Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Àwọn wo ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “aláìgbàgbọ́” nínú 2 Kọ́ríńtì 6:14?
Kọ́ríńtì kejì orí kẹfà ẹsẹ kẹrìnlá kà pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” Tá a bá wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣáájú ẹsẹ yẹn, ó ṣe kedere pé àwọn tí kì í ṣe ara ìjọ Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ bá. Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn tí Pọ́ọ̀lù ti lo ọ̀rọ̀ náà “aláìgbàgbọ́” tàbí “àwọn aláìgbàgbọ́,” ó fi hàn pé àwọn tí kì í ṣe ara ìjọ ló ń tọ́ka sí lóòótọ́.
Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù bá àwọn Kristẹni wí gidigidi nítorí pé wọ́n ń lọ sí kóòtù “níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.” (1 Kọ́ríńtì 6:6) Àwọn adájọ́ tó ń ṣiṣẹ́ ní kóòtù Kọ́ríńtì ni àwọn aláìgbàgbọ́ tí ẹsẹ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nínú lẹ́tà kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ, ó sọ pé Sátánì ti “fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú.” Wọ́n ti fi nǹkan ‘bo’ irú àwọn aláìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ lójú kí wọ́n má bàa rí ìhìn rere náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yìí ò tiẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ kankan láti sún mọ Jèhófà, nítorí Pọ́ọ̀lù ti sọ ṣáájú pé: “Nígbà tí wọ́n bá yíjú sí Jèhófà, ìbòjú náà a ká kúrò.”—2 Kọ́ríńtì 3:16; 4:4.
Àwọn aláìgbàgbọ́ kan máa ń hùwà ta-ló-máa-mú-mi bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ń bọ̀rìṣà. (2 Kọ́ríńtì 6:15, 16) Àmọ́, kì í ṣe gbogbo wọn ló lòdì sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà o. Àwọn kan nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ní ọkọ tàbí aya tó jẹ́ Kristẹni, inú wọn sì dùn láti máa bá wọn gbé. (1 Kọ́ríńtì 7:12-14; 10:27; 14:22-25; 1 Pétérù 3:1, 2) Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lókè yìí, ní gbogbo ibi tí Pọ́ọ̀lù ti lo ọ̀rọ̀ náà “aláìgbàgbọ́,” àwọn tí kì í ṣe ara ìjọ Kristẹni tó jẹ́ “àwọn onígbàgbọ́ nínú Olúwa” ló ń tọ́ka sí.—Ìṣe 2:41; 5:14; 8:12, 13.
Gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé ni ìlànà tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 6:14 fi jẹ́ ìtọ́sọ́nà tó wúlò fún àwọn Kristẹni, a sì sábà máa ń fa ẹsẹ yìí yọ láti fi gba àwọn Kristẹni tó ń wá ọkọ àtàwọn tó ń wá aya nímọ̀ràn ọlọgbọ́n. (Mátíù 19:4-6) Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì ti ṣe ìrìbọmi kò ní wá ọkọ tàbí aya láàárín àwọn aláìgbàgbọ́, nítorí pé ìwà àwọn aláìgbàgbọ́, ohun tí wọ́n ń lépa àtohun tí wọ́n gbà gbọ́ yàtọ̀ pátápátá sí táwọn Kristẹni tòótọ́.
Àmọ́, àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń wá sí ìjọ Kristẹni ńkọ́? Àwọn akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi ńkọ́? Ṣé aláìgbàgbọ́ làwọn yẹn náà ni? Rárá o. A ò lè máa pe àwọn tí wọ́n ti gba òtítọ́ ìhìn rere, tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa láti ṣe ìrìbọmi ní aláìgbàgbọ́. (Róòmù 10:10; 2 Kọ́ríńtì 4:13) Kí Kọ̀nílíù tó ṣèrìbọmi, a pè é ní “olùfọkànsìn àti ẹnì kan tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run.”—Ìṣe 10:2.
Nígbà náà, ṣé ó bọ́gbọ́n mu kí Kristẹni kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fi ẹnì kan tá a ti tẹ́wọ́ gbà gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi ṣe àfẹ́sọ́nà, níwọ̀n bí èyí kò ti ta ko ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 6:14? Rárá o, kò bọ́gbọ́n mu. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu? Èyí jẹ́ nítorí ìmọ̀ràn tó ṣe tààràtà tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ opó. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹni tí ó bá fẹ́, kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn yẹn ṣe sọ, a rọ àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ láti wá ọkọ tàbí aya kìkì láàárín àwọn tó wà “nínú Olúwa.”
Kí ni gbólóhùn náà “kìkì nínú Olúwa” àti gbólóhùn kan tó fara jọ ọ́, ìyẹn “nínú Kristi,” túmọ̀ sí? Nínú Róòmù 16:8-10 àti Kólósè 4:7, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó wà “nínú Kristi” tàbí “nínú Olúwa.” Tó o bá ka àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn, wàá rí i pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀,” “ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà,” ‘arákùnrin olùfẹ́ ọ̀wọ́n,’ “olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́,” àti “ẹrú ẹlẹgbẹ́.”
Ìgbà wo lẹnì kan tó lè di ‘ẹrú nínú Olúwa’? Ìgbà tí onítọ̀hún bá fínnúfíndọ̀ ṣe ohun tó yẹ kí ẹrú ṣe, tó sì sẹ́ ara rẹ̀ ni. Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mátíù 16:24) Ó dìgbà tẹ́nì kan bá ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run kó tó bẹ̀rẹ̀ sí tọ Kristi lẹ́yìn kó sì tó fi ara rẹ̀ fún ìfẹ́ Ọlọ́run. Lẹ́yìn ìyẹn, yóò ṣe ìrìbọmi, á sì wá di òjíṣẹ́ tí a yàn tó wà ní ipò ìtẹ́wọ́gbà níwájú Jèhófà Ọlọ́run.a Nítorí náà, láti ‘ṣe ìgbéyàwó nínú Olúwa’ túmọ̀ sí pé kí ẹnì kan fẹ́ ẹni tó fi hàn nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀ pé òun jẹ́ onígbàgbọ́, tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí “ẹrú Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi Olúwa.”—Jákọ́bù 1:1.
Nǹkan gidi lẹnì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí ń ṣe. Àmọ́, ẹni náà ò tíì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà bẹ́ẹ̀ sì ni kò tíì fi ìgbésí ayé rẹ̀ fún jíjọ́sìn Jèhófà. Ó ṣì ń ṣe àwọn ìyípadà yíyẹ lọ́wọ́ ni. Ó ní láti ṣe gbogbo ìyípadà pàtàkì tẹ́nì kan gbọ́dọ̀ ṣe láti di Kristẹni, láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ àti láti ṣe ìrìbọmi kó tó di pé á máa ronú ṣíṣe ìpinnu pàtàkì mìíràn, irú bíi ṣíṣe ìgbéyàwó.
Ká sọ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan nínú Bíbélì ń tẹ̀ síwájú dáadáa, ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kí Kristẹni kan bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ ládèéhùn pé òun á fẹ́ ẹ, bóyá kó wá ní in lọ́kàn pé òun máa ní sùúrù kí onítọ̀hún ṣe ìrìbọmi kí wọ́n sì wá jọ ṣe ìgbéyàwó? Kò bọ́gbọ́n mu. Ohun tó mú kí ẹnì kan máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè má ṣe kedere sí i mọ́, tó bá mọ̀ pé Kristẹni kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ ń gbèrò láti fẹ́ òun, tó sì mọ̀ pé kò ní fẹ́ òun láìjẹ́ pé òun ṣe ìrìbọmi.
Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó jẹ́ akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi ni kì í pẹ́ púpọ̀ kí wọ́n tó ṣe ìrìbọmi. Nítorí náà, ìmọ̀ràn tó mọ́gbọ́n dání ni ìmọ̀ràn tó wà lókè yìí tó ní ká ṣe ìgbéyàwó kìkì nínú Olúwa. Àmọ́, ká wá sọ pé ẹnì kan tó ti tóó ṣègbéyàwó, tó jẹ́ pé àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ló tọ́ ọ dàgbà, tó ti ń ṣe déédéé nínú ìjọ fún ọ̀pọ̀ ọdún, tó sì jẹ́ pé akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi ni ńkọ́? Ọ̀rọ̀ nìyẹn, àmọ́ kí ló ti ń dí onítọ̀hún lọ́wọ́ tí kò fi tíì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ láti fi ìgbésí ayé ara rẹ̀ fún Jèhófà? Kí nìdí tó fi ń lọ́ tìkọ̀? Ṣé ó ń ṣiyèméjì ni? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe aláìgbàgbọ́, síbẹ̀ náà, a ò lè sọ pé ó wà “nínú Olúwa.”
Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fúnni lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó jẹ́ fún àǹfààní wa. (Aísáyà 48:17) Tí àwọn méjì tó jọ ní àdéhùn fífẹ́ ara wọn bá ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, èyí á mú kí gbígbà tí àwọn méjèèjì gbà láti fẹ́ra wọn wà lórí ìpìlẹ̀ tẹ̀mí tó le dáadáa. Ohun kan náà làwọn méjèèjì nífẹ̀ẹ́ sí, tí wọ́n sì ń lépa. Èyí máa ń pa kún ayọ̀ ìgbéyàwó. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ṣíṣe tẹ́nì kan bá ‘ṣe ìgbéyàwó kìkì nínú Olúwa’ fi hàn pé onítọ̀hún jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, yóò sì jẹ́ kó rí ìbùkún tó wà pẹ́ títí, nítorí pé “[Jèhófà] yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.”—Sáàmù 18:25.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ kọ̀wé sí, jíjẹ́ ‘ẹrú nínú Olúwa’ kan fífi àmì òróró yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run àti arákùnrin Kristi.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
“[Jèhófà] yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.”