Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Yóò ha bójúmu fún Kristian kan láti da òwò pọ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ kan bí, níwọ̀n bí Bibeli ti sọ fún wa pé: “Ẹ máṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́”?
A rí ìmọ̀ràn yẹn ní 2 Korinti 6:14-16: “Ẹ máṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́: nítorí ìdàpọ̀ kí ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kí ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn? Ìrẹ́pọ̀ kí ni Kristi sì ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wo ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? Ìrẹ́pọ̀ kí ni tẹ́ḿpìlì Ọlọrun sì ní pẹ̀lú òrìṣà?”
Kò sí ìdí kankan láti gbàgbọ́ pé aposteli Paulu pèsè ìmọ̀ràn yìí pẹ̀lú èrò fífìdí àwọn ìkàléèwọ̀ pàtó múlẹ̀, bí irú èyí tí ó tako pé kí Kristian kan da òwò pọ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ kan. Síbẹ̀, ó dájú pé ìmọ̀ràn rẹ̀ jẹmọ́ ìyẹn, àti àwọn apá ọ̀nà ìgbésí-ayé mìíràn.
Paulu kọ ìmọ̀ràn yẹn sí àwọn Kristian arákùnrin rẹ̀ ní Korinti ìgbàanì. Bí wọ́n ti ń gbé inú ìlú kan tí ó kún fún ìwà-ìbàjẹ́ ní pàtàkì, wọ́n níláti wọ̀dìmú pẹ̀lú àwọn ewu ìwàrere àti ti ẹ̀mí lójoojúmọ́. Àyàfi bí wọ́n bá ṣọ́ra, ṣíṣíra sílẹ̀ sí àwọn agbára-ìdarí tí kò gbéniró lè fi kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ sọ ìpinnu wọn láti jẹ́ ènìyàn tí ó dáyàtọ̀ gédégédé, “ìran tí a yàn, olú-àlùfáà, orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀” di aláìlágbára.—1 Peteru 2:9.
Ṣáájú kí ó tó kọ ohun tí ó farahàn ní 2 Korinti 6:14-16, Paulu ti bójútó ìṣòro wíwúwo kan tí ó wà láàárín àwọn ará rẹ̀ ní Korinti. Wọ́n ti fààyè gba ọ̀ràn ìwà-pálapàla bíburújáì kan láti wà láàárín wọn, nítorí náà Paulu darí wọn láti lé ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronúpìwàdà náà jáde, tàbí yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. (1 Korinti 5:1) Ìwà-àìtọ́ ọkùnrin yẹn fihàn pé ẹgbẹ́ búburú tàbí ìkówọnú ipò ìwàrere ti ayé tí a kò ṣọ́rá fún lè nípa lórí àwọn Kristian.
Àwọn Kristian ní Korinti ni wọ́n níláti yẹra fún ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ọkùnrin tí a lé jáde náà, ṣùgbọ́n ìyẹn ha túmọ̀sí pé wọ́n níláti ya araawọn sọ́tọ̀ pátápátá kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ bí? Wọ́n ha níláti yẹra pátápátá fún gbogbo ìfarakanra tàbí ìbálò pẹ̀lú àwọn tí kìí ṣe Kristian, ní dídi irú ẹ̀ya-ìsìn anìkàndágbé kan, bí àwọn Ju tí wọ́n ṣí kúrò lọ sí Qumran lẹ́bàá Òkun Òkú bí? Ẹ jẹ́ kí Paulu dáhùn: “Èmi ti kọ̀wé sí yín nínú ìwé mi pé, kí ẹ máṣe bá àwọn àgbèrè kẹ́gbẹ́ pọ̀: ṣùgbọ́n kìí ṣe pẹ̀lú àwọn àgbèrè ayé yìí pátápátá . . . nítorí nígbà náà ẹ kò lè ṣàìmá ti ayé kúrò.”—1 Korinti 5:9, 10.
Ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀sí ṣe kedere. Paulu mọ̀ dájú pé àwọn Kristian ṣì wà lórí planẹti yìí síbẹ̀, tí wọ́n ń gbé láàárín àwọn aláìgbàgbọ́ tí ìwàrere wọn rẹlẹ̀ tí àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n wọn yàtọ̀, tí ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé lójoojúmọ́ ni wọ́n ń ní ìfarakanra pẹ̀lú wọn. Níwọ̀n ìgbà tí ìyẹn jẹ́ èyí tí a kò lè yẹra fún gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, àwọn Kristian níláti wà lójúfò sí ewu irú ìfarakanra bẹ́ẹ̀.
Nísinsìnyí ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò lẹ́tà kejì ti Paulu sí àwọn ará Korinti lẹ́ẹ̀kan síi. Ó ṣàlàyé pé àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró jẹ́ òjíṣẹ́ títóótun ti Ọlọrun, ikọ̀ tí ń ṣojú fún Kristi. Ó sọ fún wọn láti ṣọ́ra fún okùnfà fún ìkọ̀sẹ̀ èyíkéyìí tí ó lè fi iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn hàn lọ́nà òdì. (2 Korinti 4:1–6:3) Paulu rọ àwọn ará rẹ̀ ní Korinti, tí wọ́n dàbí ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí ní tààràtà, láti mú kí ìfẹ́ni wọn gbòòrò síi. (2 Korinti 6:13) Lẹ́yìn ìyẹn ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” Ó lo ọ̀wọ́ àwọn ìyàtọ̀ ìfiwéra ayíniléròpadà láti tẹnumọ́ kókó yẹn.
Àyíká-ọ̀rọ̀ náà fihàn pé kìí ṣe pé Paulu ń kó àfiyèsí jọ sórí àgbègbè ìgbésí-ayé pàtó kan, irú bí òwò tàbí ìgbanisíṣẹ́, tí ó sì ń fi ìlànà bí-àṣà tí a níláti fipá múni tẹ̀lé ní ọ̀nà yẹn lélẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun ń pèsè ìmọ̀ràn tí ó gbòòrò, tí ó yèkooro, tí ó sì lè ran àwọn arákùnrin rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n lọ́wọ́.
Ìmọ̀ràn yìí yóò ha ṣeé fisílò, fún àpẹẹrẹ, nínú ọ̀ràn ti Kristian kan tí ó ní ọkàn-ìfẹ́ nínú ìgbéyàwó bí? Dájúdájú. Nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, aposteli náà gba àwọn ará Korinti tí wọ́n fẹ́ láti ṣègbéyàwó nímọ̀ràn láti ṣe bẹ́ẹ̀ “kìkì nínú Oluwa.” (1 Korinti 7:39) Ó tẹnumọ́ ọgbọ́n tí ó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nípa ohun tí ó kọ lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ọ́ ní 2 Korinti 6:14-18. Bí Kristian kan bá níláti ní i lọ́kàn láti gbé ẹnìkan tí kìí ṣe ìráńṣẹ́ Jehofa tí kìí sìí ṣe ọmọlẹ́yìn Kristi níyàwó, òun lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin yóò máa ronú nípa dídi ẹni tí a sopọ̀ mọ́ aláìgbàgbọ́ kan. (Fiwé Lefitiku 19:19; Deuteronomi 22:10.) Ní kedere, àìbáradọ́gba náà tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ yóò mú àwọn ìṣòro wá, títíkan ìwọ̀nyí tí ó jẹ́ tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, aláìgbàgbọ́ náà lè lépa ìjọsìn ọlọ́run èké nísinsìnyí tàbí ní ọjọ́-iwájú. Paulu ronú pé: “Ìrẹ́pọ̀ kí ni Kristi sì ní pẹ̀lú Beliali?”
Kí ni, bí ó ti wù kí ó rí, nípa ìhà ọ̀nà ìgbésí-ayé mìíràn—dída òwò pọ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? Nínú àwọn ọ̀ràn kan Kristian kan lè nímọ̀lára pé wíwá ọ̀nà àtijẹ àti títọ́jú ìdílé rẹ̀ béèrè fún dídókòwò pọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan tí kìí ṣe Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni. (1 Timoteu 5:8) Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tí ó wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ lásán:
Kristian kan lè fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ajé títa irú ọjà kan, ṣùgbọ́n ọ̀nà kanṣoṣo tí ó wà yóò jẹ́ láti tẹ́wọ́gba àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kan tí ó lómìnira àtidé ibi tí ẹrù-ọjà tàbí owó-àkànlò tí a nílò wà. Kristian mìíràn fẹ́ láti dáko (tàbí sin irú ohun ọ̀sìn kan); ṣùgbọ́n kò sí ilẹ̀ lárọ̀ọ́wọ́tó, nítorí náà òun yóò níláti ṣe é papọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan tí ó múratán láti fún un ní ilẹ̀ tí yóò sì máa ṣàjọpín èrè èyíkéyìí pẹ̀lú rẹ̀. Bóyá kò ṣeéṣe fún Kristian mìíràn kan láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ajé omi-ẹ̀rọ nítorí pé Kesari fọwọ́sí kìkì ìwọ̀nba ìwé-àṣẹ, tí a sì ti gbà wọ́n tán; ọ̀nà kanṣoṣo yóò jẹ́ fún un láti darapọ̀ mọ́ ìbátan aláìgbàgbọ́ kan tí ó ní ìwé-àṣẹ lọ́wọ́.—Marku 12:17.
Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ àkàwé lásán. Kìí ṣe pé a ń gbìyànjú láti mẹ́nukan gbogbo ṣíṣeéṣe tí ó wà, bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe pé a ń sọ gbólóhùn-ọ̀rọ̀ ìtẹ́wọ́gbà tàbí àìtẹ́wọ́gbà èyíkéyìí. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí ní ọkàn, ìwọ kò ha lè rí ìdí tí a kò fi níláti ṣàìnáání ìmọ̀ràn tí ó wà ní 2 Korinti 6:14-18 bí?
Kristian kan tí ó da òwò pọ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ kan, yálà ó jẹ́ ìbátan tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, ni òun pẹ̀lú lè ṣalábàápàdé àwọn ìṣòro àti àdánwò tí a kò retí tẹ́lẹ̀. Bóyá ẹnìkejì náà parí-èrò pé ọ̀nà láti gbà jèrè tí ó pójú owó ni láti máṣe kọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye owó tí ń wọlé tàbí láti máṣe kọ àkọsílẹ̀ kan tí a béèrè fún nípa àwọn òṣìṣẹ́ àti iye tí wọ́n ń gbà, àní bí ìyẹn bá tilẹ̀ tàpá sí àwọn ìlànà ìjọba. Inú rẹ̀ lè dùn láti sanwó bìrìbìrì fún àwọn tí ń kọ́jà wá fún àwọn ọjà tí a kò kọ sórí ìwé ìsanwó tí a fàṣẹsí. Kristian kan yóò ha kópa nínú ìyẹn tàbí nínú àbòsí mìíràn tí ó fara pẹ́ ìyẹn bí? Kí sì ni Kristian náà yóò ṣe nígbà tí àkókò bá tó fún awọn méjèèjì láti fọwọ́sí àwọn ìwé owó-orí tàbí àwọn ìwé tí ó bá òfin mu mìíràn nípa bí wọ́n ṣe ń ṣòwò wọn?—Eksodu 23:1; Romu 13:1, 7.
Tàbí alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ nínú iṣẹ́-ajé tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́ náà lè fẹ́ láti ra àwọn ọjà tí ó tan mọ́ ọlidé àwọn abọ̀rìṣà, fi àwọn káàdì ọlidé ránṣẹ́ ní orúkọ ilé-iṣẹ́ náà, kí ó sì ṣe ibi iṣẹ́-ajé náà lọ́ṣọ̀ọ́ fún àwọn ọlidé ìsìn. Paulu béèrè pé: “Ìrẹ́pọ̀ kí ni tẹ́ḿpìlì Ọlọrun sì ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ni tẹ́ḿpìlì Ọlọrun alààyè.” Ọ̀rọ̀ náà ti ṣe wẹ́kú tó: “Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sí ọ̀tọ̀, ni Oluwa wí, kí ẹ máṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́; èmi ó sì gbà yín”! (2 Korinti 6:16, 17) Ní fífi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yẹn sílò, ọ̀pọ̀ àwọn Kristian, dé ibi tí ó ṣeéṣe ti yan irú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí yóò ṣí wọn payá sí ìṣòro tí kò tó nǹkan tí ó ṣeéṣe kí ó dìde.—Heberu 13:5, 6, 18.
Ìjọ ni a kò pàṣẹ fún láti máa kíyèsí tàbí wádìí gbogbo ohun tí àwọn Kristian ń ṣe nínú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, yálà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbà síṣẹ́ tàbí gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ni iṣẹ́-ajé. Nítòótọ́, bí ó bá di mímọ̀ pé Kristian kan jẹ́ alẹ̀dí-àpò-pọ̀ fún ìwà-àìtọ́, irú bíi gbígbé ìjọsìn èké tàbí irú irọ́ pípa tàbí olè jíjà kan lárugẹ, ìjọ yóò níláti gbé ìgbésẹ̀ láti di àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Jehofa mú.
Kókó pàtàkì náà, bí ó ti wù kí ó rí, ni pé ìmọ̀ràn Paulu tí a mísí, “Ẹ máṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́,” lè ran àwọn Kristian lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ìṣòro àti ìgbésẹ̀ ìdájọ́ èyíkéyìí tí a nílò. Àwọn Kristian ọlọgbọ́n yóò fi ìmọ̀ràn yẹn sọ́kàn tí wọn kò sì ní yàn láti kówọnú àwọn ipò níbi tí wọn yóò ti wà lábẹ́ àfikún ìkìmọ́lẹ̀ láti fi àwọn ìlànà Bibeli bánidọ́rẹ̀ẹ́. Bí ẹnìkan bá nímọ̀lára pé òun gbọ́dọ̀ da òwò pọ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́, àwọn yòókù kò níláti yára láti ṣèdájọ́ tàbí ṣe lámèyítọ́ rẹ̀, ní mímọ̀ dájú pé òun yóò níláti dáhùn fún yíyàn rẹ̀. Ní pàtàkì, kìí ṣe pé Paulu ń fi ìlànà bí-àṣà, tí ó ṣeé fipá múni tẹ̀lé ìlòdìsí dída òwò pọ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ lélẹ̀. Síbẹ̀, ìmọ̀ràn rẹ̀ ni a kò níláti patì. Ọlọrun ni ó mísí ìmọ̀ràn yẹn ó sì jẹ́ kí á ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Bibeli fún àǹfààní wa. A jẹ́ ọlọgbọ́n láti kọbiara sí i.