Kòṣeémánìí Lètò Àjọ Jèhófà
ǸJẸ́ o ti gbọ́ tẹ́nì kan ń sọ pé, “Mo gba Ọlọ́run gbọ́ o, àmọ́ ń kò nígbàgbọ́ nínú ètò ẹ̀sìn kankan?” Àwọn tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ onítara ẹ̀sìn, tí wọn kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ, ṣùgbọ́n tẹ́sìn wọ́n ti wá já wọn kulẹ̀ nítorí tí kò lè pèsè ohun tẹ̀mí tí wọn ń fẹ́ ló sábà máa ń sọ irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ètò ẹ̀sìn lápapọ̀ ti já kulẹ̀ síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ṣì fẹ́ sin Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, wọ́n gbà pé ó kúkú sàn kí àwọn máa sìn ín lọ́nà tó tẹ́ àwọn lọ́rùn ju pé káwọn máa dara pọ̀ mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ètò kan.
Kí ni Bíbélì sọ? Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ fẹ́ kí àwọn Kristẹni dara pọ̀ mọ́ ètò kan?
Ṣíṣètò Àwọn Kristẹni Ìjímìjí Ṣe Wọ́n Láǹfààní
Ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa, Jèhófà tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí àwùjọ ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n pàdé “ní ibì kan náà,” ìyẹn ni, nínú yàrá òkè kan nílùú Jerúsálẹ́mù. Òun kò tú u dà sórí àwọn onígbàgbọ́ mélòó kan, tí kálukú ń ṣe tirẹ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. (Ìṣe 2:1) Àkókò yẹn la dá ìjọ Kristẹni tó wá di ètò tó kárí ayé sílẹ̀. Èyí ṣe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ìjímìjí yẹn láǹfààní gan-an. Èé ṣe? Ìdí kan ni pé, a ti fún wọn níṣẹ́ pàtàkì kan tẹ́lẹ̀—ìyẹn ni wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14) Nínú ìjọ, àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di mẹ́ńbà yóò lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n ti ní ìrírí nípa báa ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà.
Kò pẹ́ rárá tí iṣẹ́ Ìjọba náà fi nasẹ̀ dé igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Jerúsálẹ́mù. Láàárín ọdún 62 àti 64 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn Kristẹni tí wọ́n “tú ká káàkiri ní Pọ́ńtù, Gálátíà, Kapadókíà, Éṣíà, àti Bítíníà,” gbogbo ìlú wọ̀nyẹn wà ní ibi tí à ń pè ní Turkey lónìí. (1 Pétérù 1:1) Àwọn onígbàgbọ́ tún wà ní Palẹ́sìnì, Lẹ́bánónì, Síríà, Kípírọ́sì, Gíríìsì, Kírétè, àti Ítálì. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé rẹ̀ sí àwọn ará Kólósè lọ́dún 60 sí 61 Sànmánì Tiwa, ‘wọ́n ti wàásù ìhìn rere náà nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.’—Kólósè 1:23.
Àǹfààní tí èèyàn máa ń jẹ nínú dídara pọ̀ mọ́ ètò àjọ kan ni ìṣírí tí àwọn Kristẹni lè máa fúnra wọn. Tí àwọn Kristẹni bá ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ, wọ́n á lè máa gbọ́ àwọn àwíyé tó ń tani jí, wọ́n á lè kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, wọn ó máa sọ àwọn ìrírí tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun fún ara wọn, wọ́n sì lè dara pọ̀ mọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nínú àdúrà. (1 Kọ́ríńtì, orí 14) Àwọn ọkùnrin tó dàgbà dénú ló lè “ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.”—1 Pétérù 5:2.
Gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà ìjọ, àwọn Kristẹni tún máa ń ní àǹfààní láti mọ ara wọn dunjú, wọ́n á sì wá nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Kàkà tí dídara pọ̀ mọ́ ìjọ yóò fi fa ìnira fún àwọn Kristẹni ìjímìjí, ńṣe ló gbé wọn ró, tó sì fún wọn lókun.—Ìṣe 2:42; 14:27; 1 Kọ́ríńtì 14:26; Kólósè 4:15, 16.
Ìdí mìíràn tí ìjọ tó wà níṣọ̀kan jákèjádò ayé, tàbí ètò àjọ fi jẹ́ kòṣeémánìí ni pé, ó ń gbé ẹ̀mí ìṣọ̀kan lárugẹ. Àwọn Kristẹni máa ń kọ́ láti “máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan.” (1 Kọ́ríńtì 1:10) Èyí ṣe pàtàkì. Ipò àtilẹ̀wá àwọn mẹ́ńbà ìjọ yàtọ̀ síra ní ti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń sọ, ìwà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ síra. (Ìṣe 2:1-11) Nígbà mìíràn pàápàá, wọ́n lè ní èrò tó yàtọ̀ síra lórí ọ̀ràn kan. Àmọ́ ṣá o, a ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti yanjú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ láàárín ìjọ.—Ìṣe 15:1, 2; Fílípì 4:2, 3.
Àwọn ìbéèrè tó takókó tí àwọn alàgbà àdúgbò kò lè yanjú ni wọ́n máa ń darí rẹ̀ sí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò tó dàgbà dénú, àwọn bíi Pọ́ọ̀lù. Tó bá jẹ́ ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tó ṣe kókó ni, wọ́n á darí rẹ̀ sí ẹgbẹ́ olùṣàkóso tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Tẹ́lẹ̀ rí, àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi ni mẹ́ńbà ẹgbẹ́ olùṣàkóso, àmọ́ nígbà tó yá, àǹfààní náà nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn àgbà ọkùnrin tó wà nínú ìjọ Jerúsálẹ́mù. Ìjọ kọ̀ọ̀kan lo fira rẹ̀ sábẹ́ ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún ẹgbẹ́ olùṣàkóso náà àti àwọn aṣojú rẹ̀ láti ṣètò iṣẹ́ òjíṣẹ́, láti yan àwọn ọkùnrin sípò iṣẹ́ ìsìn, àti láti ṣe ìpinnu lórí ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn. Tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso bá ti yanjú ọ̀ràn kan, ìpinnu yẹn làwọn ìjọ máa rọ̀ mọ́, wọ́n á sì “yọ̀ nítorí ìṣírí náà.”—Ìṣe 15:1, 2, 28, 30, 31.
Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà lo ètò àjọ kan ní ọ̀rúndún kìíní. Ṣùgbọ́n lónìí ńkọ́?
A Nílò Ètò Àjọ Kan Lónìí
Gẹ́gẹ́ bíi tàwọn ẹlẹgbẹ́ wa ọ̀rúndún kìíní, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí mú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní ọ̀kúnkúndùn. Ọ̀nà kan tí a gbà ń ṣiṣẹ́ yìí ni nípa pípín Bíbélì àti àwọn ìwé tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí sì ń béèrè pé ká ṣe nǹkan létòlétò.
A gbọ́dọ̀ múra àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni sílẹ̀ dáadáa, ká yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní láti rí i pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ péye, ká ṣètò àtitẹ̀ ẹ́, ká sì kó o ránṣẹ́ sáwọn ìjọ. Ẹ̀wẹ̀, olúkúlùkù Kristẹni gbọ́dọ̀ yọ̀ǹda láti mú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ kà á. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló ti gbọ́ iṣẹ́ Ìjọba náà lọ́nà yìí. Àwọn akéde ìhìn rere náà tún ń sapá láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ́nà tó wà létòlétò, wọ́n ń rí i dájú pé àwọn ò wàásù lemọ́lemọ́ láwọn àgbègbè kan káwọn sì fi àgbègbè mìíràn sílẹ̀. Gbogbo èyí ló ń béèrè fún ètò.
Níwọ̀n bí “Ọlọ́run kì í [ti í]ṣe ojúsàájú,” a gbọ́dọ̀ túmọ̀ Bíbélì àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí àwọn èdè mìíràn. (Ìṣe 10:34) Ní báyìí o, a ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde ní èdè méjìléláàádóje, èkejì rẹ̀ Jí!, sì ń jáde ní èdè mẹ́tàlélọ́gọ́rin. Èyí ń béèrè pé ká ní àwọn atúmọ̀ èdè táa ṣètò wọn dáadáa káàkiri àgbáyé.
Àwọn mẹ́ńbà ìjọ máa ń gba ìṣírí nígbà tí wọ́n bá lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti àpéjọ. Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń gbọ́ àwọn àwíyé Bíbélì tó tani jí, ibẹ̀ ni wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ pa pọ̀, tí wọ́n ti ń gbọ́ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró, tí wọ́n sì ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn nínú àdúrà. Gẹ́gẹ́ bó sì ti rí pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n ń gbádùn ìbẹ̀wò tí ń fúnni lókun tí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ń ṣe sọ́dọ̀ wọn. Nípa báyìí, àwọn Kristẹni òde òní wá di “agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.”—Jòhánù 10:16.
Àmọ́ ṣá o, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ẹni pípé, bí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ní ìjímìjí pẹ̀lú kì í ti í ṣe ẹni pípé. Síbẹ̀, wọ́n wà ní ìṣọ̀kan. Àbàjáde rẹ̀ ni pé, wọ́n ti wàásù Ìjọba náà jákèjádò ilẹ̀ ayé.—Ìṣe 15:36-40; Éfésù 4:13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn Kristẹni òde òní ló di “agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan”