ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 9/15 ojú ìwé 16-21
  • Ṣé Ohun Tí Jèhófà Ń béèrè Lọ́wọ́ Wa Pọ̀ Jù Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ohun Tí Jèhófà Ń béèrè Lọ́wọ́ Wa Pọ̀ Jù Ni?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jèhófà Béèrè Láyé Ọjọ́un
  • Òfin Tí Jèhófà fún Ísírẹ́lì
  • Ṣé Òfin Jèhófà Nira Ni?
  • Ohun Náà Gan-an Tí Jèhófà Ń Béèrè
  • Kò Pọ̀ Jù
  • Jagunjagun àti Ọmọbìnrin Kékeré Kan
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ó Kọ́kọ́ Ṣàìgbọràn àmọ́ Nígbà Tó Yá Ó Ṣègbọràn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkọ Ọ̀gá Rẹ̀ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ọmọbìnrin Kékeré Kan Tí Ó Fìgboyà Sọ̀rọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 9/15 ojú ìwé 16-21

Ṣé Ohun Tí Jèhófà Ń béèrè Lọ́wọ́ Wa Pọ̀ Jù Ni?

“Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—MÍKÀ 6:8.

1. Kí ló lè fà á tí àwọn kan kò fi sin Jèhófà?

JÈHÓFÀ n béèrè nǹkan kan lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀. Àmọ́, lẹ́yìn kíka àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí bí a ti ṣàyọlò rẹ̀ láti inú àsọtẹ́lẹ̀ Míkà, o lè wá parí èrò sí pé àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń béèrè kò pọ̀ jù. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ni kò sin Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, àwọn kan tí wọ́n tiẹ̀ ń sìn ín tẹ́lẹ̀ kò sìn ín mọ́. Èé ṣe? Nítorí wọ́n rò pé ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa ti pọ̀ jù. Ṣé bẹ́ẹ̀ ni? Àbí èrò tí ẹnì kan ní nípa ohun tí Jèhófà ń béèrè gan-an ló ń fa ìṣòro? Ìtàn kan tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ yóò fún wa ní òye tó jinlẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí.

2. Ta ni Náámánì, kí sì ni wòlíì Jèhófà sọ pé kó ṣe?

2 Ẹ̀tẹ̀ bo Náámánì, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà, àmọ́, ẹnì kan sọ fún un pé wòlíì Jèhófà kan wà ní Ísírẹ́lì tó lè wò ó sàn. Bí Náámánì àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ṣe gbéra nìyẹn tí wọ́n sì rìnrìn àjò lọ sí Ísírẹ́lì, níkẹyìn, wọ́n dé ilé Èlíṣà, wòlíì Ọlọ́run. Dípò tí Èlíṣà ì bá fi jáde wá kí àlejò rẹ̀ pàtàkì yìí, ṣe ló ní kí ìránṣẹ́ kan lọ sọ fún Náámánì pé: “Kí o wẹ̀ ní ìgbà méje nínú Jọ́dánì kí ẹran ara rẹ lè padà sára rẹ; kí o sì mọ́.”—2 Àwọn Ọba 5:10.

3. Èé ṣe tí Náámánì fi kọ́kọ́ kọ̀ láti ṣe ohun tí Jèhófà béèrè?

3 Bí Náámánì bá gba ohun tí wòlíì Ọlọ́run ní kó ṣe yìí, àrùn burúkú tó ń ṣe é yóò sàn. Ǹjẹ́ a wá lè sọ pé ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ti pọ̀ jù? Rárá o. Síbẹ̀, Náámánì ò fẹ́ ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Ńṣe ló yarí, tó sọ pé: “Ábánà àti Fápárì, àwọn odò Damásíkù, kò ha sàn ju gbogbo omi Ísírẹ́lì? Ṣé n kò lè wẹ̀ nínú wọn ni kí n sì mọ́ dájúdájú?” Bí Náámánì ti sọ̀rọ̀ yìí tán, ló kágídí borí, ló bá tirẹ̀ lọ.—2 Àwọn Ọba 5:12.

4, 5. (a) Kí ni èrè ìgbọ́ràn Náámánì, kí ló sì ṣe nígbà tó gbà á tán? (b) Kí la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?

4 Kí ló jẹ́ ìṣòro Náámánì gan-an? Kì í ṣe pé ohun tí wọ́n ní kó ṣe yẹn ṣòro jù fún un láti ṣe. Àwọn ìránṣẹ́ Náámánì wá fọgbọ́n sọ fún un pé: “Ká ní ohun ńlá kan ni wòlíì náà bá ọ sọ, ìwọ kí yóò ha ṣe é bí? Mélòómélòó wá ni, níwọ̀n bí ó ti wí fún ọ pé, ‘Wẹ̀, kí o sì mọ́’?” (2 Àwọn Ọba 5:13) Ẹ̀mí tí Náámánì fi gbà á ni ìṣòro tó wà níbẹ̀. Ó rò pé wọn kò fi ọ̀wọ̀ tó yẹ òun wọ òun àti pé ó gbà pé ohun tí wọ́n ní kí òun ṣe kò lè ṣiṣẹ́ kankan, ó sì tún tàbùkù òun. Àmọ́, Náámánì tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dọ́gbọ́n fi fún un, ó sì lọ ri ara rẹ̀ bọ Odò Jọ́dánì nígbà méje. Fojú inú wo bí ayọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó nígbà tí ‘ẹran ara rẹ̀ padà wá gẹ́gẹ́ bí ẹran ara ọmọdékùnrin kékeré, tó sì mọ́’! Ó kún fún ìmoore. Ní àfikún sí i, Náámánì polongo pé láti ọjọ́ náà lọ, òun kò ní sin ọlọ́run mìíràn mọ́ bí kò ṣe Jèhófà.—2 Àwọn Ọba 5:14-17.

5 Jálẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn ni Jèhófà ti ń rọ àwọn ènìyàn láti tẹ̀ lé àwọn òfin kan. A rọ̀ ọ́ láti gbé mélòó kan lára wọn yẹ̀ wò. Bí o ti ń gbé wọn yẹ̀ wò, máa bi ara rẹ ohun tóò bá ṣe, ká ní ìwọ ni Jèhófà sọ pé kó ṣe irú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Lẹ́yìn náà, a ó wá gbé ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa lónìí yẹ̀ wò.

Ohun Tí Jèhófà Béèrè Láyé Ọjọ́un

6. Kí la béèrè lọ́wọ́ tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́, kí ni ìwọ náà ì bá ṣe sí irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀?

6 Jèhófà pàṣẹ fún Ádámù àti Éfà, tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́, láti bímọ, kí wọ́n ṣèkáwọ́ ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì jọba lórí gbogbo ẹranko. Ó tún fi ilé ńlá kan tó dà bí ọgbà ìtura jíǹkí ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:9-15) Àmọ́, ó fún wọn lófin. Igi kan wà níbẹ̀ tí wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, ìyẹn ni ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ igi eléso tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Aà ṣáà lè pèyẹn ní bíbéèrè ohun tó pọ̀ jù, àbó pọ̀ jù? Ǹjẹ́ oò ní gbádùn ṣíṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ète àtiwàláàyè títí láé nínú ìlera pípé? Ká tilẹ̀ sọ pé atannijẹ kan wá sínú ọgbà náà, ǹjẹ́ oò ní kọ ìtànjẹ rẹ̀? Ǹjẹ́ oò sì ní gbà pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti fún ọ lófin kan ṣoṣo yẹn?—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.

7. (a) Irú iṣẹ́ wo la yàn fún Nóà, àtakò wo ló sì rí? (b) Ojú wo lo fi wo ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ Nóà?

7 Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jèhófà sọ fún Nóà pé kó kan áàkì kan kí ó lè tipasẹ̀ rẹ̀ la àkúnya omi tí yóò kárí ayé já. Bí a bá wo bí áàkì náà ṣe tóbi tó, a óò rí i pé iṣẹ́ náà kò rọrùn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bó ti ń bá iṣẹ́ náà lọ, ni wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń kógun tì í. Síbẹ̀, ẹ wo àǹfààní ńlá tó jẹ́ fún Nóà láti dáàbò bo agboolé rẹ̀, ká má tiẹ̀ tí ì sọ ti ọ̀pọ̀ ẹranko tó tún dáàbò bò pẹ̀lú! (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-8, 14-16; Hébérù 11:7; 2 Pétérù 2:5) Ká níwọ la fún nírú iṣẹ́ yẹn, ǹjẹ́ o kò ní sa gbogbo agbára rẹ láti ṣe é parí? Àbí wàá kàyẹn sí pé Jèhófà ń béèrè ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ rẹ?

8. Kí la sọ pé kí Ábúráhámù ṣe, kí sì ni bó ṣe gbà láìjanpata ṣàkàwé?

8 Ọlọ́run ní kí Ábúráhámù ṣe ohun kan tó ṣòro gan-an, ó sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, mú ọmọkùnrin rẹ, ọmọkùnrin rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi, Ísákì, kí o sì rìnnà àjò lọ sí ilẹ̀ Móráyà, kí o sì fi í rúbọ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:2) Níwọ̀n bí Jèhófà ti ṣèlérí pé Ísákì tí kò tí ì ní ọmọ nígbà náà yóò ní ọmọ, a wá dán ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní nínú agbára Ọlọ́run wò, láti mọ̀ bóyá ó gbà lóòótọ́ pé Ọlọ́run lè mú kí Ísákì padà wà láàyè. Nígbà tí Ábúráhámù fẹ́ fi Ísákì rúbọ, Ọlọ́run dá ọmọkùnrin náà sí. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣàkàwé bí Ọlọ́run yóò ṣe fi Ọmọ tirẹ̀ rúbọ fún aráyé, lẹ́yìn náà, yóò sì jí i dìde.—Jẹ́nẹ́sísì 17:19; 22:9-18; Jòhánù 3:16; Ìṣe 2:23, 24, 29-32; Hébérù 11:17-19.

9. Èé ṣe tí a kò fi lè sọ pé ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ Ábúráhámù pọ̀ jù?

9 Àwọn kan lè rò pé Jèhófà Ọlọ́run ń béèrè ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ Ábúráhámù. Àmọ́, ṣé bẹ́ẹ̀ ni? Ṣé lóòótọ́ ló jẹ́ ìwà ìkà pé Ẹlẹ́dàá wa, ẹni tó lè jí òkú dìde, béèrè pé kí a gbọ́ràn sóun lẹ́nu, kódà bó tilẹ̀ máa yọrí sí pé ká sùn nínú ikú fúngbà díẹ̀? Jésù Kristi àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ìjímìjí kò ronú bẹ́ẹ̀. Wọ́n gbà pé kí a ṣe àwọn léṣe, kódà wọn ò kọ̀ láti kú, kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Jòhánù 10:11, 17, 18; Ìṣe 5:40-42; 21:13) Bí ipò nǹkan bá béèrè fún un, ṣe wàá ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀? Gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn nǹkan tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n gbà láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀.

Òfin Tí Jèhófà fún Ísírẹ́lì

10. Àwọn wo ló ṣèlérí láti ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà béèrè, kí ló sì fún wọn?

10 Àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù nípasẹ̀ Ísákì ọmọ rẹ̀ àti Jékọ́bù tàbí Ísírẹ́lì ọmọ-ọmọ rẹ̀, ló di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì. (Jẹ́nẹ́sísì 32:28; 46:1-3; 2 Sámúẹ́lì 7:23, 24) Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n ṣèlérí láti ṣe ohunkóhun tí Ọlọ́run bá béèrè lọ́wọ́ wọn. Wọ́n sọ pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.” (Ẹ́kísódù 19:8) Kí Jèhófà lè ṣe ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ fún wọn, ìyẹn ni pé kó máa ṣàkóso wọn, ó fún orílẹ̀-èdè náà ní òfin tó lé ní ẹgbẹ̀ta, títí kan Òfin Mẹ́wàá. Láìpẹ́, àwọn òfin wọ̀nyí, tí Ọlọ́run fún wọn nípasẹ̀ Mósè, wá di èyí tí a wulẹ̀ mọ̀ sí Òfin.—Ẹ́sírà 7:6; Lúùkù 10:25-27; Jòhánù 1:17.

11. Kí ni ọ̀kan lára ète Òfin náà, àwọn ìlànà wo ló sì ṣèrànwọ́ láti mú ète náà ṣẹ?

11 Ọ̀kan nínú ète Òfin náà ni láti dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa pípèsè àwọn ìlànà tó gbámúṣé fún wọn lórí àwọn ọ̀ràn bí ìṣekúṣe, ìṣòwò, àti àbójútó ọmọ. (Ẹ́kísódù 20:14; Léfítíkù 18:6-18, 22-24; 19:35, 36; Diutarónómì 6:6-9) Àwọn òfin tún wà fún wọn nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sí àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, títí kan ọwọ́ tí wọ́n gbọ́dọ̀ fi mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn pẹ̀lú. (Léfítíkù 19:18; Diutarónómì 22:4, 10) Àwọn ìlànà tó ní í ṣe pẹ̀lú àjọyọ̀ ọdọọdún àti pípàdé pọ̀ fún ìjọsìn tún ń ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo ipò tẹ̀mí àwọn ènìyàn náà.—Léfítíkù 23:1-43; Diutarónómì 31:10-13.

12. Kí ni olórí ète Òfin náà?

12 Ète pàtàkì tí Òfin náà ní ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn, nígbà tó kọ̀wé pé: “A fi kún un láti mú kí àwọn ìrélànàkọjá fara hàn kedere, títí irú-ọmọ [Kristi] tí a ṣe ìlérí fún yóò fi dé.” (Gálátíà 3:19) Òfin náà rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé aláìpé ni wọ́n. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé wọ́n nílò ẹbọ pípé tí yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò pátápátá. (Hébérù 10:1-4) Nítorí bẹ́ẹ̀ ni a ṣe pète Òfin náà láti múra àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ kí wọ́n lè tẹ́wọ́ gba Jésù, tó jẹ́ Mèsáyà, tàbí Kristi. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè polongo wa ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́.”—Gálátíà 3:24.

Ṣé Òfin Jèhófà Nira Ni?

13. (a) Kí ni àwọn aláìpé ènìyàn ka Òfin náà sí, èé sì ti ṣe? (b) Ṣé lóòótọ́ ni Òfin náà nira?

13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin náà jẹ́ “mímọ́, ó jẹ́ òdodo, ó sì dára,” síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ló kà á sí ìnira. (Róòmù 7:12) Nítorí Òfin náà pé, kò ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti kúnjú òṣùwọ̀n rẹ̀ tó ga. (Sáàmù 19:7) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi pè é ní “àjàgà tí àwọn baba ńlá wa tàbí àwa kò lè rù.” (Ìṣe 15:10) Dájúdájú, Òfin náà fúnra rẹ̀ kò nira, ṣíṣègbọràn sí i sì ṣe àwọn ènìyàn náà láǹfààní.

14. Kí ni àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ tó fi hàn pé Òfin náà ṣàǹfààní tó ga gan-an fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

14 Fún àpẹẹrẹ, a kì í fi olè sẹ́wọ̀n lábẹ́ Òfin náà, kàkà bẹ́ẹ̀ ó ní láti ṣiṣẹ́ kó sì san ohun tó jí náà ní ìlọ́po méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tí wọ́n jí nǹkan rẹ̀ kò pàdánù, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbé ẹrù ìnira àtibọ́ àwọn tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àṣekára lórí. (Ẹ́kísódù 22:1, 3, 4, 7) Ó ka oúnjẹ tó lè dá àìsàn síni lára léèwọ̀. Bí a kò bá se ẹran ẹlẹ́dẹ̀ dáadáa, ó lè fa ibà trichinosis, ehoro pẹ̀lú sì máa ń ní ibà tularemia lára. (Léfítíkù 11:4-12) Bákan náà ni Òfin yìí ṣe jẹ́ ààbò nípa kíka fífọwọ́ kan òkú léèwọ̀. Bí ẹnì kan bá fọwọ́ kan òkú, ó gbọ́dọ̀ wẹ kí ó sì fọ aṣọ rẹ̀ pẹ̀lú. (Léfítíkù 11:31-36; Númérì 19:11-22) Béèyàn bá gbọnsẹ̀, ó gbọ́dọ̀ wa yẹ̀pẹ̀ bò ó, láti dáàbò boni lọ́wọ́ kòkòrò àrùn, ohun kan tó jẹ́ pé àwọn ọ̀rúndún àìpẹ́ yìí làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí rẹ̀.—Diutarónómì 23:13.

15. Kí ló jẹ́ ìnira fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

15 Òfin náà kò béèrè ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ àwọn ènìyàn náà. Àmọ́, a ò lè sọ ohun kan náà nípa àwọn ọkùnrin tó wá gbaṣẹ́ títúmọ̀ Òfin náà. Látàrí àwọn òfin tí wọ́n gbé kalẹ̀, ìwé atúmọ̀ èdè A Dictionary of the Bible, tí James Hastings tẹ̀ jáde, sọ pé: “Gbogbo àṣẹ inú Bíbélì ni wọ́n fi àwọn òfin pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ rọ̀gbà yí ká. . . . Wọ́n gbìyànjú láti mú gbogbo ọ̀ràn tí wọ́n bá lè ronú kàn wá sábẹ́ Òfin, wọ́n fi ọgbọ́n tó fi ìwà ìkà hàn to gbogbo ìwà ènìyàn sábẹ́ òfin tí kò gba tẹni rò, táa gbé ka ọgbọ́n orí lásán. . . . Wọ́n pa ẹ̀rí-ọkàn àwọn èèyàn kú pátápátá; wọ́n fi òbítíbitì òfin tó jẹ mọ́ ọ̀ràn oréfèé pa agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kú pátápátá.”

16. Kí ni Jésù sọ nípa àwọn àdábọwọ́ òfin àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ táwọn aṣáájú ìsìn sọ di ẹrù sáwọn èèyàn lọ́rùn?

16 Jésù Kristi fi àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n gbé òbítíbitì ìlànà ka àwọn ènìyàn lórí bú, nípa sísọ pé: “Wọ́n di àwọn ẹrù wíwúwo, wọ́n sì gbé wọn lé èjìká àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò fẹ́ láti fi ìka wọn sún wọn kẹ́rẹ́.” (Mátíù 23:2, 4) Ó tọ́ka sí i pé àwọn àdábọwọ́ òfin àti ti àtọwọ́dọ́wọ́ wọn tó ti di ẹrù sáwọn èèyàn lọ́rùn, títí kan àṣejù tí wọ́n ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń wẹ ara wọn, ti sọ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀ nílẹ̀.” (Máàkù 7:1-13; Mátíù 23:13, 24-26) Àmọ́ ṣá o, kí Jésù tó wá sáyé ni àwọn olùkọ́ ní Ísírẹ́lì ti máa ń túmọ̀ àwọn ohun tí Jèhófà béèrè sí nǹkan òdì.

Ohun Náà Gan-an Tí Jèhófà Ń Béèrè

17. Èé ṣe tí inú Jèhófà kò fi dùn sí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ọmọ Ísírẹ́lì ń rú?

17 Nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà, Jèhófà sọ pé: “Odindi ọrẹ ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá àwọn ẹran tí a bọ́ dáadáa ti tó mi gẹ́ẹ́; èmi kò sì ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti òbúkọ.” (Aísáyà 1:10, 11) Èé ṣe tí inú Ọlọ́run kò fi dùn sí àwọn ìrúbọ tí òun fúnra rẹ̀ béèrè nínú Òfin? (Léfítíkù 1:1–4:35) Ìdí ni pé àwọn ènìyàn náà rí i fín púpọ̀. Nítorí náà, a fún wọn ní ìṣínilétí pé: “Ẹ wẹ̀; ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́; ẹ mú búburú ìbánilò yín kúrò ní iwájú mi; ẹ ṣíwọ́ ṣíṣe búburú. Ẹ kọ́ ṣíṣe rere; ẹ wá ìdájọ́ òdodo; ẹ tún ojú ìwòye aninilára ṣe; ẹ ṣe ìdájọ́ ọmọdékùnrin aláìníbaba; ẹ gba ẹjọ́ opó rò.” (Aísáyà 1:16, 17) Ǹjẹ́ èyí ò ràn wá lọ́wọ́ láti mọyì ohun tí Jèhófà ń fẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?

18. Kí ni ohun náà gan-an tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

18 Jésù fi ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ gan-an hàn. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin?” Jésù dáhùn pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo Òfin so kọ́, àti àwọn Wòlíì.” (Mátíù 22:36-40; Léfítíkù 19:18; Diutarónómì 6:4-6) Wòlíì Mósè tún tẹnu mọ́ kókó kan náà nígbà tó béèrè pé: “Kí sì ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, bí kò ṣe láti máa fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o lè máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ; láti máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀?”—Diutarónómì 10:12, 13; 15:7, 8.

19. Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fẹ́ máa fi hàn pé àwọn jẹ́ ẹni mímọ́, ṣùgbọ́n kí ni Jèhófà sọ fún wọn?

19 Pẹ̀lú pé oníwà àìtọ́ paraku làwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n fẹ́ fara hàn bí ẹni mímọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún nìkan ni Òfin sọ pé kí wọ́n máa gbààwẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i gbà á ní gbogbo ìgbà. (Léfítíkù 16:30, 31) Ṣùgbọ́n Jèhófà bá wọn wí, ó sọ pé: “Èyí ha kọ́ ni ààwẹ̀ tí mo yàn? Láti tú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìwà burúkú, láti tú ọ̀já ọ̀pá àjàgà, àti láti rán àwọn tí a ni lára lọ lómìnira, àti pé kí ẹ fa gbogbo ọ̀pá àjàgà já sí méjì? Kì í ha ṣe pípín oúnjẹ rẹ fún ẹni tí ebi ń pa, àti pé kí o mú àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, àwọn aláìnílé, wá sínú ilé rẹ? Pé, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ rí ẹnì kan tí ó wà ní ìhòòhò, kí o bò ó, àti pé kí o má fi ara rẹ pa mọ́ fún ẹran ara tìrẹ?”—Aísáyà 58:3-7.

20. Torí kí ni Jésù ṣe fi àwọn alágàbàgebè onísìn bú?

20 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ olódodo lójú ara wọn wọ̀nyẹn ní ìṣòro kan náà tí àwọn alágàbàgebè onísìn yẹn ní, àwọn tí Jésù sọ fún pé: “Ẹ ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá efinrin àti ewéko dílì àti ewéko kúmínì, ṣùgbọ́n ẹ ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́. Àwọn ohun wọ̀nyí pọndandan ní ṣíṣe, síbẹ̀ àwọn ohun yòókù ni kí ẹ má ṣàìkà sí.” (Mátíù 23:23; Léfítíkù 27:30) Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Jèhófà ń fẹ́ látọ̀dọ̀ wa gan-an?

21. Báwo ni wòlíì Míkà ṣe ṣàkópọ̀ ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa àti ohun tí kò béèrè?

21 Kí a lè lóye ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa àti ohun tí kò béèrè, Míkà tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run béèrè pé: “Kí ni èmi yóò gbé wá pàdé Jèhófà? Kí ni èmi yóò fi tẹrí ba fún Ọlọ́run ní ibi gíga lókè? Èmi yóò ha gbé odindi ọrẹ ẹbọ sísun wá pàdé rẹ̀, pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan? Inú Jèhófà yóò ha dùn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò, sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá ọ̀gbàrá òróró? Èmi yóò ha fi ọmọkùnrin mi àkọ́bí lélẹ̀ fún ìdìtẹ̀ mi, èso ikùn mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi? Ó ti sọ fún ọ, ìwọ ará ayé, ohun tí ó dára. Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—Míkà 6:6-8.

22. Kí ni lájorí ohun tí Jèhófà fẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn tó wà lábẹ́ Òfin?

22 Nítorí náà, kí ni lájorí ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ àwọn tó wà lábẹ́ Òfin náà? Láìsí àní-àní, ohun náà ni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Láfikún sí i, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo Òfin pátá di èyí tí a mú ṣẹ nínú àsọjáde kan ṣoṣo, èyíinì ni: ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’” (Gálátíà 5:14) Bákan náà ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ni Róòmù pé: “Ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ ti mú òfin ṣẹ. . . . Ìfẹ́ ni ìmúṣẹ òfin.”—Róòmù 13:8-10.

Kò Pọ̀ Jù

23, 24. (a) Èé ṣe tí a kò fi gbọ́dọ̀ ka ohun tí Jèhófà sọ pé kí a ṣe sí ohun tó pọ̀ jù? (b) Kí ni a ó gbé yẹ̀ wò tẹ̀ lé e?

23 Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́, tó ń gba tẹni rò, tó sì láàánú? Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo náà, Jésù Kristi, wá sórí ilẹ̀ ayé láti wá fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn lọ́nà tó ga—kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ bí wọ́n ṣe jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún Jèhófà tó. Nígbà tí Jésù ń ṣàkàwé ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sọ nípa àwọn ológoṣẹ́ tí ò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí pé: “Kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.” Ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31) Láìsí àní-àní, a kò gbọ́dọ̀ ka ohunkóhun tí irú Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ bá sọ pé ká ṣe sí ohun tó pọ̀ jù!

24 Àmọ́, kí ni Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa lónìí? Èé sì ti ṣe táwọn kan fi ń rò pé ohun tí Ọlọ́run ń béèrè ti pọ̀ jù? Nígbà táa bá ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, a ó rí ìdí tó fi jẹ́ àǹfààní àgbàyanu láti ṣe ohunkóhun tí Jèhófà bá béèrè lọ́wọ́ wa.

Ṣé O Lè Dáhùn?

◻ Èé ṣe tí àwọn kan lè máà fẹ́ sin Jèhófà?

◻ Báwo ni àwọn ohun tí Jèhófà ń béèrè ṣe ń yí padà láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá?

◻ Ète mélòó ni Òfin náà wà fún?

◻ Èé ṣe ti ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa kò fi pọ̀ jù?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn àdábọwọ́ òfin, bíi ṣíṣe àṣejù nígbà tí wọ́n bá ń wẹ ara wọn, ti sọ ìjọsìn wọn di ohun ìnira

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́