ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w01 11/15 ojú ìwé 2-4
  • Ǹjẹ́ Ìrètí Kankan Tiẹ̀ Wà Pé A Ó Gbà Wá Là?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ìrètí Kankan Tiẹ̀ Wà Pé A Ó Gbà Wá Là?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí “Ìrètí Ìgbàlà” Wà Lọ́kàn Rẹ Digbí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìgbàlà Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Gan-An
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Kí Ni Ìgbàlà?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìfihàn 21:4—“Ọlọ́run Yóò sì Nu Omijé Gbogbo Nù Kúrò ni Ojú Wọn”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
w01 11/15 ojú ìwé 2-4

Ǹjẹ́ Ìrètí Kankan Tiẹ̀ Wà Pé A Ó Gbà Wá Là?

Ọ̀rúndún ogún làwọn èèyàn pè ní ọ̀kan lára àwọn ọ̀rúndún tí wọ́n ti tàjẹ̀ sílẹ̀ jù lọ nínú ìtàn ìran ènìyàn. Ìwà ọ̀daràn, ogun, rògbòdìyàn kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìjoògùnyó, àìṣòótọ́, àti ìwà ipá ti pọ̀ kọjá sísọ láàárín àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sígbà tá a wà yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ìrora àti ìyà tí àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú ń mú wá tún wà níbẹ̀. Ta ló máa sọ pé òun ò fẹ́ bọ́ nínú àìmọye ìṣòro tó wà láyé lónìí? Bá a ṣe ń wo ọjọ́ iwájú, ǹjẹ́ ìrètí kankan tiẹ̀ wà pé a ó gbà wá là?

GBÉ ìran tá a fi han àpọ́sítélì Jòhánù ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn yẹ̀ wò. Ó kọ̀wé pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Wòlíì Aísáyà náà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní ti tòótọ́, òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn. Ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òun yóò sì mú kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ ọ́.”—Aísáyà 25:8.

Ṣáà fojú inú wo bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí Ọlọ́run bá mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ! A ó gba ìran ènìyàn là, tàbí ká dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ ìnilára àti ìwà ipá, àti kúrò lọ́wọ́ ohun tó ń fa ìjìyà àti wàhálà. Àní, àìsàn ọjọ́ ogbó, àti ikú pàápàá kò ní sí mọ́! Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ́ ipò pípé lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43; Jòhánù 17:3) Ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí i. “Ìfẹ́ [Ọlọ́run ni] pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:3, 4.

Àmọ́, ká tó lè jàǹfààní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ lóye ipa tí Jésù kó nínú ìgbàlà wa, kí a sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Jésù alára sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń tọ́ka sí ipa pàtàkì tí Jésù Kristi kó nínú ọ̀ràn yìí, ó sọ pé: “Kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn, nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.” (Ìṣe 4:12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Sílà, alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ rọ ẹnì kan tó ń fi òtítọ́ inú ṣèwádìí pé: “Gba Jésù Olúwa gbọ́, ìwọ yóò sì rí ìgbàlà, ìwọ àti agbo ilé rẹ.”—Ìṣe 16:30, 31.

Dájúdájú, Jésù Kristi ni “Olórí Aṣojú ìyè,” ipasẹ̀ rẹ̀ nìkan ṣoṣo la sì lè gbà rí ìgbàlà. (Ìṣe 3:15) Àmọ́, báwo ló ṣe jẹ́ pé ọkùnrin kan ṣoṣo ló lè gbà wá là? Lílóye ipa tó kó nínú ọ̀ràn yìí dáradára yóò jẹ́ kí ìrètí ìgbàlà wa túbọ̀ lágbára sí i.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ojú ìwé 3: Àwọn ọkọ̀ òfuurufú afibọ́ǹbùṣọṣẹ́: Fọ́tò USAF; àwọn ọmọ tí ebi ń pa: ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ/J. FRAND; ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi ń jagun tó ń jóná: Fọ́tò U.S. Navy

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́