Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jésù Ṣóòótọ́ Ni Àbí Ìtàn Àròsọ?
“ÀWỌN ènìyàn mú ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di òǹdè wá sọ́dọ̀ rẹ̀ [Jésù Kristi]; òun sì fi ọ̀rọ̀ lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì wo gbogbo àwọn tí nǹkan kò sàn fún sàn.” (Mátíù 8:16) “Ó [Jésù] gbéra nílẹ̀, ó sì bá ẹ̀fúùfù náà wí lọ́nà mímúná, ó sì wí fún òkun náà pé: ‘Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!’ Ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀, ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.” (Máàkù 4:39) Báwo lo ṣe rí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sí ná? Ǹjẹ́ o gbà pé òótọ́ làwọn nǹkan wọ̀nyẹn ṣẹlẹ̀ àbí o rò pé ìtàn àròsọ lásán ni wọ́n?
Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣiyèméjì pé bóya ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jóòótọ́. Ìtẹ̀síwájú téèyàn ti ní nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, irú bíi àmújáde awò tá a fi ń wo ọ̀nà jíjìn àtèyí tó ń sọ ohun kékeré di ńlá, ṣíṣe àwárí àwọn ohun tí ń bẹ ní gbalasa òfuurufú àti ìmọ̀ nípa yíyí apilẹ̀ àbùdá pa dà, kì í jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ gba ìròyìn nípa iṣẹ́ ìyanu gbọ́ títí kan ìròyìn nípa iṣẹ́ àrà tó ju agbára ẹ̀dá lọ.
Àwọn kan gbà pé ìtàn iṣẹ́ ìyanu kì í ṣe ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi, wọ́n ní ìtàn àròsọ ni. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí òǹkọ̀wé kan sọ, ìyẹn ẹni tó kọ ìwé tí wọ́n ní ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa “ẹni náà gan-an” tí Jésù jẹ́, ó sọ pé ohun tí wọ́n wúlẹ̀ fi ìtàn iṣẹ́ ìyanu Kristi ṣe kò ju láti “polówó” ẹ̀sìn Kristẹni kó lè túbọ̀ gbilẹ̀ sí i.
Àwọn kan ka àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe sí wàyó. Kódà, wọ́n máa ń pé Jésù ní ẹlẹ̀tàn nígbà míì. Justin Martyr tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa sọ pé àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ Jésù “tiẹ̀ pè é ní onídán àti ẹni tó ń tan àwọn èèyàn jẹ.” Àwọn kan gbà pé Jésù “kò ṣe iṣẹ́ ìyanu bí ọ̀kan lára àwọn wòlíì Júù, àmọ́ pé ó ṣe é gẹ́gẹ́ bí onídán tó kọ́ṣẹ́ ní tẹ́ńpìlì àwọn abọgibọ̀pẹ.”
Àlàyé Nípa Ohun Tí Wọ́n Sọ Pé Kò Ṣeé Ṣe
O lè máa rò pé báwọn èèyàn ṣe ń ṣiyèméjì yẹn fi hàn pé ìdí pàtàkì kan wà táwọn èèyàn kan fi ń lọ́ tìkọ̀ láti gbà pé iṣẹ́ ìyanu ṣeé ṣe. Láti gbà pé agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ lè ṣe irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìṣòro fún wọn, àní kò tiẹ̀ ṣeé ṣe fún wọn láti gbà ni. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó lóun gbà pé Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀ sọ pé: “Iṣẹ́ ìyanu kankan ò ṣẹlẹ̀ rí.” Lẹ́yìn náà ló wá fa ọ̀rọ̀ David Hume ọmọ ilẹ̀ Scotland nì, tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí ní ọ̀rúndún kejìdínlógún yọ, ẹni tó kọ̀wé pé: “Iṣẹ́ ìyanu kò bá ìlànà bí nǹkan ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ látọjọ́ táláyé ti dáyé mu.”
Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò ní fẹ́ sọ pé nǹkan kan wà tí ò lè ṣeé ṣé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé iṣẹ́ ìyanu jẹ́ “ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí a kò lè fi ìlànà bí àwọn nǹkan ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ látọjọ́ táláyé ti dáyé ṣàlàyé rẹ̀.” Tá a bá fi ojú àlàyé yẹn wo ọ̀ràn náà, ńṣe ni ìrìn àjò ní òfuurufú, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ láìlo wáyà àti fífi sátẹ́láìtì rin ìrìn àjò lójú ọ̀run yóò dà bí “iṣẹ́ ìyanu” lójú ọ̀pọ̀ èèyàn tó gbé ayé ní ohun tí ò ju ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Dájúdájú, kò bọ́gbọ́n mu láti sọ pé iṣẹ́ ìyanu kò lè ṣeé ṣe kìkì nítorí pé ibi tí òye wa mọ nísinsìnyí kò lè jẹ́ ká ṣàlàyé rẹ̀.
Tá a bá gbé ẹ̀rí bíi mélòó kan yẹ̀ wò nínú Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa iṣẹ́ ìyanu tí Jésù Kristi ṣe, kí ni àyẹ̀wò ọ̀hún máa gbé jáde? Ṣóòótọ́ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe àbí ìtàn àròsọ ni wọ́n?