Ìtàn Ìgbésí Ayé
Mo Rí Ogún Àkànṣe Gbà
GẸ́GẸ́ BÍ CAROL ALLEN TI SỌ Ọ́
Mo dá nìkan dúró, bí mo ti gbá ìwé mi tuntun mọ́ra gbágbáágbá. Ẹ̀rù ń bà mí gan an, bẹ́ẹ̀ lomi sì ń dà lójú mi pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. Ó ṣe tán, ọmọdébìnrin ọlọ́dún méje péré ni mí tí mo sọ nù sílùú onílùú, tí omilẹgbẹ èèyàn sì yí mi ká!
LẸ́NU àìpẹ́ yìí, ìyẹn ní nǹkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, mo ṣì rántí ohun tójú mí rí nígbà ọmọdé yẹn dáadáa bó ti ń padà wá sí mi lọ́kàn, ìbẹ̀wò tí èmi àti Paul, ọkọ mi, ṣe sí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower rírẹwà, tó wà ní Patterson, New York ló fa ìrántí ọ̀hún. Wọ́n ké sí i láti wá sí kíláàsì kejì ti ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Bí a ti ń wò káàkiri ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí ìtànṣán oòrùn tànmọ́lẹ̀ sí, mo ṣàkíyèsí àfihàn títóbi kan pẹ̀lú àkọlé náà, “ÀWỌN ÀPÉJỌPỌ̀.” Lọ́wọ́ àárín ni fọ́tò ògbólógbòó kan wà, pẹ̀lú àwòrán àwọn ọmọdé tí wọn ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀dà ìwé tó jáde nígbà tí mo wà lọ́mọdé lọ́wọ́ wọn, tí wọ́n ń fì í síwá-sẹ́yìn! Mo yára ka ohun tí wọ́n kọ sára àwòrán náà: “1941 Ní St. Louis, Missouri, nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ bẹ̀rẹ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] ọmọdé—tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún márùn-ún sí méjìdínlógún—pé jọ síwájú pèpéle tó wà ní ọ̀gangan pápá ìṣeré náà. . . . Arákùnrin Rutherford sì kéde ìmújáde ìwé tuntun náà, Children.”
Wọ́n fún ọmọ kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀dà tirẹ̀. Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ padà lọ síbi tí àwọn òbí wọn jókòó sí—èmi nìkan ló ṣẹ́ kù nínú wọn. Mo ti sọ nù! Alábòójútó èrò kan tó lọ́yàyà mú mi ó sì gbé mi dúró sórí àpótí ọrẹ gíga kan, ó wá sọ fún mi pé kí ń máa fojú wá ẹni ti mo bá mọ̀. Pẹ̀lú àìbalẹ̀ ọkàn ni mo fi ń fojú wá àárín àwọn tó ń rọ́ gìrọ́gìrọ́ gba ẹnu ọ̀nà àtẹ̀gùn fífẹ̀ náà lọ sísàlẹ̀. Lójijì ni mo rí ojú kan ti mo mọ̀! Mo pariwo: “Arákùnrin Bob! Arákùnrin Bob!” Èmi nìyí! Ni Bob Rainer bá gbé mi lọ síbi táwọn òbí mi tó ti ń dààmú wà.
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Àárọ̀ Ọjọ́ Tó Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Mi
Wíwo àfihàn yẹn jẹ́ kí iyè mi sọ kí n sì wá rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan—ìyẹn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó nípa lórí ìgbésí ayé mi tó sì ṣamọ̀nà sí wíwà táa wà ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ rírẹwà ti Patterson náà. Àwọn ìrònú mi lọ sórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ohun tó ti ju ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn lọ, àwọn ohun tí mo ti gbọ́ nípa wọn, àgàgà látẹnu àwọn òbí mi àgbà àti lẹ́nu àwọn òbí mi.
Ní December 1894, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn, kàn sí bàbá-bàbá mi, Clayton J. Woodworth, ní ilé rẹ̀ ní Scranton, Pennsylvania, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Clayton ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ni. Ó kọ lẹ́tà kan sí ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society, Charles Taze Russell, wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde nínú Watchtower June 15, 1895 (Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Ó ṣàlàyé pé:
“Tọkọtaya ọ̀dọ́ ni wá, a ti jẹ́ mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì aláfẹnujẹ́ fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá; àmọ́ ní báyìí o, a gbà gbọ́ pé, a ń gbẹ́sẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ ojúmọ́ tuntun tó ń mọ́ báyìí fún àwọn ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ tó ti ya ara wọn sí mímọ́. . . . Káwa méjèèjì tó lálàá pé a máa pàdé ara wa ló ti jẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa gidigidi pé ká lè ṣiṣẹ́ sin Olúwa, bó bá sì jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ ni, ká lè sìn ín gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní pápá ilẹ̀ òkèèrè.”
Lẹ́yìn náà, ní 1903, Sebastian àti Catherine Kresge, tí wọ́n jẹ́ bàbá àti ìyá àgbà fún màmá mi, fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́tí sí ìhìn Bíbélì tí àwọn aṣojú Watch Tower méjì mú wá síbi tí wọ́n ń gbé ní abúlé títóbi tó wà ní Òkè Ńlá ẹlẹ́wà ti Pocono ní Pennsylvania. Àwọn ọmọbìnrin wọn, Cora àti Mary, náà ń gbé níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọkọ wọn, Washington àti Edmund Howell. Odindi ọ̀sẹ̀ kan gbáko ni Carl Hammerle àti Ray Ratcliffe tí wọ́n jẹ́ aṣojú Watch Tower fi wà lọ́dọ̀ wọ́n, tí wọ́n ń kọ́ wọn ní ohun púpọ̀. Àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé yìí ló fetí sílẹ̀, tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó nítara.
Ní ọdún yẹn gan-an, ní 1903, Cora àti Washington Howell bí ọmọbìnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Catherine. Bó ṣe wá fẹ́ bàbá mi Clayton J. Woodworth Kékeré nígbẹ̀yìn jẹ́ ìtàn tó gbádùn mọ́ni tí mo sì gbà pé ó nítumọ̀. Ó fi ìjìnlẹ̀ òye tó kún fún ìfẹ́ àti àníyàn òbí tí bàbá-bàbá mi, Clayton J. Woodworth Àgbà, ní hàn.
Bàbá Mi Rí Ìrànlọ́wọ́ Onífẹ̀ẹ́ Gbà
A bí bàbá mi, Clayton kékeré, ní 1906, ní Scranton, nǹkan bíi ọgọ́rin kìlómítà sí abúlé àwọn Howell. Ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn, Bàbá àgbà, Woodworth di ojúlùmọ̀ ìdílé Howell títóbi, ó sì máa ń gbádùn aájò àlejò wọn tí gbogbo èèyàn mọ̀ wọ́n mọ́. Ó ran ìjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà ní àdúgbò yẹn lọ́wọ́ gidigidi. Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n ké sí Bàbá àgbà láti wá darí ìgbéyàwó àwọn ọmọkùnrin Howell mẹ́ta, pẹ̀lú ire ọmọkùnrin tiẹ̀ lọ́kàn rẹ̀, ó máa ń rí sí i pé òún ń mú ọmọkùnrin náà dání lọ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìgbéyàwó wọ̀nyí.
Lásìkò yẹn, dádì kì í fi bẹ́ẹ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lóòótọ́ òun ló máa ń fi ọkọ̀ gbé Bàbá àgbà lọ sáwọn ibi tó ti máa ń ṣe ìbẹ̀wò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ìṣírí tí Bàbá àgbà ń fún un, Dádì ò fi gbogbo ara kópa nínú iṣẹ́ náà. Ní gbogbo àsìkò yẹn, kò sí nǹkan mìíràn tó jẹ bàbá mi lọ́kàn ju orin kíkọ lọ, ó sì ti ń bá a lọ sórí sísọ ọ di iṣẹ́ ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kan.
Catherine, tó jẹ́ ọmọbìnrin Cora àti Washington Howell, náà ti di olórin tó mọṣẹ́ dunjú, ó máa ń kọrin, ó sì tún ń kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń tẹ dùrù. Àmọ́, bó ṣe di pé iṣẹ́ pàtàkì kan fẹ́ yọjú fún un, bẹ́ẹ̀ ló gbé ìlépa yẹn tì tó sì bẹ̀rẹ̀ si í lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Kò tún sí ẹlòmíràn tó dára ju ẹni yìí lọ tí Bàbá àgbà lè ní lọ́kàn fún ọmọkùnrin rẹ̀—ìyẹn lójú tèmi o! Bí Dádì ṣe ṣe batisí nìyẹn, tó sì gbé Mọ́mì níyàwó ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, ní June 1931.
Ìgbà gbogbo ni Bàbá àgbà máa ń fi iṣẹ́ orin kíkọ tí ọmọ rẹ̀ mọ̀ yìí yangàn. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí wọ́n pe Dádì láti wá ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àpapọ̀ ẹgbẹ́ akọrin àpéjọpọ̀ ńlá fún àpéjọpọ̀ àgbáyé tó wáyé ní Cleveland, Ohio ní 1946. Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, Dádì darí ẹgbẹ́ akọrin ní àwọn àpéjọpọ̀ mìíràn tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Àdánwò Bàbá Àgbà àti Ìgbésí Ayé Nínú Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
Ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ Patterson, èmi àti Paul tún dé ibi tí wọ́n pàtẹ àwòrán tí a rí níhìn-ín ní ojú ìwé tó wà lápá kejì yìí sí. Kíá ni mo dá àwòrán náà mọ̀, nítorí pé Bàbá àgbà fi ẹ̀dà kan rẹ̀ ránṣẹ́ sí mi ní nǹkan tó lé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn. Òun lẹni tó dúró ní ìkangun lápá ọ̀tún yẹn.
Láàárín rúkèrúdò ti ìfọkànsìn orílẹ̀-èdè ẹni tó gbòde kan lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́jọ yìí—títí kan Joseph F. Rutherford (òun ló jókòó sáàárín), tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society—ní wọ́n fi sẹ́wọ̀n láìbófinmu tí wọn ò sì gbà kí wọ́n gba ìdúró wọn. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n dá lórí ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìdìpọ̀ keje ìwé Studies in the Scriptures, táa pe orúkọ rẹ̀ ní The Finished Mystery. Wọ́n ṣi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lóye pé ó ń fún Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà níṣìírí láti má ṣe kópa nínú Ogun Àgbáyé Kìíní.
Fún ọ̀pọ̀ ọdún, Charles Taze Russell ti kọ ìdìpọ̀ Studies in the Scriptures mẹ́fà àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n kò kọ ìdìpọ̀ keje kó tó kú. Nítorí náà, wọ́n fún Bàbá àgbà àti Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mìíràn ní àwọn ìwé rẹ̀, àwọn ni wọ́n sì kọ ìdìpọ̀ keje. Ìwé yìí jáde ní 1917, ṣáájú kí ogun náà tó parí. Níbi ìgbẹ́jọ́ náà, wọ́n dá ẹ̀wọ̀n ogún ọdún fún Bàbá àgbà àti fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó kù, lórí ẹ̀sùn mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n fi kàn wọ́n.
Àkọlé orí àwòrán tó wà ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ Patterson náà sọ pé: “Lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án tí wọ́n ti ju Rutherford àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ sẹ́wọ̀n—tí ogun náà sì ti parí—ní March 21, 1919, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn pàṣẹ pé kí wọ́n gba ìdúró àwọn olùjẹ́jọ́ mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ náà, nígbà tó sì di March 26, wọ́n dá wọn sílẹ̀ ní Brooklyn pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá dọ́là gẹ́gẹ́ bí owó ìdúró fún ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ní May 5, 1920, wọ́n dá J. F. Rutherford àti àwọn tó kù sílẹ̀ lómìnira.”
Lẹ́yìn tí wọ́n ti dájọ́ ẹ̀wọ̀n fún wọn, àwọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ kọ́kọ́ lo ọjọ́ bíi mélòó kan ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Raymond Street ní Brooklyn, New York kó tó di pé wọ́n kó wọn lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Atlanta, Georgia. Láti ibẹ̀ ni bàbá ti kọ̀wé tó fi júwe bí wọ́n ṣe fi òun sínú iyàrá ẹ̀wọ̀n tí kò ju nǹkan bíi mítà méjì ààbọ̀ ní gígùn àti nǹkan bíi mítà méjì níbùú lọ “nínú ìdọ̀tí tí òórùn burúkú rẹ̀ kò ṣe é fẹnu sọ tí ibẹ̀ sì rí jákujàku.” Ó sọ pé: “Pitimu làwọn ìwé ìròyìn kún ibẹ̀, tóo bá sì kọ́kọ́ ní i lọ́kàn pé o kò ní kà wọ́n sí, kò sẹ́ni tó máa sọ fún ẹ kóo tó mọ̀ pé àwọn bébà wọ̀nyẹn, àti ọṣẹ àtàwọn àkísà yẹn lo máa máa lò láti fi wẹ̀ tóo sì máa fi tọ́jú ara rẹ.”
Síbẹ̀, ìyẹn kò ní kí Bàbá àgbà má dápàárá gẹ́gẹ́ bó ti máa ń ṣe, ó pe ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ní “Ilé ìtura Raymondie,” ní sísọ pé, “ìgbàkígbà tí oúnjẹ mí bá ti tán ní màá fi ibí sílẹ̀.” Ó tún ṣàpèjúwe àwọn ojú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọjá nínú àgbàlá rẹ̀. Nígbà kan, bó ti tẹsẹ̀ dúró díẹ̀ kí wọ́n lè bá a ya irun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni jáwójáwó kan bá já aago tó máa ń fi sápò gbà, àmọ́, gẹ́gẹ́ bó ti sọ, “ṣéènì aago náà já kò sì rí i mú lọ.” Nígbà kan tí mo ń ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì ti Brookyln ní 1958, Grant Suiter, tó jẹ́ akọ̀wé àti akápò fún Watch Tower Society nígbà yẹn pè mí sínú ọ́fíìsì rẹ̀ ó sì fún mi ní aago yẹn. Ó ṣì ń jọ mí lójú títí dòní.
Ipa Tó Ní Lórí Bàbá
Ọmọ ọdún méjìlá péré ni bàbá mi nígbà tí wọ́n fi Bàbá àgbà sẹ́wọ̀n láìbófinmu ní 1918. Ni Màmá àgbà bá fi ilé wọn sílẹ̀, lòun pẹ̀lú bàbá mi bá lọ ń gbé lọ́dọ̀ màmá rẹ̀ àti àwọn arábìnrin rẹ̀ mẹ́ta. Arthur ni orúkọ ìdílé tí Màmá àgbà ń jẹ́ nígbà tó wà ní ọlọ́mọge, tìdùnnú-tìdùnnú sì ni ìdílé náà fi máa ń sọ pé ọ̀kan lára mọ̀lẹ́bí àwọn, Chester Alan Arthur ni ààrẹ kọkànlélógún fún Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
Lẹ́yìn tí wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ fún Bàbá àgbà Woodworth, fún ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n fi kàn án, ó ṣe kedere pé ìdílé Arthur ronú pé ó ti ba ìdílé àwọn lórúkọ jẹ́. Ìgbà yẹn ò dáa lára bàbá mi rárá. Bóyá ìyẹn gan-an ló jẹ́ okùnfà fún kíkọ̀ tó kọ́kọ́ kọ̀ láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba.
Nígbà tí wọ́n dá Bàbá àgbà sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó kó ìdílé rẹ̀, wọ́n sì lọ ń gbé nínú ilé títóbi kan tí wọ́n fi sìmẹ́ǹtì ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ní òpópónà Quincy ní Scranton. Mo mọ ilé yẹn nígbà tí mo wà ní kékeré—mo tún mọ àwọn tán-ń-ganran rírẹwà tí Màmá àgbà ní dáadáa. A máa ń pè wọ́n ní àwo rẹ̀ ọlọ́wọ̀, nítorí kò sẹ́ni tí Màmá àgbà máa ń gbà kó bá òun fọ̀ wọ́n, àyàfi òun nìkan. Lẹ́yìn tí Màmá àgbà kú ní 1943, Mọ́mì bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn àwo tó lẹ́wà yẹn ṣàlejò, ó sì ń lò wọ́n.
Jíjẹ́ Kí Ọwọ́ Dí Nínú Iṣẹ́ Ìsìn
Nígbà tó tún di ọjọ́ kan nínú ọgbà Patterson, bí mo ṣe dé ibi tí àwòrán Arákùnrin Rutherford wà nìyẹn, níbi tó ti ń sọ̀rọ̀ ní àpéjọpọ̀ Cedar Point, Ohio, ní 1919. Níbẹ̀, ó rọ gbogbo ènìyàn láti fìtara kópa nínú kíkéde Ìjọba Ọlọ́run àti pé kí wọ́n lo ìwé ìròyìn tuntun tó jáde ní àpéjọpọ̀ yẹn, ìyẹn ni The Golden Age. Bàbá àgbà ni wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí olóòtú rẹ̀, ó sì kọ àwọn àpilẹ̀kọ sínú rẹ̀ títí di àwọn ọdún 1940, nígbà tó kù díẹ̀ kó kú. Ní 1937, wọ́n yí orúkọ ìwé ìròyìn náà padà sí Consolation, àti sí Awake! ní 1946.
Bàbá àgbà máa ń kọ àwọn àpilẹ̀kọ rẹ̀ nílé, ní Scranton àti ní oríléeṣẹ́ Watch Tower, tó jẹ́ nǹkan bí òjì lé rúgba [240] kìlómítà sí Brooklyn, ó sì máa ń lo ọ̀sẹ̀ méjìméjì ní ibì kọ̀ọ̀kan. Dádì sọ pé òún rántí bí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé Bàbá àgbà ṣe máa ń dún lọ́pọ̀ ìgbà ní ìdájí, ní déédéé aago márùn-ún òwúrọ̀. Síbẹ̀, Bàbá àgbà kì í fi ẹrù iṣẹ́ nínípìn-ín nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù ṣeré rárá. Àní, ó tilẹ̀ tún ṣe ẹ̀wù ọkùnrin tó ní àwọn àpò abẹ́nú ńlá tó ṣeé kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí. Naomi Howell, ìyàwó àbúrò màmá mi tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún ṣì ní ọ̀kan. Ó tún ṣe àpò ìkówèésí fún àwọn obìnrin.
Nígbà kan, lẹ́yìn ìjíròrò Bíbélì tó gbádùnmọ́ni kan, ẹni tóun àti Bàbá àgbà jọ ṣiṣẹ́ sọ fún un pé: “C. J., o ṣe àṣìṣe kan o.”
Bàbá àgbà bi í léèrè pé, “àṣìṣe wo nìyẹn?” Ó yẹ àpò inú ẹ̀wù bàbá wò. Kò sí ìwé kankan níbẹ̀.
“O gbàgbé láti fi ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé The Golden Age lọ̀ ọ́.” Làwọn méjèèjì bá kú sẹ́rìn-ín nítorí pé olóòtú gbàgbé láti fi ìwé ìròyìn rẹ̀ lọni.
Àwọn Ìrántí Bí Mo Ṣe Dàgbà
Mo rántí bí mo ṣe jókòó lórí itan Bàbá àgbà nígbà tí mo wà lọ́mọdé, tí mo gbé ọwọ́ mi kékeré sórí tirẹ̀, tó sì ń sọ “Ìtàn Ìka Ọwọ́” fún mi. Ó bẹ̀rẹ̀ látorí “Àtàǹpàkò Tommy” ó bọ́ sórí “Ìka Ìjúwe Peter,” ó sì sọ ohun tó ṣe pàtàkì nípa ìka kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà ó rọra ṣu gbogbo wọn papọ̀ bó ti ń sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ wa pé: “Ìgbà tí gbogbo wọ́n bá ṣiṣẹ́ pọ̀ ló dára jù lọ, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń ran àwọn tó kù lọ́wọ́.”
Lẹ́yìn tí àwọn òbí mi ṣègbéyàwó, wọ́n ṣí lọ sí Cleveland, Ohio, wọ́n sì wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ed àti Mary Hooper. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni ìdílé àwọn méjèèjì láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún yìí. Àwọn òbí mi àti Dádì àgbà pẹ̀lú Mọ́mì àgbà, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe máa ń pe Ed àti Mary, wá di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Tọkọtaya Hooper ti pàdánù ọmọ kan ṣoṣo tí wọ́n bí, ọmọbìnrin ni, nítorí náà nígbà tí mo dáyé ní 1934, mo wá di “ọmọbìnrin” tí wọ́n fẹ́ràn gan-an. Níwọ̀n bí ó tí jẹ́ pé irú àyíká kan tó kún fún ipò tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ni a ti tọ́ mi dàgbà, mi ò tí ì pé ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run tí mo sì ṣèrìbọmi.
Láti kékeré ni Bíbélì kíkà ti jẹ́ apá kan ìgbésí ayé mi. Àpèjúwe bí ìgbésí ayé yóò ṣe rí nínú ayé tuntun Ọlọ́run, èyí tó wà nínú Aísáyà 11:6-9 jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àyọkà inú Ìwé Mímọ́ tí mo fẹ́ràn jù lọ. Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo gbìyànjú láti ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin ni ọdún 1944, lẹ́yìn tí mo gba ẹ̀dà American Standard Version tèmi, èyí tí wọ́n mú jáde ní ẹ̀dà àkànṣe ní àpéjọpọ̀ Buffalo, ní New York. Inú mi mà dùn láti ka ìtumọ̀ yìí o, nínú èyí tí a ti dá orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, padà síbi tó yẹ ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà ẹgbẹ̀rún méje nínú “Májẹ̀mú Láéláé”!
Àkókò ìdùnnú ni òpin ọ̀sẹ̀ máa ń jẹ́. Àwọn òbí mi àti ìdílé Hooper máa ń mú mi dáni láti lọ jẹ́rìí ní àwọn ìgbèríko. A máa ń gbé oúnjẹ ọ̀sán dání, a sì máa ń ṣe fàájì lẹ́bàá odò kan. Lẹ́yìn náà, àá wá lọ si oko ẹnì kan fún àsọyé Bíbélì fún gbogbo ènìyàn, èyí ti a ti pe gbogbo àwọn aládùúgbò náà sí. Ìgbésí ayé rọrùn. Ayọ̀ wà nínú àwọn ìdílé wa wọ̀nyí. Àwọn kan lára àwọn ìdílé ìgbà náà wá di alábòójútó arìnrìn-àjò níkẹyìn, títí kan Ed Hooper, Bob Rainer, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Richard Rainer ṣì ń bá iṣẹ́ tirẹ̀ lọ, tòun ti Linda, aya rẹ̀.
Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ló máa ń gbádùn mọ́ni jù lọ. Mó máa ń dé sọ́dọ̀ ìdílé Howell ní abúlé wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n ìyá mi. Ní 1949, Grace tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n ìyá mi fẹ́ Malcolm Allen. Mi ò mọ̀ rárá pé mo ṣì máa wá fẹ́ arákùnrin rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Marion tó jẹ́ ọmọ àbúrò màmá mi ní tiẹ̀ ń sìn gẹ́gẹ́ bí Míṣọ́nnárì ní Uruguay. Ó fẹ́ Howard Hilborn ní 1966. Àwọn ìbátan mi méjèèjì yìí pẹ̀lú àwọn ọkọ wọn sìn ní orílé-iṣẹ́ Brooklyn fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà.
Bàbá Àgbà àti Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Mi
Láàárín àwọn ọdún tí mo fi wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, Bàbá àgbà kì í yé kọ̀wé sí mi. Àwọn lẹ́tà rẹ̀ máa ń ní àwọn fọ́tò ìdílé nínú, ó sì máa ń tẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé sẹ́yìn wọn, èyí tó fi ń sọ ìtàn ìdílé fún mi. Bí mo ṣe ri ẹ̀dà tèmi gbà nínú fọ́tò rẹ̀ níbi ti wọ́n ti fi òun àtàwọn tó kù sẹ́wọ̀n láìbófinmu nìyẹn.
Nígbà tó fi máa di ìparí 1951, àrùn jẹjẹrẹ kò jẹ́ kí Bàbá àgbà lè sọ̀rọ̀ mọ́. Ó ṣì máa ń dápàárá síbẹ̀síbẹ̀, àmọ́, ó ní láti máa kọ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìwé kékeré kan tó máa ń mú káàkiri. January 1952 ni kíláàsì tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga máa kẹ́kọ̀ọ́ yege. Ní ìbẹ̀rẹ̀ December, mo fi ẹ̀dà ọ̀rọ̀ tí mo máa sọ níbi ayẹyẹ náà ránṣẹ́ sí Bàbá àgbà. Ó kọ ọ̀rọ̀ olóòtú díẹ̀ sí i, lẹ́yìn náà ló wá kọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin sojú ìwé tó kẹ́yìn pé: “Inú Bàbá Àgbà dùn.” Ó parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní December 18, 1951, ní ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin.a Ojú ribiribi ni mo ṣì fi ń wo ìwé tó ti ń ṣá yẹn, èyí tó ní àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sọ níbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege mi nínú àti àwọn ọ̀rọ̀ Bàbá àgbà tó wà lójú ìwé rẹ̀ tó kẹ́yìn.
Kété lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́yege mi, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń pe iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún. Ní 1958, mo lọ sí àpéjọpọ̀ tí omilẹgbẹ èèyàn wá, tó wáyé ní New York City, níbi tí iye ènìyàn tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀tàlérúgba ó dín méje, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti méjìlélógún [253,922] láti orílẹ̀ èdè mẹ́tàlélọ́gọ́fà ti kún Pápá Ìṣeré Yankee àti Polo Grounds dẹ́múdẹ́mú lọ́jọ́ térò pọ̀ jù lọ. Lọ́jọ́ kan níbẹ̀, mo pàdé aṣojú kan láti Áfíríkà tí wọ́n kọ “Woodworth Mills” sára káàdì ìdánimọ̀ tó wà láyà rẹ̀. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ṣáájú ìgbà yìí ni wọ́n sọ ọ́ lórúkọ tí Bàbá àgbà ń jẹ́!
Mo Láyọ̀ Nítorí Ogún Mi
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, màmá mi tún padà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ó kú ní ogójì ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn ní 1988, aṣáájú ọ̀nà ṣì ni títí di ìgbà yẹn! Dádì máa ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà láwọn ìgbà tó bá lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó kú ní oṣù mẹ́sàn-án ṣáájú Mọ́mì. Àwọn tí a bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ di ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n títí ayé. Díẹ̀ lára àwọn ọmọ wọn ọkùnrin lọ sìn ní oríléeṣẹ́ Brooklyn, àwọn yòókù si wọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà.
Ọdún 1959 jẹ́ ọdún tó ṣe pàtàkì gan an fún mi. Ìgbà yẹn ni wọ́n fi mí mọ Paul Allen. Wọ́n ti yàn án gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò ní 1946, nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ni kíláàsì keje ti Gílíádì, ìyẹn ilé ẹ̀kọ́ kan táa ti ń dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́kọ̀ọ́ láti di míṣọ́nnárì. Nígbà táa pàdé, kò síkankan nínú wa tó mọ̀ pé Cleveland, Ohio, níbi tí mo ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ni ibi tí Paul yóò ti lọ ṣiṣẹ́ lẹ́yìn náà. Dádì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, Mọ́mì náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú. A ṣègbéyàwó ní July 1963, ní abúlé àwọn Howell, pẹ̀lú àwọn ìdílé wa lọ́tùn-ún àti lósì tí Ed Hooper sì sọ̀rọ̀ ìgbéyàwó wa. Àlá kan tó wá ṣẹ ni.
Paul kò fìgbà kankan ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Nígbà táa kúrò ní Cleveland láti lọ síbi tí wọ́n tún yàn án sí láti lọ ṣiṣẹ́, gbogbo ohun ìní wa pátá ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Volkswagen mi ti 1961 gbà ṣẹ́mú. Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ọ̀rẹ́ máa ń wá ní àwọn ọjọ́ Monday láti wò wá nígbà táa bá ń dẹrù, ìyẹn ní ọjọ́ táa máa ń lọ sí ìjọ mìíràn. Àfi bí ìran àpéwò ìta gbangba ni, bí àwọn àpótí, àpò ìfàlọ́wọ́, àpótí táa ń kó àwọn fáìlì sí, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àti àwọn nǹkan mìíràn ṣe ń wọlé ṣinrá sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kóńkóló yẹn.
Èmi àti Paul ti rin àìlóǹkà kìlómítà, tí à ń gbádùn àwọn ohun tó dùn mọ́ni nínú ìgbésí ayé ìsinsìnyí tí a sì tún jọ ń fara da àwọn ìṣòrò inú rẹ̀—gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀ nínú agbára tí Jèhófà nìkan ṣoṣo ń fúnni. Àwọn ọdún wọ̀nyẹn ti jẹ́ èyí tó kún fún ayọ̀, tó kún fún ìfẹ́ fún Jèhófà, fún ara wa, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ wa ọlọ́jọ́ pípẹ́ àtàwọn tó jẹ́ tuntun. Oṣù méjì táa lò ní Patterson nígbà tí Paul ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́, ló ṣì jẹ́ apá tó dùn jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Wíwo ètò àjọ Jèhófà ti orí ilẹ̀ ayé kínníkínní ti túbọ̀ fìdí ẹ̀rí ìdánilójú tí wọ́n fún mi gẹ́gẹ́ bí apá kan ogún tẹ̀mí ṣíṣeyebíye múlẹ̀ pé: Lóòótọ́ èyí gan an ni ètò àjọ Ọlọ́run. Ayọ̀ ńlá ló mà jẹ́ o láti lè jẹ́ apá kékeré kan nínú rẹ̀!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé Ìṣọ, February 15, 1952, ojú ìwé 128 (Èdè Gẹ̀ẹ́sì).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi àti Ed Hooper kété ṣáájú àpéjọpọ̀ St. Louis ti 1941, níbi tí mo ti gba ẹ̀dà ìwé “Children” tèmi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Bàbá àgbà ní 1948
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ní oko àwọn Howell nígbà tí àwọn òbí mi (nínú àkámọ́) ṣègbéyàwó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́jọ tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n láìbófinmu ní 1918 (Bàbá àgbà ló dúró ní ìkangun lápá ọ̀tún)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Gbogbo ohun ìní tí a ní láyé ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ “Volkswagen” wa gbà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Èmi àti Paul, ọkọ mi