Ìtàn Ìgbésí Ayé
Bí Mo Ṣe Jàǹfààní Látinú Jíjẹ́ Tí Ìdílé Mi Jẹ́ Adúróṣinṣin
GẸ́GẸ́ BÍ KATHLEEN COOKE ṢE SỌ Ọ́
LỌ́DÚN 1911, ìyá ìyá mi tó ń jẹ́ Mary Ellen Thompson lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ nílùú Glasgow, ní Scotland, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Lákòókò yẹn, ó lọ gbọ́ àsọyé kan látẹnu Arákùnrin Charles Taze Russell, tó jẹ́ ògúnnágbòǹgbò lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a wá mọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó yá. Inú ìyá mi àgbà dùn gan-an sí ọ̀rọ̀ tó gbọ́ yẹn. Nígbà tó padà dé orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà, ó wá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà ládùúgbò rẹ̀ kàn. Lóṣù April ọdún 1914, ó wà lára àwọn mẹ́rìndínlógún tó ṣèrìbọmi nípàdé àgbègbè àkọ́kọ́ táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lórílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà. Ọmọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Edith tó wá di ìyá mi jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà nígbà yẹn.
Lẹ́yìn ikú Arákùnrin Russell lọ́dún 1916, ìyapa wáyé láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé. Iye àwọn adúróṣinṣin tó wà nílùú Durban dín kù gan-an látorí ọgọ́ta sí nǹkan bíi méjìlá. Ìyá bàbá mi tó ń jẹ́ Ingeborg Myrdal àti ọmọ rẹ̀, Henry, tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi nígbà yẹn kò fi àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sílẹ̀. Lọ́dún 1924, Henry di apínwèé-ìsìn-kiri, ìyẹn orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù nígbà yẹn. Odindi ọdún márùn-ún ló fi wàásù ní ibi púpọ̀ lápá gúúsù Áfíríkà. Lọ́dún 1930, Henry àti Edith fẹ́ ara wọn, wọ́n sì bí mi lọ́dún mẹ́ta lẹ́yìn náà.
Àwọn Ẹbí Mi
A gbé orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì fúngbà díẹ̀, ṣùgbọ́n lọ́dún 1939, a kó lọ sọ́dọ̀ bàbá ìyá mi àti ìyá ìyá mi tí wọ́n ń jẹ́ Thompson. Ilé wọn wà nílùú Johannesburg lórílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà. Bàbá àgbà kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì, nígbà mìíràn ó máa ń ta ko ìyá àgbà, àmọ́ ó jẹ́ ẹni tó kóni mọ́ra gan-an. Wọ́n bí àbúrò mi obìnrin tó ń jẹ́ Thelma lọ́dún 1940. Èmi pẹ̀lú rẹ̀ kọ́ bá a ṣe ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń fa àkókò oúnjẹ wa gùn lálẹ́ ká lè ráyè sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́jọ́ yẹn tàbí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn.
Ìdílé wa máa ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tó máa ń dé sílé wa, pàápàá àwọn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Wọ́n máa ń bá wa sọ̀rọ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́, ọ̀rọ̀ wọn sì mú kí ìmọrírì tá a ní fún ogún wa tẹ̀mí máa pọ̀ sí i. Èyí jẹ́ kó wu èmi àti Thelma gan-an láti di aṣáájú-ọ̀nà bíi tiwọn.
Látìgbà tá a ti wà lọ́mọdé ni wọ́n ti jẹ́ ká mọ̀ pé ìwé kíkà máa ń gbádùn mọ́ni. Bàbá mi, ìyá mi àti ìyà mi àgbà máa ń ka àwọn ìwé ìtàn tó dára fún wa, wọ́n sì tún máa ń ka Bíbélì fún wa. Bí oúnjẹ ti ṣe pàtàkì fún ara làwọn ìpàdé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ṣe pàtàkì fún wa gan-an. Bàbá mi ni ìránṣẹ́ ẹgbẹ́ ní Ìjọ Johannesburg nígbà yẹn (ìyẹn àwọn tí à ń pè ní alága àwọn alábòójútó nísinsìnyí), nítorí náà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ tètè dé sípàdé. Nígbà tá a ṣèpàdé àgbègbè kan, ọwọ́ bàbá mi dí nínú iṣẹ́ bíbójú tó àpéjọ náà, màmá mi sì ń ṣèrànwọ́ láti ṣètò ibi táwọn àlejò máa dé sí.
Ìpàdé Àgbègbè Kan Tó Jẹ́ Àkànṣe fún Wa
Ìpàdé àgbègbè tó wáyé lọ́dún 1948 nílùú Johannesburg jẹ́ àkànṣe. Ìyẹn nìgbà àkọ́kọ́ táwọn kan wá láti orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York, nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Bàbá mi ni wọ́n yàn láti máa fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ gbé arákùnrin Nathan Knorr àti Milton Henschel lákòókò tí wọ́n fi wà níbẹ̀. Ìpàdé àgbègbè yẹn ni mo sì ti ṣèrìbọmi.
Kété lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún bàbá mi nígbà tí bàbá rẹ̀ sọ fún un pé òun kábàámọ̀ pé lẹ́yìn tí Arákùnrin Russell kú, òun jẹ́ káwọn tó yapa kúrò lọ́dọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì darí òun. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà ló kú. Àmọ́, ìyá bàbá mi tó ń jẹ́ Myrdal dúró ṣinṣin títí tó fi parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lọ́dún 1955.
Àwọn Ohun Tó Gbé Mi Dé Ibi Tí Mo Dé Yìí
Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní ọjọ́ kìíní oṣù February ọdún 1949. Kò pẹ́ sígbà yẹn la gbọ́ pé ìpàdé àgbáyé yóò wáyé lọ́dún tó tẹ̀ lé e nílùú New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, inú wa sì bẹ̀rẹ̀ sí í dùn. Ó wù wá gan-an láti lọ, àmọ́ agbára wa kò gbé e. Ìgbà yẹn ni bàbá ìyá mi tó ń jẹ́ Thompson wá kú lóṣù February ọdún 1950. Ìyà àgbà sì fi owó tó jogún san owó ọkọ̀ àwa márààrún.
Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ká tó lọ, lẹ́tà kan dé láti orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York. Wọ́n fi lẹ́tà náà pè mí láti wá sí kíláàsì kẹrìndínlógún ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì tó wà fáwọn míṣọ́nnárì. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi nítorí mi ò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún! Nígbà tí kíláàsì yẹn bẹ̀rẹ̀, mo wà lára akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́wàá tó ti orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà wá láti gbádùn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ yẹn.
Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege lóṣù February ọdún 1951, mẹ́jọ lára wa padà sí orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà láti lọ máa ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Láwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ ìgbà lèmi àti èkejì mi ṣiṣẹ́ láwọn ìlú kéékèèké tí wọ́n ti ń sọ èdè Afrikaans. Níbẹ̀rẹ̀, mi ò lè sọ èdè yẹn. Mo rántí ọjọ́ kan tí mò ń gun kẹ̀kẹ́ bọ̀ wá sílé tí mò ń sunkún nítorí pe mi ò lè sọ èdè yẹn dáadáa nígbà tí mò ń wàásù. Àmọ́, nígbà tó yá, mo wá mọ̀ ọ́n sọ gan-an, Jèhófà sì mú kí ìsapá mi yọrí rere.
Mo Ṣègbéyàwó, Mo sì Kópa Nínú Iṣẹ́ Arìnrìn-àjò
Lọ́dún 1955, mo mọ arákùnrin John Cooke. Òun ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù nílẹ̀ Faransé, nílẹ̀ Potogí àti nílẹ̀ Sípéènì kí Ogun Àgbáyé Kejì tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ogun ọ̀hún. Ọdún tó di míṣọ́nnárì nílẹ̀ Áfíríkà ni mo bá a pàdé. Lẹ́yìn ìgbà náà, ó kọ̀wé pé: “Ohun ìyanu mẹ́ta ló ṣẹlẹ̀ sí mi láàárín ọ̀sẹ̀ kan ṣoṣo . . . Arákùnrin kan tó lawọ́ gan-an fún mi ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kékeré kan, wọ́n sọ mí di ìránṣẹ́ àgbègbè, mo sì rí ọmọbìnrin kan tí mo fẹ́ràn.”a Oṣù December ọdún 1957 la ṣègbéyàwó.
Nígbà tá à ń fẹ́ra wa sọ́nà, John mú un dá mi lójú pé tá a bá fẹ́ra wa màá gbádùn ayé mi gan-an, òótọ́ sì ni. A bẹ ìjọ wò káàkiri orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà, pàápàá jù lọ ibi táwọn adúláwọ̀ pọ̀ sí. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ là ń dojú kọ ìṣòro gbígba àṣẹ láti wọ ibi táwọn adúláwọ̀ wà, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ tún wá sọ ìṣòro tó ń dojú kọ wá tá a bá fẹ́ sùn níbẹ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ilẹ̀ẹ́lẹ̀ la máa ń sùn sí nínú ilé ìtajà kan tó wà lágbègbè àwọn aláwọ̀ funfun, a kì í sì í jẹ́ káwọn tó ń kọjá lọ rí wa. Ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí aláwọ̀ funfun tó sún mọ́ ibi tá à ń bẹ̀ wò jù lọ la sábà máa ń dé sí, bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀ kìlómítà ni ibẹ̀ fi jìnnà síbi táwọn adúláwọ̀ wà.
Ṣíṣe àpéjọ nínú àwọn ibi ìpàdé tí wọ́n kọ́ sínú igbó tún jẹ́ ìṣòro. A máa ń fi sinimá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà hàn àwọn èèyàn, ìyẹn sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọyì ẹgbẹ́ ará wa tó kárí ayé. A máa ń gbé ẹ̀rọ amúnáwá tiwa dání nítorí kì í sábà síná mànàmáná láwọn àgbègbè yẹn. A tún dojú kọ ìṣòro láwọn àgbègbè tó wà lábẹ́ àkóso Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì níbi tí wọ́n ti fòfin de àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa nígbà yẹn. A sì tún kojú ìṣòro kíkọ́ èdè Súlú. Síbẹ̀, inú wa dùn pé a lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́.
Lóṣù August ọdún 1961, John, ọkọ mi di olùkọ́ àkọ́kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ nílẹ̀ Gúúsù Áfíríkà. Ọ̀sẹ̀ mẹ́rin ni wọ́n fi ń ṣe é, ó sì wà fún ríran àwọn tó jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ lọ́wọ́. Ọkọ mi mọ èèyàn kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn nítorí pé àlàyé rẹ̀ máa ń rọrùn, àwọn àpèjúwe tó máa ń lò sì ṣe kedere. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan àtààbọ̀ tá a fi ń rìnrìn àjò láti ibì kan síbòmíràn láti kọ́ kíláàsì tí wọ́n ń fi èdè Gẹ̀ẹ́sì dárí. Nígbà tí ọkọ mi bá ń kọ́ wọn ní kíláàsì, èmi máa ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò ibẹ̀ jáde lọ wàásù. Ó jọ wá lójú gan-an nígbà tá a rí lẹ́tà gbà pé ká wá sìn lẹ́ka iléeṣẹ́ wa tó wà nítòsí ìlú Johannesburg nílẹ̀ Gúúsù Áfíríkà, wọ́n sì ní ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́jọ́ kìíní oṣù July, ọdún 1964.
Lákòókò yìí, bó ṣe ń ṣe ọkọ mi kò yé wa mọ́. Lẹ́yìn ìgbà tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ti mú un lọ́dún 1948, kò fi bẹ́ẹ̀ lókun nínú mọ́. Òtútù àti ọ̀fìnkìn sábà máa ń yọ ọ́ lẹ́nu, yóò sì dùbúlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, kò ní lè ṣe ohunkóhun, kò sì ní rí ẹnikẹ́ni. Dókítà tá a lọ rí kí wọ́n tó pè wá sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa sọ pé ìdààmú ọkàn ni ìṣòro ọkọ mi.
Kò rọrùn fún wa rárá láti dín iṣẹ́ wa kù bí dókítà yẹn ṣe dámọ̀ràn rẹ̀ fún wa. Ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, wọ́n ní kí ọkọ mi máa ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń bójú tó ọ̀ràn Iṣẹ́ Ìsìn, wọ́n sì yan èmi síbi tí wọ́n ti ń ka ìwé láti ṣàtúnṣe àwọn àṣìṣe to bá wà níbẹ̀. Àǹfààní ńláǹlà ló sì jẹ́ láti ní yàrá tiwa! Ọkọ́ mi ti sìn rí láwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí ká tó ṣègbéyàwó. Nítorí náà lọ́dún 1967 wọ́n sọ fún wa pé ká lọ dara pọ̀ mọ́ ìdílé Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo tó ń sọ èdè Potogí nítòsí Bẹ́tẹ́lì, ká lè jọ máa wàásù lágbègbè táwọn tó ń sọ èdè Potogí pọ̀ sí nítòsí ìlú Johannesburg. Èyí túmọ̀ sí pé mo ní láti kọ́ èdè pótogí.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé káàkiri àgbègbè náà làwọn tó ń sọ èdè Potogí wà, a máa ń rìnrìn àjò gan-an, kódà nígbà mìíràn, a máa ń rin ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kìlómítà láti lè dé ọ̀dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ Bíbélì. Lákòókò yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí láti Mòsáńbíìkì tí wọ́n ń sọ èdè Potogí bẹ̀rẹ̀ sí í wá sọ́dọ̀ wa nígbà àpéjọ, èyí sì jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà fún àwọn ẹni tuntun tó wà láàárín wa. Lọ́dún mọ́kànlá tá a fi wàásù pẹ̀lú àwọn tó ń sọ èdè Potogí, àwùjọ wa kékeré tó jẹ́ nǹkan bí ọgbọ̀n èèyàn pọ̀ sí i, ó sì di ìjọ mẹ́rin.
Àwọn Nǹkan Ń Yí Padà Nílé
Lákòókò yẹn, àwọn nǹkan ti ń yí padà nílé àwọn òbí mi. Lọ́dún 1960, àbúrò mi obìnrin, Thelma, fẹ́ John Urban, aṣáájú-ọ̀nà kan láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́dún 1965, wọ́n lọ sí Kíláàsì Ogójì ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì wọ́n sì sìn lórílẹ̀-èdè Brazil fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Lọ́dún 1990, wọ́n padà sí ìpínlẹ̀ Ohio lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti bójú tó àwọn òbí John nítorí pé ara wọ́n kò le. Láìka wàhálà tójú wọn rí nítorí bíbójútó àwọn òbí wọn, wọ́n ṣì wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún títí dòní yìí.
Ìyá ìyá mi jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí tó fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lọ́dún 1965 lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98]. Ọdún yẹn náà ni bàbá mi fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sọ fún èmi àti ọkọ mi pé ká ṣèrànwọ́ lágbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí, bàbá mi àti màmá mi yọ̀ǹda láti dara pọ̀ mọ́ wa. Ìrànwọ́ ńlá gbáà ni wọ́n jẹ́ fún àwùjọ yẹn. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, a fìdí ìjọ àkọ́kọ́ múlẹ̀ níbẹ̀. Kété lẹ́yìn náà ni màmá mi ní àrùn jẹjẹrẹ, èyí sì gbẹ̀mí rẹ̀ lọ́dún 1971. Bàbá mi sì kú lọ́dún méje lẹ́yìn náà.
Mò Fàyà Rán Àìlera Ọkọ Mi
Nígbà tó di àwọn ọdún 1970, ó hàn kedere pé àìsàn ọkọ mi ń le sí i. Díẹ̀díẹ̀, ó ní láti fi àwọn kan sílẹ̀ lára iṣẹ́ ìsìn tó fẹ́ràn gan-an, títí kan dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa àti dídarí ìjíròrò Bíbélì tá a máa ń ṣe níbẹ̀ lárààárọ̀. Wọ́n yí iṣẹ́ rẹ̀ padà láti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn sí ẹ̀ka Ìkówèéránṣẹ́. Nígbà tó yá, wọ́n tún ní kó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú ọgbà òdòdó.
Ìtara tí ọkọ mi ní mú kó ṣòro fún un láti ṣe ìyípadà. Nígbà tí mo bá ń rọ̀ ọ́ ṣáá pé kó dín iṣẹ́ tó ń ṣe kù, ńṣe ló máa ń bá mí ṣàwàdà, táá máa sọ pé ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ni mo jẹ́ lọ́rùn ẹsẹ̀ òun, àmọ́, ó sábà máa ń gbá mi mọ́ra láti fi hàn pé òun mọrírì mi. Nígbà tó yá, a rí i pé á dára ká kúrò ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí yẹn, ká kúkú máa lọ sí ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Bẹ́tẹ́lì.
Bí àìsàn ọkọ mi ti ń le sí i, rírí tí mò ń rí i pé àjọṣe àárín òun àti Jèhófà dára gan-an, ń múnú mi dùn. Nígbà tí ọkọ mi bá jí lọ́gànjọ́ òru nínú ìdààmú ọkàn ńláǹlà, a jọ máa ń sọ̀rọ̀ títí ara rẹ̀ á fi wálẹ̀ tóun fúnra rẹ̀ á fi lè gbàdúrà sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà tó yá, ó gbìyànjú láti fúnra rẹ̀ kápá ipò ìdààmú yẹn nípa kíka ohun tó wà ní Fílípì 4:6, 7 lóhùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun . . . ” Lẹ́yìn náà, ara rẹ̀ á wálẹ̀, á sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń ta jí, màá sì rọra máa wo ètè rẹ̀ bó ṣe ń mì bó ti ń gbàdúrà taratara sí Jèhófà láìdánudúró.
Níwọ̀n bí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa kò ti fi bẹ́ẹ̀ gba àwa táà ń sìn níbẹ̀ mọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ẹ̀ka iléeṣẹ́ ńlá tuntun kan síbì kan tí kò jìnnà sílùú Johannesburg. Èmi àti ọkọ mi máa ń lọ síbi tó dára tó sì tuni lára yìí, kò sí ariwo àti afẹ́fẹ́ tí kò dára tó máa ń wà nígboro níbẹ̀. Ara túbọ̀ tu ọkọ mi nígbà tí wọ́n fún wa láyè láti kó lọ sínú àwọn ilé kan níbẹ̀ fúngbà díẹ̀ ná, kó tó di pé wọ́n parí kíkọ́ ẹ̀ka tuntun náà.
Àwọn Ìṣòro Tuntun Yọjú
Bí ọkọ mi ti ń dẹni tí kò lè ronú dáadáa mọ́, ó túbọ̀ ń ṣòro fún un láti ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un. Àmọ́ nígbà tí mo bá rí ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń ràn án lọ́wọ́, ó máa ń mórí mi wú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí arákùnrin kan bá ń lọ sí ilé ìkàwé láti lọ ṣe àwọn ìwádìí kan, ó máa ń mú ọkọ mi dání. Ìwé àṣàrò kúkúrú àtìwé ìròyìn sì máa ń kún inú àpò ọkọ mi fọ́fọ́ nígbà tó bá ń jáde lọ pẹ̀lú arákùnrin náà. Èyí jẹ́ kí ọkọ mi rí i pé òun náà ṣì ń gbé àwọn nǹkan kan ṣe, ó sì jẹ́ kó lè níyì lọ́wọ́ ara rẹ̀.
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọkọ mi ò lè kàwé mọ́ nítorí pé ọjọ́ ogbó ń mú kó máa ṣarán. A mọrírì àwọn kásẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sínú wọn àtàwọn kásẹ́ẹ̀tì orin. A máa ń gbọ́ àwọn kásẹ́ẹ̀tì náà ní àgbọ́túngbọ́. Ara ọkọ mi kì í balẹ̀ tí mi ò bá jókòó tì í kí n sì máa gbọ́ kásẹ́ẹ̀tì náà pẹ̀lú rẹ̀, nítorí náà mo máa ń hun nǹkan láwọn àkókò yẹn. Ìyẹn sì jẹ́ ká ní ọ̀pọ̀ súwẹ́tà àti bùláńkẹ́ẹ̀tì!
Nígbà tó yá, àìsàn ọkọ mi gba kí n túbọ̀ máa bójú tó o gan-an. Àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sábà máa ń rẹ̀ mí gan-an láti kàwé tàbí láti kẹ́kọ̀ọ́, àǹfààní ló jẹ́ fún mi láti bójú tó o títí dópin. Òpin yẹn dé lọ́dún 1998 nígbà tí ọkọ mi, John, kú wọ́ọ́rọ́wọ́ sọ́wọ́ mi lẹ́yìn tó pé ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin [85], tó sì dúró ṣinṣin títí dópin. Mò ń fojú sọ́nà láti rí i nígbà àjíǹde pẹ̀lú ara líle àti ọpọlọ pípé!
Àwọn Ohun Tó Ń Tù Mí Lára
Lẹ́yìn tí ọkọ mi kú, kò rọrùn fún mi láti máa dá ṣe àwọn nǹkan. Nítorí náà, lóṣù May ọdún 1999, mo lọ kí àbúrò mi, Thelma àti ọkọ rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Rírí tí mo rí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, pàápàá nígbà tí mo lọ ṣèbẹ̀wò sí orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New York, tù mí lára gan-an, ó sì múnú mi dùn jọjọ! Ó dájú pé ìṣírí tẹ̀mí tí mò ń fẹ́ gan-an nìyẹn.
Tí mo bá ń ronú nípa ìgbésí ayé àwọn èèyàn mi tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, ó máa ń jẹ́ kí n rántí ọ̀pọ̀ àǹfààní tí mo ti ní. Látinú ìtọ́ni tí wọ́n fún mi àti àpẹẹrẹ wọn, pa pọ̀ pẹ̀lú ìrànwọ́ wọn, mo ti kọ́ láti máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn orílẹ̀-èdè mìíràn àti ẹ̀yà mìíràn. Mo ti kọ́ béèyàn ṣe ń ní sùúrù àti ìfaradà, mo sì tún ti kọ́ béèyàn ṣe ń fara mọ́ onírúurú ipò tó bá yọjú. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo rí i pé Jèhófà, Olùgbọ́ àdúrà ti fi inú rere hàn sí mi. Bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára mi jọ ti onísáàmù, ẹni tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ìwọ yàn, tí ìwọ sì mú kí ó tọ̀ ọ́ wá, kí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ. Dájúdájú, àwọn ohun rere inú ilé rẹ yóò tẹ́ wa lọ́rùn.”—Sáàmù 65:4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ile-Iṣọ Na ti August 1, 1959 ojú ìwé 468 sí 472, (èdè Gẹ̀ẹ́sì).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìyá ìyá mi àtàwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Èmi àtàwọn òbí mi nígbà tí mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1948
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Èmi àti Albert Schroeder, ẹni tó ń gba orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́sàn-án mìíràn láti orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Èmi àti ọkọ mi, John, lọ́dún 1984