Ìtàn Ìgbésí Ayé
Yíyọ̀ǹda Ara Wa Tinútinú Ti Jẹ́ Kí Ayé Wa Dára Kó Sì Láyọ̀
GẸ́GẸ́ BÍ MARIAN ÀTI ROSA SZUMIGA ṢE SỌ Ọ́
Sáàmù 54:6 sọ pé: “Tinútinú ni èmi yóò fi rúbọ sí ọ.” Gbólóhùn yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ atọ́nà fún Marian Szumiga àti Rosa ìyàwó rẹ̀ táwọn méjèèjì ń gbé nílẹ̀ Faransé. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni wọ́n sọ díẹ̀ lára nǹkan pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn aláyọ̀ tí wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún.
MARIAN: Onísìn Roman Kátólíìkì làwọn òbí mi, ilẹ̀ Poland ni wọ́n sì ti wá. Bàbá mi ò lọ sílé ìwé rárá. Àmọ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ó kọ́ bá a ṣe ń mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà nígbà tó wà nínú ibi tí wọ́n máa ń fara pa mọ́ sí lójú ogun. Olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni bàbá mi, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni ṣọ́ọ̀ṣì já a kulẹ̀.
Ìṣẹ̀lẹ̀ kan wà tí kò lè gbàgbé láé. Lọ́jọ́ kan nígbà ogun, àlùfáà kan wá sí ẹ̀ka ọmọ ogun ibi tí bàbá mi wà. Nígbà tí àdó abúgbàù kan bú nítòsí wọn, ńṣe ni jìnnìjìnnì bá àlùfáà náà tó sì sá lọ. Ó bẹ̀rẹ̀ sí i fi àgbélébùú tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ na ẹṣin tó gùn kó bàa lè sáré dáadáa. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún bàbá mi pé “aṣojú” Ọlọ́run lo ohun “mímọ́” kó lè tètè sá lọ. Láìka àwọn ohun burúkú tójú bàbá mi rí lójú ogun náà sí, ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run kò yìnrìn. Ó sábà máa ń sọ pé Ọlọ́run ló dáàbò bo òun tóun fi padà bọ̀ látojú ogun.
“Ilẹ̀ Poland Kékeré”
Ní ọdún 1911, bàbá mi fẹ́ ọmọbìnrin kan láti abúlé kan tó wà nítòsí. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Anna Cisowski. Kété lẹ́yìn ogun náà ní ọdún 1919, bàbá àti ìyá mi ṣí láti ilẹ̀ Poland lọ sí ilẹ̀ Faransé, níbi tí bàbá mi ti wá ń ṣiṣẹ́ ìwakùsà. Wọ́n bí mi ní March 1926 ní ìlú Cagnac-les-Mines tó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Faransé. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni àwọn òbí mi fìdí kalẹ̀ sí àgbègbè tí àwọn ará Poland ń gbé nílùú Loos-en-Gohelle, nítòsí Lens ní àríwá ilẹ̀ Faransé. Ẹni tó ń ṣe búrẹ́dì níbẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Poland ni, alápatà ibẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Poland ni, àlùfáà ibẹ̀ pàápàá ọmọ ilẹ̀ Poland ni. Abájọ tí wọ́n fi ń pe àgbègbè yìí ní Ilẹ̀ Poland Kékeré. Àwọn òbí mi máa ń ṣe iṣẹ́ tó n ṣe ará ìlú láǹfààní. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni bàbá mi máa ń ṣètò àwọn eré títí kan eré orí ìtàgé, ó tún máa ń ṣètò orin àti bí wọ́n ṣe ń kọ ọ́. Ó sì tún máa ń bá àlùfáà sọ̀rọ̀ déédéé, tá máa bi í láwọn ìbéèrè, àmọ́ inú rẹ̀ kì í dùn nígbà tí àlùfáà bá ń dáhùn pé, “Ọ̀pọ̀ nǹkan ló jẹ́ àwámáridìí.”
Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1930, àwọn obìnrin méjì kan ilẹ̀kùn wa. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Wọ́n fún bàbá mi ní Bíbélì kan, ó sì ti pẹ́ gan-an tó ti fẹ́ láti ka Bíbélì. Bàbá àti ìyá mi tún fi ìháragàgà ka àwọn ìwé tá a gbé karí Bíbélì tí àwọn obìnrin náà fún wọn. Ohun tí àwọn òbí mi ń kà nínú àwọn ìwé náà wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ àwọn òbí mi máa ń dí, síbẹ̀ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i lọ sí àwọn ìpàdé tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣètò rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí àwọn òbí mi ń bá àlùfáà sọ máa ń di àríyànjiyàn tó le, nígbà tó di ọjọ́ kan ó le débi pé àlùfáà náà halẹ̀ mọ́ wọn pé bí wọn ò bá jáwọ́ nínú bíbá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kẹ́gbẹ́ òun a lé Stéphanie ẹ̀gbọ́n mi obìnrin kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ katikísìmù. Bàbá mi dáhùn pé, “Má wulẹ̀ darà ẹ láàmú. Láti ìsinsìnyí lọ, òunàtàwọn ọmọ mi tó kù yóò máa bá wa lọ sí àwọn ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Bàbá mi kúrò nínú ẹ̀sìn yẹn, òun àti màmá mi sì ṣèrìbọmi ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1932. Lákòókò yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] akéde Ìjọba náà ló wà nílẹ̀ Faransé.
Rosa: Àwọn òbí mi wá láti ilẹ̀ Hungary, bíi ti ìdílé Marian, wọ́n fìdí kalẹ̀ sí àríwá ilẹ̀ Faransé láti máa ṣiṣẹ́ níbi ìwakùsà. Ọdún 1925 ni wọ́n bí mi. Ní ọdún 1937, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Auguste Beugin tàbí Papa Auguste bí a ṣe máa ń pè é, bẹ̀rẹ̀ sí í mú Ilé Ìṣọ́ lédè Hungary wá fún àwọn òbí mi. Wọ́n máa ń gbádùn àwọn ìwé ìròyìn náà gan-an, àmọ́ kò sí èyíkéyìí lára wọn tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo kéré lọ́jọ́ orí, ohun tí mo ń kà nínú Ilé Ìṣọ́ wọ̀ mi lọ́kàn gan-an ni, àti pé Suzanne Beugin, ìyàwó ọmọ Papa Auguste, fẹ́ràn mi gan-an ni. Àwọn òbí mi gbà á láyè láti máa mú mi lọ sí àwọn ìpàdé. Nígbà tó yá mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́. Bàbá mi máa ń bínú sí lílọ tí mo ń lọ sí ìpàdé lọ́jọọjọ́ Sunday. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn dáadáa ni, ó máa ń ṣàròyé pé, “O ò kì í sí nílé láàárín ọ̀sẹ̀, tó bá sì tún di àwọn ọjọ́ Sunday wàá gba ìpàdé rẹ lọ!” Bó ti wù kó rí, mò ń lọ sí ìpàdé déédéé. Nígbà tó di ọjọ́ kan ni bàbá mi sọ fún mi pé, “Ó yá, kó ẹrù ẹ kó o sì jáde kúrò nílé yìí!” Ilẹ̀ ti ṣú lọ́jọ́ ti mò ń wí yìí. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún péré ni mí, mi ò sì mọ ibi tí n máa lọ. Mo gbéra ó di ilé Suzanne, mò ń sunkún wùrùwùrù. Mo dúró sọ́dọ̀ Suzanne fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan kí bàbá mi tó rán ẹ̀gbọ́n mi obìnrin pé kó wá mú mi wá sílé. Onítìjú èèyàn ni mí, ṣùgbọ́n ohun tí 1 Jòhánù 4: 8 sọ ràn mí lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in. Ìwé Mímọ́ yẹn sọ pé “ṣùgbọ́n ìfẹ́ pípé a máa ju ìbẹ̀rù sóde.” Mo ṣèrìbọmi ní ọdún 1942.
Ogún Tẹ̀mí Kan Tó Ṣeyebíye
Marian: Mo ṣèrìbọmi ní ọdún 1942, èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin Stéphanie òun Mélanie àti Stéphane ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin. Nílé wa, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń darí gbogbo nǹkan tá à ń ṣe. Nígbà tá a bá jókòó sídìí tábìlì, bàbá mi máa ń ka Bíbélì fún wa ní èdè Polish. Lálaalẹ́, àwọn òbí wa sábà máa ń sọ ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà fún wa. Àwọn àkókò tá a ń gbọ́ nǹkan tẹ̀mí tí ń gbéni ro yìí jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ká sì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e. Àìlera kò jẹ́ kí bàbá mi lè ṣiṣẹ́ mọ́, àmọ́ kò jáwọ́ nínú pípèsè àwọn nǹkan tẹ̀mí àti tara fún wa.
Níwọ̀n bí àyè ti wá wà fún bàbá mi, ó máa ń bá àwọn ọ̀dọ́ inú ìjọ wa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ lédè Polish. Ìgbà yẹn ni mo kọ́ bí a ṣe ń ka èdè Polish. Bàbá mi tún fún àwọn èwe níṣìírí láwọn ọ̀nà mìíràn. Nígbà kan tí Arákùnrin Gustave Zopfer, tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Faransé nígbà yẹn wá sí ìjọ wa, bàbá mi ṣètò ẹgbẹ́ akọrin àti àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ti múra bíi táwọn ará ìgbàanì, ó dá lórí ayẹyẹ tí Ọba Bẹliṣásárì ṣe àti ìkọ̀wé ara ògiri. (Dáníẹ́lì 5: 1-31) Ẹni tó ṣe Dáníẹ́lì nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà ni Louis Piéchota tí kò juwọ́ sílẹ̀ nígbà to dojú kọ àtakò nígbà ìjọba Násì.a Ní àárín irú àwọn èèyàn bí èyí ni wọ́n ti tọ́ wa dàgbà. A rí i pé nǹkan tẹ̀mí jẹ́ àwọn òbí wa lógún. Lónìí, mo rí i pé ogún tó ṣeyebíye ni àwọn òbí wa fi sílẹ̀ fún wa.
Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1939, wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé. Nígbà kan, wọ́n wa yẹ gbogbo inú ìlú wa wò. Àwọn sójà Jámánì yí gbogbo ilé tó wà nílùú náà ká. Bàbá mi ṣe ibi àyè kan sábẹ́ ibi tá a máa ń kó aṣọ sí to wà nínú yàrá wa, a sì máa ń kó oríṣiríṣi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa mọ́ síbẹ̀. Àmọ́ ṣá o, mélòó kan lára ìwé kékeré tó ń jẹ́ Fascism or Freedom wà nínú ibi-ìkó-nǹkan-sí tó wà lára tábìlì ìjẹun. Bàbá mi yára fi àwọn ìwé náà pa mọ́ sí àpò aṣọ tó fi kọ́ sí igun ilé. Àwọn sójà méjì àtàwọn ọlọ́pàá Faransé yẹ gbogbo inú ilé wa wò. Ọkàn wa ò balẹ̀ bí a ti ń retí ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn sójà náà bẹ̀rẹ̀ sí yẹ àwọn aṣọ tá a fi kọ́ sí igun ilé wò. Lẹ́yìn ìyẹn, ó wọnú ilé ìdáná níbi tá a wà, ó sì kó àwọn ìwé kékeré náà lọ́wọ́. Ó wò wá ṣùn-ùn, ó sì kó àwọn ìwé náà sórí tábìlì ó sì lọ ń yẹ ibòmíràn wò. Mo yára kó àwọn ìwé kékeré náà mo sì kó wọ́n sínú àpótí tí àwọn sójà náà ti yẹ̀ wò tẹ́lẹ̀. Sójà náà ò tiẹ̀ béèrè àwọn ìwé kékeré náà mọ́, ó jọ pé ó ti gbàgbé wọn!
Mo Wọ Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò-Kíkún
Ní ọdún 1948, mo pinnu láti yọ̀ǹda ará mi kí n lè fi àkókò kíkún sin Jèhófà nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo gba lẹ́tà kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Faransé. Ohun tó wà nínú lẹ́tà náà ni pé kí n lọ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní ìjọ tó wà nílùú Sedan, nítòsí orílẹ̀-èdè Belgium. Inú àwọn òbí mi dùn nígbà tí wọ́n rí i pé mò bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lọ́nà yẹn. Síbẹ̀ náà, bàbá mi sọ fún mi pé iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà kì í ṣe iṣẹ́ gbẹ̀fẹ́. Iṣẹ́ àṣekára ni. Àmọ́, ó sọ fún mi pé ìgbà tó bá wù mi ni mo lè wá sí ilé yìí o, ó tún lóun ṣe tán láti ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá níṣòro èyíkéyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, wọ́n ra kẹ̀kẹ́ tuntun kan fún mi. Mo ṣì ní rìsíìtì kẹ̀kẹ́ ọ̀hún lọ́wọ́, nígbà tí mo bá wò ó, omijé a lé ròrò sójú mi. Bàbá àti ìyá mi kú ní ọdún 1961, àmọ́ mo ṣì máa ń rántí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí bàbá mi ti sọ fún mi; àwọn ọ̀rọ̀ náà ti fún mi níṣìírí wọ́n sì ti tù mí nínú jálẹ̀ gbogbo ọdún tí mo fi ṣiṣẹ́ ìsìn.
Ẹlòmíràn to tún fun mi níṣìírí ni arábìnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin tó wà ní ìjọ Sedan. Orúkọ rẹ̀ ni Elise Motte. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn mo máa ń gun kẹ̀kẹ́ mi lọ sí àwọn abúlé tó wà lágbègbè wa láti lọ wàásù, Elise á wọ ọkọ̀ ojú irin wá bá mi. Àmọ́, lọ́jọ́ kan àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó ń bá ọkọ̀ ojú irin ṣiṣẹ́ daṣẹ́ sílẹ̀, Elise ò sì lè wálé mọ́. Ohun kan ṣoṣo tí mo rò pé mo lè ṣe ni pé kí n gbé màmá àgbàlagbà yìí sórí ibi ìkẹ́rùsí tó wà lẹ́yìn kẹ̀kẹ́ mi kí n sì gbé lọ sílé—àmọ́ ibẹ̀ kò rọrùn fún un rárá láti jókòó sí. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, mo mú tìmùtìmù kan dání tó máa jókòó lé, mo sì lọ gbé Elise nílé rẹ̀. Bí kò ṣe wọ ọkọ̀ ojú irin mọ́ nìyẹn, owó ọkọ̀ tó ń fi pa mọ́ látìgbà yẹn ló máa fi ń ra ọtí tá a máa ń mu lákòókò oúnjẹ ọ̀sán. Ta ló lè rò pé kẹ̀kẹ́ mi máa di kẹ̀kẹ́ akérò?
Iṣẹ́ Mi Ń Pọ̀ Sí I
Ní ọdún 1950, wọ́n ni kí n máa ṣe alábòójútó àyíká ní gbogbo àríwá ilẹ̀ Faransé. Nítorí pé ẹni ọdún mẹ́tàlélógún péré ni mi, ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí. Mo rò pé ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣàṣìṣe ni! Àwọn ìbéèrè tó ń jà gùdù lọ́kàn mi ni pé: ‘Ǹjẹ́ mo dàgbà tó nípa tẹ̀mí àti tara láti ṣe iṣẹ́ yìí? Kí ni mo ti máa ṣe ọ̀ràn gbígbé ní oríṣiríṣi ilé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?’ Èyí tó le jù níbẹ̀ ni pé láti ọmọ ọdún mẹ́fà ni mo ti ní ìṣòro ojú tí kò ríran dáadáa. Èyí mú ki ọ̀kan lára ojú mi dà. Nítorí èyí, mo máa ń ronú nípa ohun táwọn èèyàn lè máa sọ nípa mi. Mo dúpẹ́ pé lákòókò yẹn Stefan Behunick, tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gilead tó wà fún àwọn míṣọ́nnárì ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Wọ́n ti lé arákùnrin Behunick kúrò nílẹ̀ Poland nítorí iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa wá ní kó lọ sí ilẹ̀ Faransé. Ìgboyà tó ní wú mi lórí púpọ̀. Ó ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà àti òtítọ́. Àwọn kan rò pé ó lé koko mọ́ mi, àmọ́, mo kọ́ ohun púpọ̀ lára rẹ̀. Ìgboyà tó ní mú kí èmi náà nígboyà.
Iṣẹ́ alábòójútó àyíká jẹ́ kí n gbádùn àwọn ìrírí alárinrin kan nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Ní ọdún 1953, wọ́n ni kí n lọ sọ́dọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Paoli, tó ń gbé ní gúúsù ìlú Paris. Ó ti forúkọ sílẹ̀ fún gbígba Ilé Ìṣọ́. Mo rí i, ó sì sọ fún mi pé òun ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ológun, òun sì ń gbádùn àwọn Ilé Ìṣọ́ tóun ń kà. Ó wá sọ fún mi pé lẹ́yìn tí òun ka àpilẹ̀kọ kan nípa Ìrántí Ikú Kristi nínú ìtẹ̀jáde ẹnu àìpẹ́ yìí, òun ṣayẹyẹ Ìrántí Ikú Kristi fúnra òun, òun sì fi ìyókù alẹ́ ọjọ́ yẹn ka ìwé Sáàmù. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọ̀sán ọjọ́ náà la fi jọ sọ̀rọ̀. Kí n tó kúrò níbẹ̀ a sọ̀rọ̀ ṣókí nípa ìrìbọmi. Lẹ́yìn ìgbà yẹn mo fi ìwé pè é wá sí àpéjọ àyíká wa tí a óò ṣe níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1954. Ó wá, bí Arákùnrin Paoli ṣe di ọ̀kan lára àwọn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tó ṣèrìbọmi nìyẹn. Irú àwọn ìrírí báyìí ṣì máa ń fún mi láyọ̀ gan-an.
Rosa: Ní October 1948, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà. Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti sìn ní ìlú Anor, nítòsí orílẹ̀-èdè Belgium, wọ́n yàn mí sí ìlú Paris pẹ̀lú obìnrin aṣáájú ọ̀nà mìíràn tó ń jẹ́ Irène Kolanski (nísinsìnyí ó ń jẹ́ Leroy). À ń gbé nínú yàrá kékeré kan láàárín ìlú Saint-Germain-des-Près. Nítorí pé ìgbèríko ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, ẹ̀rú máa ń bà mí nígbà tí mo bá rí àwọn ará ìlú Paris. Mo rò pé gbogbo wọn ló lajú tí wọ́n sì gbọ́n féfé. Àmọ́ kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún wọn ni mo wá mọ̀ pé wọn ò yàtọ̀ sí àwọn èèyàn yòókù. Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn tó ń bójú tó ilé máa ń lé wa da nù, ó sì máa ń ṣòro láti rẹ́ni bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn kan ṣì ń gbọ́ ìwàásù wa.
Nígbà àpéjọ kan ní ọdún 1951, wọ́n fọ̀rọ̀ wá èmi àti Irène lẹ́nu wò nípa iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà wa. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò? Ọ̀dọ́ alábòójútó àyíká kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Marian Szumiga ni. A ti pàdé lẹ́ẹ̀kan rí, àmọ́ lẹ́yìn àpéjọ yẹn, a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà síra wa. Ọ̀rọ̀ èmi àti Marian bára mu gan-an ni, títí dorí pé ọdún kan náà lá jọ ṣèrìbọmi, a sì di aṣáájú ọ̀nà lọ́dún kan náà. Paríparí rẹ̀ ni pé àwa méjèèjì fẹ́ máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún nìṣó. Nítorí náà, lẹ́yìn tá a ti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà, a ṣègbéyàwó ní July 31, ọdún 1956. Báyìí ni mo ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun. Kì í ṣe pé mo di ìyàwó nìkan, àmọ́ mo tún ní láti máa bá Marian lọ́ káàkiri nínú iṣẹ́ àyíká, ìyẹn sì túmọ̀ sí pé ilé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni n óò máa sùn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Níbẹ̀rẹ̀ kò rọrùn fún mi, àmọ́ ayọ̀ ńláǹlà ló ńbẹ níwájú.
Ìgbésí Ayé Tó Dára
Marian: Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, a ti ní àǹfààní ṣíṣèrànwọ́ nínú ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ àpéjọ. Èyí tá a ṣe lọ́dún 1966, ní Bordeaux ni mo tiẹ̀ máa ń rántí dáadáa. Lákòókò yẹn, wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Potogí. Nítorí ìdí yìí wọ́n tún ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà ní èdè Potogí fún àǹfààní àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n lè wá sí orílẹ̀-èdè Faransé. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arábìnrin àti arákùnrin ló wá láti ilẹ̀ Potogí, àmọ́ ìṣòro tá a dojú kọ ni pé kò sí ibi tí wọ́n máa dé sí. Nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Bordeaux kò ní àyè tó ní ilé wọn, a háyà ilé sinimá kan tí wọ́n máa dé sí. A kó gbogbo àga ibẹ̀ kúrò a sì fi aṣọ tí wọ́n ta sórí ìtàgé ibẹ̀ dá yàrá ńlá náà sí méjì, apá kan fún àwọn arákùnrin, apá kejì fún àwọn arábìnrin. A tún ṣe ilé ìwẹ̀ àti ọpọ́n ìfọwọ́, a kó tìmùtìmù koríko sílẹ̀ a sì fi aṣọ bò ó. Ètò tá a ṣe yìí tẹ́ gbogbo àwọn ará lọ́rùn.
Lẹ́yìn ìpàdé àárọ̀ àti tọ̀sán, a máa ń lọ kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní yàrá ńlá tá a fi wọ́n sí náà. Àkókò amóríyá lèyí jẹ́. Ẹ wo bí ìrírí tí wọ́n ní ṣe fún wa níṣìírí tó láìka ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi fojú winá àtakò! Omijé lé ròrò sójú gbogbo wa nígbà tí wọ́n lọ lẹ́yìn tí àpéjọ náà parí.
Mo rí àǹfààní mìíràn gbà lọ́dún méjì ṣáájú, ìyẹn lọ́dún 1964, nígbà tí wọ́n ní kí ń lọ ṣe alábòójútó agbègbè. Lẹ́ẹ̀kan sí i mo rò pé agbára mi ò lé gbé iṣẹ́ náà. Ṣùgbọ́n mo sọ fún ara mi pé ohun tó fi lè mú kí wọ́n yan iṣẹ́ yìí fún mi, á jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé mo lè ṣe é nìyẹn. Ìrírí alárinrin ló jẹ́ láti bá àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò mìíràn ṣiṣẹ́ pọ̀. Mo kọ́ ohun púpọ̀ lára wọn. Ọ̀pọ̀ lára wọn ní sùúrù àti ìfaradà, àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn sì ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Ó ti wá yé mi pé bí a bá fi sùúrù dúró de Jèhófà, ó mọ ibi tá a ti wá bá wa.
Ní ọdún 1982 ọ́fíìsì ẹ̀ka wa sọ fún wa pé kí a tún lọ bójú tó àwùjọ kékeré tó ní èèyàn méjìlá tí ń sọ èdè Polish ní Boulogne-Billancourt, ní ẹ̀yìn òde ìlú Paris. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa. Mo mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí àwa Ẹlẹ́rìí máa ń lò ní èdè Polish, àmọ́ ó máa ń ṣòro fún mi láti sọ gbólóhùn kan délẹ̀. Síbẹ̀ náà, inú rere àti ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí àwọn arákùnrin wọ̀nyẹn ní ràn mí lọ́wọ́ gidigidi. Lónìí, nǹkan bí àádọ́sàn-án [170] akéde ló wà nínú ìjọ yẹn, àwọn aṣáájú ọ̀nà ibẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́ta. Nígbà tó yá, èmi àti Rosa tún ń lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn àwùjọ àti ìjọ tó ń sọ èdè Polish ní orílẹ̀-èdè Austria, Denmark àti Jámánì.
Ipò Àwọn Nǹkan Ń Yí Padà
Ká máa bẹ oríṣiríṣi ìjọ wò ti mọ́ wa lára, àmọ́ ara mi tí kò le mọ́ ti mú kí á dá iṣẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò tá à ń ṣe dúró lọ́dún 2001. A wá ilé kékeré kan nílùú Pithiviers, níbi tí Ruth àbúrò mi obìnrin ń gbé. Ẹ̀ka ọ́fíìsì fún wá láǹfààní iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì ní ká máa lo iye wákàtí tí agbára wa bá ká nínú iṣẹ́ wàásù.
Rosa: Nǹkan le fún mi gan-an lẹ́yìn ọdún àkọ́kọ́ tá a kúrò lẹ́nu iṣẹ́ àyíká. Ìyípadà náà lé gan-an débi tó ń ṣe mi bíi pé mi ò wúlò mọ́. Nígbà náà ni mo wá rán ara mi létí pé, ‘O ṣì lè lo àkókò àti agbára rẹ tó kù dáadáa tó o bá ń ṣe aṣáájú ọ̀nà.’ Lónìí, mo láyọ̀ pé èmi àtàwọn aṣáájú ọ̀nà inú ìjọ wa jùmọ̀ ń ṣiṣẹ́ pọ̀.
Ìgbà Gbogbo Ni Jèhófà Ń Bójú Tó Wa
Marian: Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ti lé lọ́dún méjìdínláàádọ́ta ti èmi àti Rosa ti jọ wà pa pọ̀. Jálẹ̀ gbogbo ọdún tá a lò nínú iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, o ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Kò fìgbà kan rí sọ pé, ‘Ì bá wù mí ká fìdí kalẹ̀ síbì kan ká sì ní ìdílé tiwa.’
Rosa: Ẹlòmíì máa ń sọ fún mi nígbà míì pé, “Bí àwọn èèyàn ṣe ń gbé ìgbésí ayé kọ́ ló ò ń gbé tiẹ̀ yìí. Ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn lò ń gbé ní gbogbo ìgbà.” Báwo ló tiẹ̀ ṣe yẹ kéèyàn máa gbé ìgbésí ayé ná? Ọ̀pọ̀ ìgbà láwọn èèyàn máa ń fi ọ̀pọ̀ ohun tó lè dènà ìlépa àwọn ohun tẹ̀mí dí ara wọn lọ́wọ́. Ohun téèyàn nílò kò ju ibùsùn tó dára, tábìlì kan, àtàwọn ohun kòṣeémáàní mélòó kan. Gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, ohun ìní tá a ní ò tó nǹkan, síbẹ̀ a ní gbogbo ohun tá a nílò láti fi ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ìgbà mìíràn wà tí wọ́n máa ń bi mí pé, “Kí lo máa ṣe nígbà tó o bá dàgbà, ìwọ tó ò nílé tiẹ̀ fúnra ẹ̀ tí wọn ò sì ní fún ọ lówó ìfẹ̀yìntì.” Ìgbà yẹn ni màá wá sọ ohun tó wà nínú Sáàmù 34:10 fún wọn pé: “Ní ti àwọn tí ń wá Jèhófà, wọn kì yóò ṣaláìní ohun rere èyíkéyìí.” Ìgbà gbogbo ni Jèhófà sì máa ń bójú tó wa.
Marian: Bó ṣe rí gan-an nìyẹn! Àní sẹ́, Jèhófà ti fún wa ju ohun tá a nílò pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1958, wọ́n yàn mí láti ṣojú àyíká wa ní ìpàdé àgbáyé nílùú New York. Àmọ́, a ò lówó tá a ó fi sanwó ọkọ̀ ti Rosa. Lálẹ́ ọjọ́ kan arákùnrin kan fún wa ní àpò ìwé kan tó kọ “New York” sí lára. Ẹ̀bùn tó fi sínú àpò ìwé náà ló jẹ́ kí Rosa lè bá mi lọ!
Èmi àti Rosa kò kábàámọ̀ kankan nípa àwọn ọdún tá a lò nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. A ò pàdánù ohunkóhun, ńṣe lá jèrè gbogbo nǹkan, ìyẹn ìgbésí ayé tó dára tó sì láyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. Ọlọ́run ìyanu ni Jèhófà. A ti kọ́ bí a ṣe ń fi gbogbo ọkàn gbẹ́kẹ̀ lé e, ìfẹ́ tá a ní fún un sì ti jinlẹ̀ sí i. Àwọn kan lára àwọn Kristẹni arákùnrin wa ti kú nítorí pé wọ́n pà ìwà títọ́ wọn mọ́. Síbẹ̀ náà, mo gbà pé èèyàn lè ṣe bíi tiwọn nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà títí dọjọ́ ikú. Ìyẹn ni èmi àti Rosa ń ṣe títí di ìsinsìnyí, èyí sì ni ohun tí a ti pinnu pé a óò máa ṣe lọ ní ọjọ́ iwájú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtàn ìgbésí ayé Louis Piéchota tó ní àkọlé náà, “Mo La ‘Irin-àjò sinu Iku’ Já” wà nínú Ile-Iṣọ Naa ti February 15, 1981.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
François àti Anna Szumiga àtàwọn ọmọ wọn, Stéphanie, Stéphane, Mélanie, àti Marian ní nǹkan bí ọdún 1930. Marian ló dúró sórí tábìlì kékeré
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Lókè: Àwa rèé níbi tá a ti ń fi ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì lọni níbi ọjà kan nílùú Armentières, àríwá ilẹ̀ Faransé, lọ́dún 1950
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Apá òsì: Stefan Behunick àti Marian rèé ní 1950
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Marian àti Rosa nígbà tí ìgbéyàwó wọn ku ọ̀la
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Rosa (lápá òsì pátápátá) àti aṣáájú ọ̀nà tí wọn jọ máa ń ṣiṣẹ́, ìyẹn Irène (tó jẹ́ ẹni kẹrin láti apá òsì), wọ́n ń polongo àpéjọ kan lọ́dún 1951
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kẹ̀kẹ́ la fi ń rìnrìn àjò nígbà ìbẹ̀wò àyíká