Ànímọ́ Kan Tó Mú Kéèyàn Yàtọ̀ Sẹ́ranko
Iṣẹ́ Jodie ni kó máa bá àwọn èèyàn yẹ ẹrù ẹni tó bá kú wò kó sì sọ iye tí wọ́n lè ta àwọn ẹrù náà. Ó fẹ́ bá obìnrin kan yẹ ẹrù ẹ̀gbọ́n ẹ̀ obìnrin tó kú wò kó sì tún bá a tà wọ́n. Bó ṣe ń yẹ ibi ìyáná tó wà nílé náà wò ló bá rí àwọn ògbólógbòó àpótí méjì níbẹ̀. Nígbà tó rí ohun tó wà nínú ọ̀kan lára àwọn àpótí náà, ẹnu yà á. Wọ́n fi bébà tó ń dán yinrinyinrin di owó sínú rẹ̀, ọgọ́rùn-ún dọ́là ni ọ̀kọ̀ọ̀kan owó náà, àpapọ̀ rẹ̀ wá jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́rin [82,000] dọ́là! Jodie nìkan ló wà nínú yàrá náà. Kí ni kó wá ṣe? Ṣé kó rọra gbé àpótí náà lọ ni àbí kó sọ fún obìnrin tó gbéṣẹ́ fún un pé òun rí owó níbẹ̀?
ÌDÀÀMÚ tó bá Jodie yìí jẹ́ ká rí ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ tó mú káwa èèyàn yàtọ̀ pátápátá sáwọn ẹranko. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀kan lára ànímọ́ àrà ọ̀tọ̀ táwa èèyàn ní ni pé a lè ronú lórí ọ̀ràn kan dáadáa láti mọ̀ bóyá ó yẹ ká ṣe é tàbí ká máà ṣe é.” Bí ajá kan tí ebi ń pa bá rí ẹran lórí tábìlì, kò ní béèrè bóyá kóun jẹ ẹ́ tàbí kóun má jẹ ẹ́ kó tó gbé ẹran náà. Àmọ́, Jodie ni tiẹ̀ ní làákàyè láti mọ̀ bóyá ohun tí òun fẹ́ ṣe dára tàbí kò dára. Tó bá sọ owó náà di tiẹ̀, olè ló jà yẹn, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí àṣírí rẹ̀ máà tú. Lóòótọ́, owó náà kì í ṣe tiẹ̀; àmọ́ ẹni tó gbéṣẹ́ fún un ò mọ̀ pé owó wà níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wà ládùúgbò Jodie ló máa kà á sí ìwà òmùgọ̀ tó bá kó owó náà fún obìnrin tó gbéṣẹ́ yìí fún un.
Tó bá jẹ́ pé ìwọ ló rí owó tí Jodie rí yìí, kí lo máa ṣe? Bó o bá ṣe dáhùn ìbéèrè yìí la ó fi mọ irú ìwà tó ò ń hù.
Kí Ni Híhu Ìwà Tó Dáa Túmọ̀ Sí?
Tá a bá sọ pé ẹnì kan níwà tó dáa, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún jẹ́ ọmọlúwàbí, ó ń ṣe ohun tó tọ́ àtohun tó yẹ.
Tẹ́lẹ̀rí, ìsìn ló ń sọ bó ṣe yẹ káwọn èèyàn máa hùwà. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ti ní ipa gan-an lórí ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ò fara mọ́ onírúurú ìlànà ìsìn, wọ́n ní kò sí ọgbọ́n nínú ohun tí Bíbélì sọ, wọ́n sì sọ pé ìwà tí Bíbélì ní kéèyàn máa hù kò bágbà mu. Ìlànà wo laráyé wá ń tẹ̀ lé báyìí? Ìwé lórí ọ̀ràn ìṣòwò, Ethics in Business Life, sọ pé “Ẹ̀kọ́ ìwé ti borí . . . àṣẹ tí ìsìn ní tẹ́lẹ̀.” Dípò káwọn èèyàn máa lọ sílé ẹ̀sìn láti gba ìtọ́ni nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa hùwà, ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń kọ́ni ní ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti lọ ń gba ìtọ́ni. Paul McNeill, tó jẹ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà àti nípa òfin sọ pé: “Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ló wá ń ṣiṣẹ́ àwọn àlùfáà báyìí. . . . Ìlànà àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n làwọn èèyàn wá ń tẹ̀ lé báyìí dípò kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà ìsìn bí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀.”
Nígbà tó o bá fẹ́ pinnu ohun kan tó ṣe pàtàkì, báwo lo ṣe ń mọ bóyá ó tọ́ tàbí kò tọ́? Ṣé Ọlọ́run ló máa ń sọ irú ìwà tó yẹ kó o hù ni àbí ìwọ fúnra rẹ?