáni lẹ́bi nínú, àti ìbátan tí kò dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀. “Má . . . gbàgbé” ohun tí Jèhófà ti ṣe fún olúkúlùkù wa nípa èyí.
Ó “Ń Gba Ìwàláàyè Rẹ Padà Kúrò”
Dáfídì kọrin pé: “[Jèhófà] ń gba ìwàláàyè rẹ padà kúrò nínú kòtò.” (Sáàmù 103:4) “Kòtò” yẹn túmọ̀ sí sàréè gbogbo aráyé—Ṣìọ́ọ̀lù, tàbí Hédíìsì. Àní kí Dáfídì tó di ọba lórí Ísírẹ́lì rárá, ikú ti gbé e hánu rí. Fún àpẹẹrẹ, Sọ́ọ̀lù, Ọba Ísírẹ́lì kórìíra Dáfídì burúkú-burúkú, ó sì pète àtipa á lọ́pọ̀ ìgbà. (1 Sámúẹ́lì 18:9-29; 19:10; 23:6-29) Àwọn Filísínì pẹ̀lú ń wá ikú Dáfídì. (1 Sámúẹ́lì 21:10-15) Ṣùgbọ́n ní gbogbo ìgbà, Jèhófà ń gbà á kúrò nínú “kòtò.” Ẹ wo bí Dáfídì ti kún fún ọpẹ́ tó bó ṣe ń rántí gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí Jèhófà ti ṣe!
Ìrẹ ńkọ́? Ǹjẹ́ Jèhófà tiẹ̀ ti dúró tì ẹ́ làwọn àkókò ìdààmú tàbí nígbà tí àdánù bá ẹ? Àbí o tiẹ̀ ti mọ̀ nípa àwọn ìgbà kan tó dá ẹ̀mí àwọn olóòótọ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀ sí kúrò nínú kòtò Ṣìọ́ọ̀lù ní àkókò wa? Bóyá àwọn ìtàn tóo ti kà nínú ìwé ìròyìn yìí nípa bó ṣe dáni nídè tilẹ̀ ti wú ẹ lórí. Èé ṣe tí o kò wáyè jókòó, kóo sì fi ẹ̀mí ìmọrírì ronú lórí nǹkan wọ̀nyí tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe? Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ ọ́, gbogbo wa pátá la ní ìdí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìrètí àjíǹde.—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
Jèhófà fún wa ní ìwàláàyè, ó tún fún wa ní ohun tí ń mú ìgbésí ayé gbádùn mọ́ni, kó sì wuni ní gbígbé. Onísáàmù náà pòkìkí pé Ọlọ́run “ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú dé ọ ládé.” (Sáàmù 103:4) Ní àkókò àìní, Jèhófà kì í fi wá sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ táa lè fojú rí àti nípasẹ̀ àwọn alàgbà, tàbí olùṣọ́ àgùntàn, tí a yàn, tó wà nínú ìjọ. Irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí a lè kojú àwọn ipò tí ń dánni wò láìjẹ́ pé a pàdánù ọ̀wọ̀ àti iyì wa. Àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn bìkítà púpọ̀ nípa àwọn àgùntàn. Wọ́n ń fún àwọn tí ń ṣàìsàn àti àwọn tó sorí kọ́ níṣìírí, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti mú àwọn tó ṣubú padà bọ̀ sípò. (Aísáyà 32:1, 2; 1 Pétérù 5:2, 3; Júdà 22, 23) Ẹ̀mí Jèhófà ní ń sún àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí láti fi ìyọ́nú àti ìfẹ́ hàn sí agbo náà. Ní tòótọ́, “inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú” rẹ̀ dà bí adé tó bẹwà kún wa, tó sì fi kún ọlá wa! Ká má ṣe gbàgbé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ láé, ṣùgbọ́n ká máa fi ìbùkún fún Jèhófà àti orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Bó ṣe ń ba ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ̀ lọ, Dáfídì onísáàmù náà kọrin pé: “[Jèhófà] ń fi ohun rere tẹ́ ọ lọ́rùn ní ìgbà ayé rẹ; ìgbà èwe rẹ ń sọ ara rẹ̀ dọ̀tun gẹ́gẹ́ bí ti idì.” (Sáàmù 103:5) Ìgbésí ayé onítẹ̀ẹ́lọ́rùn àti aláyọ̀ ni Jèhófà ń fúnni. Họ́wù, ìmọ̀ òtítọ́ alára jẹ́ ohun iyebíye tí kò láfiwé, tó sì jẹ́ orísun ayọ̀ ńláǹlà! Ẹ sì wo bí iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́ ti jẹ́ èyí tí ń fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn tó, ìyẹn ni iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ẹ wo bí inú wa ti máa dùn tó táa bá rí ẹnì kan tó fẹ́ kọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́, kí a sì wá ran ẹni náà lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà kí ó sì máa fi ìbùkún fún un! Síbẹ̀, yálà àwọn èèyàn lágbègbè wa fetí sílẹ̀ tàbí wọn kò fetí sílẹ̀, àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ tó jẹ mọ́ yíya orúkọ Jèhófà sí mímọ́ àti dídá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre.
Báa ti ń jára mọ́ iṣẹ́ pípòkìkí Ìjọba Ọlọ́run, ta ni kì í rẹ̀ tàbí tí agara kì í dá? Ṣùgbọ́n Jèhófà ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun, nípa mímú kí wọ́n ‘dà bí idì’ tó ní ìyẹ́ tó lágbára, tó sì lè fò lọ sókè réré. Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó pé Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ń pèsè irú “okun alágbára gíga” bẹ́ẹ̀ fún wa kí a bàa lè máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láti ọjọ́ dé ọjọ́!—Aísáyà 40:29-31.
Láti ṣàkàwé ohun táà ń sọ: Gbogbo ọjọ́ iṣẹ́ ni Clara ń lọ síbi iṣẹ́, síbẹ̀ ó tún ń lo nǹkan bí àádọ́ta wákàtí lóṣooṣù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó sọ pé: “Nígbà mìíràn ó máa ń rẹ̀ mí, ṣùgbọ́n màá sáà tiraka jáde fún iṣẹ́ ìsìn pápá torí pé mo ti ṣètò láti bá ẹnì kan jáde. Ṣùgbọ́n gbàrà tí mo bá ti dóde, agbára á kàn dé ni.” Ìwọ pẹ̀lú ti lè nírìírí irú okun bẹ́ẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ǹjẹ́ kí a sún ẹ láti sọ bí Dáfídì ti sọ nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú sáàmù yìí pé: “Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi, àní ohun gbogbo tí ń bẹ nínú mi, fi ìbùkún fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.”
Jèhófà Ń Dá Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Nídè
Onísáàmù náà tún kọrin pé: “Jèhófà ń mú àwọn ìṣe òdodo ṣẹ ní kíkún àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a ń lù ní jìbìtì. Ó sọ àwọn ọ̀nà rẹ̀ di mímọ̀ fún Mósè, àní ìbálò rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Sáàmù 103:6, 7) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “jìbìtì” tí àwọn ará Íjíbítì aninilára lu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè ni Dáfídì ní lọ́kàn. Ṣíṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe sọ ọ̀nà ìdáǹdè rẹ̀ di mímọ̀ fún Mósè ti ní láti ru ẹ̀mí ìmoore sókè nínú ọkàn-àyà Dáfídì.
Àwa náà lè ní irú ẹ̀mí ìmoore bẹ́ẹ̀ nípa ríronú lórí bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò. Ṣùgbọ́n yóò dára báa bá ń fara balẹ̀ ronú lórí ìrírí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tòde òní, irú àwọn ìrírí táa mẹ́nu kàn ní orí kọkàndínlọ́gbọ̀n àti ọgbọ̀n nínú ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom. Àwọn ìtàn tó wà nínú rẹ̀ àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí Watch Tower Society tẹ̀ jáde ń jẹ́ ká rí bí Jèhófà ti ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ lóde òní láti fara da ìfisẹ́wọ̀n, ìkọluni láti ọwọ́ àwọn èèyànkéèyàn, ìfòfindè, àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àti àgọ́ ìmúniṣiṣẹ́ bí akúra. Àwọn ará ti dojú kọ ọ̀pọ̀ ìdánwò ní àwọn ilẹ̀ tí ogun ti sọ di ẹdun arinlẹ̀, irú bí Burundi, Liberia, Rwanda, àti Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí. Nígbàkigbà tí inúnibíni bá sì dé, ìgbà gbogbo ni ọwọ́ Jèhófà ti mú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ dúró. Ríronú lórí iṣẹ́ wọ̀nyí tí Jèhófà, atóbilọ́lá Ọlọ́run wa ti ṣe, lè ṣe wá láǹfààní bí ṣíṣàṣàrò lórí àkọsílẹ̀ ìdáǹdè kúrò ní Íjíbítì ti ṣe Dáfídì láǹfààní.
Tún ronú nípa ọ̀nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà fi ń dá wa nídè kúrò nínú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀. Ó ti pèsè “ẹ̀jẹ̀ Kristi” láti “wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́.” (Hébérù 9:14) Nígbà táa bá ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, táa sì tọrọ ìdáríjì lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Kristi táa ta sílẹ̀, Ọlọ́run máa ń mú kí ìrélànàkọjá wa jìnnà sí wa—“bí yíyọ oòrùn ti jìnnà rere sí wíwọ̀ oòrùn”—ó sì máa ń mú kí a padà rí ojú rere òun. Sì tún ronú nípa àwọn ìpèsè tí Jèhófà ṣe nípasẹ̀ àwọn ìpàdé Kristẹni, àjọṣe tí ń gbéni ró, àwọn olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ, àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì táa ń rí gbà láti ọwọ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45) Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí Jèhófà ṣe kò ha ń sún wa láti fún ìbátan táa ní pẹ̀lú rẹ̀ lókun bí? Dáfídì kéde pé: “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. . . . Òun kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ ni òun kì í mú ohun tí ó yẹ wá wá sórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣìnà wa.” (Sáàmù 103:8-14) Ó dájú pé ṣíṣàṣàrò lórí àbójútó onífẹ̀ẹ́ Jèhófà lè sún wa láti máa yìn ín lógo, ká sì máa gbé orúkọ mímọ́ rẹ̀ lárugẹ.
“Ẹ Fi Ìbùkún fún Jèhófà, Gbogbo Ẹ̀yin Iṣẹ́ Rẹ̀”
Bí a bá fi wéra pẹ̀lú àìleèkú Jèhófà, “Ọlọ́run ayérayé,” ráńpẹ́ ni “ọjọ́” “ẹni kíkú” lóòótọ́—ó “dà bí ti koríko tútù.” Ṣùgbọ́n Dáfídì fi ẹ̀mí ìmọrírì sọ pé: “Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà jẹ́ láti àkókò tí ó lọ kánrin àní dé àkókò tí ó lọ kánrin sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ sí àwọn ọmọ-ọmọ, sí àwọn tí ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ àti sí àwọn tí ó rántí àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ̀ láti máa pa wọ́n mọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 21:33, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé ti New World Translation of the Holy Scriptures, With References; Sáàmù 103:15-18) Jèhófà kì í gbàgbé àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀. Tó bá tó àkókò lójú rẹ̀, yóò fún wọn ní ìyè ayérayé.—Jòhánù 3:16; 17:3.
Dáfídì fi hàn pé òun mọyì ipò ọba Jèhófà, ó sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ọ̀run gan-an; àkóso rẹ̀ sì ń jọba lórí ohun gbogbo.” (Sáàmù 103:19) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà kan rí a lè fojú rí ibùjókòó ipò ọba Jèhófà nígbà tí ìjọba Ísírẹ́lì ń ṣojú fún un, síbẹ̀ ọ̀run ni ìtẹ́ Ọlọ́run wà. Nítorí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, òun ni Alákòóso Gíga Jù Lọ lágbàáyé, ó sì ń ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ète rẹ̀.
Dáfídì tilẹ̀ gba áńgẹ́lì ẹ̀dá ẹ̀mí tí ń bẹ lọ́run pàápàá níyànjú. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀, tí ẹ tóbi jọjọ nínú agbára, tí ẹ ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, nípa fífetísí ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ẹ̀yin òjíṣẹ́ rẹ̀, tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin iṣẹ́ rẹ̀, ní gbogbo ibi tí ó ń jọba lé. Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi.” (Sáàmù 103:20-22) Ǹjẹ́ kò yẹ kí ríronú táa bá ń ronú lórí àwọn ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ń ṣe fún wa, máa sún wa láti fi ìbùkún fún un? Bó ṣe yẹ kó rí gan-an nìyẹn! Ó sì dájú pé ìró ohùn tiwa nínú ìyìn sí Ọlọ́run kò lè rá láàárín ìhó ìyìn ńláǹlà tí ń jáde látẹnu àwọn olùyin Ọlọ́run, títí kan àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ pàápàá. Ǹjẹ́ kí a máa fi tọkàntọkàn yin Baba wa ọ̀run, kí a máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere nígbà gbogbo. Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ Dáfídì sọ́kàn pé, “Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti pa àwọn orúkọ kan dà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Dáfídì ṣàṣàrò lórí àwọn ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ṣe. Ìwọ ńkọ́?