Ìtàn Ìgbésí Ayé
Mo Gbé Ìgbésí Ayé Aláyọ̀ Láìfi Ìrora Ọkàn Pè
GẸ́GẸ́ BÍ AUDREY HYDE ṢE SỌ Ọ́
Nígbà tí mo wo ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta tí mo lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, mo lè sọ pé mo ti gbé ìgbésí ayé aláyọ̀. Ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta ni mo fi sìn ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára àwọn ọdún náà. Ká sòótọ́, ìbànújẹ́ ńlá gbáà ló jẹ́ nígbà tí ọkọ mi àkọ́kọ́ ní àrùn jẹjẹrẹ, tí àrùn náà sì ṣe é títí tó fi gbẹ̀mí rẹ̀ àti nígbà tí àrùn ọdẹ orí abọ́jọ́-ogbó-rìn pa ọkọ mi kejì. Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí n sọ fún ọ ohun tó mú kí n máa láyọ̀ nígbà gbogbo láìfi àwọn àjálù wọ̀nyẹn pè.
ABÚLÉKO kan tó wà nítòsí ìlú kékeré kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Haxtun ni mo gbé dàgbà. Ìlú náà wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ń bẹ lápá àríwá ìlà oòrùn Colorado, nítòsí ààlà ìlú Nebraska. Èmi lẹnì karùn-ún lára ọmọ mẹ́fà tí àwọn òbí mi tórúkọ wọn ń jẹ́ Orille àti Nina Mock bí. Àárín ọdún 1913 sí 1920 ni wọ́n bí Russell, Wayne, Clara àti Ardis, wọ́n sì bí mi lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Wọ́n bí Curtis ní ọdún 1925.
Ní ọdún 1913, Màmá di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ti ń pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn ún. Nígbà tó ṣe, gbogbo àwa tó kù nínú ìdílé di Ẹlẹ́rìí.
Ìgbésí Ayé Alárinrin ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Náà
Bàbá jẹ́ ẹnì kan tó fẹ́ ìlọsíwájú. Gbogbo ilé wa tó wà nínú abà la fa iná sí, àwọn tó sì faná sínú ilé wọn ò wọ́pọ̀ láyé ìgbà yẹn. A gbádùn àwọn nǹkan tá a máa ń rí nínú oko wa àtèyí tá a máa ń rí lára ohun ọ̀sìn wa, irú bíi ẹyin táwọn adìyẹ wa máa ń yé, wàrà, ọ̀rá inú wàrà àti bọ́tà tí a máa ń rí lára àwọn màlúù wa. A máa ń fi ẹṣin ṣe iṣẹ́ ìtúlẹ̀, a sì máa ń gbin èso strawberry, ọ̀dùnkún, àlìkámà àti àgbàdo.
Bàbá gbà pé ó yẹ kí gbogbo àwa ọmọ fi iṣẹ́ ṣíṣe kọ́ra. Kí n tiẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé ni wọ́n ti kọ́ mi bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú pápá. Mo rántí ìgbà tí mo máa ń wà nínú oòrùn nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, tí màá máa kọ ebè nínú ọgbà. Màá wá béèrè lọ́wọ́ ara mi pé, ‘Ṣé màá lè kọ ebè yìí dé ìparí báyìí?’ Màá máa làágùn yọ̀bọ̀, oyin á tún máa ta mí. Nígbà míì, àánú ara mi á wá máa ṣe mí, torí pé àwọn ọmọ mìíràn kì í ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó bíi tiwa. Àmọ́ o, ká sòótọ́, nígbà tí mo bá ronú kan ìgbà tí mo wà lọ́mọdé, ńṣe ni mo máa ń dúpẹ́ pé wọ́n fi iṣẹ́ ṣíṣe kọ́ wa.
Gbogbo wa la níṣẹ́ tí wọ́n ti yàn fún wa. Ardis mọ wàrà fún jù mí lọ, nítorí náà iṣẹ́ tèmi ni pé kí n tọ́jú ilé ẹṣin, kí n máa fi ṣọ́bìrì kó ìgbẹ́ wọn jáde. Bá a sì ṣe ń ṣiṣẹ́ tó yẹn náà, a tún máa ń ṣàwàdà, a sì máa ń ṣeré ìdárayá. Èmi àti Ardis máa ń gbá bọ́ọ̀lù ọlọ́wọ́. Òun á dúró sí ẹ̀gbẹ́ kan, èmi á dúró sí ẹ̀gbẹ́ kejì.
Tó bá dọwọ́ alẹ́, ojú ọ̀run tó mọ́lẹ̀ rekete máa ń lẹ́wà gan-an téèyàn bá ń wò ó láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà. Ọ̀kẹ́ àìmọye ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run máa ń jẹ́ kí n rántí Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa. Àní bí mo ṣe kéré tó yẹn, mo máa ń ronú lórí Sáàmù 147:4 tó kà pé: “Ó [Jèhófà] ka iye àwọn ìràwọ̀; gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ wọn pè.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ní àwọn alẹ́ tó mọ́lẹ̀ rekete yìí ni ajá wa tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Judge máa ń gbé orí lé itan mi, tá sì máa bá mi ṣeré. Mo sábà máa ń jókòó sí ọ̀dẹ̀dẹ̀ ilé wa lọ́sàn-án, tí màá máa wo bí afẹ́fẹ́ ṣe ń fẹ́ àwọn àlìkámà tí kò tíì pọ́n, àwọ̀ wọn á wá rí bíi ti fàdákà nínú oòrùn.
Àpẹẹrẹ Rere Tí Màmá Fi Lélẹ̀
Aya rere, tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ ni màmá mi. Àmọ́ Bàbá ni olórí ìdílé o, Màmá sì kọ́ wa láti máa bọ̀wọ̀ fún un. Ní ọdún 1939, Bàbá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A mọ̀ pé Bàbá fẹ́ràn wa bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń fún wa ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ṣe, kò kẹ́ wa bà jẹ́ rárá. Tó bá di ìgbà òtútù, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń so ẹṣin méjì pọ̀, á sì so kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tí a óò jókòó sí mọ́ ara ẹṣin náà, lẹ́yìn náà á wá máa gbé wa kiri lórí yìnyín. Áà, bí yìnyín yẹn ṣe máa ń dán yinrin mà gbádùn mọ́ wa o!
Àmọ́ ṣá o, Màmá ló kọ́ wa láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti láti bọ̀wọ̀ fún Bíbélì. A kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run àti pé òun ní Orísun ìwàláàyè. (Sáàmù 36:9; 83:18) A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ti fún wa ni àwọn ìtọ́ni tó máa ṣe wá láǹfààní, kì í ṣe èyí tó máa ba ayọ́ wa jẹ́. (Aísáyà 48:17) Gbogbo ìgbà ni Màmá máa ń tẹnu mọ́ ọn pé a ní iṣẹ́ pàtàkì kan láti ṣe. Wọ́n kọ́ wa pé Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
Ìgbàkígbà tí mo bá ti iléèwé dé sí ilé nígbà yẹn lọ́hùn ún, tí mi ò sì bá Màmá nílé, màá wá a lọ. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mi ò tíì ju nǹkan bí ọdún mẹ́fà sí méje lọ, inú abà ni mo ti lọ rí Màmá. Ni òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ gan-an. A wà lórí òkè ibi tí a máa ń tọ́jú koríko gbígbẹ sí, mo wá béèrè lọ́wọ́ Màmá bóyá Ọlọ́run fẹ́ fa Ìkún Omi lẹ́ẹ̀kejì. Ó fi dá mi lójú pé Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun kì yóò fi omi pa ayé yìí run mọ́. Mo tún rántí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń sá pa mọ́ sínú ihò abẹ́lẹ̀, nítorí ìjì sábà máa ń jà gan-an láyé ìgbà yẹn.
Kí Màmá tó bí mi ló ti máa ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn kan máa ń ṣe ìpàdé nínú ilé wa, gbogbo wọn ló sì ní ìrètí gbígbé lọ́dọ̀ Kristi ní ọ̀run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó nira fún Màmá láti máa wàásù láti ilé dé ilé, síbẹ̀ ìfẹ́ tó ní sí Ọlọ́run borí ẹ̀rù tó ń bà á. Màmá jẹ́ olóòótọ́ títí dọjọ́ ikú rẹ̀ ní November 24, 1969, ní ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin. Mo rọra sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ sí i létí pé: “Màmá, ẹ̀ ń lọ sọ́run, ẹ óò sì wà pẹ̀lú àwọn ojúlùmọ̀ yín.” Inú mi mà dùn gan-an o pé mo wà lọ́dọ̀ Màmá lọ́jọ́ náà mo sì jẹ́ kó mọ̀ pé ìrètí tó ní yẹn dá mi lójú! Ó fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ fún mi pé, “Ọpẹ́lọpẹ́ rẹ lára mi.”
A Bẹ̀rẹ̀ sí Wàásù
Ní ọdún 1939, Russell di aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa ń pé àwọn tó jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní Oklahoma àti Nebraska títí di ọdún 1944 nígbà tí wọ́n pè é láti wá sìn ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà (tá à ń pé ní Bẹ́tẹ́lì), ní Brooklyn, New York. Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní September 20, 1941, mo sì sìn ní onírúurú àgbègbè ní Colorado, Kansas, àti Nebraska. Ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà láyé ìgbà yẹn dùn gan-an ni, kì í ṣe nítorí pé mo ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà nìkan ni àmọ́ nítorí pé mo tún kọ́ láti gbára lé e.
Láàárín ìgbà tí Russell bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, Wayne wà ní yunifásítì tó wà ní apá àríwá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lẹ́yìn tó ti ṣiṣẹ́ ajé fúngbà díẹ̀. Nígbà tó ṣe, wọ́n ní kó máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì. Ó sìn fúngbà díẹ̀ ní Oko Society tó wà nítòsí ìlú Ithaca, New York. Ibẹ̀ la ti ń gbin oúnjẹ tá a fi ń bọ́ ìdílé kékeré tó wà ní Oko Society títí kan nǹkan bíi igba òṣìṣẹ́ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn. Wayne lo ẹ̀bùn iṣẹ́ rẹ̀ àti ìmọ̀ rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà títí dọjọ́ ikú rẹ̀ ní ọdún 1988.
Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Ardis fẹ́ James Kern, wọ́n sì bí ọmọ márùn-ún. Ó ṣaláìsí ní 1997. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin kejì tó ń jẹ́ Clara ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí dòní olónìí, mo sì máa ń lọ kí i nílé rẹ tó wà ní Colorado nígbà tí mo ba gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́. Àbúrò wa ọkùnrin tó kéré jù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Curtis wá sí Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn láàárín àwọn ọdún 1940. Ó máa ń fi ọkọ̀ akẹ́rù kó àwọn ohun èlò láti Oko Society lọ sí Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn. Òun ò fẹ́yàwó ní tiẹ̀, ó sì ṣaláìsí lọ́dún 1971.
Iṣẹ́ Ìsìn Bẹ́tẹ́lì Ni Ọkàn Mí Fẹ́
Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ló kọ́kọ́ lọ sí Bẹ́tẹ́lì, ó sì wù mí kí èmi náà lọ sìn níbẹ̀ pẹ̀lú. Ó dá mi lójú pé ìwà rere tí wọ́n hù níbẹ̀ ló mú kí wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì. Ìtàn nípa ètò àjọ Ọlọ́run tí Màmá máa ń sọ fún mi àti rírí tí mo fojú ara mi ri ìmúṣẹ àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ló jẹ́ kó wù mí láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Mo bá Jèhófà jẹ́jẹ̀ẹ́ nínú àdúrà pé tó bá lè jẹ́ kí n lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, mi ò ní kúrò níbẹ̀ àyàfi tí mo bá ní ojúṣe Kristẹni tí mo gbọ́dọ̀ bójú tó.
Mo dé sí Bẹ́tẹ́lì ní June 20, 1945, iṣẹ́ ìtọ́jú ilé ni wọ́n sì yàn fún mi láti máa ṣe. Yàrá mẹ́tàlá ni mo máa ń tọ́jú, màá tẹ́ bẹ́ẹ̀dì mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tó wà nínú àwọn yàrá náà, màá tún nu ọ̀dẹ̀dẹ̀ àtàwọn fèrèsé. Iṣẹ́ kékeré kọ́ o. Ojoojúmọ́ nígbà tí mo bá wà níbi iṣẹ́ ni mo máa ń sọ fún ara mi pé, ‘Mo mọ̀ pé ó ti rẹ̀ ẹ́, àmọ́ Bẹ́tẹ́lì, ilé Ọlọ́run lo wà o!’
Èmi àti Nathan Knorr Ṣègbéyàwó
Láti àwọn ọdún 1920 síwájú, wọ́n máa ń sọ fáwọn òṣìṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó pé kí wọ́n kúrò ní Bẹ́tẹ́lì, kí wọ́n lọ sìn fún ire Ìjọba náà níbòmíràn. Àmọ́, níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950, wọ́n gbà kí àwọn bíi mélòó kan tí wọ́n ti pẹ́ díẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì ṣe ìgbéyàwó kí wọ́n sì dúró sí Bẹ́tẹ́lì. Nítorí náà, nígbà tí Nathan H. Knorr, tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ Ìjọba náà jákèjádò ayé fi ìfẹ́ hàn sí mi, mo sọ lọ́kàn ara mi pé, ‘Áà, ẹni tí ò ní kúrò ní Bẹ́tẹ́lì rèé!’
Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni Nathan ń bójú tó nínú ìgbòkègbodò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé. Nítorí náà, ó bá mi sòótọ́ ọ̀rọ̀, ó fún mi ní ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ kí n ronú lórí ọ̀rọ̀ náà dáadáa kí n tó gbà láti fẹ́ òun. Láyé ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń lọ sí àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri ayé, ó sì máa ń lo ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ nígbà mìíràn. Nítorí náà, ó sọ fún mi pé a lè máà ríra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.
Nígbà tí mo wà ní ọmọge, ìgbà ìrúwé ló máa ń wù mí pé kí n ṣe ìgbéyàwó, kí n sì lọ fún ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì ẹ̀yìn ìgbéyàwó ní erékùṣù Pàsífíìkì ti Hawaii. Àmọ́, ìgbà òtútù la ṣe ìgbéyàwó ní January 31, 1953, a sì bẹ̀rẹ̀ ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì ẹ̀yìn ìgbéyàwó lọ́sàn-án ọjọ́ Saturday kan náà títí di ọjọ́ Sunday ní New Jersey. Nígbà tó di ọjọ́ Monday, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, a lọ lo ọ̀sẹ̀ kan fún ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì lẹ́yìn ìgbéyàwó wa.
Alábàákẹ́gbẹ́ Tó Jẹ́ Òṣìṣẹ́kára
Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni Nathan nígbà tó wá sí Bẹ́tẹ́lì ní ọdún 1923. Ó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jíire látọ̀dọ̀ àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn, irú bíi Joseph F. Rutherford, tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí àti Robert J. Martin tó jẹ́ máníjà ilé ìtẹ̀wé. Nígbà tí Arákùnrin Martin kú ní September 1932, Nathan di máníjà ilé ìtẹ̀wé. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Arákùnrin Rutherford ní kí Nathan tẹ̀ lé òun nígbà tó ń lọ ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Yúróòpù. Nígbà tí arákùnrin Rutherford kú ní ọdún 1942, wọ́n yan Nathan ṣe alábòójútó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé.
Nathan jẹ́ ẹnì kan tó fẹ́ ìtẹ̀síwájú, gbogbo ìgbà ló máa ń wéwèé nípa ọ̀nà tí ìbísí fi máa wà lọ́jọ́ ọ̀la. Àwọn kan rò pé ohun tó ń ṣe yẹn kò tọ̀nà, nítorí wọ́n gbà pé òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán. Àní, nígbà tí arákùnrin kan rí ohun tí Nathan ń wéwèé, ó sọ fún un pé: “Arákùnrin Knorr, kí ni ìtumọ̀ gbogbo eléyìí tó ò ń ṣe yìí? Ṣé o ò gbà pé òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ni?” Nathan fèsì pé: “Mo gbà pé òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé, àmọ́ tí òpin náà kò bá tètè dé, àá múra sílẹ̀ dè é.”
Nǹkan tí Nathan ní lọ́kàn àtiṣe ni láti dá ilé ẹ̀kọ́ àwọn míṣọ́nnárì sílẹ̀. Nítorí náà, ilé ẹ̀kọ́ àwọn míṣọ́nnárì bẹ̀rẹ̀ ní February 1, 1943 ní Oko Society níbi tí Wayne, ẹ̀gbọ̀n mi ọkùnrin ti ń sìn nígbà yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ Bíbélì tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò fi nǹkan bí oṣù márùn-ún kọ́ nílé ìwé yìí máa pọ̀ gan-an, síbẹ̀ Nathan rí i dájú pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń ṣe eré ìdárayá. Nígbà yẹn lọ́hùn ún tí ilé ìwé náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ó máa ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbá bọ́ọ̀lù ọlọ́wọ́, àmọ́ nígbà tó yá, kò bá wọn ṣe eré náà mọ́ nítorí ẹ̀rù ń bà á pé tóun bá lọ ṣèṣe, òun ò ní lè lọ sí àpéjọ àgbègbè tí yóò wáyé ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Ó wá ń ṣe olùdarí eré. Inú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dùn nígbà tó yí òfin eré bọ́ọ̀lù náà padà fún àǹfààní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ti orílẹ̀-èdè mìíràn wá.
Àwọn Ìrìn-Àjò Tí Èmi àti Nathan Jọ Lọ
Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí bá Nathan rìnrìn àjò lọ sí onírúurú orílẹ̀-èdè. Mo gbádùn láti máa sọ ìrírí fún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àtàwọn míṣọ́nnárì. Mo fojú ara mi rí ìfẹ́ àti ìfọkànsìn tí wọ́n ní, mo sì kọ́ nípa ìgbòkègbodò wọn àti nípa bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé ní orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí. Látìgbà náà wá, mi ò yéé gba lẹ́tà ìmọrírì nítorí irú àwọn ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀.
Tí mo bá ronú kan àwọn ibi tí mo ti rìnrìn àjò lọ, ọ̀pọ̀ ìrírí ló máa ń wá sí mi lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a lọ sí orílẹ̀-èdè Poland, àwọn arábìnrin méjì jọ ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ síra wọn níṣojú mi. Ni mo bá bi wọn pé, “Kí ló dé tẹ́ ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́?” Wọ́n ni kí n máà bínú, pé ó ti mọ́ àwọn lára láti máa sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ nígbà tí àwọn aláṣẹ fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Poland, tí àwọn aláṣẹ sì máa ń fi ẹ̀rọ pa mọ́ sínú ilé àwọn Ẹlẹ́rìí kí wọ́n lè máa gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ.
Arábìnrin Adach wà lára ọ̀pọ̀ èèyàn tó sìn lákòókò tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa ní Poland. Irun arábìnrin náà gùn gan-an. Nígbà kan, ó fọwọ́ gbá irun rẹ̀ sẹ́yìn, ó wá fi àpá ńlá kan hàn mí níbi tí ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wọn ti lù ú. Ẹ̀rù bà mí nígbà tí mo rí ohun tí ìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa fà.
Yàtọ̀ sí Bẹ́tẹ́lì, orílẹ̀-èdè Hawaii ni ibi tí mo tún fẹ́ràn jù lọ. Mo rántí àpéjọ àgbègbè kan tá a ṣe níbẹ̀ ní ìlú Hilo lọ́dún 1957. Mánigbàgbé ni àpéjọ náà, iye àwọn tó wá sí àpéjọ náà pọ̀ ju iye àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ lórílẹ̀-èdè náà. Olórí ìlú náà gba Nathan tọwọ́tẹsẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá kí wa, wọ́n sì fi òdòdó ṣe ọ̀ṣọ́ sí wa lọ́rùn láti fi yẹ́ wa sí.
Àpéjọ àgbègbè mìíràn tí mi ò lè gbàgbé ni èyí tó wáyé ní Nuremberg, Jámánì, ní ọdún 1955 ní gbàgede tí àwọn ológun Hitler ti ń yan tẹ́lẹ̀. Kò sẹ́ni tí ò gbọ́ ìlérí tí Hitler ṣe pé òun máa sọ àwọn èèyàn Jèhófà di àwátì ní orílẹ̀-èdè Jámánì, àmọ́ ibi gbàgede yìí kan náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà péjú pésẹ̀ sí láti ṣèpàdé! Ni mo bá bú sẹ́kún ayọ̀. Pèpéle náà tóbi gan-an, òpó ńláńlá mẹ́rìnlélógóje ló gbé e ró. Nígbà tí mo dúró sórí pèpéle, mo rí àwọn èèyàn tí wọ́n lọ súà, iye wọn lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún ó lé ẹgbẹ̀rún méje [107,000]. Ibi táwọn èèyàn jókòó sí gùn lọ sẹ́yìn gan-an tó fi jẹ́ pé mo fẹ́rẹ̀ẹ́ máà lè rí ìlà tó gbẹ̀yìn.
Tẹ́ ẹ bá rí àwọn ará tó jẹ́ ọmọ Jámánì wọ̀nyẹn, ẹ ó mọ̀ pé wọ́n jẹ́ oníwà títọ́, ẹ ó sì mọ̀ pé wọ́n rí okun tẹ̀mí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà lákòókò tí ìjọba Násì fi ń ṣe inúnibíni sí wọn. Èyí mú kí ìpinnu wa láti jẹ́ ẹni ìdúróṣinṣin kí á sì pa ìwà títọ́ wa mọ́ sí Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i. Nathan ló sọ ọ̀rọ̀ àsọkágbá, nígbà tó sì parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó juwọ́ sí àwùjọ náà pé, ó dàbọ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ làwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí fi áńkáṣíìfù wọn juwọ́ sí i. Ńṣe làwọn áńkáṣíìfù tí wọ́n fi ń juwọ́ sí i náà dà bí òdòdó tó pọ̀ rẹpẹtẹ.
Mi ò tún lè gbàgbé ìgbà tá a lọ sí ilẹ̀ Potogí ní December 1974. A wà ní ìpàdé àkọ́kọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí ṣe ní ìlú Lisbon lẹ́yìn tí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe di èyí tí wọ́n fọwọ́ sí lábẹ́ òfin. Odindi àádọ́ta ọdún gbáko ni wọ́n fi fòfin dé iṣẹ́ wa! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kìkì ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá [14,000] akéde Ìjọba náà ló wà ní orílẹ̀-èdè náà nígbà yẹn, iye àwọn tó pésẹ̀ fún ìpàdé méjèèjì yìí lé ní ẹgbàá mẹ́tàlélógún [46,000]. Omi bọ́ lójú mi nígbà táwọn ará sọ pé: “Kò sí pé à ń ṣèpàdé ní ìdákọ́ńkọ́ mọ́. A ti dòmìnira.”
Látìgbà tí mo ti ń bá Nathan rìnrìn àjò títí dòní olónìí yìí, mo máa ń gbádùn ìwàásù láìjẹ́-bí-àṣà, ì bá à jẹ́ nínú ọkọ̀ òfuurufú, nílé oúnjẹ tàbí lójú pópó. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ dání láti fi wàásù. Nígbà kan tí ọkọ òfuurufú ò tètè dé, tá a wá ń dúró dè é, obìnrin kan béèrè ibi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ mi. Ìbéèrè yìí ló mú kí n wàásù fún òun àtàwọn tó ń fetí sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa. Iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì àti iṣẹ́ ìwàásù ti mú kí ọwọ́ mi dí, ó sì ti fún mi láyọ̀ púpọ̀.
Àìsàn Nathan àti Ọ̀rọ̀ Ìyànjú Tó Fi Dágbére Fún Mi
Ní 1976, àìsàn jẹjẹrẹ dá Nathan gúnlẹ̀, àmọ́ èmi àtàwọn ara ilé Bẹ́tẹ́lì ṣèrànwọ́ fún un láti máa bá a yí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn náà ń yọ ọ́ lẹ́nu, síbẹ̀ a máa ń sọ fún onírúurú àwọn ará, tí wọ́n ti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì yíká ayé wá sí Brooklyn fún ìdálẹ́kọ̀ọ́, pé kí wọ́n wá sí yàrá wa. Mo rántí ìgbà tí Don àti Earline Steele, Lloyd àti Melba Barry, Douglas àti Mary Guest, Martin àti Gertrud Poetzinger, Price Hughes àtàwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ wá kí wa. Wọ́n máa ń sọ ìrírí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà fún wa. Ìrírí tó máa ń dùn mọ́ mi jù lọ ni èyí tó bá jẹ mọ́ ìdúróṣinṣin àwọn ará wa nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa.
Nígbà tí Nathan rí i pé òun ò ní pẹ́ kú, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú fún mi tó máa ràn mí lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro tó máa ń bá opó. Ó ní: “Ìgbéyàwó wa jẹ́ aláyọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni tiwọn ò rí bẹ́ẹ̀.” Ẹ̀mí ìgbatẹnirò tí Nathan ní wà lára nǹkan tó mú kí ìgbéyàwó wa jẹ́ aláyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí a bá bá onírúurú èèyàn pàdé láwọn ibi tá a lọ, á sọ fún mi pé: “Audrey, tí mi ò bá sọ orúkọ wọn fún ọ nígbà míì, ohun tó fà á ni pé mo ti gbàgbé orúkọ wọn.” Inú mi dùn gan-an pé ó sọ èyí fún mi ṣáájú.
Nathan rán mi létí pé: “Lẹ́yìn ikú, ìrètí wa dájú, a ò sì ní jẹ̀rora mọ́ láé.” Lẹ́yìn náà, ó wá rọ̀ mí pé: “Máa wo ọjọ́ iwájú, nítorí pé èrè rẹ ń bẹ lọ́jọ́ iwájú. Má máa ronú nípa àwọn nǹkan tó ti kọjá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wàá ṣì máa rántí wọn. Nígbà tó bá yá, wàá mọ́kàn kúrò lára wọn. Má ṣe bọkàn jẹ́, má sì jẹ́ kí àánú ara rẹ máa ṣe ọ́. Jẹ́ kí inú rẹ̀ máa dùn nítorí ayọ̀ àti ìbùkún tó o ti ní. Láìpẹ́ jọjọ, wàá rí i pé àwọn nǹkan tó o bá ń rántí yóò máa fún ọ láyọ̀. Agbára ìrántí jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé: “Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí, máa ṣoore fáwọn èèyàn. Èyí yóò mú kó o rí ayọ̀ nínú wíwà tó o wà láàyè.” Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Nathan parí ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní June 8, 1977.
Ìgbéyàwó Èmi àti Glenn Hyde
Nathan ti sọ fún mi pé mo lè máa ronú lórí ìgbésí ayé tá a ti jọ gbé tàbí kí n bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun. Nítorí náà ní 1978, ìyẹn lẹ́yìn tí wọ́n gbé mi lọ́ sí Oko Watchtower ní Wallkill, New York, mo fẹ́ Glenn Hyde, ọkùnrin arẹwà kan tí kì í sọ̀rọ̀ púpọ̀ tó sì jẹ́ èèyàn jẹ́jẹ́. Kí Glenn tó di Ẹlẹ́rìí, iṣẹ́ ológun ojú omi ló ń ṣe lákòókò tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń bá orílẹ̀-èdè Japan jagun.
Inú ọkọ̀ àwọn ológun ojú omi ni Glenn máa ń wà, ibi tí ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ náà wà ni wọ́n sì fi í sí. Ariwo tí ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ náà máa ń pa ti jẹ́ kí Glenn dẹni tí kì í gbọ̀rọ̀ dáadáa mọ́. Nígbà tí ogun náà parí, ó di panápaná. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi lá àlákálàá nítorí àwọn nǹkan tójú ẹ̀ ti rí nígbà ogun. Ipasẹ̀ akọ̀wé rẹ̀ tó wàásù fún un láìjẹ́-bí-àṣà ló fi rí òtítọ́ Bíbélì.
Nígbà tó yá, ní 1968, wọ́n pe Glenn sí Bẹ́tẹ́lì láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí panápaná ní Brooklyn. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Oko Watchtower ní ẹ́ńjìnnì panápaná tirẹ̀, wọ́n gbé Glenn lọ sí ibẹ̀ ní 1975. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àrùn ọdẹ orí abọ́jọ́-ogbó-rìn bẹ̀rẹ̀ sí yọ ọ́ lẹ́nu. Glenn ṣaláìsí lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tá a ti jọ jẹ́ tọkọtaya.
Báwo ni máà ṣe wá kojú gbogbo wàhálà yìí? Ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí Nathan sọ fún mi nígbà tó rí i pé òun ò ní pẹ́ kú ló tún wá jẹ́ ìtùnú fún mi. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ka ọ̀rọ̀ tó kọ sílẹ̀ nípa bí mo ṣe lè kojú ìṣòro tó ń bá àwọn opó. Mo ṣì máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú wọ̀nyẹn fún àwọn tí ọkọ wọn bá kú, èyí sì máa ń tù wọ́n nínú pẹ̀lú. Bẹ́ẹ̀ ni o, ohun tó ti dára ni pé ká máa wo ọjọ́ iwájú gẹ́gẹ́ bó ṣe ní kí n máa ṣe.
Ẹgbẹ́ Ará Tó Ṣeyebíye
Àwọn ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì gan-an ni ohun tó mú kí ìgbésí ayé mi jẹ́ aláyọ̀. Ọ̀kan lára wọn ni Esther Lopez, tó kẹ́kọ̀ọ́ yege lọ́dún 1944 ní kíláàsì kẹta ti Watchtower Bible School of Gilead. Ó padà sí Brooklyn ní February 1950, ó wá ń túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè Spanish. Lọ́pọ̀ ìgbà tí Nathan bá lọ sí ìrìn-àjò, Esther lẹni tó tún sún mọ́ mi jù lọ. Oko Watchtower lòun náà wà. Nísinsìnyí tó ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún, ara rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ le mọ́, ilé ìtọ́jú aláìsàn wa ni wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀.
Russell àti Clara nìkan ló wà láàyè nínú gbogbo àwọn èèyàn mi. Russell ti lé ní ẹni àádọ́rùn-ún ọdún, ó ṣì ń fi ìṣòtítọ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn. Ó wà lára àwọn ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n ní kó dúró sí Bẹ́tẹ́lì lẹ́yìn ìgbéyàwó. Ní 1952, òun àti Jean Larson tí òun náà jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ṣe ìgbéyàwó. Max tó jẹ́ arákùnrin Jean wá sí Bẹ́tẹ́lì ní 1939, òun ló gbapò Nathan ní 1942 gẹ́gẹ́ bí máníjà ilé ìtẹ̀wé. Ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ ni Max ń bójú tó ní Bẹ́tẹ́lì, títí kan ṣíṣe ìtọ́jú ìyàwó rẹ̀ tó ní àrùn iṣan líle gbagidi.
Nígbà tí mo wo ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta tí mo ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, mo lè sọ pé mo ti gbé ìgbésí ayé aláyọ̀. Bẹ́tẹ́lì ti di ilé mi, mo sì ń bá a lọ láti fi ọkàn tó kún fún ayọ̀ sìn níbẹ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mi tí wọ́n jẹ́ kí n mọ ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ṣíṣe, tí wọ́n sì gbin ìfẹ́ láti sin Jèhófà sí mi lọ́kàn. Àmọ́, olórí ohun tó ń mú kí ìgbésí ayé ẹni jẹ́ aláyọ̀ ni ẹgbẹ́ ara tó ṣọ̀wọ́n àti ìrètí pé a óò bá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa gbé pa pọ̀ nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, tí a ó máa jìjọ sin Jèhófà, Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà títí lọ gbére.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn òbí mi rèé lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn ní June 1912
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún: Russell, Wayne, Clara, Ardis, èmi, àti Curtis ní 1927
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi rèé láàárín Frances àti Barbara McNaught, nígbà tá a fi ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní 1944
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi rèé ní Bẹ́tẹ́lì ní 1951. Láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún: Èmi, Esther Lopez, àti Jean tó jẹ́ aya ẹ̀gbọ́n mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Nathan àtàwọn òbí rẹ̀ rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Nathan ní 1955
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Èmi àti Nathan rèé ní Hawaii
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Èmi àti Glenn, ọkọ mi kejì