Ẹ Sapá Gidigidi Láti Wàásù Fáwọn Ọkùnrin
1. Àìní kánjúkánjú wo ló wà báyìí láti bójú tó ọ̀ràn nípa Ìjọba Ọlọ́run?
1 Bí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù ṣe ń gbilẹ̀ sí i láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, a túbọ̀ nílò àwọn ọkùnrin tó tóótun nípa tẹ̀mí ní kánjúkánjú, láti máa múpò iwájú. (Máàkù 4:30-32; Ìṣe 20:28; 1 Tím. 3:1-13) Síbẹ̀, láwọn ibì kan, àwọn obìnrin tó ń gbọ́ ìwàásù wa pọ̀ ju àwọn ọkùnrin lọ. Àwọn kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé àṣà ìbílẹ̀ wọn gba pé kí wọ́n fa ohun tó bá jẹ mọ́ ọ̀ràn ẹ̀sìn àti kíkọ́ àwọn ọmọ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé ìyàwó wọn lọ́wọ́. Báwo la ṣe lè jẹ́ káwọn ọkùnrin tó pọ̀ sí i fẹ́ láti tẹ́ àìní wọn nípa tẹ̀mí lọ́rùn, kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn tòótọ́?
2. Báwo ni ìsapá Pọ́ọ̀lù àti Pétérù láti jẹ́rìí fáwọn ọkùnrin ṣe sèso rere?
2 Ẹ Wá Àwọn Ọkùnrin Kàn: Bí olórí ìdílé kan bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sábà máa ń ran àwọn tó kù nínú ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ìjọsìn mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n ju Pọ́ọ̀lù àti Sílà sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ń wàásù, wọ́n jẹ́rìí fún onítúbú kan. Ọkùnrin náà àti gbogbo agboolé rẹ̀ sì ṣèrìbọmi. (Ìṣe 16:25-34) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wàásù ní Kọ́ríńtì, “Kírípọ́sì tí ó jẹ́ alága sínágọ́gù di onígbàgbọ́ nínú Olúwa, bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo agbo ilé rẹ̀.” (Ìṣe 18:8) Jèhófà lo Pétérù láti jẹ́rìí fún Kọ̀nílíù, ọ̀gá àwọn ọmọ ogun tí Bíbélì ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “olùfọkànsìn àti ẹnì kan tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run.” Kọ̀nílíù pẹ̀lú àwọn ìbátan rẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ sì ṣèrìbọmi.—Ìṣe 10:1-48.
3. Tó o bá fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Fílípì, àwọn tó wà “ní ipò gíga” wo lo lè wàásù fún?
3 Bá a bá jẹ́rìí fáwọn ọkùnrin tó wà “ní ipò gíga,” àǹfààní tó pọ̀ lè tibẹ̀ wá. (1 Tím. 2:1, 2) Bí àpẹẹrẹ, áńgẹ́lì Jèhófà gba Fílípì nímọ̀ràn pé kó bá “ọkùnrin kan tí ó wà ní ipò agbára,” tó ń bójú tó gbogbo ìṣúra ọbabìnrin àwọn ará Etiópíà sọ̀rọ̀. Fílípì gbọ́ tọ́kùnrin náà “ń ka ìwé wòlíì Aísáyà sókè,” ó sì ṣàlàyé ìhìn rere nípa Jésù fún un. Ará Etiópíà yìí di ọmọ ẹ̀yìn, ó sì ṣeé ṣe kó máa wàásù ìhìn rere bó ṣe ń pa dà lọ sílùú ẹ̀. Ó ṣeé ṣé kó tún wàásù fún ọbabìnrin àtàwọn tó wà ní àgbàlá rẹ̀, àwọn tó jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n máà láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere.—Ìṣe 8:26-39.
4. Báwo la ṣe lè jẹ́ káwọn ọkùnrin púpọ̀ sí i gbọ́ ìhìn rere?
4 Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Wàásù Fáwọn Ọkùnrin Púpọ̀ Sí I: Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ọkùnrin sábà máa ń wà lẹ́nu iṣẹ́ lọ́sàn-án, ṣó o lè ṣètò láti lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ nírọ̀lẹ́, lópin ọ̀sẹ̀ tàbí nígbà ọlidé? Bó o bá ń wàásù déédéé lágbègbè tílé ìtajà pọ̀ sí, wàá lè wàásù fáwọn ọkùnrin tí kì í sábàá sí nílé. Àwọn arákùnrin tún lè sapá gidigidi láti jẹ́rìí fáwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, nígbà tẹ́ ẹ bá ń wàásù láti ilé dé ilé, pàápàá láwọn ìpínlẹ̀ tẹ́ ẹ ti máa ń wàásù déédéé, àwọn arákùnrin lè sọ pé baálé ilé làwọn fẹ́ bá sọ̀rọ̀.
5. Kí ló yẹ kí arábìnrin kan ṣe bí ọkùnrin tó wàásù fún bá fìfẹ́ hàn sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?
5 Bí arábìnrin kan bá wàásù fún ọkùnrin kan, tọ́kùnrin náà sì fìfẹ́ hàn, kí arábìnrin náà má ṣe dá nìkan pa dà lọ síbẹ̀. Òun àti ọkọ ẹ̀ lè jọ pa dà lọ síbẹ̀ tàbí kó lọ pẹ̀lú akéde míì. Bí ọkùnrin náà bá ti ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ohun tó máa dáa jù lọ ni pé kó fa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lé arákùnrin kan tó tóótun lọ́wọ́.
6. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ká lè “jèrè àwọn ènìyàn púpọ̀ jù lọ”?
6 Lo Àwọn Kókó Ọ̀rọ̀ Táwọn Ọkùnrin Nífẹ̀ẹ́ Sí: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń ronú nípa àwọn tó fẹ́ bá sọ̀rọ̀ kó lè mọ bó ṣe máa gbọ́rọ̀ ẹ̀ kalẹ̀, kó bàa lè “jèrè àwọn ènìyàn púpọ̀ jù lọ.” (1 Kọ́r. 9: 19-23) Bákan náà, ó yẹ ká múra sílẹ̀ láti sọ àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó ṣeé ṣe káwọn ọkùnrin tá a bá bá pàdé fẹ́ láti gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, lára àwọn ohun tó máa ń jẹ àwọn ọkùnrin lógún ni ìṣòro ọrọ̀ ajé, ìjọba rere àti bí wọ́n á ṣe máa bójú tó ọ̀ràn ààbò àti àlàáfíà ìdílé wọn. Wọ́n tún lè fẹ́ mọ̀ nípa ète ìgbésí ayé, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú àti ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà. Tá a bá ń lo irú òye báyìí nígbà tá a bá ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn, wọ́n á túbọ̀ máa fetí sọ́rọ̀ wa.—Òwe16:23.
7. Báwo ni gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ṣe lè nípa rere lórí ọkọ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tó wá sípàdé?
7 Ran Àwọn Ọkọ Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Lọ́wọ́: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwà rere àwọn Kristẹni arábìnrin wa ló sábà máa ń nípa tó pọ̀ jù lórí àwọn ọkọ wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, àwọn ará ìjọ tún lè nípa tó dáa lórí wọn. (1 Pét. 3:1-4) Bí ọkọ kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá tẹ̀ lé ìyàwó ẹ̀ wá sípàdé, bá a bá fọ̀yàyà kí i, ìyẹn lè wàásù fún un ju ọ̀rọ̀ ẹnu wa lọ. Wíwá tó wá sípàdé fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ dé ìwọ̀n àyè kan, ó sì ṣeé ṣe kó fẹ́ ká kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
8. Báwo làwọn arákùnrin ṣe lè ran àwọn ọkọ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, tí wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, lọ́wọ́?
8 Nígbà míì, ó lè máà kọ́kọ́ fi bẹ́ẹ̀ wu àwọn ọkọ kan láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́ ní kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀, wọ́n lè fẹ́ láti jíròrò ohun tó wà nínú Bíbélì pẹ̀lú arákùnrin kan tí wọ́n jọ mọwọ́ ara wọn. Nínú ìjọ kan, àwọn arákùnrin kan máa ń lọ kí ìdílé kan tí ẹ̀sìn wọn ò jọra, wọ́n sì máa ń bá baálé ilé náà sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ sí. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ tó dá lórí Bíbélì, ọkùnrin náà sì ti ṣèrìbọmi báyìí. Níbòmíì, arákùnrin kan bá ọkọ kan tó lọ́yàyà, àmọ́ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, kọ́ ọgbà yíká ilé ẹ̀. Torí bí arákùnrin yẹn ṣe fìfẹ́ hàn sí ọkùnrin yìí, ó gbà kó máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Gál. 6:10; Fílí. 2:4) Bó o bá jẹ́ arákùnrin, o ò ṣe gbìyànjú láti kàn sí ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ọkọ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí?
9. Kí làwọn ọkùnrin tá a bá dá lẹ́kọ̀ọ́ lè gbé ṣe lọ́jọ́ iwájú?
9 Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Wúlò Lọ́jọ́ Iwájú: Àwọn ọkùnrin tó bá fetí sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń sapá láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọsìn Jèhófà lè wá dẹni tó wà lára àwọn “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” ìyẹn àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni tí wọ́n ń lo okun àti agbára wọn láti ran ìjọ àwọn èèyàn Jèhófà lọ́wọ́. (Éfé. 4:8; Sm. 68:18) Tọkàntọkàn àti pẹ̀lú ìháragàgà làwọn ọkùnrin wọ̀nyí fi ń yọ̀ǹda ara wọn láti bójú tó ìjọ. (1 Pét. 5:2, 3) Ìbùkún ńlá mà làwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn jẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé o!
10. Báwo lọ̀pọ̀ èèyàn ṣe jàǹfààní látinú ìsapá Ananíà láti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́?
10 Bí àpẹẹrẹ, Sọ́ọ̀lù di àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni tẹ́lẹ̀. (Róòmù 11:13) Èyí ló mú kí Ananíà kọ́kọ́ lọ́ tìkọ̀ láti wàásù fún un. Síbẹ̀, Ananíà tẹ̀ lé ìtọ́ni Olúwa, ó sì bá Sọ́ọ̀lù, tá a wá mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, sọ̀rọ̀. Fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára àwọn tó gbọ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù fi jàǹfààní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, títí kan àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ṣì ń jàǹfààní nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Ìṣe 9:3-19; 2 Tím. 3: 16, 17.
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe ìyípadà tó bá pọn dandan ká bàa lè wàásù fáwọn ọkùnrin?
11 Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa ṣe ìyípadà tó bá pọn dandan ká lè máa wàásù fáwọn ọkùnrin. Bá a bá fi ṣe góńgó wa, ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ tá a sì ń bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run dáadáa.