Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Ọrẹ Àtinúwá Láti Gbé Ìjọsìn Mímọ́ Ga
ÀWỌN ọmọ Ísírẹ́lì fojú ara wọn rí agbára tí Jèhófà ní láti gbani là. Níṣojú wọn kòrókòró ni Òkun Pupa ṣe pín sí méjì gbẹrẹgẹdẹ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu, tí wọ́n fi ráyè rin orí ilẹ̀ gbígbẹ́ kọjá, tí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Íjíbítì. Nísọdá odò ọ̀hún, látòkèèrè tí nǹkan kan o ti lè ṣe wọ́n, ni wọ́n ti ń wo bí odò kan náà ṣe ya bo àwọn tí ń lépa wọn. Jèhófà ti gba ẹ̀mí wọn là!—Ẹ́kísódù 14:21-31.
Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé, àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ka ohun tí Ọlọ́run ṣe fún wọn sí. Nígbà tí Mósè wà lórí Òkè Sínáì, ni wọ́n bá dá wúrà wọn jọ fún Áárónì, tí wọ́n sì fúngun mọ́ ọn pé, kó ṣe òrìṣà kan fáwọn, táwọn o máa jọ́sìn. Pípadà tí Mósè ó padà dé, ibi tí àwùjọ àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí ti ń jẹ, tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń jó, tí wọ́n ń forí balẹ̀ fún ọmọ màlúù oníwúrà ló bá wọn! Pẹ̀lú àṣẹ Jèhófà, nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] èèyàn—tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn tó dáná ọ̀tẹ̀ náà sílẹ̀ gan-an—la pá. Lọ́jọ́ yẹn, àwọn èèyàn Ọlọ́run kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì nípa bó ṣe pọndandan tó láti máa fún Jèhófà ní ìjọsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé.—Ẹ́kísódù 32:1-6, 19-29.
Láìpẹ́ sí àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Mósè múra láti ṣe ohun tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un, ìyẹn ni láti kọ́ àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ kan tó ṣeé gbé rìn, ká sì máa jọ́sìn níbẹ̀. Kíkọ́ àgọ́ yìí yóò gba àwọn ohun ìkọ́lé olówó gọbọi, yóò sì béèrè pé kí wọ́n ní àwọn tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́. Ibo ni wọ́n ti fẹ́ rí gbogbo èyí? Kí la sì lè rí kọ́ nínú ìtàn Bíbélì yìí?
Fífi Ohun Èlò Ìkọ́lé Ṣètìlẹyìn àti Yíyọ̀ǹda Ara Ẹni
Nípasẹ̀ Mósè, Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ gba ọrẹ fún Jèhófà. Kí gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún Jèhófà.” Irú ọrẹ wo? Lára àwọn ohun tí Mósè ní kí wọ́n mú wá ni, wúrà, fàdákà, bàbà, fọ́nrán òwú, aṣọ, awọ, igi, àti òkúta iyebíye.—Ẹ́kísódù 35:5-9.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ànító àti àníṣẹ́kù láti ṣe irú ìtọrẹ ńlá yìí. Rántí pé, nígbà tí wọ́n fi Íjíbítì sílẹ̀, wúrà àti fàdákà, àti ọ̀pọ̀ aṣọ wà lára ohun tí wọ́n kó kúrò níbẹ̀. Àní, “wọ́n . . . gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.”a (Ẹ́kísódù 12:35, 36) Ṣáájú àkókò yìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi tinútinú kó ohun ọ̀ṣọ́ wọn sílẹ̀ fún yíya eré fún ìjọsìn èké. Ǹjẹ́ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ yá wọn lára láti ṣe ìtọrẹ fún gbígbé ìjọsìn tòótọ́ ga?
Ṣàkíyèsí pé Mósè kò sọ iye pàtó tí ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ mú wá, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fọ̀rọ̀ gún wọn lára kí wọ́n bàá lè ṣètọrẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló wulẹ̀ rọ “gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán.” Ó hàn gbangba pé Mósè kò mú àwọn ènìyàn Ọlọ́run lápàpàǹdodo. Ó gbà pé olúkúlùkù yóò fi gbogbo ohun tó bá lè fi ṣètọrẹ sílẹ̀.—Fi wé 2 Kọ́ríńtì 8:10-12.
Bó ti wù kó rí, kì í ṣe ohun èlò ìkọ́lé nìkan níṣẹ́ náà máa gbà. Jèhófà tún sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Sì jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó ní ọkàn-àyà ọgbọ́n láàárín yín wá ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ.” Lóòótọ́, iṣẹ́ ìkọ́lé yìí ń béèrè àwọn òṣìṣẹ́ tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́. Àní, “onírúurú ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà”—títí kan afigiṣọ̀ṣọ́, gbẹ́ringbẹ́rin, àti àwọn tí ń fi òkúta ṣọ̀ṣọ́—ni a óò nílò láti parí iṣẹ́ yìí. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà ni yóò darí ẹ̀bùn tí àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyí ní, tíṣẹ́ náà bá sì parí, òun ni yóò gba ògo rẹ̀.—Ẹ́kísódù 35:10, 30-35; 36:1, 2.
Kíá làwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ohun ìní wọn jọ, tí wọ́n sì yọ̀ǹda ara wọn. Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Wọ́n wá, olúkúlùkù ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ sún un ṣiṣẹ́, àti olúkúlùkù ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ ru ú sókè, wọ́n mú ọrẹ Jèhófà wá fún iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ àti fún ẹ̀wù mímọ́ náà. Wọ́n sì ń wá ṣáá, àwọn ọkùnrin pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin, gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán.”—Ẹ́kísódù 35:21, 22.
Ẹ̀kọ́ Táa Rí Kọ́
Lónìí ọrẹ àtinúwá ń ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ bàǹtà-banta ti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kẹ́sẹ járí. Ọ̀pọ̀ ìgbà lèyí sì máa ń béèrè owó. Nígbà mí-ìn, àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin ń lo ìrírí rẹpẹtẹ tí wọ́n ti ní láti ṣèrànwọ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àti àwọn ilé tí a ó lò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì. Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ tún wà láwọn ilé Bẹ́tẹ́lì tó lé ní ọgọ́rùn-ún tó wà yíká ayé, iṣẹ́ tó ń béèrè fún onírúurú òye iṣẹ́. Kí gbogbo àwọn tó ti fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn fún irú iṣẹ́ yìí mọ̀ dájú pé, Jèhófà ò ní gbàgbé iṣẹ́ takuntakun wọn láéláé!—Hébérù 6:10.
Bẹ́ẹ̀ náà sì ni akitiyan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Gbogbo wa la rọ̀ láti ra ìgbà padà, ká lè máa fìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Mátíù 24:14; Éfésù 5:15-17) Àwọn kan ń ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún, tàbí aṣáájú ọ̀nà. Nítorí bí ipò nǹkan ti rí, àwọn mìíràn ò lè lo àkókò púpọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn pẹ̀lú ń mú inú Jèhófà dùn. Bíi ti ọrẹ kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn, Jèhófà ò sọ iye àkókò pàtó tí ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ lò. Ṣùgbọ́n, ohun tó ń fẹ́ ni pé, kí olúkúlùkù wa sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, ọkàn wa, èrò inú wa, àti okun wa. (Máàkù 12:30) Báa bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó dá wa lójú pé yóò san èrè fún wa nítorí ọrẹ àtinúwá táà ń ṣe fún gbígbé ìjọsìn tòótọ́ ga.—Hébérù 11:6.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wọn ò jalè o. Ṣe ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní kí àwọn ọmọ Íjíbítì ṣe ìtọrẹ, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ láìfipá mú wọn. Táa bá tún ní ká wò ó, àwọn ọmọ Íjíbítì kò lẹ́tọ̀ọ́ kankan láti fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹrú, nítorí náà, wọ́n jẹ àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní owó ọ̀yà iye ọdún tí wọ́n ti fi ṣiṣẹ́ àṣekára sìn wọ́n.