Gbígbóríyìn Fúnni Ń Mára Tuni
1 Pẹ̀lú omijé lójú ni ọmọdébìnrin kan fi béèrè lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ nígbà tí wọ́n fẹ́ sùn pé: “Ṣé mi ò ṣe dáadáa lónìí ni?” Ìbéèrè yẹn ya ìyá rẹ̀ lẹ́nu gan-an ni. Pẹ̀lú bí ìyá náà ṣe kíyè sí i pé ọmọdébìnrin òun sa gbogbo ipá rẹ̀ tó láti hùwà ọmọlúwàbí lọ́jọ́ yẹn, kò tiẹ̀ yin ọmọ náà rárá. Ó yẹ kí ẹkún tí ọmọdébìnrin náà sun rán gbogbo wa létí pé kò sẹ́ni tí kì í fẹ́ kí wọ́n yin òun—yálà ó jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà. Ǹjẹ́ a máa ń mú kí ara tu àwọn tó wà ní sàkáání wa nípa fífi ìmọrírì hàn fún ohun tí wọ́n bá ṣe?—Òwe 25:11.
2 Àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni máa ń ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere tó yẹ ká yìn wọ́n fún. Àwọn alàgbà, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àtàwọn aṣáájú ọ̀nà ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó ẹrù iṣẹ́ wọn. (1 Tím. 4:10; 5:17) Àwọn òbí olùbẹ̀rù Ọlọ́run ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà ní ọ̀nà Jèhófà. (Éfé. 6:4) Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni ń sapá kíkankíkan láti yẹra fún “ẹ̀mí ayé.” (1 Kọ́r. 2:12; Éfé. 2:1-3) Àwọn mìíràn ń sin Jèhófà tọkàntọkàn láìka ọjọ́ ogbó, àìlera tàbí àwọn àdánwò mìíràn sí. (2 Kọ́r. 12:7) Ó yẹ ká máa gbóríyìn fún irú àwọn ẹni báwọ̀nyí. Ǹjẹ́ a máa ń fi hàn pé a mọrírì ìsapá wọn nípa gbígbóríyìn fún wọn?
3 Lẹ́nì Kọ̀ọ̀kan àti ní Pàtó: Ó dájú pé gbogbo wa la máa ń mọrírì rẹ̀ bí a bá gbóríyìn fún gbogbo ìjọ lápapọ̀ látorí pèpéle. Àmọ́ ṣá o, ó máa ń tuni lára gan-an bí a bá gbóríyìn fún wa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Bí àpẹẹrẹ, ní orí 16 nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ó sọ̀rọ̀ ìgbóríyìn ní pàtó fún Fébè, Pírísíkà àti Ákúílà, Tírífénà àti Tírífósà àti Pésísì, àtàwọn mìíràn. (Róòmù 16:1-4, 12) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ á tu àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyẹn lára gan-an ni! Irú ọ̀rọ̀ ìyìn bẹ́ẹ̀ ń fi àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lọ́kàn balẹ̀ pé kòṣeémánìí ni wọ́n ó sì ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí. Ṣé o ti sọ̀rọ̀ ìgbóríyìn fún ẹnì kan ní pàtó lẹ́nu àìpẹ́ yìí?—Éfé. 4:29.
4 Látọkàn Wá: Kí ó bàa lè tuni lára, ó yẹ kí gbígbóríyìn fúnni ti inú ọkàn wá. Àwọn èèyàn lè mọ̀ bóyá ohun táà ń sọ ti inú ọkàn wa wá tàbí ńṣe la wulẹ̀ ‘ń fi ahọ́n wa pọ́n wọn lásán.’ (Òwe 28:23) Bí a bá fi kọ́ra láti máa kíyè sí ànímọ́ rere táwọn ẹlòmíràn ní, ọkàn wa á sún wa láti gbóríyìn fún wọn. Ǹjẹ́ kí ó má ṣe rẹ̀ wá láti máa gbóríyìn fúnni, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé ‘ọ̀rọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò mà dára o’—Òwe 15:23.