Kí Ló Ń mú Kí Ayé Ẹni Dára?
NÍGBÀ tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jesse, ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún tó sì wà nílé ẹ̀kọ́ girama pé kí lèèyàn wà láyé fún, ó dáhùn pé: “Nígbà tí ẹ̀mí èèyàn bá ṣì wà, kéèyàn jayé orí ẹ̀ dáadáa.” Àmọ́ èrò ti Suzie yàtọ̀ o. Ó sọ pé: “Ó dá mi lójú gan-an pé ohun tó ń mú káyé ẹnì dáa sinmi lórí ohun téèyàn bá fayé rẹ̀ ṣe.”
Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú rí nípa idi tá a fi wà láyé? Ǹjẹ́ ohun pàtó kan wà tó kan gbogbo aráyé lápapọ̀? Àbí Suzie tọ̀nà nígbà tó sọ pé ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bá fi ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe ló jà jù? Bó ti wù kí àwùjọ wa gòkè àgbà tó ní ti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, a ṣì máa ń fẹ́ mọ ìdí tá a fi wà láyé. Àkókò kan máa ń wà nígbèésí ayé wa tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa máa ń béèrè pé, ‘Kí nídìí tá a fi wà láàyè?’
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ti gbìyànjú láti dáhùn ìbéèrè yẹn. Kí wá ni ìdáhùn wọn? David P. Barash, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ nípa ìrònú òun ìhùwà àti ẹ̀kọ́ nípa ẹranko sọ pé: “Kò sóhun kan gbòógì nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó ṣàlàyé ìdí tá a fi wà láàyè.” Ní ti àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè tó dá lórí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ìdí kan ṣoṣo ni wọ́n gbà pé àwọn ohun abẹ̀mí torí ẹ̀ wà. Ìdí náà ni pé kí wọ́n mú irú wọn jáde. Èyí ló mú kí Ọ̀jọ̀gbọ́n Barash sọ pé: “Nínú ayé tó lọ salalu, tó kàn wà ṣáá, tí ò sì bìkítà nípa èèyàn, ọwọ́ àwa ẹ̀dá èèyàn ló wà láti mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀ nípa ṣíṣe àwọn ìpinnu tó yé wa yékéyéké, tá a sì mọ ìdí tá a fi ṣe wọn.”
Ẹni Tó Ń Mú Kí Ayé Ẹni Nítumọ̀
Nígbà náà, ṣé gbogbo ohun tá a wà láàyè fún ni pé kí kálukú kàn máa ṣe ohun tó bá wù ú? Dípò ká máa táràrà kiri nínú ayé tó kàn wà ṣáá, tí kò ní ìtumọ̀ kankan, ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti jẹ́ ká mọ̀ pé ó nídìí tá a fi wà láàyè. Àwa ẹ̀dá èèyàn ò ṣèèṣì wà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó gba Ẹlẹ́dàá ní àìlóǹkà ọdún láti ṣètò ilé ayé yìí sílẹ̀ de èèyàn. Kò sí ohun kankan tó jẹ́ pé ńṣe ló ṣèèṣì wà. Ọlọ́run rí i dájú pé gbogbo ohun tí òun ṣe ló “dára gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31; Aísáyà 45:18) Nítorí kí ni? Nítorí pé ó nídìí tí Ọlọ́run fi dá èèyàn.
Síbẹ̀, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Ọlọ́run kò kádàrá ọjọ́ ọ̀la ẹnì kankan, yálà nípa àkọọ́lẹ̀ àtọ̀runwá tàbí nípa àbùdá onítọ̀hún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tá a jogún máa ń nípa lórí wa, ọwọ́ wa lèyí tó pọ̀ jù wà láti ṣàkóso àwọn ìṣesí wa. Gbogbo wa la lómìnira láti yan ọ̀nà tá a fẹ́ gbà gbé ìgbésí ayé wa.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ kálukú wa ló wà láti yan ohun tó máa fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, àṣìṣe pátápátá ni yóò jẹ́ tá a bá lọ yọ Ẹlẹ́dàá kúrò nínú àwọn ohun tá a fẹ́ gbé ṣe. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ti rí i pé láìní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, èèyàn ò lè gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ kankan tàbí ìgbésí ayé tó ní láárí. Ìsopọ̀ pàtàkì tó wà láàárín Ọlọ́run àti ìdí tá a fi wà láàyè hàn nínú orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, èyí tó túmọ̀ ní ṣáńgílítí sí, “Alèwílèṣe.” (Ẹ́kísódù 6:3; Sáàmù 83:18) Ìyẹn ni pé, ó máa ń mú ìlérí yòówù tó bá ṣe ṣẹ ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀-lé, ó sì máa ń ṣàṣeparí ohunkóhun tó bá ní lọ́kàn láti ṣe. (Ẹ́kísódù 3:14; Aísáyà 55:10, 11) Ronú lórí bí orúkọ yẹn ṣe ṣe pàtàkì tó. Orúkọ náà, Jèhófà, jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú fún gbogbo wa pé Ọlọ́run ni Ẹni tó wà títí lọ kánrin tí ń mú kí ìgbésí ayé ẹni nítumọ̀.
Gbígbà téèyàn bá kàn tiẹ̀ gbà pé Ẹlẹ́dàá wà máa ń nípa tó lágbára lórí ojú téèyàn fi ń wo ìgbésí ayé. Linet tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún sọ pé: “Bí mo ṣe ń wo gbogbo nǹkan dáradára tí Jèhófà dá àti ìdí tó fi dá wọn máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé ó nídìí tí Ọlọ́run fi dá èmi náà.” Amber náà sọ pé: “Nígbà táwọn kan bá ń sọ pé ‘àwọn ò mọ̀ bóyá Ọlọ́run wà,’ mo máa ń kún fún ọpẹ́ nítorí mo mọ̀ pé ó wà. Àwọn nǹkan tí Jèhófà dá ti tó ẹ̀rí lọ́tọ̀ pé ó wà.” (Róòmù 1:20) Àmọ́ o, ọ̀tọ̀ ni kéèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wà, ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn ní àjọṣe tó nítumọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
Bíbá Ọlọ́run Dọ́rẹ̀ẹ́
Níbi tá a dé yìí náà, Bíbélì lè ṣèrànwọ́. Àwọn orí tó ṣáájú nínú rẹ̀ fi hàn kedere pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó dá Ádámù àti Éfà tán, kò fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa méfò nípa ẹni tóun jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbà gbogbo ló máa ń bá wọn sọ̀rọ̀. Kò fi wọ́n sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe ṣe ìgbésí ayé wọn kóun sì wá gbájú mọ́ nǹkan mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún wọn ní ìtọ́ni pàtó nípa ọ̀nà tó dára jù lọ tí wọ́n yóò gbà gbé ìgbésí ayé wọn. Ó fún wọn níṣẹ́ tó gbádùn mọ́ wọn, ó sì ṣètò bí wọ́n á ṣe máa gba ìmọ̀ nìṣó. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-30; 2:7-9) Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tí wàá retí nìyẹn látọ̀dọ̀ òbí tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀? Wá ronú ohun tí èyí túmọ̀ sí. Denielle sọ pé: “Mímọ̀ pé Ọlọ́run dá ayé ó sì ṣẹ̀dá wa lọ́nà tá a ó fi gbádùn àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ kí n rí i pé ó fẹ́ ká láyọ̀.”
Kò tán síbẹ̀ o, gẹ́gẹ́ bí àwọn bàbá dáadáa ṣe máa ń ṣe, Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ òun ní àjọṣe pẹ̀lú òun. Lórí kókó yìí, Ìṣe 17:27 mú un dá wa lójú pé: “Kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” Àbájáde wo lèyí ń mú wá? Amber sọ pé: “Mímọ̀ tí mo wá mọ Jèhófà ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ pé mi ò dá wà rárá. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, mo lẹ́ni tí mo lè yíjú sí nígbà gbogbo.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, bó o ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà sí i, wàá rí i pé onínúure ni, pé kì í ṣe ojúsàájú, ó sì jẹ́ ẹni rere. O lè gbára lé e. Jeff sọ pé: “Nígbà tí Jèhófà di ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, mo mọ̀ pé kò tún sí ẹlòmíràn tó lè tì mí lẹ́yìn ju Jèhófà lọ.”
Àmọ́, ó dunni pé, ọ̀pọ̀ nǹkan tí ò bójú mu làwọn èèyàn ti sọ nípa Jèhófà. Òun ni wọ́n ń di ẹ̀bi ọ̀pọ̀ ìyà tó ń jẹ aráyé àtàwọn ìwàkiwà tó ń lọ nínú ìsìn rù. Wọ́n lóun ló wà lẹ́yìn àwọn ìwà ìkà kan tó burú jáì tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ọmọ èèyàn. Àmọ́ Diutarónómì 32:4, 5 ṣàlàyé pé: “Gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. . . . Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun níhà ọ̀dọ̀ àwọn fúnra wọn; wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀, àbùkù náà jẹ́ tiwọn.” Nítorí náà, iṣẹ́ já lé wa léjìká láti wádìí ọ̀rọ̀ náà wò fúnra wa.—Diutarónómì 30:19, 20.
Ète Ọlọ́run Yóò Ṣẹ
Àmọ́ o, ohun yòówù ká pinnu láti fayé wa ṣe, kò sí ohunkóhun tó máa dí Ọlọ́run lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn pé òun fẹ́ ṣe sí ilẹ̀ ayé yìí àti fún ìran èèyàn. Ó ṣe tán, òun ni Ẹlẹ́dàá. Kí wá ni ohun tó fẹ́ ṣe náà? Jésù Kristi mẹ́nu kàn án nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè nígbà tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” Lẹ́yìn náà, nípasẹ̀ àpọ́sítélì rẹ̀ Jòhánù, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti pinnu “láti run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5; Ìṣípayá 11:18) Nítorí pé Jésù wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà tó ń ṣẹ̀dá àwọn nǹkan, ó mọ̀ pé látìbẹ̀rẹ̀, ète Ọlọ́run ni pé kí ìdílé ẹ̀dá èèyàn tí gbogbo wọn á jẹ́ ẹni pípé máa gbé nínú Párádísè títí láé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27; Jòhánù 1:1-3) Ọlọ́run kì í yí padà. (Málákì 3:6) Ọlọ́run ṣèlérí fún wa pé: “Dájúdájú, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣẹlẹ̀; àti gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu, èyíinì ni yóò ṣẹ.”—Aísáyà 14:24.
Lákòókò wa yìí, Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpìlẹ̀ àwùjọ kan tó wà níṣọ̀kan lélẹ̀, èyí tí a kò gbé ka ìwà ìwọra àti ẹ̀mí ìmọtara ẹni-nìkan irú èyí tó gbalé ayé kan lónìí, àmọ́ tó jẹ́ ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti aládùúgbò la gbé e kà. (Jòhánù 13:35; Éfésù 4:15, 16; Fílípì 2:1-4) Wọ́n jẹ́ àwùjọ kan tó yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n fẹ́ ìtẹ̀síwájú, tí iṣẹ́ tí a gbé lé wọn lọ́wọ́ sì jẹ́ wọ́n lọ́kàn gan-an, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀ kí ètò àwọn nǹkan wọ̀nyí tó wá sópin. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ní orílẹ̀ èdè tó ju igba ó lé ọgbọ̀n [230] lọ, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Kristẹni tí wọ́n ń jọ́sìn pa pọ̀ báyìí, wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn tí wọ́n sì wà níṣọ̀kan.
Jẹ́ Kí Ayé Rẹ Nítumọ̀
Bó o bá ń wá bí ayé rẹ á ṣe túbọ̀ nítumọ̀, yóò dára kó o mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ń ké sí ọ láti kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn òun, ìyẹn “orílẹ̀-èdè òdodo” rẹ̀, kó o sì ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí ni o. (Aísáyà 26:2) Àmọ́, o lè máa rò pé, ‘Báwo làwọn Kristẹni yìí ṣe ń gbé ìgbésí ayé tiwọn? Ṣé lóòótọ́ ni màá fẹ́ láti di ara wọn?’ Gbọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ:
Quentin: Ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ayé yìí ni ìjọ jẹ́ fún mi. Mímọ̀ pé Jèhófà ń kó ipa tó jọjú nínú ìgbésí ayé mi ń jẹ́ kí n rí i pé ó wà àti pé ó fẹ́ kí n láyọ̀.”
Jeff: “Ìjọ ni ibi tó dára jù lọ tí mo ti lè rí ìṣírí gbà. Àwọn arákùnrin mi àtàwọn arábìnrin mi wa níbẹ̀, tí wọ́n ń tì mí lẹ́yìn tí wọ́n sì ń yìn mí. Lóòótọ́, ẹbí mi ni wọ́n.”
Linet: “Ayọ̀ tó máa ń wá látinú rírí i kí ẹnì kan tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì kí ẹni náà sì pinnu láti sin Jèhófà kò láfiwé. Èyí ń fún mi láyọ̀ gan-an nínú ìgbésí ayé mi.”
Cody: “Bí kì í bá ṣe Jèhófà, ìgbésí ayé mi ì bá má lójútùú rárá. Ńṣe ni ǹ bá máa ti orí ohun kan bọ́ sí òmíràn bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń ṣe, tí wọ́n ń wá ayọ̀ síbẹ̀ tọ́wọ́ wọn ò tẹ̀ ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ti fún mi làǹfààní tí kò ṣeé fẹnu sọ, ó jẹ́ kí n lájọṣe pẹ̀lú òun, ìyẹn sì jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀ gan-an.”
O ò ṣe ṣèwádìí fúnra rẹ? Wàá rí i pé tó o bá sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run tí í ṣe Ẹlẹ́dàá rẹ, ayé rẹ yóò dára.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Níní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run ń mú káyé wa dára
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]
Fọ́tò NASA