Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
“Àwọn Ẹni Ìgbàgbé” Ti Wá Di Ẹni Ìrántí
NÍBẸ̀RẸ̀ ọdún 2001, Haykaz, ọmọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ síbi ìpàtẹ kan tí wọ́n pè ní “Àwọn Ẹni Ìgbàgbé” nílùú Bern, lórílẹ̀-èdè Switzerland. Níbi ìpàtẹ náà, wọ́n pàtẹ àwọn ìwé àti àwòrán tó fi inúnibíni tí ìjọba Násì ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà hàn. Nígbà tí Haykaz wòran tán, ó sọ pé: “Mo ti máa ń gbọ́ nípa ìwà òǹrorò àti ìyà tí wọ́n fi jẹ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà ìjọba Násì, àmọ́ èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí màá fojú ara mi rí àwọn ìwé àti fọ́tò gidi tó fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn hàn. Àwọn nǹkan tí wọ́n pàtẹ, ìròyìn látẹnu àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ táwọn òpìtàn sọ níbi ìpàtẹ náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.”
Láìpẹ́ púpọ̀ sígbà yẹn, wọ́n ní kí Haykaz kọ ìròyìn kan fáwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ nílé ìwé girama, ó pe àkọlé rẹ̀ ní “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ẹni Ìgbàgbé Nígbà Ìjọba Násì.” Olùkọ́ rẹ̀ fọwọ́ sí i pé kí Haykaz kọ ọ̀rọ̀ lórí àkọlé náà, àmọ́ ó ní kó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ìwé mìíràn táwọn èèyàn tẹ̀ jáde. Tayọ̀tayọ̀ ni Haykaz fi gbà pé òun á ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé, “Mo ṣe àkópọ̀ àwọn ìwé kan ti mo ṣàyẹ̀wò rẹ̀, ìyẹn àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà ìjọba Násì. Mo tún kọ ohun tí mo fojú ara mi rí níbi ìpàtẹ tí wọ́n pè ní ‘Àwọn Ẹni Ìgbàgbé.’ Oríṣiríṣi àpèjúwe ló wà nínú ìròyìn olójú ewé mẹ́tàlélógójì náà, àwọn fọ́tò sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.”
Ní November 2002, Haykaz ka ìròyìn náà sí etígbọ̀ọ́ àwọn ọmọ iléèwé rẹ̀, àwọn olùkọ́ rẹ̀, ìdílé rẹ̀, àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àkókò wá tó fún ìbéèrè àti ìdáhùn, èyí sì jẹ́ kó láǹfààní láti ṣàlàyé àwọn ohun tó gbà gbọ́ tá a gbé ka Bíbélì. Nígbà tí ọmọbìnrin kan lára àwọn tó wà níbẹ̀ bi í pé kí nìdí tó fi kọ ọ̀rọ̀ lórí àkọlé yẹn, Haykaz ṣàlàyé fún un pé ọ̀pọ̀ àwọn ìwé ìtàn ní kì í sọ̀rọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pé òun fẹ́ káwọn èèyàn mọ bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń fi ìgboyà gbèjà ìgbàgbọ́ Kristẹni. Kí ni àbájáde gbogbo ohun tó kà fún wọn yìí?
Haykaz sọ pé “ẹnu ya àwọn ọmọ iléèwé mi. Wọn ò mọ̀ rárá pé àwọn èèyàn ṣe inúnibíni rírorò sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan. Àti pé ọ̀pọ̀ lára wọn ni ò mọ̀ pé àmì ìdánimọ̀ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wà lára aṣọ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n fi sínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Násì, ìyẹn sì ni àmì onígun mẹ́tà aláwọ̀ àlùkò.”
Lẹ́yìn tí Haykaz ka ìwé tó kọ yìí tán, ó wá láǹfààní tó pọ̀ láti bá àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sọ̀rọ̀ àti láti ṣàlàyé ohun táwa Ẹlẹ́rìí mọ̀ pé ó bá Bíbélì mu tá a máa ń ṣe nípa ọ̀ràn ìfàjẹ̀sínilára, ọtí líle àti ìwà híhù. Haykaz sọ pé, “Kò sí èyíkéyìí lára àwọn ọmọ kíláàsì mi tó fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.” Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tọ́jú ìwé tó kọ́ yìí sí yàrá ìkówèésí tó wà nílé ìwé wọn. Èyí jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà làwọn èèyàn yóò máa rántí ìgboyà tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.