Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Gbígbóríyìn fún Wọn
1 Bó bá jẹ́ pé pẹ̀lú òótọ́ inú la fi ń gbóríyìn fáwọn èèyàn, á fún wọn níṣìírí, á mú kí wọ́n fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò, wọ́n á sì láyọ̀. Ọ̀pọ̀ akéde ti rí i pé àwọn tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń fẹ́ láti tẹ́tí gbọ́ wa nítorí ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn ṣókí tá a bá fòótọ́ inú sọ fún wọn. Báwo la ṣe wá lè gbóríyìn fáwọn èèyàn nígbà tá a bá ń wàásù ìhìn rere fún wọn?
2 Máa Kíyè sí Wọn: Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti gbé Jésù Kristi ga lọ́run, Jésù ò fojú pa iṣẹ́ rere táwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà Kékeré ń ṣe rẹ́. (Ìṣí. 2:2, 3, 13, 19; 3:8) Bákan náà, bá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a ó lè máa wá bá a ṣe máa gbóríyìn fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó tọ́ ká gbóríyìn fún ẹni tí àyíká rẹ̀ mọ́, òbí tó ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ tàbí onílé tó yá mọ́ni. Ǹjẹ́ o máa ń tètè rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bí àǹfààní láti gbóríyìn fáwọn èèyàn?
3 Jẹ́ Ẹni Tó Ń Fetí Sílẹ̀ Dáadáa: Bó o bá ń wàásù fáwọn èèyàn, jẹ́ káwọn náà sọ èrò wọn nípa bíbi wọ́n láwọn ìbéèrè tó bétí mu. Bu ọlá fún wọn nípa fífara balẹ̀ gbọ́ àlàyé wọn. (Róòmù 12:10) O ò ní ṣàìrí nǹkan kan látinú àlàyé yẹn tó o lè tìtorí rẹ̀ gbóríyìn fún wọn pẹ̀lú òótọ́ inú, èyí tó o lè lò bí àtẹ̀gùn láti fìdí ìjíròrò náà múlẹ̀.
4 Lo Òye: Kí la lè ṣe bí ìdáhùn onílé bá yàtọ̀ sí òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì? Dípò tá a ó fi ta ko èrò tí kò tọ̀nà yẹn, ṣe ló yẹ ká gbóríyìn fún onílé náà nítorí ohun tó sọ ká sì máa bá ìjíròrò nìṣó nípa fífọ irú èsì bíi “mo lè rí i pé o nífẹ̀ẹ́ sí ìjíròrò yìí gan-an ni.” (Kól. 4:6) Kódà kẹ́ni náà tiẹ̀ jẹ́ alárìíyànjiyàn, a ṣì lè máa gbóríyìn fún un látàrí bó ṣe jẹ́ kí kókó tá à ń jíròrò náà jẹ ẹ́ lọ́kàn. Irú èsì tó ń tuni lára bẹ́ẹ̀ lè pẹ̀rọ̀ sínú ẹni tó dà bíi pé ó ń ta ko ìhìn rere.—Òwe 25:15.
5 Bá a bá fẹ́ kí gbígbóríyìn tá à ń gbóríyìn fáwọn èèyàn fún wọn níṣìírí, a gbọ́dọ̀ fòótọ́ inú ṣe é. Irú àwọn gbólóhùn tó ń gbéni ró bẹ́ẹ̀ máa ń bọlá fún Jèhófà ó sì lè jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.