Ẹ̀yin Ọ̀dọ́ Ẹ Jẹ́ Káwọn Òbí Yín Ràn Yín Lọ́wọ́ Kẹ́ Ẹ Lè Dáàbò Bo Ọkàn Yín!
KÍ LO rò pé ó jẹ́ olórí ìṣòro awakọ̀ òkun? Ṣé bó ṣe máa la agbami òkun já ni? Ìyẹn kọ́ ló sábà máa ń ṣòro fún awakọ̀ òkun. Ìdí ni pé kì í ṣe ojú agbami ni ọkọ̀ òkun ti sábà máa ń rì bí kò ṣe nítòsí èbúté. Àní ó ṣòro láti wa ọkọ̀ ojú omi gúnlẹ̀ sébùúté ju àtimú kí ọkọ̀ òfuurufú balẹ̀ sí pápákọ̀ lọ. Kí nìdí?
Kí awakọ̀ òkun kan tó lè wakọ̀ gúnlẹ̀ sébùúté, ó ní láti kíyè sí gbogbo ewu tó wà ní èbúté náà. Bó ṣe ń ṣọ́ra kó má kọ lu àwọn ọkọ̀ mìíràn tó wà lébùúté láá máa rò ti bí omi náà ṣe ń yára ṣàn sí nísàlẹ̀. Kò sì gbọ́dọ̀ gorí òkìtì yanrìn àti àpáta tó wà nísàlẹ̀ òkun tàbí àwọn àwókù ọkọ̀ tó wà nísàlẹ̀ òkun. Ewu yìí máa ń pọ̀ sí i tó bá lọ jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí awakọ̀ náà máa wá sébùúté náà nìyẹn.
Kó lè borí ìṣòro yìí, awakọ̀ òkun yìí á gba atukọ̀ kan tó mọ èbúté yẹn dunjú. Atukọ̀ tó mọ èbúté dunjú yìí á wá dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ awakọ̀ òkun náà níbi tó máa ń jókòó sí, á sì máa tọ́ ọ sọ́nà. Wọ́n á wá jọ wo ohun tó lè fa ewu wọ́n á sì jọ darí ọkọ̀ náà gba ibi tí ò ti ní forí sọ nǹkan títí tí yóò fi dé èbúté.
Iṣẹ́ ribiribi tí atukọ̀ tó mọ èbúté dunjú yìí ń ṣe ló ṣàpẹẹrẹ ìrànwọ́ aláìláfiwé tó wà fáwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tí wọ́n ní láti la agbami òkun ìgbésí ayé yìí já. Kí ni ìrànwọ́ ọ̀hún? Kí nìdí táwọn èwe fi nílò rẹ̀?
Jẹ́ ká máa bá àpèjúwe ọkọ̀ òkun tá à ń bá bọ̀ lọ. Tó bá jẹ́ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ bàlágà ni, ńṣe lo dà bí awakọ̀ òkun nítorí pé bópẹ́bóyá, fúnra rẹ ni wàá máa bójú tó ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé rẹ. Àwọn òbí rẹ tí wọ́n ń gbìyànjú láti tọ́ ọ sọ́nà kó o lè la àwọn ìṣòro líle já ni wọ́n sì dà bí atukọ̀ òkun tó mọ èbúté dunjú. Àmọ́, láwọn ọdún tó o fi wà ní ọ̀dọ́langba, ó lè má rọrùn fún ọ láti gba ìmọ̀ràn táwọn òbí rẹ bá fún ọ. Kí nìdí?
Ọkàn ẹni ló sábà máa ń fa ìṣòro yìí. Ọkàn rẹ lè máa fà sí ohun tí kò dára tàbí kó mú kó o máa yarí pé o ò ní ṣe ohun tó o rò pé ó ń dín òmìnira tó o ní kù. Bíbélì sọ pé “ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Jèhófà jẹ́ kó o mọ̀ pé wàá rí àdánwò lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì kìlọ̀ pé “Ọkàn enia kún fun ẹ̀tan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jayi!” (Jeremiah 17:9, Bibeli Mimọ) Yàtọ̀ sí pé kí ọkàn ọ̀dọ́ kan máa fà sí ohun burúkú lábẹ́lẹ̀, ọkàn rẹ̀ tún lè tàn án jẹ tí á fi bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé òun mọ̀ ju àwọn òbí òun lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ nírìírí jù ú lọ̀ fíìfíì. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ kó o máa wá ìrànwọ́ àwọn òbí rẹ nígbà tó o bá ń la àwọn ìṣòro ìgbà ọ̀dọ́langba kọjá.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbọ́ràn Sáwọn Òbí Rẹ Lẹ́nu?
Olórí ìdí tó fi yẹ kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, Jèhófà, ẹni tó dá ìdílé sílẹ̀, ló sọ pé kó o fetí sí ìtọ́ni táwọn òbí rẹ bá ń fún ọ. (Éfésù 3:15) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn òbí rẹ ni Ọlọ́run ni kó bójú tó ọ, ìmọ̀ràn Ọlọ́run ni pé: “Ẹnyin ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ́.” (Éfésù 6:1-3, Bibeli Mimọ; Sáàmù 78:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó o ti di ọ̀dọ́langba, síbẹ̀, ojúṣe àwọn òbí rẹ ṣì ni láti máa tọ́ ẹ sọ́nà, o sì gbọ́dọ̀ fetí sí wọn. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé kí àwọn ọmọ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó lò fi hàn pé gbogbo ọmọdé lọ̀rọ̀ náà kàn, ohun tó wù kí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Mátíù 23:37, Jésù pe gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ní “ọmọ” Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ sì rèé, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ń gbébẹ̀ ló jẹ́ àgbàlagbà.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ayé ọjọ́un ló ṣì ń bá a lọ ní ṣíṣègbọràn sáwọn òbí wọn lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti dàgbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jékọ́bù ti di géńdé, ó mọ̀ pé ó yẹ kóun pa àṣẹ bàbá òun mọ́ pé òun kò gbọ́dọ̀ fẹ́ obìnrin tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 28:1, 2) Kò sì sí àní-àní pé Jékọ́bù á ti kíyè sí i pé fífẹ́ tí arákùnrin òun lọ fẹ́ àwọn obìnrin Kénáánì tó jẹ́ kèfèrí ba àwọn òbí òun nínú jẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 27:46.
Yàtọ̀ sí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé àwọn òbí rẹ lọ́wọ́ pé kí wọ́n máa tọ́ ọ sọ́nà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òbí rẹ tó jẹ́ Kristẹni ló tóótun jù lọ láti gbà ọ́ nímọ̀ràn. Ní pàtàkì, ìyẹn jẹ́ nítorí pé wọ́n mọ̀ ọ́ dáadáa, kò sì sí àní-àní pé ojúlówó ìfẹ́ ni wọ́n fi ń hàn sí ọ láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá. Bíi ti ògbóǹkangí awakọ̀ òkun yẹn, ohun tójú àwọn òbí rẹ ti rí ló mú kí wọ́n máa bá ọ sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Àwọn náà ti fìgbà kan rí ní “àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.” Nígbà tó sì tún jẹ́ pé Kristẹni tòótọ́ ni wọ́n, àwọn fúnra wọn ti rí àǹfààní tó wà nínú títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì.—2 Tímótì 2:22.
Bí àwọn tó nírìírí bẹ́ẹ̀ yẹn ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ, ìrànwọ́ wà fún ẹ ti wàá fi lè kẹ́sẹ járí, kódà nínú àwọn ìṣòro tó le koko jù lọ. Àpẹẹrẹ kan ni ti ìbákẹ́gbẹ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin. Báwo làwọn òbí rẹ tó jẹ́ Kristẹni ṣe lè tọ́ ọ sọ́nà lórí ọ̀ràn tó gbẹgẹ́ yìí?
Nígbà Tí Ọkàn Rẹ Bá Ń Fà sí Ọmọkùnrin Kan Tàbí Ọmọbìnrin Kan
Àwọn atukọ̀ òkun tó mọ èbúté dunjú máa ń sọ fún àwọn tó ń wakọ̀ òkun pé kí wọ́n má ṣe wakọ̀ sún mọ́ òkìtì yanrìn tó wà nísàlẹ̀ òkun. Àwọn òkìtì yanrìn tó wà nísàlẹ̀ òkun rọ̀, wọ́n sì léwu nítorí pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń sún láti ibì kan síbòmíràn. Bákan náà, àwọn òbí rẹ yóò fẹ́ kó o jìnnà sí àwọn ohun tó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí mọ̀ pé ìfẹ́ tí ọkùnrin àtobìnrin máa ń ní sí ara wọn máa ń lágbára gan-an, ó sì lè ṣòro láti sọ bó ṣe jẹ́ gan-an. Àmọ́ tí ìfẹ́ yẹn bá lọ gbà ọ́ lọ́kàn, ó lè ṣàkóbá fún ọ.
Àpẹẹrẹ Dínà jẹ́ ká mọ jàǹbá tó wà nínú kéèyàn máa sún mọ́ ewu. Ó lè jẹ́ pé ṣíṣe tí Dínà fẹ́ ṣojúmìító àti fífẹ́ tó fẹ́ láti gbádùn ara rẹ̀ ló mú kó lọ máa bá àwọn ọmọbìnrin Kénáánì tí wọn jẹ́ oníṣekúṣe kẹ́gbẹ́. Kò pẹ́ rárá tí ohun tó dà bí ìgbádùn lásán yìí fi mú un jẹ̀ka àbámọ̀ nítorí pé ‘ọ̀dọ́kùnrin tí ó ní ọlá jù lọ’ nínú ìlú yẹn fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ bá a ṣèṣekúṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 34:1, 2, 19.
Àkókò tá a wà yìí táwọn èèyàn ò mọ̀ ju kí wọ́n kàn máa sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ lọ ló mú kí ewu yìí túbọ̀ máa lágbára sí i. (Hóséà 5:4) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́ lè máa sọ pé kò sóhun tó gbádùn mọ́ èèyàn tó kí ọ̀dọ́kùnrin kan àti ọ̀dọ́bìnrin kan jọ máa gbádùn ara wọn. Ọkàn rẹ lè máa yọ̀ lórí èrò dídá wà pẹ̀lú ọ̀dọ́kùnrin kan tàbí ọ̀dọ́bìnrin kan tí ìrísí rẹ̀ fà ọ mọ́ra. Ṣùgbọ́n àwọn òbí tó jẹ́ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ yóò gbìyànjú láti dáàbò bò ẹ́ kó o má bàa bá àwọn ọ̀dọ́ tí kì í pa àwọ́n ìlànà Ọlọ́run mọ́ kẹ́gbẹ́.
Laura gbà pé fífẹ́ láti mọ ohun tó ń lọ lè máà jẹ́ káwọn ọ̀dọ́langba rí ewu tó wà nínú nǹkan tí wọ́n fẹ́ ṣe. Ó sọ pé: “Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin tá a jọ wà ní kíláàsì ń sọ fún mi pé àwọn bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó fani mọ́ra jó títí di ààjìn òru, ńṣe ni wọ́n ń sọ ọ́ bíi pé ìrírí téèyàn ò lè gbàgbé láéláé ni. Mo mọ̀ pé àsọdùn ni wọ́n ń sọ o, síbẹ̀ náà, mo ṣì fẹ́ láti mọ ohun tó ń lọ, èrò ọkàn mi ṣì ni pé mò ń pàdánù ọ̀pọ̀ ìgbádùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé àwọn òbí mi lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé mi ò gbọ́dọ̀ lọ sí irú àwọn ibi bẹ́ẹ̀, síbẹ̀, ó ṣì máa ń wù mí láti lọ.”
Ó máa ń pẹ́ kí ọkọ̀ òkun tó lè dúró nítorí pé kò ní bíréèkì. Àwọn òbí mọ̀ pé bí ìfẹ́ onígbòónára ṣe rí nìyẹn. Ìwé Òwe fi ọkùnrin kan tí ìfẹ́ tí ò níjàánu ń tì wé màlúù tí wọ́n ń fà lọ sí ibi tí wọ́n á ti pa á. (Òwe 7:21-23) O ò ní fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ọ, kó má bàa kó ìrònú bá ọ kó má sì ba ipò tẹ̀mí rẹ jẹ́. Àwọn òbí rẹ lè mọ̀ nígbà tí ọkàn rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣì ọ́ lọ́nà lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì lè gbà ọ́ nímọ̀ràn. Ǹjẹ́ wàá ní ọgbọ́n tó o máa fi gbọ́rọ̀ sí wọn lẹ́nu kó o má bàa ko àgbákò?—Òwe 1:8; 27:12.
Bákan náà, o nílò ìrànwọ́ àwọn òbí rẹ nígbà tó o bá fẹ́ borí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Báwo ni wọ́n ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́?
Àwọn Ojúgbà Rẹ Lè Sọ Ẹ́ Dà Bí Wọ́n Ṣe Dà
Ìgbì tó lágbára gan-an àti ìṣàn tó gàgaàrá lè darí ọkọ̀ òkun gba ibòmíràn. Awakọ̀ òkun gbọ́dọ̀ darí ọkọ̀ náà pa dà sójú ọ̀nà kí omi má bàa gbé e lọ. Lọ́nà kan náà, ipa tí àwọn ọ̀dọ́ mìíràn bá ní lórí rẹ lè yí ọ padà kó sì darí rẹ kúrò lójú ọ̀nà tẹ̀mí, àyàfi tó o bá ṣe àwọn ohun tí kò ní jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà fi hàn pé, “ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Rántí bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “arìndìn,” pé ó túmọ̀ sí ẹni tí kò mọ Jèhófà tàbí ẹni tó pinnu pé òun ò ní rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.
Àmọ́, ó lè máà rọrùn fún ọ láti kẹ̀yìn sí èrò àti àṣà àwọn ọmọ kíláàsì rẹ o. María José sọ pé: “Mo fẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ mìíràn tẹ́wọ́ gbà mí. Níwọ̀n bí mi ò sì ti fẹ́ kí wọ́n rò pé mo yàtọ̀, mo fara wé wọn gan-an.” Kó o tó mọ̀, àwọn ojúgbà rẹ lè ti nípa lórí rẹ nínú orin tó o yàn láti máa gbọ́, nínú irú aṣọ tó o fẹ́ láti máa wọ̀, kódà nínú ọ̀nà tó ò ń gbà sọ̀rọ̀. Ó lè ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ara rẹ máa ń balẹ̀ tó o bá wà lọ́dọ̀ àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ọjọ́ orí kan náà. Ìyẹn bá ìwà ẹ̀dá mu, àmọ́ á mú kí wọ́n tètè nípa tó lágbára lórí rẹ, ìyẹn sì lè fa ìparun.—Òwe 1:10-16.
Caroline rántí ìṣòro tó ní lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Látìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá làwọn ọmọbìnrin tí mò ń bá kẹ́gbẹ́ tí ń ní ọ̀rẹ́kùnrin, ó sì tó ọdún mélòó kan tó fi ṣe mí bíi pé kémi náà ní ọ̀rẹ́kùnrin. Àmọ́, màmá mi ṣamọ̀nà mi la ìgbà tó le koko yẹn já. Ọ̀pọ̀ wákàtí ní màmá mi á fi wà pẹ̀lú mi, tí wọ́n á máa fetí sí mi, tí wọ́n á máa bá mi fèrò wérò tí wọ́n á sì máa ràn mí lọ́wọ́ ki ń lè rí ìdí tó fi yẹ kí n túbọ̀ dàgbà kí n tó ní irú ìbákẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀.”
Bíi ti ìyá Caroline, àwọn òbí rẹ lè rí i pé ó pọn dandan kí wọn kìlọ̀ fún ọ nípa ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, wọ́n tiẹ̀ lè sọ pé o ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò kan tàbí kí wọ́n sọ fún ọ pé o ò gbọ́dọ̀ bá àwọn kan kẹ́gbẹ́ pàápàá. Nathan rántí pé ọ̀pọ̀ ìgbà lòun àtàwọn òbí òun jọ máa ń jiyàn lórí irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi sábà máa ń pè mí pé kí n bá àwọn jáde, àmọ́ àwọn òbí mi ò fẹ́ kí n máa wà ní sàkáání àwọn tó pọ̀ bẹ́ẹ̀ yẹn tàbí kí n máa lọ sí àpèjẹ ńlá tí ò ní sẹ́ni tó máa yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò ní ti ìwà tí wọ́n bá hù níbẹ̀. Nígbà yẹn, mi ò mọ ìdí tí àwọn òbí mìíràn fi máa ń fàyè gba àwọn ọmọ wọn ju bí àwọn òbí mi ṣe máa ń fàyè gbà mí lọ.”
Àmọ́ Nathan wá mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ nígbà tó yá. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé nínú ọ̀ràn tèmi, ‘ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.’ Ó dà bí ẹni pé ìwà òmùgọ̀ yìí máa ń tètè hàn nígbà tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin bá ń kóra wọn kiri. Ọ̀kan lára wọn á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun kan tí ò dáa, òmíràn á ṣe ohun tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹlòmíràn á wá ṣe ohun tó burú jáì. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn tó kù náà á fẹ́ bá wọn lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Kódà àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n sọ pé àwọn ń sin Jèhófà lè kó sínú pańpẹ́ yìí.”—Òwe 22:15.
Nathan àti María José bá ọkàn wọn jìjàkadì nígbà tí àwọn òbí wọn ò fàyè gbà wọ́n pé kí wọ́n ṣe ohun tí àwọn ojúgbà wọn fi lọ̀ wọ́n. Àmọ́, wọ́n gbọ́rọ̀ sáwọn òbí wọn lẹ́nu, inú wọ́n sì dùn lẹ́yìn náà pé àwọn ṣègbọràn. Ìwé Òwe sọ pé: “Dẹ etí rẹ sílẹ̀ kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ gan-an sí ìmọ̀ mi.”—Òwe 22:17.
Ó Yẹ Kó Ó Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Òbí Rẹ
Bí ọkọ̀ òkun bá fì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó máa ń ṣòroó darí, tó bá sì wá lọ fì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan jù, ó lè tètè dojú dé. Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa ló máa ń ṣe bíi pé ká ṣe ohun tí kò dára. Láìka pé ìwà àìtọ́ ló máa ń wu èèyàn láti hù sí, àwọn ọ̀dọ́ ṣì lè gúnlẹ̀ sébùúté rere, kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí nígbèésí ayé, bí wọ́n bá fara balẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn òbí wọn.
Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí rẹ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tó ò fi ní tẹ́wọ́ gba èrò pé ọ̀nà mìíràn kan wà tó yàtọ̀ sí ọ̀nà tóóró tó lọ sí ìyè àti ọ̀nà fífẹ̀ tó lọ sí ìparun. (Mátíù 7:13, 14) Kò ní bọ́gbọ́n mu kó o ronú pé o lè jẹ̀gbádùn díẹ̀ lára ohun tí kò dára láìrú òfin Ọlọ́run ní ti gidi, bíi pé o lè “tọ́” ẹ̀ṣẹ̀ “wò” láìgbé e mì. Ńṣe ni àwọn tí wọ́n ń gbìyànjú àtiṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń “tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra,” ìyẹn ni pé, wọ́n ń sìn Jèhófà dé àyè kan wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tó wà nínú ayé, ọkọ̀ tẹ̀mí àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ sì lè tètè dojú dé. (1 Àwọn Ọba 18:21; 1 Jòhánù 2:15) Kí nìdí tí ìyẹn fi máa ń ṣẹlẹ̀? Ìdí ni pé híhùwà ẹ̀ṣẹ̀ ló máa ń wá sí wa lọ́kàn.
Ńṣe làwọn ohun tí ò dáa tọ́kàn wa máa ń fà sí nítorí pé a jẹ́ aláìpé máa ń lágbára sí i tá ò bá kápá rẹ̀. Ìtọ́wò ẹ̀ṣẹ̀ lásán kò ní tẹ́ ‘ọkàn wa tó ń ṣe àdàkàdekè’ lọ́run mọ́. Ọkàn wa á tún fẹ́ ká dẹ́ṣẹ̀ yẹn sí i. (Jeremáyà 17:9) Tá a bá wá lọ bẹ̀rẹ̀ sí í sú lọ nípa tẹ̀mí, ayé á bẹ̀rẹ̀ sí í ní ipa tó túbọ̀ lágbára gan-an lórí wa. (Hébérù 2:1) O lè má mọ̀ pé ò ń fì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tàbí pé o ti ń sú lọ nípa tẹ̀mí, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí rẹ mọ̀. Lóòótọ́, wọ́n lè má mọ kọ̀ǹpútà lò bíi tìẹ, àmọ́ tó bá kan ọ̀ràn ọkàn tó ń ṣe àdàkàdekè, wọ́n mọ̀ ọ́n jù ọ́ lọ fíìfíì. Wọ́n sì fẹ́ ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè “máa ṣamọ̀nà ọkàn-àyà rẹ nìṣó ní ọ̀nà” tí yóò yọrí sí ìyè.—Òwe 23:19.
Má ṣe retí pé àwọn òbí kò lè ṣe àṣìṣe kankan nígbà tí wọ́n bá ń tọ́ ẹ sọ́nà lórí àwọn ọ̀ràn tó le, irú bí orin, eré ìnàjú àti ìmúra. Àwọn òbí rẹ lè máà ní ọgbọ́n bíi ti Sólómọ́nì, wọ́n sì lè máà ní sùúrù bíi ti Jóòbù. Bíi ti atukọ̀ òkun tó mọ èbúté dunjú, ìgbà mìíràn wà tí wọ́n lè ṣàṣejù nítorí pé wọ́n fẹ́ dáàbò bò ọ́ kéwu má bàa wu ọ́. Síbẹ̀, ìtọ́sọ́nà wọn yóò ṣe ọ́ láǹfààní tó o bá fiyè sí “ìbáwí baba rẹ, [tí o kò] sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.”—Òwe 1:8, 9.
Àwọn ọ̀dọ́ mìíràn lè máa bẹnu àtẹ́ lu àwọn òbí wọn. Àmọ́, tí àwọn òbí rẹ bá jẹ́ ẹni tó ń tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ wí, wọ́n wà fún ọ bí atukọ̀ òkun tó mọ èbúté dunjú ní ipòkípò tó o bá wà àti ní gbogbo ìgbà tó o bá ní ìṣòro. Bí ẹni tí ń wakọ̀ òkun ṣe máa ń gba ìmọ̀ràn atukọ̀ òkun tó mọ èbúté dunjú, ó ṣe pàtàkì kí o jẹ́ kí àwọn òbí rẹ máa tọ́ ẹ sọ́nà, kí wọ́n máa darí rẹ sí ọ̀nà ọgbọ́n. Èrè jaburata ló máa tibẹ̀ wá.
“Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá, agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, láti dá ọ nídè kúrò ní ọ̀nà búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun àyídáyidà, kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń fi àwọn ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán sílẹ̀ láti rìn ní àwọn ọ̀nà òkùnkùn . . . Nítorí àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀.”—Òwe 2:10-13, 21.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ipa tí àwọn ọ̀dọ́ mìíràn bá ní lórí rẹ lè tì ẹ́ kúrò lójú ọ̀nà tẹ̀mí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Má gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa wá ìtọ́sọ́nà àwọn òbí wọn bí ẹni tí ń wakọ̀ òkun ṣe máa ń wá ìmọ̀ràn atukọ̀ òkun tó mọ èbúté dunjú
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Fọ́tò: www.comstock.com