ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 10/1 ojú ìwé 3-4
  • Ogún Kan Tó O Lè Gbọ́kàn Lé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ogún Kan Tó O Lè Gbọ́kàn Lé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Ni Yóò Jogún Ayé’—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Dáàbò Bo Ogún Iyebíye Tí Jèhófà Fún Ẹ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóṣúà
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Ogún Wa Ṣíṣeyebíye—Kí Ló Túmọ̀ Sí Fún ọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 10/1 ojú ìwé 3-4

Ogún Kan Tó O Lè Gbọ́kàn Lé

“TÓ O bá rí lẹ́tà kan gbà látọ̀dọ̀ ẹnì kan tó sọ pé wọ́n ń dá ogún kan dúró dè ọ́, kó o ṣọ́ra o. Kó o má bàa bọ́ sọ́wọ́ gbájúẹ̀.”

Ìkìlọ̀ tí Ẹ̀ka Tó Ń Ṣàyẹ̀wò Ilé Iṣẹ́ Ìfìwéránṣẹ́ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe sí ìkànnì rẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nìyẹn. Kí ló mú kí wọ́n ṣe irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló máa ń gba lẹ́tà tó sọ pé, ‘Mọ̀lẹ́bí rẹ kan ti kú, ó sì fi ogún kan sílẹ̀ fún ọ.’ Nítorí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fi ọgbọ̀n dọ́là tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ránṣẹ́ síbi tí lẹ́tà náà ti wá kí wọ́n lè fi ‘ìsọfúnni nípa ilẹ̀ àti dúkìá’ náà ránṣẹ́, ìyẹn ìwé tí wọ́n retí pé ó máa ṣàlàyé ibi tí ogún náà wà àti báwọn ṣe lè rí i gbà. Àmọ́, pàbó ni gbogbo ẹ̀ já sí. Ìsọfúnni kan náà ni gbogbo àwọn tó fi owó yìí ránṣẹ́ rí gbà, kò sẹ́ni tó jogún ohunkóhun nínú gbogbo wọn.

Tìtorí pé àwọn èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ogún jíjẹ ló mú káwọn kan dá irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, Bíbélì fi hàn pé ohun tó dára làwọn tó ń fi ogún sílẹ̀ ń ṣe, ó sọ pé: “Ẹni rere yóò fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ-ọmọ.” (Òwe 13:22) Ká sòótọ́, Jésù Kristi fúnra rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ tá a mọ̀ bí ẹní mowó tá a sì nífẹ̀ẹ́ sí gidigidi nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn [“ọlọkàn-tutù,” Bibeli Mimọ] níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 5:5.

Ọ̀rọ̀ Jésù yìí rán wa létí ohun tí Ọlọ́run mí sí Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì láti kọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò yẹn, tó sọ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò [“jogun aiye,” Bibeli Mimọ], ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.

‘Jogún ayé’—ìyẹn á mà dára gan-an o! Àmọ́ ṣé ó dá wa lójú pé èyí kì í ṣe ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mìíràn láti tú àwọn èèyàn jẹ? Ó dá wa lójú mọ̀nà. Níwọ̀n bí ayé yìí ti wà lára àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà dá, òun tó jẹ́ Olùṣẹ̀dá àti Ẹni tó ni ayé lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé kí ẹnikẹ́ni tó bá wu òun jogún rẹ̀. Jèhófà sì ti tipasẹ̀ Dáfídì Ọba ṣe ìlérí alásọtẹ́lẹ̀ yìí fún Jésù Kristi, Ọmọ Rẹ̀ ọ̀wọ́n pé: “Béèrè lọ́wọ́ mi, kí èmi lè fi àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ àti àwọn òpin ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ.” (Sáàmù 2:8) Nítorí èyí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù ni “ẹni tí [Ọlọ́run] yàn ṣe ajogún ohun gbogbo.” (Hébérù 1:2) Nítorí náà, a lè ní ìgbọ́kànlé tó lágbára pé òótọ́ pọ́ńbélé ni Jésù ń sọ nígbà tó sọ pé àwọn ọlọ́kàn tútù ‘ni yóò jogún ayé,’ ó sì dájú pé ó ní ọlá àṣẹ tó yẹ láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.—Mátíù 28:18.

Ìbéèrè pàtàkì tá a máa béèrè báyìí ni pé, Báwo ni ìlérí yẹn ṣe máa ṣẹ? Ibikíbi tá a bá yíjú sí lóde òní, ó dà bíi pé àwọn tó ń jẹ gàba léni lórí àtàwọn ọlọ́kàn-gíga ni nǹkan ń ṣẹnuure fún jù lọ, àwọn ni ọwọ́ wọn sì máa ń tẹ gbogbo ohun tí wọ́n bá ń wá. Kí ló máa wá ṣẹ́ kù fáwọn ọlọ́kàn tútù láti jogún? Yàtọ̀ síyẹn, ìṣòro ìbàyíkájẹ́ ti sọ ayé yìí dìdàkudà, àwọn oníwọra àtàwọn tí kì í ro ti ọjọ́ ọ̀la sì ń fi búrùjí inú rẹ̀ ṣèrè jẹ. Ṣé ayé kan tiẹ̀ máa wà tá dára tó ohun téèyàn ń jogún ni? A rọ̀ ọ́ pé kó o ka àpilẹ̀kọ tó kàn kó o lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àtàwọn ìbéèrè pàtàkì mìíràn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ṣé wàá rí ogún gidi gbà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́