Ìtàn Ìgbésí Ayé
Mo Jáde Látinú Àjàalẹ̀ Tó Sókùnkùn Lọ Sí Àgbègbè Olókè ní Switzerland
GẸ́GẸ́ BÍ LOTHAR WALTHER ṢE SỌ Ọ́
Lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún mẹ́ta gbáko ní àjàalẹ̀ tó ṣókùnkùn ní Ìlà Oòrùn Jámánì tí Ìjọba Kọ́múníìsì ń ṣàkóso, wọ́n dá mi sílẹ̀, mo sì ń hára gàgà látí lọ gbádùn òmìnira tí wọ́n fún mi, kí èmi àti ìdílé mi jọ máa ṣeré.
ÀMỌ́, mi ò mọ̀ pé ńṣe ni ọmọkùnrin mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johannes tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́fà máa fajú ro nígbà tó bá rí mi. Ọdún yẹn gan-an ló pé ọdún mẹ́tà tó ti rí mi kẹ́yìn. Àlejò pàtápàtá ló rò pé mo jẹ́.
Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ àwọn òbí mi, kò rí bí ti ọmọkùnrin mi yìí. Àjọṣe tó wà láàárín wa dára gan-an nílé wa ní ìlú Chemnitz, ní orílẹ̀-èdè Jámánì níbi tí wọ́n ti bí mi lọ́dún 1928. Bàbá mi jẹ́ ẹnì kan tó máa ń sọ ohunkóhun tí kò bá ti tẹ́ ẹ lọ́rùn nípa ìsìn. Ó rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ó sọ pé àwọn sójà tó jẹ́ “Kristẹni” tí wọ́n ń gbé lágbègbè méjì tó dójú kọra máa ń kí ara wọn “Ẹ kú ọdún, ẹ kú ìyèdún” ní December 25 àmọ́ tó bá dọjọ́ kejì wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí para wọn. Lójú bàbá mi, ìsìn ló ń ṣe àgàbàgebè jù lọ láyé yìí.
Ìgbàgbọ́ Rọ́pò Ìbànújẹ́
Mo dúpẹ́ pé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ò ṣẹlẹ̀ lójú mi. Ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún ni mí nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, díẹ̀ ló kù wọn ì bá fà mi wọṣẹ́ sójà nígbà yẹn. Síbẹ̀, ó máa ń ká mi lára nígbà tí mo bá ronú nípa àwọn ìbéèrè bíi, ‘Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń gbẹ̀mí ara wọn bẹ́ẹ̀ yẹn? Ta ni mo lè gbẹ́kẹ̀ lé? Ibo ni mo ti lè rí ààbò tòótọ́?’ Ìlà Oòrùn Jámánì là ń gbé nígbà yẹn, Ìjọba Soviet ló sì ń ṣàkóso rẹ̀. Àwọn tí ogun hàn léèmọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìlànà tí Ìjọba Kọ́múníìsì gbé kalẹ̀, ìyẹn ìlànà ìdájọ́ òdodo, ìlànà ẹ̀dá kan ò ga jùkan lọ, ẹ̀mí ìfìmọ̀ṣọ̀kan àti ti àlàáfíà. Kò pẹ́ tí gbogbo nǹkan fi tojú sú ọ̀pọ̀ lára àwọn olóòótọ́ èèyàn wọ̀nyí, òṣèlú ló sì fà á kì í ṣe ìsìn.
Ìgbà tí mò ń gbìyànjú láti wá ìdáhùn tó nítumọ̀ sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn ni ẹ̀gbọ́n ìyá mi obìnrin tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ àwọn ohun tó gbà gbọ́ fún mi. Ó fún mi ní ìwé kan tá a gbé karí Bíbélì, ìwé náà ló mú kí n ka orí kẹrìnlélógún nínú ìwé Mátíù látòkèdélẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́. Àlàyé tó mọ́gbọ́n dání tó sì ṣe kedere tí ìwé náà ṣe wú mi lórí gan-an, ìwé náà sì fi hàn pé àkókò tá à ń gbé yìí jẹ́ “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó tún sọ ohun tó fa ìṣòro aráyé.—Mátíù 24:3; Ìṣípayá 12:9.
Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo rí ọ̀pọ̀ ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà, bí mo sì ṣe ń ka àwọn ìwé náà, ọkàn mi sọ fún mi pé mo ti rí òtítọ́ tí mo ti ń wá kiri lójú méjèèjì. Ó jẹ́ ayọ̀ ńlá láti mọ̀ pé a ti gbé Jésù Kristi gorí ìtẹ́ ní ọ̀run lọ́dún 1914 àti pé kò ní pẹ́ ṣẹ́gun gbogbo àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kí ó bàa lè bù kún àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn. Àwárí ńlá ló jẹ́ fún mi nígbà tí òye ohun tí ẹbọ ìràpadà jẹ́ wá yé mi yékéyéké. Ó mú kí n gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà Ọlọ́run láti tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Ìkésíni tó wà nínú Jákọ́bù 4:8 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni, ó sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”
Láìka bí ayọ̀ mi ṣe pọ̀ tó sí nítorí ẹ̀sìn tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí, àwọn òbí mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ò kọ́kọ́ tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ tí mò ń bá wọn sọ. Àmọ́, èyí ò paná ìfẹ́ tí mo ní láti máa lọ sípàdé Kristẹni tí àwùjọ kékeré ti àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe nítòsí ìlú Chemnitz. Ohun kan tó wá yà mí lẹ́nu ni pé àwọn òbí mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin bá mi lọ́ sí ìpàdé àkọ́kọ́ tí mo lọ! Ìgbà òtútù ní ọdún 1945 sí 1956 lohun tí mò ń sọ yìí ṣẹlẹ̀. Nígbà tó yá, tá a fìdí àwùjọ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan múlẹ̀ níbi tá à ń gbé ní ìlú Harthau, bàbá àti ìyá mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ déédéé.
“Ọmọdé Lásán Ni Mí”
Àwọn òtítọ́ pàtàkì nípa Bíbélì tí mo kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àti bíbá àwọn èèyàn Jèhófà kẹ́gbẹ́ déédéé ló sún mi láti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣe ìrìbọmi ní May 25, 1946. Inú mi dùn gan-an nígbà tí bàbá àti ìyà mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, nígbà tó sì yá àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta di Ẹlẹ́rìí olóòótọ́. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ṣì ń ṣe déédéé nínú ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó wà ní Chemnitz títí di ìsinsìnyí. Màmá mi fi ìṣòtítọ́ sìn títí tó fi kú lọ́dún 1965, bàbá mi náà fi ìṣòtítọ́ sìn títí dọjọ́ ikú rẹ̀ lọ́dún 1986.
Ní oṣù kẹfà lẹ́yìn tí mo ṣe ìrìbọmi, mo bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Báyìí ni mo ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn tí màá fi gbogbo ọjọ́ ayé mi ṣe “ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.” (2 Tímótì 4:2) Láìpẹ́ sígbà yẹn, àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú. Wọ́n ń wá àwọn ajíhìnrere alákòókò-kíkún tí yóò lọ máa wàásù ní àgbègbè kan tó jìnnà ní ìlà oòrùn Jámánì. Èmi àti arákùnrin kan kọ̀wé béèrè pé kí wọ́n rán wa lọ síbẹ̀, àmọ́ mo rò pé mi ò nírìírí tó, mi ò sì tíì dàgbà tó fún irú iṣẹ́ bàǹtàbanta yẹn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹni ọdún méjìdínlógún ni mí nígbà yẹn, èrò tí mo ní dà bí ti Jeremáyà tó sọ pé: “Págà, Jèhófà . . . ! Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.” (Jeremáyà 1:6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ń bà mí díẹ̀díẹ̀, àwọn arákùnrin tó ń mú ipò iwájú yàn wá sí iṣẹ́ náà pé ká lọ gbìyànjú rẹ̀ wò. Nítorí náà, wọ́n yàn wá sí Belzig, ìyẹn ìlú kékeré kan ní ìpínlẹ̀ Brandenburg.
Kò rọrùn rárá láti wàásù ní ìpínlẹ̀ yìí, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye la rí kọ́ níbẹ̀. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn gbajúgbajà obìnrin nídìí okòwò tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ Ìjọba náà, wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ kò bá àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó ti wà tipẹ́ ní abúlé yẹn mu, àwọn ará ibẹ̀ sì tún máa ń fura sí ohunkóhun tó bá ti jẹ́ tuntun. Àwọn àlùfáà Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì ta kò wá délẹ̀délẹ̀, wọ́n tún fẹ̀sùn irọ́ kàn wá lórí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Àmọ́, nítorí pé Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé fún ìtọ́sọ́nà àti ààbò, ó ṣeé ṣe fún wa láti ran àwọn bíi mélòó kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì lọ́wọ́ láti rí òtítọ́.
Ẹ̀tanú Ìsìn Túbọ̀ Ń Lágbára Sí I
Ọdún 1948 jẹ́ ọdún ti mo rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà, tí mo sì tún bá ìṣòro tí mi ò ronú kàn pàdé. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n yàn mí síṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní Rudolstadt, ní ìpínlẹ̀ Thuringia. Ibẹ̀ ni mo ti mọ ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin olóòótọ́, mo sì gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ wọn. Ìbùkún mìíràn tún dé ní July ọdún yẹn kan náà. Mo fẹ́ ọ̀dọ́ Kristẹni obìnrin kan tó ń jẹ́ Erika Ullmann, ó jẹ́ olóòótọ́ ó sì nítara, látìgbà tí mo ti ń lọ sípàdé ní Ìjọ Chemnitz ni mo ti mọ̀ ọ́n. A jọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní Harthau, ìlú mi. Àmọ́ bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, Erika ò lè máa bá a lọ nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún mọ́ nítorí àìlera àti nítorí àwọn ìdí mìíràn.
Nǹkan ṣòro gan-an fáwọn èèyàn Jèhófà lákòókò yẹn. Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìjọba tó wà nílùú Chemnitz fagi lé káàdì tí mo fi ń ra oúnjẹ ní ẹ̀dínwó nítorí kí n lè fi iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe sílẹ̀ kí n lè lọ máa ṣiṣẹ́ owó. Ọ̀ràn mi ló mú káwọn arákùnrin tó ń mú ipò iwájú lọ sọ fún Ìjọba pé kí wọ́n fọwọ́ sí iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin. Ìjọba ò fọwọ́ sí i, àti pé ní June 23, 1950 wọ́n ní kí n wá san owó kan tàbí kí n fi ẹ̀wọ̀n ọgbọ̀n ọjọ́ gbára. A pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àmọ́ ilé ẹjọ́ gíga gbá ẹjọ́ náà dànù, wọ́n sì fi mí sẹ́wọ̀n.
Kékeré nìyẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ àtakò àti ìpọ́njú tí máà ṣì bá pàdé. Ní September 1950, ìyẹn lẹ́yìn nǹkan bí oṣù kan tí ìjọba Kọ́múníìsì gbé ọ̀rọ̀ kan jáde ní ilé iṣẹ́ ìròyìn láti fi bà wá lórúkọ jẹ́, wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. Nítorí pé à ń yára gbèrú tí a ò sì dá sí ọ̀ràn ìlú, wọ́n sọ pé amí eléwu tó ti ìwọ̀ oòrùn ayé wá la jẹ́, pé ńṣe là ń fi ẹ̀sìn bojú láti máa ṣe “iṣẹ́ ibi.” Lọ́jọ́ tí wọ́n ṣòfin yẹn ni ìyàwó mi bí ọmọ wa ọkùnrin tá a pè ní Johannes nílé nígbà tí èmi sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbẹ̀bí sọ fún àwọn aláṣẹ Àjọ Aláàbò pé kí wọ́n máà wọnú ilé wa, wọ́n ṣì pàpà wọlé nítorí pé wọ́n ń wá ẹ̀rí tí wọ́n á fi ti ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá lẹ́yìn. Àmọ́, wọ́n ò rí ẹ̀rí kankan. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ní kí ẹnì kan máa wá sí ìjọ wa láti ṣe amí fún wọn. Èyí ló mú kí wọ́n fàṣẹ ọba mú gbogbo àwọn arákùnrin tó ń mú ipò iwájú ní October 1953 títí kan èmi alára.
Ìgbà Tí Mo Wà Nínú Àjàalẹ̀ Tó Ṣókùnkùn
Lẹ́yìn tí wọ́n dá wa lẹ́bi tán tí wọ́n sì kéde pé a óò ṣẹ̀wọ̀n látorí ọdún mẹ́tà sí márùn ún, wọ́n kó wa lọ́ síbi táwọn arákùnrin wa wà ní àjàalẹ̀ tóóró kan ní Ilé Ńlá Olódi Osterstein, nílùú Zwickau. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò tí a bá ara wa burú kọjá ohun tá a lè máa fẹnu sọ, ayọ̀ ńlá ló jẹ́ fún wa láti wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin tó dàgbà dénú. Bá ò tilẹ̀ lómìnira, à ń rí oúnjẹ jẹ́ nípa tẹ̀mí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ò nífẹ̀ẹ́ sí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, tí wọ́n sì fòfin dè é, ìwé ìròyìn náà ṣì pàpà dé inú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, ó sì dé inú yàrá tá a wà! Báwo ló ṣe débẹ̀?
Wọ́n ní kí àwọn kan lára àwọn arákùnrin náà lọ máa ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wa èédú, ibẹ̀ ni wọ́n ti bá àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nígboro pàdé, àwọn Ẹlẹ́rìí náà ló kó àwọn ìwé ìròyìn náà fún wọn. Àwọn arákùnrin náà yọ́ kẹ́lẹ́ mú àwọn ìwé ìròyìn yìí wọnú ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì lo ọgbọ́n láti pín oúnjẹ tẹ̀mí tá a nílò wọ̀nyí dé ọ̀dọ̀ àwa tó kù. Inú mi dùn gan-an láti rí àbójútó àti ìtọ́sọ́nà Jèhófà lọ́nà yìí!
Níparí ọdún 1954, wọ́n gbé wa kúrò níbi tá a wà lọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tó rí játijàti nílùú Torgau. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀ dùn gan-an láti rí wa. Kí wọ́n tó kó wa lọ síbẹ̀, àwọn ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà rántí nínú àwọn Ilé Ìṣọ́ tó ti pẹ́ ni wọ́n máa ń sọ ní àsọtúnsọ láti fi gbé ara wọn ró nípa tẹ̀mí. Wọ́n ń hára gàgà láti rí àkọ̀tun oúnjẹ tẹ̀mí gbà! Ní báyìí, iṣẹ́ kàn wá láti sọ àwọn nǹkan tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Zwickau fún wọn. Àmọ́, báwo la ṣe lè ṣe èyí nígbà tí wọ́n ṣòfin pé a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ síra wa nígbà ìrìn wa ojoojúmọ́? Tóò, àwọn arákùnrin sọ fún wa bá a ṣe máa ṣe é, Jèhófà náà sì dáàbò rẹ̀ tó nípọn bò wá. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, ká sì máa ṣe àṣàrò lé e lórí nígbà tá a lómìnira tá a sì láǹfààní rẹ̀.
Àkókò Láti Ṣe Ìpinnu Pàtàkì
Jèhófà ló ràn wá lọ́wọ́ láti dúró nínú òtítọ́. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa nígbà tí wọ́n dá àwọn kan lára wa sílẹ̀ ní ìparí ọdún 1956. Ìdùnnú ṣubú layọ̀ nígbà tí wọ́n ṣí ilẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pé ká máa lọ! Ọmọ mi ti pé ọdún mẹ́fà nígbà náà, ayọ̀ ńlá ló sì jẹ́ fún mi láti tún padà lọ bá ìyàwó mi ká sì jọ máa tọ́ ọmọ wa. Fún àkókò kan, ojú àlejò ni Johannes fi máa ń wò mí, àmọ́ kò pẹ́ tí ìfẹ́ àárín èmi àti òun fi gbèrú.
Nígbà náà lọ́hùn-ún, nǹkan le koko fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé ní Ìlà Oòrùn Jámánì. Àtakò tó ń peléke sí i tí wọ́n ń ṣe sí wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni àti àìdá sí ọ̀ràn ìlú fi hàn pé nǹkan kò ní rọrùn fún wa, èyí sì túmọ̀ sí pé ewu, àníyàn àti agara yóò bò wá mọ́lẹ̀. Nítorí náà, èmi àti Erika fara balẹ̀ gbé ipò wa yẹ̀ wò, a sì gbàdúrà nípa rẹ̀, a wá wò ó pé ó yẹ ká ṣí kúrò níbi tá a wà yẹn ká bàa lè gbé ìgbésí ayé nínú ipò tó dára kí àníyàn má bàa pa wá. Ìfẹ́ wa ni pé ká lómìnira láti sin Jèhófà kí á sì lè máa lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí.
Ní ìgbà ìrúwé ní ọdún 1957, ó ṣeé ṣe fún wa láti ṣí lọ sí ìlú Stuttgart ní Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì. Wọn ò fòfin de iṣẹ́ ìjíhìnrere nílùú náà, ó sì ṣeé ṣe fún wa láti máa bá àwọn ará wa kẹ́gbẹ́ fàlàlà. Àwọn ará náà dúró tì wá gbágbáágbá. Ọdún méje la lò pẹ̀lú ìjọ Hedelfingen. Ìgbà yẹn ni ọmọ wa bẹ̀rẹ̀ iléèwé, ó sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ètò. Ní September 1962, mo láǹfààní láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní Wiesbaden. Ilé ẹ̀kọ́ yìí ni wọ́n ti gbà mí níyànjú pé kí èmi àti ìdílé mi lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n gbọ́ èdè Jámánì. Àwọn apá ibì kan ní orílẹ̀-èdè Jámánì àti Switzerland wà lára àgbègbè náà.
Ìgbà Tí Mo Ṣí Lọ sí Àgbègbè Olókè Ní Switzerland
Nítorí náà, a kó lọ sí orílẹ̀-èdè Switzerland ní ọdún 1963. Nígbà tá a débẹ̀, wọ́n ní ká lọ máa wàásù pẹ̀lú ìjọ kan nílùú Brunnen tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Odò Lucerne rírẹwà ní àárín àgbègbè olókè ní Switzerland. Lọ́kàn wa, ńṣe ló dà bí pé a wà nínú Párádísè. Àmọ́, a ní láti kọ́ èdè Jámánì tí wọ́n ń sọ ládùúgbò ibẹ̀, a sì ní láti jẹ́ kí irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé níbẹ̀ àti ìwà wọn mọ́ wa lára. Síbẹ̀síbẹ̀, a gbádùn iṣẹ́ wa àti wíwàásù láàárín àwọn ẹni àlàáfíà wọ̀nyẹn. Ọdún mẹ́rìnlá la lò ní Brunnen. Ibẹ̀ lọ́mọ wa dàgbà sí.
Ní ọdún 1977, tó kù díẹ̀ kí n pé ẹni àádọ́ta ọdún, a gba ìwé ìkésíni pé ká wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Thun, ní orílẹ̀-èdè Switzerland. Àǹfààní tá ò retí ni iṣẹ́ yìí jẹ́ fún wa, a sì fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á. Èmi àti ìyàwó mi lo ọdún mẹ́sàn-án nínú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, a sì máa ń rántí àwọn ọdún wọ̀nyẹn pé ó kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé Kristẹni wa àti nínú ìtẹ̀síwájú tá a ní nípa tẹ̀mí. A gbádùn iṣẹ́ ìwàásù tí àwa àtàwọn akéde tó wà nílùú Thun àti ní àgbègbè ìlú náà ṣe, gbogbo ìgbà là ń wo àwọn “iṣẹ́ àgbàyanu” Jèhófà, ìyẹn àwọn Òkè Bernese tí yìnyín bò.—Sáàmù 9:1.
A Tún Ṣí Kúrò Lẹ́ẹ̀kan Sí I
A tún ṣí kúrò lẹ́ẹ̀kan sí i ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1986. Wọ́n ní ká lọ máa sín gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní ìpínlẹ̀ títóbi tí wọ́n yàn fún Ìjọ Buchs tó wà ní apá ìlà oòrùn Switzerland. A tún ní láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan lágbègbè yẹn. Àmọ́, nítorí pé ìfẹ́ láti sin Jèhófà ló ń sún wa láti sìn níbikíbi tá a ti wúlò jù lọ, a gbà láti ṣe iṣẹ́ náà, Jèhófà sì bù kún wa. Nígbà míì, mo máa ń ṣe adelé alábòójútó arìnrìn-àjò láti máa bẹ àwọn ìjọ wò àti láti máa fún wọn lókùn nípa tẹ̀mí. Ó ti lé lọ́dún méjìdínlógún báyìí tá a ti wà lágbègbè yẹn, a sì ti ní ọ̀pọ̀ ìrírí tó mú wa láyọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù ní àgbègbè náà. Ìjọ Buchs ti gbèrú gan-an, inú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó dára gan-an tá a yà sí mímọ́ ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn la sì ti ń ṣe ìpàdé.
Jèhófà ti tọ́jú wa ni ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Èyí tó dára jù nínú ìgbésí ayé wa la ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, síbẹ̀ kò sígbà kan tí ìyà ohunkóhun jẹ wá rí. Ó jẹ́ ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn wa pé ọmọ wa àti ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ títí kan ìdílé àwọn ọmọ ọmọ wa ń fi ìṣòtítọ́ rìn ní ọ̀nà Jèhófà.
Nígbà tí mo wẹ̀yìn wò, mo gbà ní ti tòótọ́ pé a ti sin Jèhófà “ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.” Lílépa tí mo lépa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tí gbé mi kúrò nínú àjàalẹ̀ tó ṣókùnkùn tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Ìjọba Kọ́múníìsì, ó sì ti gbé mi dé àgbègbè olókè rírẹwà tó wà ní Switzerland. Èmi àti ìdílé mi kò kábàámọ̀ kankan.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
“Àwọn Tó Jẹ Àjẹtúnjẹ Ìyà” Dúró Gbọn-in Lójú Inúnibíni
Lábẹ́ àkóso ilẹ̀ olómìnira ti Jámánì tá a tún mọ̀ sí Ìlà Oòrùn Jámánì, wọ́n dìídì ya àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ́tọ̀ kí wọ́n lè máa ṣe inúnibíni sí wa. Àkọsílẹ̀ sì fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí tí iye wọn lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún ni wọ́n fi sínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti àtìmọ́lé nítorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tí wọ́n ń ṣe àti nítorí àìdásí ọ̀ràn orílẹ̀-èdè wọn.—Aísáyà 2:4.
Orúkọ tí wọ́n fún àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí yìí ni “àwọn tó jẹ àjẹtúnjẹ ìyà.” Nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [325] lára wọn ni wọ́n fi sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba Násì. Nígbà tó di àwọn ọdún 1950, àjọ Stasi, ìyẹn Àjọ Aláàbò ti ilẹ̀ olómìnira Jámánì wá wọn rí, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Kódà, àjọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó lo àwọn kan lára ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, ìjọba Násì kọ́kọ́ lò ó, lẹ́yìn náà àjọ Stasi tún wá lò ó.
Láàárín ọdún mẹ́wàá tí inúnibíni náà fi gbóná janjan, ìyẹn láti ọdún 1950 sí 1961, ọgọ́ta Ẹlẹ́rìí lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n kú nítorí ìyà, àìrí oúnjẹ jẹ, àìsàn àti ọjọ́ ogbó. Wọn fi àwọn Ẹlẹ́rìí méjìlá sí ẹ̀wọ̀n gbére, àmọ́ nígbà tó yá wọ́n dín in kù sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùndínlógún.
Lónìí, ní orílé iṣẹ́ àjọ Stasi tẹ́lẹ̀ rí tó wà ní Berlin, àwọn àwòrán kan wà níbẹ̀ tí wọn kì í gbé kúrò, àwọn àwòrán yìí ṣàfihàn díẹ̀ lára ìyà tí àwọn aláṣẹ fi jẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìlà Oòrùn Jámánì fún ogójì ọdún. Àwọn àwòrán náà àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ yìí ní ìgboyà àti okun tẹ̀mí lójú inúnibíni.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÌLÀ OÒRÙN JÁMÁNÌ
Rudolstadt
Belzig
Torgau
Chemnitz
Zwickau
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ilé Ńlá Olódi Osterstein, nílùú Zwickau
[Credit Line]
Fotosammlung des Stadtarchiv Zwickau, Deutschland
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Erika ìyàwó mi rèé