Jèhófà Ti Jẹ́ Àpáta Gàǹgà Mi
GẸ́GẸ́ BÍ EMMANUEL LIONOUDAKIS ṢE SỌ Ọ́
Màmá mi lejú mọ́ mi, ó sì sọ fún mi pé: “Tó bá jẹ́ ìpinnu tìrẹ lo fẹ́ tẹ̀ lé, a jẹ́ pé wàá filé yìí sílẹ̀ nìyẹn.” Mo ti pinnu láti máa fàkókò kíkún wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, ìdílé mi kò lè fara da ìtìjú náà mọ́ báwọn ọlọ́pàá ṣe wá ń mú mi lọ sátìmọ́lé ní gbogbo ìgbà.
ÀWỌN obí mi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rù Ọlọ́run. Wọ́n ń gbé abúlé Douliana, ní ìwọ̀ oòrùn erékùṣù Gíríìkì ti Kírétè, níbi tí wọ́n ti bí mi ní ọdún 1908. Àtìgbà èwe mi ni wọ́n ti kọ́ mi láti bẹ̀rù Ọlọ́run, kí n sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ń kò rí Bíbélì lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ tàbí àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì rí, síbẹ̀ mo nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Lẹ́yìn tí aládùúgbò wa kan ka ìdìpọ̀ mẹ́fà ìwé Studies in the Scriptures, tí C. T. Russell, ṣe jáde àti ìwé náà, Duru Ọlọrun, ló wá fìtara sọ fún mi nípa àwọn kókó tí àwọn ìwé wọ̀nyẹn la òun lójú láti rí nínú Ìwé Mímọ́. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà, ló ṣe àwọn ìwé wọ̀nyẹn jáde. Mo fi tayọ̀tayọ̀ gba ẹ̀dà Bíbélì kan àti àwọn ìwé tó wá láti ọ́fíìsì Watch Tower Society ni Áténì. Mo ṣì lè rántí bí mo ṣe wà lọ́dọ̀ aládùúgbò wa yẹn títí di ọ̀gànjọ́ òru, tí mò ń gbàdúrà sí Jèhófà, tí mo sì tanná àbẹ́là mọ́rí, tí mò ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mò ń kà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyẹn.
Ọmọ ogún ọdún ni mí nígbà tí mò ń ṣe iṣẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ tó wà lábúlé kan nítòsí tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí nínú Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn. Kò pẹ́ tí àwa mẹ́rin fi bẹ̀rẹ̀ sí pàdé fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé ní Douliana. A tún ń pín ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé kékeré, ìwé ńlá, àti àwọn Bíbélì kí a lè ran àwọn èèyàn mìíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrètí kan ṣoṣo fún ìran ènìyàn, ìyẹn ni Ìjọba Ọlọ́run.
Ní 1931, a pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn jákèjádò ayé tó tẹ́wọ́ gba orúkọ tí a gbé ka Bíbélì náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísáyà 43:10) Láàárín ọdún tó tẹ̀ lé e, a kópa nínú ìpolongo kan tí a ṣe ní gbangba láti ṣàlàyé orúkọ wa tuntun àti ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ fún àwọn aláṣẹ. Lára ìpolongo yìí náà ni pínpín ìwé kékeré kan tó ṣe pàtàkì fún gbogbo àlùfáà, adájọ́, ọlọ́pàá, àti àwọn oníṣòwò tí wọ́n wà lágbègbè wa.
Gẹ́gẹ́ bí a ti retí, àwọn àlùfáà súnná si àgbáàràgbá inúnibíni. Àkọ́kọ́ pàá tí wọ́n mú mi, wọ́n fi mi sẹ́wọ̀n ogúnjọ́. Kété lẹ́yìn tí wọ́n fi mí sílẹ̀ ni wọ́n tún mú mi tí wọ́n sì fi mí sẹ́wọ̀n oṣù kan. Nígbà tí adájọ́ kan sọ pé a kò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, a fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣe 5:29 dá a lóhùn pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” Lẹ́yìn náà ní 1932, aṣojú Watch Tower Society bẹ̀ àwùjọ wa kékeré tó wà ní Douliana wò, àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì ṣe ìrìbọmi.
Mo Rí Ìdílé Nípa Tẹ̀mí
Nítorí ìfẹ́ tí mo ní láti túbọ̀ ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà sí i, mo kọ̀wé fi ipò olùkọ́ tí mo wà sílẹ̀. Ìyẹn ló wá ga jù, màmá mi ò lè fara dà á. Ló bá ní kí n jáde nílé. Pẹ̀lú ìfọwọ́sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower tó wà ní Áténì, arákùnrin Kristẹni kan tó jẹ́ ọ̀làwọ́ tó ń gbé ní ìlú Iráklion, ní Kírétè fi tayọ̀tayọ̀ gbà mi sílé rẹ̀. Nítorí náà, ní August 1933, àwọn arákùnrin láti abúlé mi àti àwọn olùfìfẹ́hàn díẹ̀ wá sí ibùdókọ̀ láti juwọ́ sí mi pé ó dìgbà. Àkókò tí ń dótùútù pani gbáà ni, gbogbo wa ló sọkún, nígbà tó jẹ́ pé a kò mọ ìgbà tí a óò tún fojú gán-án-ní ara wa.
Nígbà tí mo dé Iráklion, mo di apá kan ìdílé tẹ̀mí kan tó nífẹ̀ẹ́. Àwọn Kristẹni arákùnrin mẹ́ta mìíràn àti arábìnrin kan tí a jọ máa ń pàdé déédéé fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìjọsìn wà níbẹ̀. Mo wá rí ìmúṣẹ ìlérí tí Jésù ṣe ní tààràtà pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó fi ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá tàbí baba tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá nítorí mi àti nítorí ìhìn rere tí kì yóò gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí, àwọn ilé àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá.” (Máàkù 10:29, 30) Iṣẹ́ tí a yàn fún mi ni kí n wàásù ní ìlú yẹn àti ní àwọn abúlé tó wà nítòsí. Lẹ́yìn tí mo wàásù ní gbogbo ìlú náà tán, mo gbéra ó di àwọn àgbègbè tí àwọn oníṣẹ́ ìjọba ń gbé ní Iráklion àti Lasithion.
Aṣáájú Ọ̀nà Tó Ń Dá Ṣiṣẹ́
Ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo fi ń rìn láti abúlé dé abúlé. Pẹ̀lú ìyẹn, mo tún ní láti ru ọ̀pọ̀ ìwé, nítorí pé ọkọ̀ tí a fi ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kì í wá déédéé. Níwọ̀n bí n kò ti ní ibi tí n ó sùn, mo máa ń lọ sílé tí wọ́n ti ń ta kọfí lábúlé náà, màá wá dúró títí tí gbogbo oníbàárà wọ́n yóò fi lọ tán—ìyẹn sábà máa ń jẹ́ lọ́gànjọ́ òru—n ó wá sùn sórí àga kan níbẹ̀, n ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì kí ẹni tó ni ṣọ́ọ̀bù tó bẹ̀rẹ̀ sí í ta kọfí fún àwọn oníbàárà rẹ̀. Àìmọye ìdun la jọ máa ń sùn sórí àga yẹn.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn kì í sábà fi ìfẹ́ hàn, síbẹ̀ mo láyọ̀ pé mo lo okun ìgbà èwe mi fún Jèhófà. Nígbà tí mo bá rí ẹnì kan tó fi ìfẹ́ hàn sí òtítọ́ Bíbélì, ó máa ń sọ ìpinnu mi láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ń gbẹ̀mí là yìí nìṣó dọ̀tun. Ìbákẹ́gbẹ́ tí mo ní pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi nípa tẹ̀mí tún ń tù mí lára. Mo máa ń rí wọn lẹ́yìn tí mo bá ti lọ fún ogúnjọ́ tàbí àádọ́ta ọjọ́, ìyẹn wà lọ́wọ́ bí ibi tí mo bá ti lọ wàásù ṣe jìnnà sí Iráklion tó.
Mo ṣì rántí bí ìrònú ṣe bá mi tó nípa bí nǹkan ṣe rí fún mi lọ́sàn-án ọjọ́ kan nígbà tí ojú ń ro mí nítorí kò sí ẹlòmíràn tó jẹ́ ará nítòsí, pàápàá nígbà tí mo ń ronú pé àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin ní Iráklion yóò ṣe ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe déédéé ní ìrọ̀lẹ́ yẹn. Ọkàn mi fà sí wọn gan-an débi pé mo pinnu láti fẹsẹ̀ rin kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó wà láàárín èmi àtàwọn. N ò yára rìn tó bẹ́ẹ̀ rí. Ẹ wo bó ṣe tù mí nínú tó láti gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ aládùn pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi ní ìrọ̀lẹ́ yẹn, tí mo sì tún gba okun nípa tẹ̀mí!
Kò pẹ́ kò jìnnà, akitiyan ìwàásù mi bẹ̀rẹ̀ sí sèso. Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí ní ayé àwọn àpọ́sítélì, ‘Jèhófà ń bá a lọ láti mú àwọn tí a ń gbà là dara pọ̀ mọ́ wa.’ (Ìṣe 2:47) Iye àwọn olùjọsìn Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí lọ sókè ní Kírétè. Àwọn ẹlòmíràn tó dara pọ̀ mọ́ mi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà kò jẹ́ kójú máa ro mí mọ́. A fara da ìyà ojúkoojú àti àtakò líle koko. Búrẹ́dì pẹ̀lú àwọn ẹyin èyíkéyìí, àti ólífì, tàbí àwọn ewébẹ̀ tí a bá fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn tí a wàásù fún gbà lọ́wọ́ wa ni oúnjẹ wa.
Ìlú Ierápetra ní gúúsù ìlà oòrùn Kírétè ni mo ti wàásù fún Minos Kokkinakis, tó ń ta aṣọ. Pẹ̀lú gbogbo ìsapá tí mo ṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀, ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló ní nítorí ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí gan-an. Àmọ́, nígbà tó wá pinnu láti fọwọ́ gidi mú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ níkẹyìn, kíá ló yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà. Òun ló tún wá di ẹni tó nítara jù lọ, tó tún gbó ṣáṣá jù lọ nínú kíkéde ìhìn rere náà. Àwọn ìyípadà wọ̀nyẹn dùn mọ́ Emmanuel Paterakis, ọmọ ọdún méjìdínlógún tó ń bá Kokkinakis ṣiṣẹ́, nínú gan-an, kò sì pẹ́ tí òun náà béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú mi mà dùn o, nígbà tí mo rí i tó ń tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí tó sì wá di míṣọ́nnárì níkẹyìn!a
Láàárín àkókò kan náà, ìjọ tí mo fi sílẹ̀ ní abúlé mi ń pọ̀ sí i, ó ti ní akéde mẹ́rìnlá báyìí. N kò lè gbàgbé ọjọ́ ti mo ka lẹ́tà tó wá látọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Despina láé, tó ń sọ fún mi pé òun àti àwọn òbí mi ti gba òtítọ́, wọ́n sì ti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí olùjọ́sìn Jèhófà!
Fífarada Inúnibíni àti Ìlékúrò Láwùjọ
Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì bẹ̀rẹ̀ sí wo iṣẹ́ ìwàásù wa bí ẹni pé eéṣú tí ń sọ nǹkan di ahoro ni wá, wọ́n sì pinnu láti run wá pátápátá. Ní oṣù March 1938, wọ́n mú mi wá síwájú adájọ́ tó sọ pé dandan ni kí n fi àgbègbè náà sílẹ̀. Mo fèsì pé ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù wa ń ṣeni láǹfààní, àti pé ẹni tí ó ní ọlá àṣẹ jù ló pàṣẹ fún wa láti máa ṣe iṣẹ́ náà, ìyẹn ni Jésù Kristi Ọba wa.—Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:8.
Ní ọjọ́ kejì, wọ́n mú mi lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ládùúgbò. Ibẹ̀ ni wọ́n ti sọ fún mi pé eléwu ènìyàn ni mo jẹ́ láwùjọ, wọ́n sì lé mi lọ sí erékùṣù Aegean ti Amorgos fún ọdún kan gbáko. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà ni wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi gbé mi lọ si erékùṣù náà pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lọ́wọ́. Kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà mìíràn rárá ní Amorgos. Ẹ wá wo bí inú mi ṣe dùn tó nígbà tí mo gbọ́ lẹ́yìn oṣù mẹ́fà pé wọ́n ti lé Ẹlẹ́rìí mìíràn wá sí erékùṣù náà! Ta ni ì bá jẹ́? Minos Kokkinakis ni, ẹni tí mo bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Kírétè. Inú mi mà dùn o, pé mo wá ní alábàákẹ́gbẹ́ nípa tẹ̀mí! Nígbà tó ṣe díẹ̀ sí i, mo láǹfààní láti ṣe ìrìbọmi fún un ní Amorgos.b
Kété lẹ́yìn tí mo padà sí Kírétè ni wọ́n tún mú mi, lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n lé mi lọ sí ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Neapólísì ní erékùṣù yẹn. Lẹ́yìn tí oṣù mẹ́fà tí wọ́n fi lé mi kúrò nílùú parí, wọ́n tún mú mi, wọ́n sì fi mí sẹ́wọ̀n fọ́jọ́ mẹ́wàá, kí wọ́n tóó padà lé mi lọ sí erékùṣù kan tó wà fún kìkì àwọn Kọ́múníìsì tí wọ́n lé kúrò láwùjọ, oṣù mẹ́rin ni ìyẹn gbà. Mo wá mọ bí àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti jẹ́ òótọ́ tó pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.”—2 Tímótì 3:12.
Ìbísí Wà Láìka Inúnibíni Sí
Díẹ̀ ló kù kí ìgbòkègbodò ìwàásù wa dúró nígbà tí àwọn ará Jámánì gbógun ti Gíríìsì ní àwọn ọdún 1940 sí 1944. Bó ti wù kó rí, kíá ní àwọn ènìyàn Jèhófà tó wà ní Gíríìsì tún ètò ara wọ́n ṣe, tí a sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù wa lákọ̀tun. Láti dí àwọn àkókò táa ti pàdánù, a wá sapá gan-an nínú iṣẹ́ Ìjọba náà, a sì fìtara ṣe é.
Gẹ́gẹ́ bí a ti retí, àtakò ìsìn tún dìde lẹ́ẹ̀kan sí i. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì ló máa ń mọ̀ọ́mọ̀ dá irú wàhálà bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. Nígbà táa wà ní ọ̀kan nínú àwọn abúlé náà, àlùfáà kan dẹ àwọn ọ̀daràn kan sí wa. Àlùfáà náà fúnra rẹ̀ ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lù mí tí ọmọ rẹ̀ náà sì ń lù mí látẹ̀yìn. Ni mo bá sá sínú ilé kan tó wà nítòsí, kí wọ́n má baà pa mí, wọ́n sì wọ́ ẹni táa jọ ń wàásù tuuru lọ sí gbọ̀ngàn abúlé náà. Níbẹ̀ ni àwọn ọ̀daràn náà ti fa àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ya, tí obìnrin kan sì ń ké láti ọ̀dẹ̀dẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì rẹ̀ pé, “Ẹ pa á sọ nù!” Níkẹyìn, dókítà kan àti ọlọ́pàá kan tó ń kọjá ló gbà wá sílẹ̀.
Lẹ́yìn náà, ní 1952, wọ́n tún mú mi, wọ́n sì tún lé mi kúrò nílùú fún oṣù mẹ́rin, ibi tí wọ́n lé mi lọ ni Kastelli Kissamos, ti Kírétè. Lọ́gán lẹ́yìn náà, mo gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti máa bẹ àwọn ìjọ wò, kí ń sì máa fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn tí mo lo ọdún méjì nínú irú iṣẹ́ arìnrìn-àjò yìí, mo fẹ́ arábìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Despina, olórúkọ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, ẹ̀rí sì fi hàn láti ìgbà náà títí di ìsinsìnyí pé adúróṣinṣin olùjọ́sìn Jèhófà ni. Lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, wọ́n yàn mí láti lọ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní ìlú Hania, ní Kírétè, níbi tí mo ti ń sìn di báyìí.
Láàárín ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́rin ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, mo ti kárí apá ibi tó pọ̀ jù lọ ní Kírétè—erékùṣù kan tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà níbùú lóròó, tí gígùn rẹ̀ sì ń lọ sí nǹkan bí àádọ́talénígba kìlómítà. Ohun tí ń mú inú mi dùn jù lọ ni bí mo ṣe ń rí àwọn Ẹlẹ́rìí tí kò ju kéréje ní àwọn ọdún 1930 tí wọ́n ti wá lọ sókè ju ọgọ́rùn-únlélẹ́gbẹ̀rún àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run lónìí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àǹfààní tó fún mi láti nípìn-ín nínú ríran ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ pípéye tó wà nínú Bíbélì, kí wọ́n sì ní ìrètí àgbàyanu fún ọjọ́ iwájú.
Jèhófà, “Olùpèsè Àsálà”
Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti jẹ́ kí n mọ̀ pé ó gba ìfaradà àti sùúrù láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run tòótọ́. Jèhófà fi ọ̀làwọ́ pèsè àwọn ànímọ́ tó pọndandan wọ̀nyí. Láàárín ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin tí mo fi wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, léraléra ni àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń wá sí mi lọ́kàn pé: “Lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, nípa ìfaradà púpọ̀, nípa àwọn ìpọ́njú, nípa àwọn ọ̀ràn àìní, nípa àwọn ìṣòro, nípa lílù, nípa ẹ̀wọ̀n, nípa rúgúdù, nípa òpò, nípa àwọn òru àìlèsùn, nípa àwọn àkókò àìsí oúnjẹ.” (2 Kọ́ríńtì 6:4, 5) Pàápàá nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn, ipò ìṣúnná owó mi kò dáa rárá. Síbẹ̀, Jèhófà kò fìgbà kankan fi èmi àti ìdílé mi sílẹ̀. Ó ti fi hàn pé òun jẹ́ Olùrànlọ́wọ́ tó lágbára tí kì í sì í jáni kulẹ̀. (Hébérù 13:5, 6) Gbogbo ìgbà la ń rí ọwọ́ onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lára bó ṣe ń kó àwọn àgùntàn jọ àti bó ṣe ń pèsè fún àwọn àìní wa.
Nígbà tí mo bá bojú wẹ̀yìn tí mo sì rí i pé, aṣálẹ̀ ti yọ òdòdó, nípa tẹ̀mí, ó dá mi lójú pé iṣẹ́ tí mo ṣe kò já sí asán. Mo ti lo okun ìgbà èwe mi lọ́nà tó ṣàǹfààní jù lọ. Fífi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé mi ti jẹ́ iṣẹ́ tó nítumọ̀ ju ìlépa èyíkéyìí mìíràn lọ. Nísinsìnyí tí mo ti di arúgbó, mo lè fi tọkàntọkàn fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti ‘rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá, ní ìgbà èwe wọn.’—Oníwàásù 12:1.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti di ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún, mo ṣì ń fi ohun tó lé ní ọgọ́fà wákàtí wàásù lóṣooṣù. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń jí ni aago méje ààbọ̀ òwúrọ̀ láti jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn lójú pópó, nílé ìtajà, tàbí ní àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí. Ní ìpíndọ́gba, mo ń fi àádọ́jọ ìwé ìròyìn sóde lóṣooṣù. Ní báyìí, n ò gbọ́ràn dáadáa mọ́, n ò sì lè tètè rántí nǹkan, ìwọ̀nyí mú kí ìgbésí ayé nira fún mi, àmọ́ àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin mi onífẹ̀ẹ́—ìdílé ńlá tí mo ni nípa tẹ̀mí—títí kan ìdílé àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì ti jẹ́ ìtìlẹ́yìn gidi fún mi.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mó ti kọ́ láti máa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Látìgbà yìí wá, ó ti fi hàn pé òun jẹ́ “àpáta gàǹgà mi àti odi agbára mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.”—Sáàmù 18:2.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti kà nípa ìtàn ìgbésí ayé Emmanuel Paterakis, wo Ilé Ìṣọ́, November 1, 1996, ojú ìwé 22 sí 27.
b Láti kà nípa ìgbẹ́jọ́ kan tí Minos Kokkinakis ti jàre, wo Ilé-Ìṣọ́nà, September 1, 1993, ojú ìwé 27 sí 31. Minos Kokkinakis kú ní January 1999.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Ní ìsàlẹ̀: Èmi àti ìyàwó mi; lápá òsì: ní 1927; ní ojú ìwé tó dojú kọ ọ́: èmi àti Minos Kokkinakis (lápá òsì) èmi àti Ẹlẹ́rìí mìíràn ní Acropolis, ní 1939, kété lẹ́yìn tí mo ti ìgbèkùn dé.