ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 12/1 ojú ìwé 4-7
  • Ìlànà Ta Ló Yẹ Kó O Tẹ̀ Lé Láti Ṣe Ohun Tó Tọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìlànà Ta Ló Yẹ Kó O Tẹ̀ Lé Láti Ṣe Ohun Tó Tọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èrò Àwọn Èèyàn Yàtọ̀ Síra
  • Ṣé Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Gbà Pé Ó Tọ́ Ló Yẹ Ká Máa Ṣe?
  • Ṣé Ohun Tó Bá Ti Dáa Lójú Rẹ Ló Tọ̀nà?
  • Bá A Ṣe Lè Nígboyà Láti Ṣe Ohun Tó Tọ́
  • Ànímọ́ Kan Tó Mú Kéèyàn Yàtọ̀ Sẹ́ranko
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ṣé A Ṣì Lè Gbára Lé Àwọn Ìlànà Bíbélì Lórí Ohun Tó Tọ́ àti Ohun Tí Kò Tọ́?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Máa Sin Jèhófà Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àwọn Ìlànà Tó Fi Lélẹ̀
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Pinnu Ohun Tí Wàá Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 12/1 ojú ìwé 4-7

Ìlànà Ta Ló Yẹ Kó O Tẹ̀ Lé Láti Ṣe Ohun Tó Tọ́?

TA LÓ lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ohun kan tọ́ tàbí kò tọ́? Àtìgbà téèyàn ti wà lókè eèpẹ̀ ni ìbéèrè yẹn ti wà nílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣe sọ, Ọlọ́run pe igi kan tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì ní “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9) Ọlọ́run ṣòfin fún ọkùnrin àti obìnrin tó kọ́kọ́ dá pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi yìí. Àmọ́, Sátánì Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run sọ fún wọn pé bí wọ́n bá jẹ nínú èso igi yìí, “ó dájú pé [ojú wọn] yóò là, ó sì dájú pé [wọn] yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:1, 5; Ìṣípayá 12:9.

Ádámù àti Éfà ní láti pinnu wàyí, ṣé kí wọ́n fara mọ́ ìlànà tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ láti mọ ohun tó dára àtohun tó burú ni àbí kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà tara wọn? (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Wọ́n rú òfin Ọlọ́run, wọ́n jẹ nínú èso igi náà. Kí ni ohun tí wọ́n ṣe wẹ́rẹ́ yìí túmọ̀ sí? Ohun tí òfin Ọlọ́run tí wọ́n rú yìí fi hàn ni pé wọ́n fẹ́ gbé ìlànà ti ara wọn kalẹ̀, wọ́n gbà pé ìyẹn á jẹ́ kí nǹkan dáa fáwọn àtàwọn ọmọ wọn ju ìgbà tí Ọlọ́run bá ń darí wọn. Ṣé nǹkan ti wá dáa fún aráyé báyìí pẹ̀lú bí wọ́n ṣe fẹ́ dà bí Ọlọ́run, tí wọ́n ń gbé ìlànà ti ara wọn kalẹ̀?

Èrò Àwọn Èèyàn Yàtọ̀ Síra

Nígbà táwọn tó kọ ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ṣe àyẹ̀wò ẹ̀kọ́ onírúurú àwọn gbajúgbajà ọ̀jọ̀gbọ́n látìgbà ìjimìjí títí di àkókò wa yìí, wọ́n sọ pé láti ìgbà ayé onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì nì, Socrates títí di ọ̀rúndún ogún, “gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń ṣe atótónu lórí ohun tí ìwà rere túmọ̀ sí gan-an àti ohun tí ìlànà nípa ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ lè jẹ́.”

Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń kọ́ èèyàn ní ìmọ̀ ọgbọ́n orí lókìkí gan-an láàárín àwọn olùkọ́ Gíríìkì ní ọ̀rúndún kárùn-ún ṣáájú Sànmánì Tiwa. Èrò wọn ni pé ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn bá fara mọ́ la fi ń mọ ìlànà ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Ọ̀kan lára irú àwọn olùkọ́ bẹ́ẹ̀ sọ pé: “Ohunkóhun tí ìlú kọ̀ọ̀kan bá ti gbà pé ó bójú mu náà ló dáa fún irú ìlú bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí àwọn ará ibẹ̀ bá ti fara mọ́ ọn.” Tó bá jẹ́ pé irú ìlànà yìí ni Jodie tá a mẹ́nu kan nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú fẹ́ tẹ̀ lé, ńṣe ló yẹ kó gbé owó yẹn, nítorí pé ohun tó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wà lágbègbè rẹ̀ tàbí “ìlú” rẹ̀ ṣe nìyẹn.

Immanuel Kant, onímọ̀ ọgbọ́n orí táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ní ọ̀rúndún kejìdínlógún ní èrò tó yàtọ̀ síyẹn. Ìwé ìròyìn Issues in Ethics sọ pé: “Immanuel Kant àtàwọn mìíràn bíi tirẹ̀ . . . gbà pé olúkúlùkù lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tó wù ú.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Kant sọ, ohun tó bá wu Jodie ló lè ṣe tí ò bá ṣáà ti pa ẹnikẹ́ni lára. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn tó wà lágbègbè rẹ̀ pinnu ohun tó máa ṣe fún un.

Báwo ni Jodie ṣe wá yanjú ọ̀ràn tó di ẹtì sí i lọ́rùn yìí? Ìlànà míì ló tẹ̀ lé. Ẹ̀kọ́ Jésù Kristi ló fi sílò, ẹni táwọn Kristẹni àtàwọn tí kì í ṣe Kristẹni ń kan sáárá sí nítorí ìlànà tó fi lélẹ̀ nípa irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù. Jésù sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún obìnrin tó gbéṣẹ́ fún Jodie nígbà tí Jodie gbé ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́rin [82,000] dọ́là lé e lọ́wọ́. Nígbà tó béèrè ìdí tí Jodie ò fi gbé owó náà lọ, Jodie ṣàlàyé pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun, ó tún sọ pé: “Owó náà kì í ṣe tèmi.” Jodie ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, èyí tó wà nínú Bíbélì nínú Mátíù 19:18, tó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.”

Ṣé Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Gbà Pé Ó Tọ́ Ló Yẹ Ká Máa Ṣe?

Ó ṣeé ṣe káwọn ènìyàn kan sọ pé òmùgọ̀ ni Jodie nítorí pé ó kó gbogbo owó náà sílẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ó tọ́ ló yẹ kéèyàn máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń gbé ní àgbègbè kan tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà níbẹ̀ ò gbà pé ó burú láti fi ọmọdé rúbọ bí àwọn kan ṣe rò láyé àtijọ́, ṣé ìyẹn á wá túmọ̀ sí pé àṣà yẹn tọ̀nà? (2 Àwọn Ọba 16:3) Tó bá jẹ́ pé níbi tí wọ́n bí ọ sí, àwọn tó wà níbẹ̀ gbà pé kò sóun tó burú nínú kéèyàn máa jẹ ẹran èèyàn ńkọ́? Ṣé ìyẹn á wá túmọ̀ sí pé kò sóun tó burú nínú kéèyàn máa jẹ ẹran èèyàn lóòótọ́? Pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń tẹ̀ lé àṣà kan kò túmọ̀ sí pé àṣà náà tọ̀nà o. Tipẹ́tipẹ́ ni Bíbélì ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n ṣọ́ra fún páńpẹ́ yẹn, ó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ fún ète ibi.”—Ẹ́kísódù 23:2.

Jésù Kristi tún sọ ìdí mìíràn téèyàn fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún gbígba èrò ọ̀pọ̀ èèyàn gẹ́gẹ́ bí èyí tá a lè fi mọ ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì ni “olùṣàkóso ayé.” (Jòhánù 14:30; Lúùkù 4:6) Sátánì ń lo ipò rẹ̀ láti ṣi “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” lọ́nà. (Ìṣípayá 12:9) Nítorí náà, tó bá jẹ́ pé èrò ọ̀pọ̀ èèyàn lo máa fi mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ sí èyí tí kò tọ́, á jẹ́ pé ojú tí Sátánì fi ń wo ọ̀ràn náà ni ìwọ náà fi ń wò ó, ìyẹn sì lè fa jàǹbá ńlá.

Ṣé Ohun Tó Bá Ti Dáa Lójú Rẹ Ló Tọ̀nà?

Ṣé kí oníkálukú máa fúnra rẹ̀ pinnu ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ ni? Bíbélì sọ pé: “Má sì gbára lé òye tìrẹ.” (Òwe 3:5) Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo èèyàn ló ti jogún àléébù kan tó lè máà jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́. Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n tẹ́wọ́ gba ìlànà tí Sátánì ọ̀dàlẹ̀ àti onímọtara-ẹni-nìkan gbé kalẹ̀, wọ́n sì jẹ́ kó di bàbá wọn nípa tẹ̀mí. Wọ́n wá tipa bẹ́ẹ̀ kó èèràn ran àwọn àtọmọdọ́mọ wọn, èèràn ọ̀hún sì ni ọkàn àdàkàdekè tí wọ́n lè fi mọ ohun tó tọ́ àmọ́ tó tún máa mú wọn ṣe ohun tí kò tọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 6:5; Róòmù 5:12; 7:21-24.

Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ìwà tó dáa túmọ̀ sí, ó sọ pé: “Kò yani lẹ́nu nígbà táwọn èèyàn bá mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe àmọ́ tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń ṣe ohun tí ọkàn wọn fẹ́. Bá a ṣe máa jẹ́ kí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa ṣe ohun tó tọ́ ti di ìṣòro ńlá ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé.” Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jeremáyà 17:9) Ǹjẹ́ o lè fọkàn tán ẹnì kan tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí aládàkàdekè tó sì lè gbékútà?

Ká sòótọ́, àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ pàápàá lè hùwà tó tọ́ wọ́n sì lè hùwà tó dára tó sì buyì fúnni. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìlànà rere tí wọ́n ń tẹ̀ lé ló bá ohun tí Bíbélì fi ń kọ́ni mu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò gbà pé Ọlọ́run wà, síbẹ̀ ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú fi hàn pé àwọn náà ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run. Èyí fi hàn pe òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ pé “àwòrán Ọlọ́run” ni á dá ènìyàn látilẹ̀wá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Ìṣe 17:26-28) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn gan-an ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn-àyà wọn.”—Róòmù 2:15.

Àmọ́ ṣá o, ohun kan ní kéèyàn mọ ohun tó tọ́, ohun mìíràn sì tún ni kéèyàn nígboyà láti ṣe ohun tó tọ́. Báwo lèèyàn ṣe lè dẹni tó ń hùwà rere? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun téèyàn ń rò lọ́kàn ló fi ń hùwà, téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó ni Bíbélì, èyí yóò ran èèyàn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun tó dára.—Sáàmù 25:4, 5.

Bá A Ṣe Lè Nígboyà Láti Ṣe Ohun Tó Tọ́

Ohun téèyàn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe tó bá fẹ́ kọ́ bóun ṣe máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni pé kó mọ bí àwọn àṣẹ rẹ̀ ṣe bọ́gbọ́n mu tó àti bí wọ́n ṣe wúlò tó. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó wúlò ló wà nínú Bíbélì tó lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ nígbà tó bá dórí ọ̀ràn mímú ọtí líle, lílo oògùn olóró, tàbí níní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Bíbélì lè ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe máa yanjú èdè àìyedè láàárín ara wọn, ó sì tún lè fún àwọn òbí ní ìlànà tí wọ́n máa tẹ̀ lé láti tọ́ àwọn ọmọ wọn.a Táwọn èèyàn bá ń hùwà bí Bíbélì ṣe ní ká máa hùwà, yóò ṣàǹfààní fún tọmọdé tàgbà, láìfi bí wọ́n ṣe kàwé tó, tàbí irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ pè.

Bí oúnjẹ aṣaralóore ṣe máa ń fún ọ lókun láti ṣíṣẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò ṣe fún ọ lókun láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú rẹ̀. Jésù fi àwọn ọ̀rọ̀ tó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wé oúnjẹ tó ń fúnni ní ìyè. (Mátíù 4:4) Ó tún sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 4:34) Oúnjẹ tẹ̀mí tí Jésù máa ń jẹ látinú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ràn án lọ́wọ́ tí ò fi kó sínú ìdẹwò, òun ló sì mú kó ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.—Lúùkù 4:1-13.

Lákọ̀ọ́kọ́, ó lè má rọrùn fún ọ láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ ara rẹ kí o sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú rẹ̀. Rántí pé oúnjẹ tó máa ṣe ara rẹ̀ lóore lè má dùn lẹ́nu rẹ nígbà tó o wà ní kékeré. Àmọ́ nítorí pé o fẹ́ dàgbà kó o sì lágbára, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ràn irú oúnjẹ aṣaralóore bẹ́ẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Bákan náà, ó lè gba àkókò gan-an kó o tó nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìlànà Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n tó o bá tẹra mọ́ ọn, wàá fẹ́ràn rẹ̀ tó bá yá, wàá sì di alágbára nípa tẹ̀mí. (Sáàmù 34:8; 2 Tímótì 3:15-17) Wàá kọ́ béèyàn ṣe ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wàá sì fẹ́ láti máa “ṣe rere.”—Sáàmù 37:3.

Ó ṣeé ṣe kó o máà rí irú owó tí Jodie rí yẹn o. Síbẹ̀síbẹ̀ ojoojúmọ́ lo máa ń ṣe àwọn ìpinnu láti ṣe ohun tó tọ́ yálà lórí ohun tó ṣe pàtàkì tàbí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà ọ́ nímọ̀ràn pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kì í ṣe pé o máa jàǹfààní nísinsìnyí nìkan ni, àmọ́ yóò tún jẹ́ kó o láǹfààní àtiwà láàyè títí láé, nítorí pé ìgbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run máa ń yọrí sí ìyè.—Mátíù 7:13, 14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tí Bíbélì fúnni lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí àtàwọn ọ̀ràn mìíràn tó ṣe pàtàkì wà nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ àti Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ àwọn ìwé yìí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Ó lè jẹ́ àwọn ẹ̀mí búburú ló wà nídìí àwọn ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ó tọ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ó ti pẹ́ gan-an táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ti máa ń ṣe atótónu lórí ọ̀rọ̀ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́

SOCRATES

KANT

CONFUCIUS

[Àwọn Credit Line]

Kant: Látinú ìwé The Historian’s History of the World; Socrates: Látinú ìwé A General History for Colleges and High Schools; Confucius: Sung Kyun Kwan University, Seoul, Korea

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Kì í ṣe pé Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ nìkan ni, ó tún ń fún wa níṣìírí láti ṣe ohun tó tọ́ pẹ̀lú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́