ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 11/15 ojú ìwé 3-4
  • Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Pẹ́ Láyé Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Pẹ́ Láyé Tó?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Aráyé Ń Sapá Kí Wọ́n Lè Ṣẹ́gun Ikú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • A Dá Wa Láti Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Títí Lọ Gbére
    Jí!—2004
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Ha Ṣeé Ṣe Lóòótọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àwọn Arúgbó Ń Pọ̀ Sí I Láyé
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 11/15 ojú ìwé 3-4

Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Pẹ́ Láyé Tó?

NÍ March 3, 1513, ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan tó máa ń ṣèwádìí káàkiri tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Juan Ponce de León rin ìrìn àjò kan tó pabanbarì. Ọkọ̀ ojú omi ló fi rin ìrìn àjò ọ̀hún láti orílẹ̀-èdè Puerto Rico, ó rò pé òun máa dé erékùṣù Bimini. Ìtàn àtẹnudẹ́nu sọ pé ìsun omi ìyanu kan ló ń wá kiri, ìyẹn Ìsun Omi Àjídèwe. Ṣùgbọ́n, ibi tí ìpínlẹ̀ Florida ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wà lóde òní ló ti bá ara rẹ̀. Kò sì rí ìsun omi tó ń wá káàkiri náà, nítorí pé kò síbì kankan tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ láyé yìí.

Lóde òní, èèyàn kì í lò ju àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún láyé. Ìwé èyí-àrà ọdọọdún nì, 2002 Guinness Book of World Records, sọ pé ẹni tó tíì pẹ́ jù lọ láyé ni ó lo ọdún méjìlélọ́gọ́fà ó lé ọjọ́ mẹ́rìnlélọ́gọ́jọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì dárúkọ àwọn èèyàn tó lo ọdún tó jùyẹn lọ fíìfíì. (Jẹ́nẹ́sísì 5:3-32) Ṣùgbọ́n, John Harris, onímọ̀ nípa oògùn sọ pé: “Ìwádìí tí àwọn èèyàn ń ṣe láyé ìsinyìí fi hàn pé, lọ́jọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe kéèyàn má darúgbó kó má sì kú mọ́ pàápàá. Àwọn kan lára àwọn tó ń ṣèwádìí ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí sọ pé “èèyàn ò ní kú mọ́,” wọ́n ní “tó bá máa fi di ọdún 2099, kò sẹ́ni tó máa kú mọ́,” wọ́n tún sọ pé “èèyàn yóò ní agbára kan tó máa mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara sọ ara wọn dọ̀tun títí ayé,” wọ́n sì tún sọ àwọn nǹkan mìíràn tó fara pẹ́ ẹ.

Nínú ìwé The Dream of Eternal Life tí Mark Benecke kọ, ó sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo sẹ́ẹ̀lì inú ara ló máa ń di ọ̀tun ní ọ̀pọ̀ ìgbà jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé èèyàn. . . . Èyí fi hàn pé lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méje, ara wa á ti di ọ̀tun.” Àmọ́, èyí kì í ṣẹlẹ̀ títí ayé, nítorí pé àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara kì í pín sí kéékèèké mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pín ní iye ìgbà tí wọ́n lè pín sí kéékèèké dé. Benecke sọ pé tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni, “ara èèyàn lè sọ ara rẹ̀ dọ̀tun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àní títí láé.”

Wá ronú nípa agbára gígadabú tí ọpọlọ èèyàn ní, agbára náà sì pọ̀ fíìfíì ju ohun tá a lè fi ọpọlọ ọ̀hún ṣe láàárín àkókò kúkúrú tá a fi wà láyé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé, ọpọlọ èèyàn “kún fún ọ̀pọ̀ nǹkan tí Ọlọ́run fi sínú rẹ̀ débi pé a ò lè lò ó tán nígbà ayé ẹni.” (Ẹ̀dà ti 1976, Ìdìpọ̀ 12, ojú ìwé 998) Ìwé How the Brain Learns (Bí Ọpọlọ Ṣe Ń Ṣiṣẹ́) látọwọ́ David A. Sousa sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ni ọpọlọ èèyàn gbé.”—Ojú ìwé 78, Ẹ̀dà Èkejì, Ẹ̀tọ́ àdàkọ ti 2001.

Kí nìdí táwọn tó ń ṣèwádìí ò fi mọ ohun tó fà á téèyàn fi ń kú? Kí sì nìdí tí ọpọlọ èèyàn fi ní adúrú agbára yẹn? Ṣé kì í ṣe pé Ọlọ́run dá wa ká lè máa kẹ́kọ̀ọ́ títí láé? Kí lohun tó tiẹ̀ mú kéèyàn ronú kan ìyè àìnípẹ̀kun?

Bíbélì sọ pé: “Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni [Ọlọ́run] ti fi sínú ọkàn-àyà wọn, kí aráyé má bàa rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.” (Oníwàásù 3:11) Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé Ọlọ́run ló fi èrò wíwàláàyè títí láé sí wa lọ́kàn. Nítorí náà, a ò ní ṣaláìrí nǹkan kọ́ nípa Ọlọ́run àti nípa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Tá a bá lo ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún láyé, àní tá a bá wà láàyè títí láé, àá túbọ̀ máa kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run.

Bákan náà ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ fi hàn pé ó ṣeé ṣe kéèyàn wà láàyè títí láé. Ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ìwọ náà ńkọ́? Ǹjẹ́ o wù ọ́ láti wà láàyè títí láé?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Juan Ponce de León lọ wá ìsun omi àjídèwe

[Credit Line]

Ponce de León: Harper’s Encyclopædia of United States History

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́