ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 1/1 ojú ìwé 16-19
  • ‘Ọ̀rọ̀ Tó Bọ́ Sákòókò Mà Dára o!’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ọ̀rọ̀ Tó Bọ́ Sákòókò Mà Dára o!’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Rẹ̀
  • Àwọn Tí Ìyìn Tọ́ Sí
  • Nínú Ìdílé
  • Máa Fi Ẹ̀mí Rere Sọ Ọrọ̀ Ìyìn, sì Máa Fi Ẹ̀mí Tó Dáa Gbà Á
  • Máa Gbóríyìn Fáwọn Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Gbígbóríyìn Fúnni Ń Mára Tuni
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Gbígbóríyìn fún Wọn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbóríyìn fún Àwọn Èèyàn?
    Jí!—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 1/1 ojú ìwé 16-19

‘Ọ̀rọ̀ Tó Bọ́ Sákòókò Mà Dára o!’

NÍGBÀ tí àpéjọ ọlọ́jọ́ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò ń lọ lọ́wọ́, Kim sa gbogbo ipá rẹ̀ láti tẹ́tí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló sì tún ń gbìyànjú láti mú kí ọmọbìnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì ààbọ̀ jókòó jẹ́ẹ́. Nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà parí, arábìnrin kan tó jókòó nítòsí Kim yíjú sí i, ó sì yìn ín gan-an fún ọ̀nà tí òun àti ọkọ rẹ̀ gbà bójú tó ọmọ wọn nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ń lọ lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ ìṣírí yẹn wọ Kim lọ́kàn débi pé, ní báyìí tí ọdún díẹ̀ ti kọjá lẹ́yìn ìgbà náà, ó sọ pé: “Nígbà tó bá rẹ̀ mí gan-an nípàdé, mo máa ń ronú nípa ohun tí arábìnrin yẹn sọ. Ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ tó sọ fún mi yẹn ṣì ń fún mi níṣìírí láti máa tọ́ ọmọ wa lọ́nà tó dára.” Láìsí àní-àní, ọ̀rọ̀ téèyàn sọ tó sì bọ́ sákòókò lè fún ẹni tá a sọ ọ́ fún níṣìírí. Bíbélì sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò mà dára o!’—Òwe 15:23.

Àmọ́ ṣá o, yíyin àwọn ẹlòmíràn lè má rọrùn fáwọn kan lára wa. Nígbà míì, tá a bá ronú nípa àwọn ibi táwa fúnra wa kù sí, ó lè mú kó ṣòro fún wa láti yin àwọn ẹlòmíràn. Arákùnrin kan sọ pé: “Bí ìgbà tí mo dúró sórí ẹrẹ̀ ló ṣe máa ń rí lára mi. Bí mo bá ṣe ń yin àwọn ẹlòmíràn tó, bẹ́ẹ̀ náà ni mo ṣe máa ń ní èrò pé èmi ò já mọ́ nǹkan kan tó.” Àwọn nǹkan bí ìtìjú, àìdára-ẹni-lójú, tàbí ìbẹ̀rù pé àwọn èèyàn lè ṣini lóye tún lè mú kó ṣòro láti yin àwọn èèyàn. Yàtọ̀ síyẹn, bí wọn ò bá ń fi bẹ́ẹ̀ yìn wá nígbà tá a wà ní kékeré tàbí tí wọn ò bá tiẹ̀ ń yìn wá rárá, ó lè ṣòro fún wa láti máa yin àwọn ẹlòmíràn.

Síbẹ̀, mímọ̀ pé yíyin àwọn ẹlòmíràn máa ń nípa tó dára lórí ẹni tá a yìn àtẹni tó yinni lè mú ká sapá gan-an láti máa yin àwọn èèyàn lákòókò tó tọ́. (Òwe 3:27) Àwọn àǹfààní wo la máa wá rí tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò ní ṣókí.

Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Rẹ̀

Yíyin ẹnì kan lọ́nà tó tọ́ lè mú kẹ́ni náà túbọ̀ dáńgájíá. Arábìnrin Elaine tó jẹ́ ìyàwó ilé sọ pé: “Táwọn èèyàn bá yìn mí, ó máa ń jẹ́ kí n rí i pé wọ́n fọkàn tán mi, àti pé mi ò já wọn kulẹ̀.” Òótọ́ ni o, tá a bá yin ẹnì kan tí kò dá ara rẹ̀ lójú, èyí lè fún ẹni náà nígboyà láti lè borí àwọn ohun tó jẹ́ ìdènà fún un, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ayọ̀. Àwọn ọ̀dọ́ ló sábà máa ń jàǹfààní jù tá a bá yìn wọ́n nígbà tí wọ́n bá ṣe ohun tó dára. Ọ̀dọ́ kan tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún ṣàlàyé pé àwọn èrò tí kò tọ́ tóun máa ń ní nípa ara òun máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun. Ó sọ pé: “Mo máa ń sa gbogbo ipá mi láti múnú Jèhófà dùn, àmọ́ nígbà míì ńṣe ló máa ń dà bíi pé kò sóhun ti mo ṣe tó dára tó. Àmọ́ tẹ́nì kan bá yìn mí, ó máa ń múnú mi dùn gan-an.” Dájúdájú, òótọ́ ni òwe Bíbélì tó sọ pé: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.”—Òwe 25:11.

Yinniyinni kẹ́ni ó ṣèmíì. Òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún kan sọ pé: “Táwọn èèyàn bá yìn mí, ó máa ń fún mi níṣìírí láti túbọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí n sì túbọ̀ mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi dára sí i.” Obìnrin kan tó lọ́mọ méjì sọ pé, nígbà táwọn ará nínú ìjọ bá yin àwọn ọmọ òun nítorí pé wọ́n dáhùn nípàdé, wọ́n túbọ̀ máa ń fẹ́ láti dáhùn sí i. Kò sí àní-àní pé yíyin àwọn ọmọ kéékèèké lè mú kí wọ́n túbọ̀ fẹ́ láti ṣe dáadáa sí i nínú ìgbésí ayé wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Ká sòótọ́, gbogbo wa pátá là ń fẹ́ káwọn èèyàn mú un dá wa lójú pé àwọ́n mọyì wa àti pé a wúlò. Ayé tó kún fún wàhálà yìí lè mú kó rẹ̀ wá ká sì rẹ̀wẹ̀sì. Kristẹni kan tó jẹ́ alàgbà sọ pé: “Nígbà míì tí ọkàn mi bá rẹ̀wẹ̀sì, táwọn èèyàn bá wá yìn mí nítorí ohun kan, ńṣe ló máa ń dà bíi pé Jèhófà dáhùn àdúrà mi.” Ọ̀rọ̀ tí Elaine sọ fara jọ èyí náà, ó ní: “Nígbà míì, ńṣe ló máa ń dà bíi pé Jèhófà ń jẹ́ kí n mọ̀ pé òun tẹ́wọ́ gbà mí nígbà táwọn èèyàn bá yìn mí.”

Yíyinni lè jẹ́ kẹ́ni tá a yìn mọ̀ pé àwọn èèyàn ka òun sí. Yíyin àwọn èèyàn látọkànwá fi hàn pé à ń ronú nípa wọn ó sì máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú wọn, ó ń fini lọ́kàn balẹ̀, ó sì ń jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ara wa. Ó jẹ́ ẹ̀rí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn Kristẹni ẹlẹ́gbẹ́ wa dénú, a sì mọyì wọn. Josie, tó jẹ́ ìyálọ́mọ sọ pé: “Lákòókò kan, mo ní láti di ìgbàgbọ́ mi mú nínú ìdílé mi tá a ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lákòókò náà, ìfẹ́ táwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí fi hàn sí mi ló jẹ́ kí n lè dúró lórí ìpinnu mi láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀.” Láìsí àní-àní, “ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.”—Éfésù 4:25.

Fífẹ́ láti yin àwọn èèyàn máa ń jẹ́ ká rí ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Àwọn ànímọ́ dáadáa táwọn mìíràn ní là ń wò kì í ṣe kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Kristẹni kan tó jẹ́ alàgbà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ David sọ pé: “Mímọyì ohun táwọn mìíràn ń ṣe yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa yìn wọ́n gan-an.” Rírántí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára nípa àwọn èèyàn aláìpé yóò mú káwa náà máa yin àwọn èèyàn.—Mátíù 25:21-23; 1 Kọ́ríńtì 4:5.

Àwọn Tí Ìyìn Tọ́ Sí

Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá, òun lẹni àkọ́kọ́ lára àwọn tí ìyìn tọ́ sí. (Ìṣípayá 4:11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìyìn tá a bá fún un ló máa jẹ́ kó mọ̀ pé òun tóótun tàbí ló máa fún un níṣìírí láti ṣe dáadáa sí i, síbẹ̀, nígbà tá a bá yìn ín fún jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni àgbàyanu àti fún inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò túbọ̀ sún mọ́ wa yóò sì ṣeé ṣe fún wa láti ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀. Yíyin Ọlọ́run tún máa ń jẹ́ ká ní èrò tó tọ́ nípa àwọn àṣeyọrí wa ká má sì ṣe jọ ara wa lójú nítorí àwọn àṣeyọrí náà. Ó tún máa ń jẹ́ ká gbà pé Jèhófà ló mú káwọn àṣeyọrí náà ṣeé ṣe. (Jeremáyà 9:23, 24) Jèhófà ń ké sí gbogbo àwọn ọlọ́kàn rere pé àǹfààní wà fún wọn láti rí ìyè àìnípẹ̀kun, èyí sì jẹ́ ìdí mìíràn tó ń mú ká máa yìn ín. (Ìṣípayá 21:3, 4) Ó máa ń wu Dáfídì Ọba láti máa “yin orúkọ Ọlọ́run” àti láti máa “fi ìdúpẹ́ gbé e ga lọ́lá.” (Sáàmù 69:30) Ẹ jẹ́ kí àwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀.

Ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn tá a jọ jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà nígbà tó bá yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Bá a bá ń gbóríyìn fún wọn, ńṣe là ń pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ pé “kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Hébérù 10:24) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹnì kan tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lórí kókó yìí. Nínú lẹ́tà tó kọ sí ìjọ tó wà ní Róòmù, ó sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run mi nípasẹ̀ Jésù Kristi nítorí gbogbo yín, nítorí a ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ yín jákèjádò ayé.” (Róòmù 1:8) Bákan náà, àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ kí Gáyọ́sì tó jẹ́ Kristẹni bíi tirẹ̀ mọ̀ pé àpẹẹrẹ àtàtà ló jẹ́ nínú “rírìn nínú òtítọ́.”—3 Jòhánù 1-4.

Lónìí náà, nígbà tí ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni bá fi ànímọ́ Kristi hàn lọ́nà kan tá a fi lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, tàbí tó ṣe iṣẹ́ kan nípàdé lọ́nà tó fi hàn pé ó múra sílẹ̀ dáadáa, tàbí tó dáhùn ìbéèrè kan látọkànwá nípàdé, àǹfààní àtàtà lèyí jẹ́ fún wa láti kí onítọ̀hún pé a mọrírì ohun tó ṣe. Tàbí kẹ̀, tí ọmọ kékeré kan bá ń sapá gan-an láti wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ rí nígbà tí ìpàdé ìjọ ń lọ lọ́wọ́, a lè yìn ín. Arábìnrin Elaine tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè sọ pé: “Ẹ̀bùn gbogbo wa ò dọ́gba. Nígbà tá a bá fi hàn pé a ń kíyè sóhun táwọn mìíràn ń ṣe, ńṣe là ń fi hàn pé a mọrírì onírúurú ẹ̀bùn táwọn èèyàn Ọlọ́run ní.”

Nínú Ìdílé

Ǹjẹ́ a tiẹ̀ máa ń yin àwọn tó wà nínú ìdílé wa? Ó ń gba ọ̀pọ̀ àkókò, ìsapá àti àbójútó onífẹ̀ẹ́ kí ọkọ àti aya tó lè pèsè fún ìdílé wọn nípa tara àti nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì tún fi ìfẹ́ hàn sí wọn. Dájúdájú, ó yẹ kí wọ́n máa yin ara wọn káwọn ọmọ wọn náà sì máa yìn wọ́n. (Éfésù 5:33) Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa aya kan tó dáńgájíá pé: “Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní aláyọ̀; olúwa rẹ̀ dìde, ó sì yìn ín.”—Òwe 31:10, 28.

Ó yẹ ká máa yin àwọn ọmọ pàápàá. Àmọ́ ó dunni pé, ó máa ń yá àwọn òbí kan lára láti sọ fáwọn ọmọ wọn nípa ohun tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n máa ṣe, ṣùgbọ́n wọn kì í sábà yin àwọn ọmọ náà tí wọ́n bá ṣègbọràn tàbí tí wọ́n bá bọ̀wọ̀ fúnni. (Lúùkù 3:22) Báwọn òbí bá ń yin àwọn ọmọ wọn láti kékeré, ó sábà máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn, ọkàn wọn sì túbọ̀ máa ń balẹ̀.

Lóòótọ́, ó gba ìsapá láti yin àwọn èèyàn, àmọ́ ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ká sòótọ́, bá a bá ṣe túbọ̀ ń yin àwọn èèyàn tó yẹ ká yìn, bẹ́ẹ̀ layọ̀ wa á ṣe túbọ̀ máa pọ̀ sí i.—Ìṣe 20:35.

Máa Fi Ẹ̀mí Rere Sọ Ọrọ̀ Ìyìn, sì Máa Fi Ẹ̀mí Tó Dáa Gbà Á

Yíyin àwọn kan lè di àdánwò fún wọn. (Òwe 27:21) Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú káwọn tó lẹ́mìí ìgbéraga máa ronú pé àwọn sàn ju àwọn mìíràn lọ. (Òwe 16:18) Nípa bẹ́ẹ̀, ó gba ìṣọ́ra. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ìṣílétí tó dára gan-an fún wa, ó ní: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pín ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún un.” (Róòmù 12:3) Ọ̀nà tá a lè gbà ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa jìn sí ọ̀fìn ríronú nípa ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ ni pé ká má ṣe máa sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe jẹ́ olórí pípé tó tàbí bí wọ́n ṣe lẹ́wà tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun dáadáa táwọn èèyàn ṣe ló yẹ ká máa torí rẹ̀ yìn wọ́n.

Bá a bá ń fi ẹ̀mí rere yin àwọn èèyàn táwa náà sì ń fi ẹ̀mí tó dáa gbà á, ó lè ṣe wá láǹfàání. Ó lè sún wa láti gbà pé Jèhófà ni ìyìn tọ́ sí fún ohun rere èyíkéyìí tá a bá ṣe. Ọrọ̀ ìyìn tún lè fún wa níṣìírí láti máa ṣe dáadáa nìṣó.

Ọ̀rọ̀ ìyìn tó tinú ọkàn wa wá tá a sọ ọ́ fún ẹni tó ṣe ohun kan tó dára jẹ́ ẹ̀bùn tí gbogbo wa lè fún àwọn mìíràn. Bá a bá yin ẹnì kan dáadáa nítorí pé a ronú nípa onítọ̀hún, ó lè jọ ẹni náà lójú ju bá a ṣe rò lọ.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Lẹ́tà Náà Wọ̀ Ọ́ Lọ́kàn Gan-an

Alábòójútó arìnrìn-àjò kan rántí ìgbà kan tóun àtìyàwó rẹ̀ padà délé tí wọ́n fi wọ́n sí lẹ́yìn iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ́jọ́ kan tí òtútù mú gan-an. Ó sọ pé: “Òtútù ń mú ìyàwó mi, ó sì rẹ̀wẹ̀sì, ló bá sọ fún mi pé òun ò rò pé òun á lè máa bá iṣẹ́ náà lọ mọ́. Ó ní, ‘Ó sàn ká kúkú máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún nínú ìjọ kan, ká fìdí kalẹ̀ sójú kan, ká sì máa darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tiwa.’ Mi ò sọ fún un pé ká ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí ká má ṣe bẹ́ẹ̀, mo kàn sọ fún un pé kó jẹ́ kí ọ̀sẹ̀ yẹn ṣì parí ná ká wá wo bí nǹkan ṣe máa rí lára rẹ̀. Bó bá ṣì fẹ́ ká fi iṣẹ́ arìnrìn-àjò sílẹ̀, màá gba tirẹ̀ rò. Lọ́jọ́ yẹn gan-an, a yà nílé ìfìwéránṣẹ́ a sì rí lẹ́tà kan tó wá láti ẹ̀ka iléeṣẹ́. Òun gan-an ni wọ́n kọ lẹ́tà náà sí. Ọ̀rọ̀ ìyìn tó dùn mọ́ni ló wà nínú lẹ́tà náà, tó sọ nípa ìsapá rẹ̀ àti ìfaradà rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àti bí kò ṣe rọrùn rárá láti máa sùn lórí oríṣiríṣi ibùsùn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ọ̀rọ̀ ìyìn yẹn wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé kò tún sọ ọ́ mọ́ látìgbà náà pé òun fẹ́ fi iṣẹ́ arìnrìn-àjò sílẹ̀. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti fún mi níṣìírí pé kí n má ṣe fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ nígbà tí mo bá ń ronú láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì ọdún táwọn tọkọtaya yìí fi ń bá iṣẹ́ arìnrìn-àjò náà lọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Nínú ìjọ yín, ta lo lè yìn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn ọmọdé máa ń ṣe dáadáa gan-an tá a bá fìfẹ́ hàn sí wọn tá a sì ń yìn wọ́n

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́