ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 1/1 ojú ìwé 13-21
  • “Ìró Wọ́n Jáde Lọ Sí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ìró Wọ́n Jáde Lọ Sí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Iye Wa Ṣe Ń Pọ̀ Sí I Lónìí Lọ́nà Tó Yára Kánkán
  • Ní Àwọn Ilẹ̀ Òkèèrè
  • “Láti Inú Gbogbo Àwọn . . . Ẹ̀yà àti Ènìyàn àti Ahọ́n”
  • “Sí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé”
  • Àwọn Èèyàn “Láti Inú Gbogbo Èdè” Ń Gbọ́ Ìhìn Rere Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ìhìn Rere Fún Àwọn Èèyàn Gbogbo Orílẹ̀-èdè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Gbogbo Awọn Kristian Tootọ Gbọdọ Jẹ́ Ajihinrere
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Kíkó Àwọn Èèyàn Jọ Látinú Gbogbo Èdè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 1/1 ojú ìwé 13-21

“Ìró Wọ́n Jáde Lọ Sí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé”

‘Ẹ máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, kí ẹ sì máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.’—MÁTÍÙ 28:19.

1, 2. (a) Iṣẹ́ wo ni Jésù yàn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? (b) Kí ló mú kí àṣeyọrí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?

KÉTÉ kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó yan iṣẹ́ kan fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, kí ẹ sì máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.’ (Mátíù 28:19) Áà, iṣẹ́ bàǹtàbanta nìyẹn mà jẹ́ o!

2 Rò ó wò ná! Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nǹkan bí ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn ni a tú ẹ̀mí mímọ́ lé lórí, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ yẹn nípa sísọ fún àwọn èèyàn pé Jésù ni Mèsáyà náà ti wọn tí ń retí fún ọjọ́ pípẹ́, ẹni tí a óò tipasẹ̀ rẹ̀ rí ìgbàlà. (Ìṣe 2:1-36) Báwo ni àwùjọ kéréje yẹn yóò ṣe wàásù dé ọ̀dọ̀ “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè”? Lọ́dọ̀ èèyàn, kò lè ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n “lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.” (Mátíù 19:26) Àwọn Kristẹni ìjímìjí rí ìtìlẹyìn ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, wọ́n sì fi ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ náà. (Sekaráyà 4:6; 2 Tímótì 4:2) Nítorí náà, láàárín ẹ̀wádún díẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lè sọ pé a ti polongo ìhìn rere náà “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kólósè 1:23.

3. Kí ni kò jẹ́ ká dá “àlìkámà” tó jẹ́ ojúlówó Kristẹni mọ̀?

3 Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ọ̀rúndún kìíní ni ìjọsìn tòótọ́ fi gbilẹ̀. Àmọ́, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí Sátánì yóò gbin “èpò” tí yóò bo àwọn Kristẹni tòótọ́ tó jẹ́ “àlìkámà” mọ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún títí di àkókò ìkórè. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn nímùúṣẹ lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì.—Mátíù 13:24-39.

Bí Iye Wa Ṣe Ń Pọ̀ Sí I Lónìí Lọ́nà Tó Yára Kánkán

4, 5. Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1919, iṣẹ́ wo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe, kí sì nìdí tí iṣẹ́ yẹn fi gba ìsapá gidigidi?

4 Ọdún 1919 ni àkókò tó láti ya ojúlówó Kristẹni tó jẹ́ àlìkámà sọ́tọ̀ kúrò lára èpò. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ ṣì ń bá a lọ ní pẹrẹu. Wọ́n gbà gbọ́ dáadáa pé àwọn ń gbé láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn,” wọ́n sì mọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (2 Tímótì 3:1; Mátíù 24:14) Dájúdájú, wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ ṣì pọ̀ láti ṣe.

5 Àmọ́, bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yin Jésù ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró náà ní iṣẹ́ bàǹtàbanta kan láti ṣe. Àwọn ẹni àmì òróró tó wà nígbà yẹn kò ju ẹgbẹ̀rún díẹ̀ lọ, tí wọ́n sì wà káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan. Báwo ni yóò ṣe wá ṣeé ṣe fún wọn láti wàásù ìhìn rere náà “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé”? Má gbàgbé pé gbogbo olùgbé ayé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ju ọ̀ọ́dúnrún [300] mílíọ̀nù lọ lákòókò Késárì ti pọ̀ tó nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní. Ó sì dájú pé jálẹ̀ ọ̀rúndún ogún, ńṣe níye èèyàn túbọ̀ pọ̀ sí i lọ́nà tó yára kánkán.

6. Báwo ni ìhìn rere náà ṣe tàn kálẹ̀ tó láwọn ọdún 1930?

6 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe bíi tàwọn arákùnrin wọn ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n fi ìgbàgbọ́ ńlá nínú Jèhófà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó wà níwájú wọn, ẹ̀mí rẹ̀ sì tì wọ́n lẹ́yìn. Nígbà tó fi máa di àárín àwọn ọdún 1930, àwọn oníwàásù tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56,000] ti polongo òtítọ́ Bíbélì ní ilẹ̀ márùndínlọ́gọ́fà [115]. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti gbìyànjú, síbẹ̀ iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún wọn láti ṣe.

7. (a) Iṣẹ́ ńlá tuntun wo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dojú kọ? (b) Pẹ̀lú ìtìlẹyìn àwọn “àgùntàn mìíràn,” báwo ni iṣẹ́ ìkójọ náà ti gbèrú tó lónìí?

7 Nígbà yẹn, òye tó túbọ̀ jinlẹ̀ sí i nípa dídá àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tá a sọ nínú Ìṣípayá 7:9 mọ̀ gbé iṣẹ́ ńlá tuntun kan lé àwọn Kristẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára lọ́wọ́, ó sì tún ṣèrànwọ́ fún wọn. Àìmọye àwọn onígbàgbọ́ tó jẹ́ “àgùntàn mìíràn” tí wọ́n ní ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé ni a gbọ́dọ̀ kó jọ “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Jòhánù 10:16) Àwọn wọ̀nyí yóò máa ‘ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà tọ̀sán-tòru.’ (Ìṣípayá 7:15) Ìyẹn túmọ̀ sí pé wọn yóò ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni. (Aísáyà 61:5) Látàrí èyí, inú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dùn láti rí iye àwọn oníwàásù tó ń pọ̀ sí i látorí ẹgbẹẹgbàárùn-ún dé orí ọ̀kẹ́ àìmọye. Ní ọdún 2003, àwọn akéde tí iye wọ́n jẹ́ 6,429,351 ló kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn wọ̀nyí ló sì jẹ́ ara àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá.a Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọrírì ìrànlọ́wọ́ yìí gan-an, àwọn àgùntàn mìíràn náà sì mọrírì àǹfààní tí wọ́n ní láti ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró.—Mátíù 25:34-40.

8. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nígbà tí wọ́n dojú kọ wàhálà tó lékenkà nígbà ogun àgbáyé kejì?

8 Nígbà táwọn ẹgbẹ́ àlìkámà tún fara hàn lẹ́ẹ̀kan sí i, Sátánì gbé ogun tó gbóná janjan dìde sí wọn. (Ìṣípayá 12:17) Kí ló ṣe nígbà táwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá bẹ̀rẹ̀ sí yọjú? Ńṣe ló bínú gidigidi! Ǹjẹ́ a lè sọ pé kì í ṣe òun ló wà lẹ́yìn àtakò tí wọ́n gbé dìde sí ìjọsìn tòótọ́ jákèjádò ayé nígbà ogun àgbáyé kejì? Ọ̀nà méjèèjì tí ìjà náà pín sí làwọn Kristẹni ti dojú kọ wàhálà tó lé kenkà. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n ló fojú winá àdánwò tó le koko, àwọn kan tiẹ̀ kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Síbẹ̀ wọ́n fara mọ́ ọ̀rọ̀ onísáàmù náà pé: “Ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ni èmi yóò máa yin ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; àyà kì yóò fò mí. Kí ni ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?” (Sáàmù 56:4; Mátíù 10:28) Ẹ̀mí Jèhófà fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn lókun, wọ́n sì di ìwà títọ́ wọn mú ṣinṣin. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ìyẹn ló mú kí, “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run [máa] bá a lọ ní gbígbilẹ̀.” (Ìṣe 6:7) Nígbà tí ogun bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1939, iye àwọn Kristẹni adúróṣinṣin tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìléláàádọ́rin, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti márùnléláàádọ́rin [72,475] ló ròyìn ipa tí wọ́n kó nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Wàyí o, ìròyìn tí kò pé tán tá a rí ní ọdún 1945 tí ogun parí fi hàn pé, ẹgbàá méjìdínlọ́gọ́rin, ọ̀ọ́dúnrún ó dín ẹyọ kan [156,299] àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣe déédéé ló ń wàásù ìhìn rere náà. Áà, ẹ ò rí i pé Sátánì ti pòfo!

9. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ tuntun wo la kéde pé a dá sílẹ̀ nígbà ogun àgbáyé kejì?

9 Ó ṣe kedere pé, wàhálà tó wà nígbà ogun àgbáyé kejì kò mú káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣiyèméjì pé iṣẹ́ ìwàásù náà kò lè kẹ́sẹ járí. Àní, ní ọdún 1943, nígbà tí ogun náà sì ń gbóná girigiri, ilé ẹ̀kọ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la dá sílẹ̀. A pe ọ̀kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, tí à ń ṣe nínú gbogbo ìjọ láti dá àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́kọ̀ọ́ lórí wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Èkejì ni ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead tá a dá sílẹ̀ láti máa dá àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè lọ máa wàásù láwọn ilẹ̀ òkèèrè. Nígbà tí ogun parí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ti wà ní sẹpẹ́ fún ìgbòkègbodò tó túbọ̀ pọ̀ sí i.

10. Báwo làwọn èèyàn Jèhófà ṣe fi ìtara wọn hàn lọ́dún 2003?

10 Ẹ wo iṣẹ́ bàǹtàbanta tí wọ́n ti ṣe! Nítorí pé a dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo ènìyàn, lọ́mọdé lágbà, òbí àtàwọn ọmọ, kódà àtàwọn aláìlera ló ti kópa, wọ́n sì tún ń bá a lọ láti máa kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ ńlá tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́ náà. (Sáàmù 148:12, 13; Jóẹ́lì 2:28, 29) Ní ọdún 2003, tí a bá pín in dọ́gba-dọ́gba lóṣooṣù, iye àwọn èèyàn tó jẹ́ 825,185 ló fi ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú wọn hàn nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà bóyá fún ìgbà díẹ̀ ni o tàbí títí lọ. Lọ́dún yẹn kan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo 1,234,796,477 wákàtí láti sọ fún àwọn mìíràn nípa ìhìn rere Ìjọba náà. Ó dájú pé inú Jèhófà dùn sí ìtara táwọn èèyàn rẹ̀ fi han yìí!

Ní Àwọn Ilẹ̀ Òkèèrè

11, 12. Àwọn àpẹẹrẹ tó dára wo ló fi iṣẹ́ àtàtà táwọn míṣọ́nnárì ń ṣe hàn?

11 Bí ọdún tí ń gorí ọdún, àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ni ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ṣe gudugudu méje, àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pẹ̀lú sì ń ṣe bákan náà. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè Brazil, àwọn akéde tó wà níbẹ̀ kò pé irinwó [400] nígbà táwọn míṣọ́nnárì kọ́kọ́ débẹ̀ ní ọdún 1945. Àwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyí àtàwọn tó tún dé lẹ́yìn wọn bá àwọn ará tó jẹ́ onítara ní Brazil ṣiṣẹ́ kára ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, Jèhófà sì bù kún ìsapá wọn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ẹ wo bí ìdùnnú yóò ti ṣubú lu ayọ̀ tó fáwọn tó bá lè rántí àkókò tí wọn kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè Brazil tí wọ́n wá rí i pé iye akéde 607,362 ló ròyìn ní ọdún 2003, èyí sì jẹ́ iye tó tíì pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ!

12 Ẹ jẹ́ ká gbé ìròyìn láti orílẹ̀-èdè Japan yẹ̀ wò. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kan àwọn oníwàásù Ìjọba náà ló wà lórílẹ̀-èdè yẹn ṣáájú ogun àgbáyé kejì. Lákòókò ogun yẹn, inúnibíni tó gbóná janjan mú kí iye wọn dín kù gan-an, tó fi jẹ́ pé nígbà tí ogun parí, àwọn Ẹlẹ́rìí díẹ̀ ló ṣẹ́ kù tó wà láàyè nípa tara àti nípa tẹ̀mí. (Òwe 14:32) Ó dájú pé inú àwọn èèyàn díẹ̀ tó pa ìwà títọ́ mọ́ lọ́nà tó tayọ yìí dùn gan-an ní 1949, nígbà tí wọ́n rí àwọn míṣọ́nnárì mẹ́tàlá tá a kọ́kọ́ rán wá lára àwọn tá a dá lẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, kíá sì làwọn míṣọ́nnárì náà fìfẹ́ hàn sáwọn ará wọn nílẹ̀ Japan tí wọ́n jẹ́ ọlọ́yàyà tí wọ́n sì lẹ́mìí aájò àlejò. Ní ohun ti ó ju àádọ́ta ọdún lẹ́yìn náà ìyẹn ní ọdún 2003, orílẹ̀-èdè Japan ròyìn iye akéde tó pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ tí iye rẹ̀ jẹ́ 217,508! Dájúdájú, Jèhófà ti bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ lórílẹ̀ èdè yẹn. A rí àwọn ìròyìn bí irú èyí gbà láti ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Àwọn tó wàásù nílẹ̀ òkèèrè ti kó ipa pàtàkì láti tàn ìhìn rere náà kálẹ̀ tó fi jẹ́ pé ní ọdún 2003, a wàásù ìhìn rere náà ní 235 ilẹ̀, àwọn erékùṣù àtàwọn agbègbè mìíràn kárí ayé. Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń jáde láti inú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”

“Láti Inú Gbogbo Àwọn . . . Ẹ̀yà àti Ènìyàn àti Ahọ́n”

13, 14. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi ìjẹ́pàtàkì wíwàásù ìhìn rere náà ní “gbogbo . . . ahọ́n” hàn?

13 Fífi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ níwájú àwọn èèyàn tó pé jọ ni iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tá a ròyìn lẹ́yìn ta a ti fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ó ṣeé ṣe káwọn tó wà níbẹ̀ gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, bóyá èdè Gíríìkì. Nítorí pé “àwọn ènìyàn tó ní ìfọkànsìn” ni wọ́n, ó ṣe é ṣe kí wọ́n lóye ìjọsìn tí wọ́n ń fi èdè Hébérù ṣe ní tẹ́ńpìlì. Ṣùgbọ́n ohun tó jẹ́ kí ìwàásù náà wọ̀ wọ́n lára gan-an ni gbígbọ́ tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere náà ní èdè àbínibí wọn.—Ìṣe 2:5, 7-12.

14 Lónìí pẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè la fi ń wàásù. Kì í ṣe látinú àwọn orílẹ̀-èdè nìkan la ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá yóò ti jáde wá, ṣùgbọ́n wọn yóò jáde wá látinú “ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” pẹ̀lú. Láti ti èyí lẹ́yìn, Jèhófà gbẹnu wòlíì Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sekaráyà 8:23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lẹ́bùn fífi èdè fọ̀ mọ́, a mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti kọ́ àwọn èèyàn ní èdè mímọ́ gaara.

15, 16. Báwo làwọn míṣọ́nnárì àtàwọn mìíràn ṣe tẹ́wọ́ gbà iṣẹ́ bàǹtàbanta láti wàásù ní èdè ibi tá a yàn wọ́n sí?

15 Ká sòótọ́ lónìí, èdè díẹ̀ ló gbajúmọ̀ táwọn èèyàn ń sọ, irú bí èdè Gẹ̀ẹ́sì, èdè Faransé àti èdè Spanish. Ṣùgbọ́n àwọn tó fi ìlú wọn sílẹ̀ láti sìn ní orílẹ̀-èdè mìíràn gbìyànjú láti kọ́ èdè tí wọ́n ń sọ ládùúgbò yẹn, kí wọ́n bàa lè mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn tó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìṣe 13:48) Ó lè má rọrùn láti ṣe ìyẹn o. Nígbà táwọn ará ní orílẹ̀-èdè Tuvalu tó wà ní Gúúsù Òkun Pàsífíìkì nílò àwọn ìwé lédè wọn, míṣọ́nnárì kan gbà láti ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yẹn. Níwọ̀n bí kò ti sí ìwé atúmọ̀ èdè èyíkéyìí lárọ̀ọ́wọ́tó, ó bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ọ̀rọ̀ Tuvalu jọ sínú ìwé kan. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí a fi tẹ ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Ayeb jáde ní èdè Tuvaluan. Nígbà táwọn míṣọ́nnárì dé ìlú Curaçao, kò sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kankan, kò sì sí ìwé atúmọ̀ èdè kankan lédè tí wọ́n ń sọ, ìyẹn èdè Papiamento. Kò tún sí ọ̀nà kan gbòógì tí wọ́n fẹnu kò sí láti máa gbà kọ èdè náà. Láìfi gbogbo ìṣòro wọ̀nyí pè, láàárín ọdún méjì sí ìgbà táwọn míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ yẹn dé, a tẹ ìwé ìléwọ́ àkọ́kọ́ tó jẹ́ ti Kristẹni tá a gbé karí Bíbélì lédè yẹn. Lónìí, èdè Papiamento wà lára àwọn èdè mẹ́tàléláàádóje [133] tá a fi ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jáde nígbà kan náà tí à ń tẹ ti èdè Gẹ̀ẹ́sì.

16 Ní orílẹ̀-èdè Nàmíbíà, àwọn míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ dé ibẹ̀ kò rí Ẹlẹ́rìí kankan tó jẹ́ ọmọ ìlú ibẹ̀ tó lè bá wọn túmọ̀ èdè. Ìyẹn nìkan kọ́ o, èdè Nama tí wọ́n ń sọ ládùúgbò yẹn kò ní ọ̀rọ̀ fún àwọn ọ̀rọ̀ tá a sábà máa ń lò nínú àwọn ìwé wa, irú bí “ìjẹ́pípé.” Míṣọ́nnárì kan sọ pé: “Àwọn olùkọ́ iléèwé tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni mó sábà máa ń lò tí mo bá fẹ́ ṣètumọ̀. Níwọ̀n bí wọn kò ti ní ìmọ̀ tó pọ̀ nípa òtítọ́, ńṣe ni mo máa ń jókòó tì wọ́n kí ń lè rí i dájú pé ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀ tọ̀nà.” Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tó yá, a túmọ̀ ìwé ìléwọ́ náà Igbesi-aye Ninu Aye Titun Alalaafia Kan si èdè mẹ́rin lára èdè tí wọ́n ń sọ ní Nàmíbíà. Lónìí, à ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jáde déédéé lédè Kwanyama àti èdè Ndonga.

17, 18. Ìsapá àrà ọ̀tọ̀ wo làwọn ará Mẹ́síkò àti orílẹ̀-èdè mìíràn ń sà?

17 Ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, èdè táwọn èèyàn ń sọ jù ni èdè Spanish. Ṣùgbọ́n káwọn ará Sípéènì tó wá síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èdè là ń sọ níbẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn èdè náà ṣì wà títí dòní olónìí. Nítorí náà, èdè méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó jẹ́ ti àwọn ará Mẹ́síkò la fi ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jáde báyìí, títí kan Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Mẹ́síkò. Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lédè Maya ló jẹ́ ìtẹ̀jáde olóṣooṣù àkọ́kọ́ tá a tẹ̀ lédè àwọn Íńdíà tó wà ní Amẹ́ríkà. Àní, a rí ẹgbẹ̀rún bíi mélòó kan àwọn Maya, Aztecs, àtàwọn mìíràn nínú àwọn 572,530 akéde Ìjọba tó wà ní Mẹ́síkò.

18 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti wá ibi ìsádi lọ sílẹ̀ òkèèrè tàbí kí wọ́n fi ìlú sílẹ̀ nítorí àtijẹ àtimu. Ní báyìí, fún ìgbà àkọ́kọ́ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí wá ní àwọn ìpínlẹ̀ díẹ̀ táwọn èèyàn ti ń sọ èdè orílẹ̀-èdè mìíràn. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè Ítálì, a ní àwọn ìjọ àti àwùjọ méjìlélógún tó ń sọ èdè mìíràn tó yàtọ̀ sí èdè tí wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè yẹn. Láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará kí wọ́n bàa lè wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè mìíràn, a ṣètò lẹ́nu àìpẹ́ yìí láti kọ́ àwọn ará ní èdè mẹ́rìndínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, títí kan Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Ítálì. Ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá lọ́nà kan náà láti wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń wá sí orílẹ̀-èdè wọn. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ló ń mú káwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá jáde wá látinú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè.

“Sí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé”

19, 20. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ wo ló ń ṣẹ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ lónìí? Ṣàlàyé.

19 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Wọn kò kùnà láti gbọ́, àbí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Họ́wù, ní ti tòótọ́, ‘ìró wọ́n jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, àsọjáde wọn sì jáde lọ sí àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.’” (Róòmù 10:18) Bí ìyẹn bá jẹ́ òtítọ́ ní ọ̀rúndún kìíní lọ́hùn-ún, òde òní gan-an ló rí bẹ́ẹ̀ jù lọ! Ju ti ìgbàkígbà rí lọ nínú ìtàn, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún Jèhófà ní gbogbo ìgbà; ìgbà gbogbo ni ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi.”—Sáàmù 34:1.

20 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìṣẹ́ yẹn kò falẹ̀ rárá. Ńṣe ni iye àwọn akéde Ìjọba náà túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò la sì ń lò nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Ọ̀kẹ́ àìmọye ìpadàbẹ̀wò là ń ṣe, a sì ń darí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹni titun ló sì bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn. Lọ́dún tó kọjá, a rí 16,097,622 tó jẹ́ iye èèyàn tó tíì pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ́ tó wá sí Ìṣe Ìrántí Ikú Jésù. Ó ṣe kedere pé iṣẹ́ ṣì pọ̀ láti ṣe. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa fara wé ìdúróṣinṣin àwọn ará wa tó ti fara da inúnibíni gbígbóná janjan. Kí a sì ní irú ìtara táwọn ará wa ní láti ọdún 1919 wá, ìyẹn àwọn tó ti lo ara wọn fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa fara mọ́ ègbè orin onísáàmù náà pé: “Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà. Ẹ yin Jáà!”—Sáàmù 150:6.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìròyìn ọdọọdún tó wà lójú ìwé 18 sí 21 nínú ìwé ìròyìn yìí.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń tẹ̀ ẹ́ jáde.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Iṣẹ́ wo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe láti ọdún 1919 wá, kí sì nìdí tí iṣẹ́ yẹn fi gba ìsapá gidigidi?

• Àwọn wo là ń kó jọ láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà?

• Iṣẹ́ àtàtà wo làwọn míṣọ́nnárì àtàwọn mìíràn tó ń sìn ní ilẹ̀ òkèèrè ti ṣe?

• Ẹ̀rí wo lo lè mẹ́nu kàn láti fi hàn pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lónìí?

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 18-21]

ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 2003 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ

(Wo àdìpọ̀)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]

Wàhálà tó wà nígbà ogun àgbáyé kejì kò mú káwọn Kristẹni ṣiyèméjì nípa wíwàásù ìhìn rere náà

[Credit Line]

Ìbúgbàù: U.S. Navy photo; Òmíràn: U.S. Coast Guard Photo

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Ogunlọ́gọ̀ ńlá yóò jáde wá látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́