ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w05 9/1 ojú ìwé 3
  • Ǹjẹ́ Ìṣòtítọ́ Lérè?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ìṣòtítọ́ Lérè?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀pọ̀ Èèyàn Mọyì Ìṣòtítọ́ Àmọ́ Wọn Kì Í Fi Ṣèwà Hù
  • Kíyè Sí Àwọn Adúróṣinṣin!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Kíkojú Ìpènijà Ìdúróṣinṣin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ta Ló Yẹ Kó O Jẹ́ Adúróṣinṣin Sí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
w05 9/1 ojú ìwé 3

Ǹjẹ́ Ìṣòtítọ́ Lérè?

“ADÉa sọ fún Ṣọlá ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Ó yẹ kó o wá iṣẹ́ mìíràn ṣe. Owó tó o ń gbà nílé iṣẹ́ tó o wà yẹn ò tó rárá. Tó o bá lọ ṣiṣẹ́ níbòmíì, owó tí wàá máa gbà á pọ̀ jùyẹn lọ.”

Ṣọlá fèsì pé: “Òótọ́ lo sọ. Àmọ́ mo ti ń bá wọn ṣiṣẹ́ tipẹ́. Wọ́n ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an, mi ò sì fẹ́ dà wọ́n.”

Adé wá sọ pé: “Ohun tó dáa ni kéèyàn jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́ jíjẹ́ tó o jẹ́ olóòótọ́ sí wọn ò jẹ́ kó o lówó tó bó ṣe yẹ!”

Òótọ́ ni Adé sọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, jíjẹ́ olóòótọ́ sí ẹnì kan lè máà jẹ́ kéèyàn fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Kódà, ó lè gba àkókò àti okun ẹni, kó sì tún gba pé kéèyàn máa fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣe nǹkan. Ǹjẹ́ ó yẹ kéèyàn ṣe gbogbo wàhálà yìí torí pé ó fẹ́ jẹ́ olóòótọ́?

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Mọyì Ìṣòtítọ́ Àmọ́ Wọn Kì Í Fi Ṣèwà Hù

Nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nu-wò tí àjọ aṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Allensbach lórílẹ̀-èdè Jámánì ṣe, ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [96] nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé ìṣòtítọ́ jẹ́ ànímọ́ kan tó fani mọ́ra. Ìwádìí kejì tí Àjọ Allensbach ṣe láàárín àwọn ọmọ ọdún méjìdínlógún sí ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún fi hàn pé méjì nínú mẹ́ta àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló ka ìṣòtítọ́ sí ohun tó dára.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi gbogbo làwọn èèyàn ti gbà pé ìṣòtítọ́ dára, ọ̀tọ̀ lohun tí wọ́n máa ń ṣe tó bá di ọ̀ràn kéèyàn jẹ́ olóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, láwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù, àwọn tọkọtaya tàbí àwọn tí wọ́n wá látinú ìdílé kan náà kì í sábà jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. Àwọn ọ̀rẹ́ sábà máa ń da ara wọn. Bákan náà, ìṣòtítọ́ tó ti ń mú kí àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín agbanisíṣẹ́ àti òṣìṣẹ́ nígbà kan rí tàbí èyí tó máa ń wà láàárín oníṣòwò àti oníbàárà kò sí mọ́. Kí ló fà á?

Nígbà mìíràn kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé kì í jẹ́ káwọn èèyàn rí àyè tàbí kí wọ́n lókun nínú láti wọnú àdéhùn tó gba pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́. Àwọn tó ti rí ìjákulẹ̀ nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lè máà fẹ́ fọkàn tán ẹnikẹ́ni mọ́. Àwọn mìíràn sì lè yàn láti máa gbé ìgbésí ayé màá-jayé-òní mi-ò-mẹ̀yìn-ọ̀la, tí kò béèrè pé kéèyàn jólóòótọ́ sí ẹnikẹ́ni.

Fún ìdí kan tàbí òmíràn, àwọn èèyàn mọyì ìṣòtítọ́, àmọ́ wọn kì í fi ṣèwà hù. Nítorí náà, ìbéèrè tó yẹ ká bi ara wa ni pé: Ǹjẹ́ ìṣòtítọ́ lérè? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta ló yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ sí? Ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe é? Kí làǹfààní jíjẹ́ olóòótọ́?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e padà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

Àwọn èèyàn mọyì ìṣòtítọ́, àmọ́ wọn kì í fi ṣèwà hù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́