ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 5/15 ojú ìwé 10-15
  • Àwọn Àgbàlagbà—Ẹni Ọ̀wọ́n Ni Wọ́n Nínú Ẹgbẹ́ Ará Kristẹni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Àgbàlagbà—Ẹni Ọ̀wọ́n Ni Wọ́n Nínú Ẹgbẹ́ Ará Kristẹni
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Gbígbèrú Nígbà   Orí Ewú’
  • “Wọn Yóò Máa Bá A Lọ Ní Sísanra àti Ní Jíjàyọ̀yọ̀”
  • “Sọ Pé Adúróṣánṣán Ni Jèhófà”
  • Jèhófà Mọyì Àwọn Àgbàlagbà Olóòótọ́
  • Jèhófà Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Àgbàlagbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àwọn Ìdílé Kristian Ń Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bíbójútó Àwọn Àgbàlagbà—Ojúṣe Àwọn Kristẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ohun Tó Ń Mú Kí Ọjọ́ Ogbó Jẹ́ “Adé Ẹwà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 5/15 ojú ìwé 10-15

Àwọn Àgbàlagbà—Ẹni Ọ̀wọ́n Ni Wọ́n Nínú Ẹgbẹ́ Ará Kristẹni

“Àwọn tí a gbìn sí ilé Jèhófà . . . yóò yọ ìtànná. Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú.”—SÁÀMÙ 92:13, 14.

1. Ojú wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo àwọn àgbàlagbà?

JÈHÓFÀ nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, títí kan àwọn tó jẹ́ àgbàlagbà. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fojú bù ú lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì mílíọ̀nù àwọn àgbàlagbà táwọn èèyàn ń ṣe níṣekúṣe tàbí tí wọ́n pa tì ní orílẹ̀-èdè náà. Irú ìròyìn kan náà kárí ayé fi hàn pé kò síbí kan lórí eèpẹ̀ tí ìṣòro ṣíṣe àgbàlagbà níṣekúṣe kò sí. Àjọ kan sọ pé ohun tó fa ìṣòro yìí ni “ìwà tó wọ́pọ̀ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn . . . pé àwọn àgbàlagbà ti lo èyí tó wúlò nínú ìgbésí ayé wọn, pé wọn ò mọ nǹkan ṣe dáadáa àti pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ni wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn máa bá àwọn ṣe.

2. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà? (b) Àpèjúwe tó mọ́kàn yọ̀ wo ló wà nínú Sáàmù 92:12-15?

2 Jèhófà Ọlọ́run mọyì àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà. Ó ń wo “ẹni tí àwa jẹ́ ní inú,” ìyẹn ipò wa nípa tẹ̀mí, kò wo ibi tí agbára wa nípa tara mọ. (2 Kọ́ríńtì 4:16) Nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a rí ìdánilójú yìí tó mọ́kàn wa yọ̀ pé: “Olódodo yóò yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pẹ [Hébérù, ta·marʹ, tó túmọ̀ sí ọ̀pẹ déètì]; gẹ́gẹ́ bí kédárì ní Lẹ́bánónì, òun yóò di ńlá. Àwọn tí a gbìn sí ilé Jèhófà, nínú àwọn àgbàlá Ọlọ́run wa, wọn yóò yọ ìtànná. Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú, wọn yóò máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjàyọ̀yọ̀, láti lè sọ pé adúróṣánṣán ni Jèhófà.” (Sáàmù 92:12-15) Ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ẹsẹ wọ̀nyí yóò fi ipa ribiribi tí ẹ̀yin tẹ́ ẹ jẹ́ àgbàlagbà lè kó nínú ẹ̀gbẹ́ ara Kristẹni hàn.

‘Gbígbèrú Nígbà   Orí Ewú’

3. (a) Kí nìdí tí a fi fàwọn olódodo wé ọ̀pẹ déètì? (b) Báwo làwọn àgbàlagbà ṣe lè máa “gbèrú nígbà orí ewú”?

3 Onísáàmù fi àwọn olódodo wé igi ọ̀pẹ, irú bí ọ̀pẹ déètì tí a ‘gbìn sí àwọn àgbàlá Ọlọ́run wa.’ “Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú.” Ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn sọ pé: “Wọn o ma so eso sibẹ ninu ogbó wọn.” (Bibeli Mimọ) Ǹjẹ́ o ò gbà pé ọ̀rọ̀ ìṣírí lèyí jẹ́? Àwọn ọ̀pẹ déètì tó wà lóòró tó sì lẹ́wà wọ́pọ̀ nínú àwọn àgbàlá ní Ìlà Oòrùn ayé lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Yàtọ̀ sí pé ọ̀pẹ déètì rẹwà, ó tún níye lórí gan-an nítorí pé ó máa ń so èso púpọ̀, àwọn ọ̀pẹ mìíràn sì máa ń so fún ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ.a Bí ẹ bá fìdí múlẹ̀ ṣinṣin nínú ìjọsìn tòótọ́, ẹ̀yin náà á lè máa “bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo.”— Kólósè 1:10.

4, 5. (a) Èso pàtàkì wo ló yẹ káwọn Kristẹni máa so? (b) Mẹ́nu kan àpẹẹrẹ àwọn àgbàlagbà nínú Ìwé Mímọ́ tó so “èso ètè.”

4 Jèhófà fẹ́ káwọn Kristẹni máa so “èso ètè,” ìyẹn ni pé kí wọ́n máa fi ìyìn fún un kí wọ́n sì máa polongo ète rẹ̀. (Hébérù 13:15) Gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà, ṣé ohun tí Bíbélì sọ yìí kàn ọ́? Dájúdájú, ó kàn ọ́.

5 Àpẹẹrẹ àwọn àgbàlagbà tó fi àìṣojo jẹ́rìí orúkọ Jèhófà àti ète rẹ̀ wà nínú Bíbélì. Mósè ti lé lẹ́ni “àádọ́rin ọdún” nígbà tí Jèhófà sọ ọ́ di wòlíì àti aṣojú rẹ̀. (Sáàmù 90:10; Ẹ́kísódù 4:10-17) Ọjọ́ ogbó kò dí wòlíì Dáníẹ́lì lọ́wọ́ láti fi àìṣojo jẹ́rìí nípa ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Ó ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún nígbà tí Bẹliṣásárì ní kó wá sọ ìtumọ̀ ìkọ̀wé àràmàǹdà kan tó hàn lára ògiri. (Dáníẹ́lì orí karùn-ún) Àpọ́sítélì Jòhánù tóun náà jẹ́ àgbàlagbà ńkọ́? Lápá ìparí iṣẹ́ ìsìn gígùn rẹ̀ ló bá ara rẹ̀ lẹ́wọ̀n ní erékùṣù kékeré Pátímọ́sì “nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 1:9) Ó ṣeé ṣe kó o sì rántí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn nínú Bíbélì tó so “èso ètè” nígbà orí ewú wọn.—1 Sámúẹ́lì 8:1, 10; 12:2; 1 Àwọn Ọba 14:4, 5; Lúùkù 1:7, 67-79; 2:22-32.

6. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àwọn “àgbà ọkùnrin” láti sọ tẹ́lẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

6 Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ọ̀rọ̀ wòlíì Hébérù náà Jóẹ́lì, ó sọ pé: “‘Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,’ ni Ọlọ́run wí, ‘èmi yóò sì tú lára ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara [àtàwọn “àgbà ọkùnrin”], . . . wọn yóò sì sọ tẹ́lẹ̀.’” (Ìṣe 2:17, 18; Jóẹ́lì 2:28) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Jèhófà ti lo àwọn àgbàlagbà tó wà lára àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” láti polongo ìfẹ́ Ọlọ́run. (Jòhánù 10:16) Ó ti pẹ́ gan-an táwọn kan lára wọn tí ń fi ìṣòtítọ́ so èso Ìjọba náà bọ̀.

7. Ṣàlàyé báwọn àgbàlagbà ṣe ń so èso Ìjọba náà láìfi àìlera pè.

7 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ obìnrin kan tó ń jẹ́ Sonia tó di akéde Ìjọba náà ní àkókò kíkún ní ọdún 1941. Láìfi àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tó ń bá a fínra pè, ó máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nínú ilé rẹ̀. Sonia sọ pé: “Wíwàásù ìhìn rere náà ti di ẹ̀jẹ̀ mi. Àní, ó ti mọ́ mi lára. Mi ò lè ṣe kí n má wàásù.” Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, níbi tí Sonia àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tó ń jẹ́ Olive ti ń dúró de dókítà ní ọsibítù, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ ìrètí tó wà nínú Bíbélì fún Janet, ẹni tí àìsàn tí kò gbóògùn ń ṣe. Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí Janet wú màmá Janet tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì paraku lórí débi pé ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ó sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè lo irú àǹfààní yẹn láti so èso Ìjọba náà?

8. Báwo ni Kálébù àgbàlagbà ṣe fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, báwo làwọn àgbàlagbà Kristẹni ṣe lè ṣe bíi tiẹ̀?

8 Nípa fífi ìgboyà tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà láìfi àìlera tó ń bá ọjọ́ ogbó rìn pè, àwọn Kristẹni àgbàlagbà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ adúróṣinṣin ọmọ Ísírẹ́lì tó ń jẹ́ Kálébù, ẹni tó bá Mósè rìn fún odindi ogójì ọdún nígbà tí wọ́n wà láginjù. Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin ni Kálébù nígbà tó sọdá Odò Jọ́dánì sí Ilẹ̀ Ìlérí. Lẹ́yìn tó ti fi ọdún mẹ́fà ja àjàṣẹ́gun gẹ́gẹ́ bí sójà fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì, ì bá ti jókòó ti àṣeyọrí rẹ̀ yẹn. Ṣùgbọ́n kò ṣe bẹ́ẹ̀ o, ńṣe ló fìgboyà béèrè fún iṣẹ́ takuntakun ti gbígba “àwọn ìlú ńlá títóbi tí í ṣe olódi” tó wà ní àgbègbè olókè ńlá ti Júdà, ìyẹn ibi táwọn ọkùnrin Ánákímù tó jẹ́ òmìrán ń gbé. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, Kálébù “lé wọn kúrò, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ṣèlérí.” (Jóṣúà 14:9-14; 15:13, 14) Bí ẹ ṣe ń farúgbó ara so èso Ìjọba náà, ẹ ní ìdánilójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú yín gẹ́gẹ́ bó ṣe wà pẹ̀lú Kálébù. Bí ẹ bá sì ń bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà yóò jẹ́ kẹ́ ẹ wọnú ayé tuntun tó ṣèlérí.—Aísáyà 40:29-31; 2 Pétérù 3:13.

“Wọn Yóò Máa Bá A Lọ Ní Sísanra àti Ní Jíjàyọ̀yọ̀”

9, 10. Báwo ni ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni àgbàlagbà ṣe lè lágbára kí wọ́n sì máa bá a lọ láti ní okun nípa tẹ̀mí? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 13.)

9 Nígbà tí onísáàmù ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ àgbàlagbà ṣe wúlò tó, ó kọ̀ ọ́ lórin pé: “Olódodo yóò yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pẹ; gẹ́gẹ́ bí kédárì ní Lẹ́bánónì, òun yóò di ńlá. Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú, wọn yóò máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjàyọ̀yọ̀.”—Sáàmù 92:12, 14.

10 Báwo lẹ ṣe lè máa bá a lọ láti jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara ti ń dara àgbà? Olórí ohun tó lè mú kí ẹwà ọ̀pẹ déètì máa wà fún àkókó pípẹ́ ni pé àtòjò àtẹ̀ẹ̀rùn, kó máa rí omi déédéé. Bákan náà, ẹ̀yin náà lè rí okun látinú omi òtítọ́ Bíbélì nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ẹ sì wà nínú ètò rẹ̀. (Sáàmù 1:1-3; Jeremáyà 17:7, 8) Okun tẹ̀mí tẹ́ ẹ ní ló mú kí ẹ ṣeyebíye lójú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiyín. Gbé àpẹẹrẹ Àlùfáà Àgbà Jèhóádà yẹ̀ wò, ẹni tó tún jẹ́ àgbàlagbà.

11, 12. (a) Ipa pàtàkì wo ni Jèhóádà kó nínú ìtàn ìjọba Júdà? (b) Báwo ni Jèhóádà ṣe lo ipò rẹ̀ láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ?

11 Ó ṣeé ṣe kí Jèhóádà ti lé lẹ́ni ọgọ́rùn-ún ọdún nígbà tí Ataláyà Ayaba tí ń kánjú láti dé ipò ńlá gbàjọba Júdà nípa gbígbẹ̀mí àwọn ọmọ ọmọ tirẹ̀ fúnra rẹ̀. Kí ni Jèhóádà tó jẹ́ àgbàlagbà ṣe? Odindi ọdún mẹ́fà lòun àti ìyàwó rẹ̀ fi gbé Jèhóáṣì tó jẹ́ àrẹ̀mọ ọba kan ṣoṣo tó kù pa mọ́ sínú tẹ́ńpìlì. Ọ̀nà tó pabanbarì ni Jèhóádà fi kéde Jèhóáṣì ọmọ ọdún méje gẹ́gẹ́ bí ọba tó sì sọ pé kí wọ́n pa Ataláyà.—2 Kíróníkà 22:10-12; 23:1-3, 15, 21.

12 Jèhóádà lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣètọ́jú ọba láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Ó “dá májẹ̀mú kan láàárín òun fúnra rẹ̀ àti gbogbo àwọn ènìyàn náà àti ọba pé wọn yóò máa wà nìṣó gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Jèhófà.” Jèhóádà pàṣẹ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n bi ilé Báálì àtàwọn pẹpẹ rẹ̀ wó, kí wọ́n fọ́ àwọn ère rẹ̀ túútúú, kí wọ́n sì pa àwọn àlùfáà rẹ̀. Abẹ́ àbójútó Jèhóádà ni Jèhóáṣì ti dá iṣẹ́ ìsìn ní tẹ́ńpìlì padà tó sì tún àwọn ibi tó yẹ níbẹ̀ ṣe. “Jèhóáṣì sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ tirẹ̀ tí Jèhóádà àlùfáà fi fún un ní ìtọ́ni.” (2 Kíróníkà 23:11, 16-19; 24:11-14; 2 Àwọn Ọba 12:2) Nígbà tí Jèhóádà kú ní ẹni àádóje ọdún, wọ́n bọlá fún un lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ti pé wọ́n sin ín síbi tí wọ́n máa ń sin àwọn ọba sí, “nítorí pé ó ti ṣe rere ní Ísírẹ́lì àti sí Ọlọ́run tòótọ́ àti ilé Rẹ̀.”—2 Kíróníkà 24:15, 16.

13. Báwo làwọn Kristẹni àgbàlagbà ṣe lè máa ‘ṣe rere sí Ọlọ́run tòótọ́ àti ilé rẹ̀’?

13 Bóyá àìlera tàbí àwọn ipò mìíràn kò jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́ láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Ká tiẹ̀ wá ní bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, o ṣì lè ‘ṣe rere sí Ọlọ́run tòótọ́ àti ilé rẹ̀.’ O lè fi hàn pé ó ní ìtara fún ilé tẹ̀mí Jèhófà nípa wíwá sí ìpàdé ìjọ kí o sì máa kópa nínú wọn àti nípa ṣíṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe. Bó o ṣe múra tán láti gba ìmọ̀ràn Bíbélì tó o sì jẹ́ àdúróṣinṣin sí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àti sí ìjọ, yóò máa fún ẹgbẹ́ ara Kristẹni lápapọ̀ lókun. (Mátíù 24:45-47) O tún lè ru àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ sókè sí “ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Hébérù 10:24, 25; Fílémónì 8, 9) Wàá sì tún ṣe àwọn mìíràn láǹfààní bí o bá ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà yín nímọ̀ràn pé: “Kí àwọn àgbàlagbà ọkùnrin jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà, oníwà-àgbà, ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, onílera nínú ìgbàgbọ́, nínú ìfẹ́, nínú ìfaradà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kí àwọn àgbàlagbà obìnrin jẹ́ onífọkànsìn nínú ìhùwàsí, kì í ṣe afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe di ẹrú fún ọ̀pọ̀ wáìnì, kí wọ́n jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere.”—Títù 2:2-4.

14. Kí làwọn Kristẹni tó ti ń ṣe alábòójútó fún ọjọ́ pípẹ́ lè ṣe láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ?

14 Ǹjẹ́ o ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ fún ọ̀pọ̀ ọdún? Ìmọ̀ràn tí alàgbà kan tó ti ń sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún fúnni ni pé: “Lo ọgbọ́n tó o ti fi ọ̀pọ̀ ọdún kó jọ lọ́nà tí kò fi ìmọtara-ẹni nìkan hàn. Gbéṣẹ́ lé àwọn mìíràn lọ́wọ́, kọ́ àwọn mìíràn tó ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ ní ohun tó o mọ̀ . . . Fòye mọ ohun táwọn mìíràn lè ṣe. Ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe dáadáa sí i. Pọnmi sílẹ̀ dòùngbẹ.” (Diutarónómì 3:27, 28) Ìfẹ́ tòótọ́ tó o ní sí iṣẹ́ Ìjọba tó ń tẹ̀ síwájú yìí yóò mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún àwọn mìíràn nínú ẹgbẹ́ ará Kristẹni wa.

“Sọ Pé Adúróṣánṣán Ni Jèhófà”

15. Báwo làwọn Kristẹni àgbàlagbà ṣe ń “sọ pé adúróṣánṣán ni Jèhófà”?

15 Tayọ̀tayọ̀ làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ àgbàlagbà fi ń ṣe ojúṣe wọn láti máa “sọ pé adúróṣánṣán ni Jèhófà.” Tó bá jẹ́ pé Kristẹni àgbàlagbà ni ọ́, ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ lè fi han àwọn ẹlòmíràn pé, ‘Jèhófà ni Àpáta rẹ, ẹni tí kò sí àìṣòdodo kankan lọ́dọ̀ rẹ̀.’ (Sáàmù 92:15) Bí ọ̀pẹ kò tilẹ̀ fọhùn, síbẹ̀ ó ń jẹ́rìí sí àwọn ànímọ́ títayọ tí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ní. Ṣùgbọ́n Jèhófà ti fún ọ láǹfààní láti máa jẹ́rìí òun fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rí ìsìn tòótọ́. (Diutarónómì 32:7; Sáàmù 71:17, 18; Jóẹ́lì 1:2, 3) Kí nìdí tí ìjẹ́rìí yìí fi ṣe pàtàkì?

16. Àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló fi bó ṣe ṣe pàtàkì tó hàn láti máa “sọ pé adúróṣánṣán ni Jèhófà”?

16 Nígbà ti Jóṣúà tó jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “darúgbó, tí ó sì pọ̀ ní ọjọ́”, ó “bẹ̀rẹ̀ sí pe gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn àgbà ọkùnrin rẹ̀ àti àwọn olórí rẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ rẹ̀ àti àwọn onípò àṣẹ láàárín rẹ̀,” ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rán wọn létí bí Jèhófà ṣe jẹ́ adúróṣánṣán. Ó sọ pé: “Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín.” (Jóṣúà 23:1, 2, 14) Fún ìgbà díẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mú kí ìpinnu àwọn èèyàn náà láti jẹ́ olóòótọ́ túbọ̀ lágbára sí i. Bó ti wù kó rí, lẹ́yìn tí Jóṣúà kú, “ìran mìíràn sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde . . . , tí kò mọ Jèhófà tàbí iṣẹ́ tí ó ti ṣe fún Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣubú sínú ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, wọ́n sì ń sin àwọn Báálì.”—Àwọn Onídàájọ́ 2:8-11.

17. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò lóde òní?

17 Ìwà títọ́ ìjọ Kristẹni lónìí kò sinmi lé ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn àgbàlagbà ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Síbẹ̀, bá a bá gbọ́ ọ̀rọ̀ látẹnu àwọn àgbàlagbà nípa “iṣẹ́ ńlá” tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, á mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà àtàwọn ohun tó ṣèlérí túbọ̀ lágbára sí i. (Àwọn Onídàájọ́ 2:7; 2 Pétérù 1:16-19) Ká sọ pé o ti ń dara pọ̀ mọ́ ètò àjọ Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó ṣeé ṣe kó o rántí ìgbà tó jẹ́ pé àwọn díẹ̀ ló ń pòkìkí Ìjọba náà ládùúgbò rẹ tàbí lórílẹ̀-èdè rẹ, ó sì ṣeé ṣe kó o rántí ìgbà táwọn èèyàn ta ko iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe gan-an. Bí àkókò ṣe ń lọ, o ti rí i bí Jèhófà ṣe mú àwọn ohun ìdènà kúrò tó sí mú kí iye àwọn akéde pọ̀ sí i lọ́nà tó “yára kánkán.” (Aísáyà 54:17; 60:22) O ti kíyè sí i bí àwọn òtítọ́ Bíbélì ṣe túbọ̀ yéni sí i, o sì ti rí i bí àwọn nǹkan ṣe ń sunwọ̀n sí i nínú ètò àjọ Ọlọ́run tá a lè fojú rí. (Òwe 4:18; Aísáyà 60:17) Ǹjẹ́ o máa ń wá ọ̀nà láti fún àwọn mìíràn níṣìírí nípa sísọ àwọn ìrírí rẹ fún wọn nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ adúróṣánṣán? Èyí á mà fún ẹgbẹ́ ará Kristẹni wa lókun gan-an o!

18. (a) Ṣàlàyé bí sísọ “pé adúróṣánṣán ni Jèhófà” ṣe lè ní ipa tó wà pẹ́ títí lórí àwọn ẹlòmíràn. (b) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ adúróṣánṣán sí ọ?

18 Àwọn ìgbà tó o ti rí i bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó sì bójú tó ẹ nígbèésí ayé rẹ ńkọ́? (Sáàmù 37:25; Mátíù 6:33; 1 Pétérù 5:7) Arábìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Martha máa ń fún àwọn èèyàn níṣìírí pé: “Gbogbo ohun tó wù kó ṣẹlẹ̀, má ṣe fi Jèhófà sílẹ̀. Yóò mẹ́sẹ̀ rẹ dúró.” Ìmọ̀ràn yìí ṣiṣẹ́ gan-an fún obìnrin kan tó ń jẹ́ Tolmina, ọ̀kan lára àwọn tí Martha ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣèrìbọmi ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960. Tolmina sọ pé: “Ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi nígbà tí ọkọ mi kú, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ló mú kí n pinnu láti má ṣe pa ìpàdé kankan jẹ. Lóòótọ́, Jèhófà fún mi lókun láti máa bá a lọ.” Tolmina náà ti fún àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní irú ìmọ̀ràn kan náà láti ọ̀pọ̀ ọdún wá. Láìsí àní-àní, bí ẹ bá ń fún àwọn èèyàn níṣìírí tí ẹ sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà jẹ́ adúróṣánṣán, ipa kékeré kọ́ nìyẹn máa kó láti mú kí ìgbàgbọ́ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiyín túbọ̀ lágbára sí i.

Jèhófà Mọyì Àwọn Àgbàlagbà Olóòótọ́

19, 20. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìgbòkègbodò àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ àgbàlagbà? (b) Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

19 Nínú ayé lónìí táwọn èèyàn jẹ́ abaraámóorejẹ, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ gba tàwọn àgbàlagbà rò mọ́. (2 Tímótì 3:1, 2) Nígbà tí wọ́n bá sì sọ pé àwọn rántí wọn gan-an, ó sábà máa ń jẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ti gbé ṣe sẹ́yìn, ìyẹn ohun tí wọ́n jẹ́ nígbà kan, kì í ṣe ohun tí wọ́n jẹ́ nísinsìnyí. Bíbélì sọ ohun tó yàtọ̀ sí ìyẹn pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.” (Hébérù 6:10) Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run kò gbàgbé àwọn iṣẹ́ òdodo tí ẹ ti ṣe sẹ́yìn. Ó sì tún mọyì yín látàrí ohun tí ẹ ń bá a lọ ní ṣíṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ń wo àwọn àgbàlagbà olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó wúlò, tó lera nípa tẹ̀mí tó sì tún jẹ́ Kristẹni alágbára, àní ìgbésí ayé wọn jẹ́ ẹ̀rí pé lóòótọ́ ni Jèhófà jẹ́ alágbára.—Fílípì 4:13.

20 Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ẹgbẹ́ ará Kristẹni ni ìwọ náà fi ń wò wọ́n? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wàá fẹ́ fi ìfẹ́ hàn sí wọn. (1 Jòhánù 3:18) Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn bá a ṣe ń bójú tó wọn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èso tí ó wà lára òṣùṣù déètì kan lè tó ẹgbẹ̀rún kan, ó sì lè wọ̀n tó kìlógíráàmù mẹ́jọ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Òǹkọ̀wé kan fojú bù ú pé “[ọ̀pẹ] déètì kan lè so tó èso tọ́ọ̀nù méjì tàbí mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí àsanpadà fún ẹni tó gbìn ín kí ọ̀pẹ náà tó kú.”

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

• Báwo làwọn àgbàlagbà ṣe ń “so èso”?

• Kí nìdí tí okun tẹ̀mí táwọn Kristẹni àgbàlagbà ní fi jẹ́ ohun tó ṣeyebíye?

• Ọ̀nà wo làwọn àgbàlagbà lè máa gbà “sọ pé adúróṣánṣán ni Jèhófà”?

• Kí nìdí tí Jèhófà fi mọyì àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti ń sìn ín fún àkókò pípẹ́?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

Ohun Tó Mú Kí Ìgbàgbọ́ Wọn Ṣì Lágbára

Kí ló ti ran àwọn tó ti di Kristẹni tipẹ́tipẹ́ lọ́wọ́ láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn ṣì lágbára, kó sì lókun nípa tẹ̀mí? Ohun tí àwọn kan lára wọn sọ rèé:

“Kíka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó dá lórí àjọṣe tó wà láàárín àwa àti Jèhófà ṣe pàtàkì. Alẹ́ tó pọ̀ jù lọ ni mo máa ń ka Sáàmù 23 àti 91 látorí.”—Olive, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1930.

“Mo máa ń rí i dájú pé mò wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ ìrìbọmi, mò sì máa ń tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ bíi pé èmi ni mo fẹ́ ṣèrìbọmi. Fífi ìyàsímímọ́ mi sọ́kàn nígbà gbogbo ni ohun pàtàkì tó ti ṣèrànwọ́ fún mi láti jẹ́ olóòótọ́.”—Harry, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1946.

“Àdúrà gbígbà lójoojúmọ́ ṣe pàtàkì, ká máa bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ààbò rẹ̀, àti ìbùkún rẹ̀, ká sì máa ‘ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà wa.’” (Òwe 3:5, 6)—Antônio, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1951.

“Gbígbọ́ ìrírí àwọn tó ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún máa ń sọ ìpinnu mi láti jẹ́ adúróṣinṣin kí n sì jẹ́ olóòótọ́ sí i dọ̀tun.”—Joan, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1954.

“Ó ṣe pàtàkì kéèyàn má ṣe ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run la fi ní ohun tá a ní. Ríronú lọ́nà yìí yóò jẹ́ ká lè máa wo ibi tó yẹ ká wò fún oúnjẹ tẹ̀mí tá a nílò láti lè fara dà á títí dópin.”—Arlene, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1954.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwọn àgbàlagbà ń so èso Ìjọba náà tó níye lórí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ohun tó ṣeyebíye ni okun tẹ̀mí táwọn àgbàlagbà ní

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́