ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w05 10/15 ojú ìwé 3
  • Irú Ẹ̀kọ́ Wo Ló Lè Mú Kí Ayé Rẹ Dára?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Irú Ẹ̀kọ́ Wo Ló Lè Mú Kí Ayé Rẹ Dára?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́—Lò Ó Láti Yin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ojú Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wo Ẹ̀kọ́ Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Bíbélì Ha Ṣàìfún Ẹ̀kọ́ Ìwé Níṣìírí Bí?
    Jí!—1998
  • Ẹkọ-iwe Pẹlu Ète Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
w05 10/15 ojú ìwé 3

Irú Ẹ̀kọ́ Wo Ló Lè Mú Kí Ayé Rẹ Dára?

ǸJẸ́ ìgbà kan wà tí ìṣòro rẹ pọ̀ gan-an tó wá dà bíi pé o wà láàárín alagbalúgbú omi tó fẹ́ gbé ọ lọ? Fojú inú wo adúrú ìyà tó lè jẹ ọ́ tí o kò bá lè yanjú ọ̀kan tàbí díẹ̀ nínú ìṣòro rẹ bó ṣe yẹ! Kò sẹ́ni tó ní ọgbọ́n tó lè máa fi yanjú gbogbo ìṣòro tó ní nígbà gbogbo láìṣàṣìṣe kankan tàbí kó máa ṣèpinnu tó tọ̀nà ní gbogbo ìgbà. Ìdí rèé tí ẹ̀kọ́ fi ṣe kókó. Àmọ́, ibo lo ti lè rí ẹ̀kọ́ tó máa jẹ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe yanjú àwọn ìṣòro rẹ?

Ọ̀pọ̀ èèyàn, àtọmọdé àtàgbà, ló gbà pé ẹ̀kọ́ ilé ìwé ṣe pàtàkì gan-an. Kódà, àwọn ògbógi kan tiẹ̀ sọ pé “ó dá [àwọn] lójú ṣáká pé èèyàn ò lè ríṣẹ́ [gidi] ṣe láìjẹ́ pé ó lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga.” Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan wà nígbèésí ayé ẹ̀dá tó jẹ́ pé ipò gíga téèyàn wà ò lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ lílọ sílé ẹ̀kọ́ gíga nìkan lè mú kéèyàn di òbí rere, ọkọ tàbí aya rere, tàbí ọ̀rẹ́ àtàtà? Àwọn kan tí ìmọ̀ àti òye wọn mú káwọn èèyàn gba tiwọn láwùjọ tiẹ̀ lè máa hu àwọn ìwà kan tí kò bójú mu, ilé àwọn míì lára wọn lè má tòrò, tàbí káwọn míì tiẹ̀ para wọn.

Ìsìn làwọn kan gbà pé ó lè tọ́ àwọn sọ́nà, pé ibẹ̀ làwọn ti lè rí ẹ̀kọ́ kọ́, àmọ́ ìjákulẹ̀ ló máa ń jẹ́ fún wọn nígbà tí ìsìn ò bá fún wọn nímọ̀ràn tó wúlò tí wọ́n lè fi yanjú ìṣòro wọn. Ohun tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Emiliaa tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn, ó ní: “Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn ni mo rí i pé èmi àti ọkọ mi ò lè fẹ́ra wa mọ́. Gbogbo ìgbà la máa ń jiyàn lórí ọ̀rọ̀ kan tàbí òmíràn. Mo gbìyànjú láti gba ọtí lẹ́nu ẹ̀, àmọ́ pàbó ló já sí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń fi àwọn ọmọ wa kékeré sílẹ̀ nílé tí màá máa wá baálé mi kiri. Gbogbo ọ̀rọ̀ náà wá tojú sú mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì bóyá màá lè rí ohun tó lè ràn mí lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro náà. Wọ́n máa ń ka Bíbélì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ náà o, àmọ́ wọn ò fún mi nímọ̀ràn tó lè ràn mí lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro mi, bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó wá bá mi sọ ohun tí mo lè ṣe. Jíjókòó tí mo máa ń jókòó sí ṣọ́ọ̀ṣì fúngbà díẹ̀ tí màá máa gbàdúrà níbẹ̀ kò tánṣòro mi.” Àwọn mìíràn kì í mọ ohun tí wọ́n lè ṣe nígbà tí wọ́n bá rí i pé àwọn aṣáájú ìsìn wọn ò fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ìdí rèé tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé ìsìn ò lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tó lè jẹ́ káyé wọn dára.

Nítorí náà, o lè bi ara rẹ pé, ‘Irú ẹ̀kọ́ wo ló yẹ kí n kọ́ tó máa jẹ́ kí ayé mi dára?’ Ǹjẹ́ ìsìn Kristẹni tòótọ́ lè dáhùn ìbéèrè pàtàkì yìí? A óò sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ yìí padà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́