ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/10 ojú ìwé 5-6
  • Báwo Lo Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Ọkọ Tàbí Aya Tó Jẹ́ Aláìgbàgbọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Lo Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Ọkọ Tàbí Aya Tó Jẹ́ Aláìgbàgbọ́?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Tó Wà Nínú Ìdílé Tí Wọ́n Ti Ń Ṣe Ẹ̀sìn Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Lè Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Idà Ni Òtítọ́ Ń Mú Wá, Kì Í Ṣe Àlàáfíà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Ẹ Sapá Gidigidi Láti Wàásù Fáwọn Ọkùnrin
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 11/10 ojú ìwé 5-6

Báwo Lo Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Ọkọ Tàbí Aya Tó Jẹ́ Aláìgbàgbọ́?

1. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe àwọn Kristẹni tí ọkọ tàbí aya wọn jẹ́ aláìgbàgbọ́ nìkan ló fẹ́ kí aláìgbàgbọ́ náà tẹ́wọ́ gba òtítọ́?

1 Ǹjẹ́ àwọn akéde kan wà nínú ìjọ yín tí ọkọ tàbí aya wọn jẹ́ aláìgbàgbọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé àwọn akéde náà á fẹ́ kí ọkọ tàbí aya wọn dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ẹ̀sìn tòótọ́. Àmọ́ kì í ṣe àwọn nìkan ló ń fẹ́ kí aláìgbàgbọ́ náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” ohun tó sì wu gbogbo ìjọ náà nìyẹn. (1 Tím. 2:4) Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìgbàgbọ́ tí ọkọ tàbí aya wọn jẹ́ àkéde ìjọ wa?

2. Báwo ni ìjìnlẹ̀ òye ṣe máa jẹ́ ká lè ṣèrànwọ́ fún ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́?

2 Ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ni pé ká gbìyànjú láti fi ojú tí aláìgbàgbọ́ náà fi ń wo ọ̀ràn wò ó. Ọ̀pọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ yìí nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn, wọ́n sì máa ń gbìyànjú láti jẹ́ ọkọ tàbí aya àti òbí rere, àmọ́ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yàtọ̀ sí tiwa, ó sì lè jẹ́ pé tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń ṣe ẹ̀sìn wọn. Bóyá ìwọ̀nba ohun tí wọ́n mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ju ohun tí wọ́n gbọ́ lẹ́nu àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ wá tàbí àwọn ẹlẹ́tanú. Ó máa ń bí àwọn aláìgbàgbọ́ kan nínú pé ọkọ tàbí aya wọn ń lo àkókò tí wọ́n fi jọ máa ń wà pa pọ̀ nínú ìdílé tẹ́lẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Tá a bá ní ìjìnlẹ̀ òye, èyí á jẹ́ ká lè máa fi inú rere àti ọ̀wọ̀ bá ẹni tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ lò, á jẹ́ kí ara wa yọ̀ mọ́ wọn, a ò sì ní máa sára fún wọn.—Òwe 16:20-23.

3. Ọ̀nà wo ló dáa jù tá a lè gbà ran aláìgbàgbọ́ kan lọ́wọ́ kó lè nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́?

3 Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Wọn Jẹ Ọ́ Lógún: Tá a bá fẹ́ kí ọkọ tàbí aya kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, kò dìgbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìjíròrò Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwà wa la máa kọ́kọ́ fi fà á lọ́kàn mọ́ra. (1 Pét. 3:1, 2) Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà ṣe èyí ni pé ká máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún. Àwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ lè sún mọ́ aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, àwọn arákùnrin sì lè ṣe bákan náà sí ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

4. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ jẹ wá lógún?

4 Bí o kò bá tíì mọ aláìgbàgbọ́ náà, o lè ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, àmọ́ kó o sọ fún ọkọ tàbí aya rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni kó o tó ṣe bẹ́ẹ̀. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹni náà kò kọ́kọ́ dáhùn pa dà lọ́nà tó dáa, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Tá a bá mú ẹni náà lọ́rẹ̀ẹ́ tá a sì jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ wá lógún, èyí lè jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú tó dáa wo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Róòmù 12:20) Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí ti pe ẹni tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ àti ìdílé rẹ̀ láti wá jẹun nílé wọn kí wọ́n bàa lè mú ìdílé náà lọ́rẹ̀ẹ́ kí wọ́n sì lè mú ẹ̀tanú èyíkéyìí tó ṣeé ṣe kó wà lọ́kàn rẹ̀ kúrò. Nígbà tí wọ́n bá jọ ń jẹun, ohun tí aláìgbàgbọ́ náà nífẹ̀ẹ́ sí ni wọ́n máa ń jíròrò dípò kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Nígbà tí wọ́n bá sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í mọwọ́ ara wọn, ìjíròrò Bíbélì lè tẹ̀ lé e. Aláìgbàgbọ́ náà sì lè gbà láti wá sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé wa kó lè wá mọ ẹ̀kọ́ tí ìyàwó rẹ̀ ń kọ́, pàápàá lẹ́yìn tó ti mọ àwọn kan nínú ìjọ. Bí kò bá tiẹ̀ tíì nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, ó yẹ ká gbóríyìn fún un nítorí bó ṣe ń ti ọkọ tàbí aya rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni lẹ́yìn.

5. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè ran aláìgbàgbọ́ kan lọ́wọ́?

5 Àwọn alàgbà ló gbọ́dọ̀ mú ipò iwájú láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, kí wọ́n sì wá ọ̀nà láti jẹ́rìí fún wọn. Aláìgbàgbọ́ kan tí kì í fetí sílẹ̀ sí ìjíròrò Bíbélì lè wá fetí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fún un ní ìṣírí látinú Bíbélì lásìkò tó ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn tàbí tó bá ń ṣàìsàn tó le gan-an. Bí ìṣòro ńlá kan bá ń bá wọn fínra nínú ìdílé tí ọkọ àti aya ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, bóyá ńṣe ni ẹnì kan kú nínú ìdílé wọn, àwọn alàgbà lè ṣètò pé kí ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ náà wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fún ìdílé náà.

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká wá bá a ṣe máa ṣèrànwọ́ fún àwọn ọkọ tàbí aya tí kì í ṣe onígbàgbọ́?

6 Ẹ wo bí ayọ̀ Kristẹni kan nínú ìjọ wa ṣe máa pọ̀ tó, bí ọkọ tàbí aya rẹ̀ bá dẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́! Kì í ṣe inú Kristẹni yìí nìkan ló máa dùn o, ìdùnnú ńlá ló tún máa jẹ́ fún Jèhófà, àwọn ańgẹ́lì àtàwọn tó kù nínú ìjọ. (Lúùkù 15:7, 10) Àmọ́, bó bá ṣẹlẹ̀ pé aláìgbàgbọ́ náà kò tíì fetí sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, a ṣì lè máa yọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa bá a ṣe ń sapá, torí pé Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—2 Pét. 3:9.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Tá a bá fẹ́ kí ọkọ tàbí aya kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, kò dìgbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìjíròrò Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwà wa la máa kọ́kọ́ fi fà á lọ́kàn mọ́ra

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́