ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 2/15 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Akéde Ìjọba Ọlọ́run Gbé Ọ̀rọ̀ Lọ Sílé Ẹjọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ṣé Ibi tí Wọ́n Ti Ń Fi Iná Dáni Lóró Ni Gẹ̀hẹ́nà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Mátíù Orí 5-7
    Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Látinú Ìwé Ìhìn Rere
  • Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Fọwọ́ Sí Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 2/15 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ewu mẹ́ta wo ni Jésù kìlọ̀ nípa rẹ̀ nínú Mátíù 5:22?

Nígbà tí Jésù Kristi ń ṣe Ìwàásù Orí Òkè, ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a lọ ní kíkún fún ìrunú sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn fún kóòtù ìgbẹ́jọ́; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ ìfojú-tín-ín-rín tí kò ṣeé fẹnu sọ sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn fún Kóòtù Gíga Jù Lọ; nígbà tí ó jẹ́ pé, ẹnì yòówù tí ó bá wí pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ òkúùgbẹ́!’ yóò yẹ fún Gẹ̀hẹ́nà oníná.”—Mátíù 5:22.

Ohun táwọn Júù mọ̀ dáadáa ni Jésù lò láti fi ṣèkìlọ̀ fún wọn pé bí ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn ṣẹ̀ bá ṣe ga sí ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹni náà á ṣe pọ̀ sí. Ó lo kóòtù ìgbẹ́jọ́, Kóòtù Gíga Jù Lọ àti Gẹ̀hẹ́nà oníná.

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jésù sọ pé gbogbo ẹni tí ń bá a lọ ní kíkún fún ìrunú sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn fún “kóòtù ìgbẹ́jọ́,” ìyẹn kóòtù àdúgbò. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn Júù, àwọn ìlú táwọn ọkùnrin tó tó ọgọ́fà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ bá wà ni wọ́n máa ń kọ́ àwọn kóòtù wọ̀nyí sí. (Mátíù 10:17; Máàkù 13:9) Nírú àwọn kóòtù bẹ́ẹ̀, àwọn adájọ́ láṣẹ láti dá irú àwọn ẹjọ́ kan, títí kan ẹjọ́ ìpànìyàn pàápàá. (Diutarónómì 16:18; 19:12; 21:1, 2) Nítorí náà, ohun tí Jésù ń tipa báyìí sọ ni pé bí ẹnì kan bá ń di kùnrùngbùn sí arákùnrin rẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni onítọ̀hún ń dá.

Jésù tún sọ pé ẹni tó bá “sọ ọ̀rọ̀ ìfojú-tín-ín-rín tí kò ṣeé fẹnu sọ sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn fún Kóòtù Gíga Jù Lọ.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, rha·kaʹ (tó wà nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW) tí Bíbélì pè ní “ọ̀rọ̀ ìfojú-tín-ín-rín tí kò ṣeé fẹnu sọ” túmọ̀ sí “òfìfo” tàbí “òmùgọ̀.” Ìwé The New Thayer’s Greek-English Lexicon of the New Testament sọ pé ọ̀rọ̀ náà jẹ́ “ọ̀rọ̀ ìṣáátá táwọn Júù máa ń lò nígbà ayé Kristi.” Nípa báyìí, ńṣe ni Jésù ń kìlọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni kéèyàn kórìíra ọmọnìkejì rẹ̀ débi pé yóò máa sọ̀rọ̀ tí ń tàbùkù ẹni sí i. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi hàn pé téèyàn bá lo irú ọ̀rọ̀ náà, kì í ṣe kóòtù àdúgbò ló máa dájọ́ fún onítọ̀hún bí kò ṣe Kóòtù Gíga Jù Lọ, ìyẹn ni pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ló máa ṣèdájọ́ rẹ̀. Yàtọ̀ sí àlùfáà àgbà, àwọn àgbà ọkùnrin àti akọ̀wé tí iye wọn jẹ́ àádọ́rin ló wà nínú ìgbìmọ̀ yìí.—Máàkù 15:1.

Níkẹyìn, Jésù ṣàlàyé pé bí ẹnì kan bá sọ fún ẹlòmíràn pé, “Ìwọ òmùgọ̀ òkúùgbẹ́!” onítọ̀hún yóò yẹ fún Gẹ̀hẹ́nà oníná. Ọ̀rọ̀ náà “Gẹ̀hẹ́nà” jẹ yọ látinú ọ̀rọ̀ Hébérù yìí, geh hin·nomʹ, èyí tó túmọ̀ sí “àfonífojì Hínómù.” Apá ìwọ̀ oòrùn síhà gúúsù Jerúsálẹ́mù àtijọ́ ni àfonífojì náà wà. Nígbà ayé Jésù, pàǹtírí ni wọ́n máa ń sun níbẹ̀ àti òkú àwọn ọ̀daràn paraku tí wọ́n kà sí àwọn tí kò yẹ láti sin. Abájọ tí ọ̀rọ̀ náà, “Gẹ̀hẹ́nà” fi jẹ́ àpẹẹrẹ tó bá a mu tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun yán-ányán-án.

Kí wá ní gbólóhùn náà, “òmùgọ̀ òkúùgbẹ́” túmọ̀ sí o? Ọ̀rọ̀ tí Jésù lò níbí yìí fẹ́ jọ ọ̀rọ̀ Hébérù kan tó túmọ̀ sí “ọlọ̀tẹ̀.” Tí wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ náà sẹ́nì kan, ó fi hàn pé ẹni tí kò wúlò fún nǹkan kan lonítọ̀hún, pé onítọ̀hún jẹ́ apẹ̀yìndà tó ń ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Torí náà, téèyàn bá pe ọmọnìkejì rẹ̀ ní “òmùgọ̀ òkúùgbẹ́,” èyí ò yàtọ̀ sí pé èèyàn ń sọ pé kí Ọlọ́run fi ìyà tó tọ́ sí apẹ̀yìndà jẹ onítọ̀hún, pé kí ẹni náà ṣègbé pátápátá. Lójú Ọlọ́run, ẹni tó bá sọ irú ọ̀rọ̀ burúkú bẹ́ẹ̀ sí ẹlòmíràn lè gba irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ fúnra rẹ̀, ìyẹn ni pé Ọlọ́run lè pa á run títí ayérayé.—Diutarónómì 19:17-19.

Nítorí náà, ìlànà tó ga ju ìlànà tó wà nínú Òfin Mósè ni Jésù ń gbé kalẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn mọ̀ pé ẹni tó bá pààyàn yóò “jíhìn fún kóòtù ìgbẹ́jọ́,” kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé ìpànìyàn burú nìkan ni Jésù wúlẹ̀ tẹnu mọ́. Ó tún kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ ní àwọn arákùnrin wọn sínú rárá.—Mátíù 5:21, 22.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́