ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 3/1 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Wo Ló Ń Fi Ẹ̀kọ́ Kristi Sílò Lónìí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Wo Ló Ń Fi Ẹ̀kọ́ Kristi Sílò Lónìí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojú Wo Làwọn Èèyàn Fi Ń Wo Ẹ̀sìn Kristẹni?
  • Ṣé Kristi Ṣì Wà Pẹ̀lú Àwọn Tó Pe Ara Wọn Ní Kristẹni?
  • Ṣé Ẹ̀sìn Kristẹni Ti Kùnà?
    Jí!—2007
  • Àwọn Wo Ni Ojúlówó Kristẹni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Kí Nìdí Tí Onírúurú Ẹ̀sìn Kristẹni Fi Wà?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣé Ipa Rere ni Ẹ̀sìn Ń ní Lórí Àwọn Èèyàn ni Àbí Ipa Búburú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 3/1 ojú ìwé 3-4

Àwọn Wo Ló Ń Fi Ẹ̀kọ́ Kristi Sílò Lónìí?

JÁKÈJÁDÒ ayé làwọn èèyàn ti gbà pé Jésù Kristi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn pàtàkì tó tíì gbé ayé rí. Kódà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé òun lẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ. Fún nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún làwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ti ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Melvyn Bragg kọ̀wé pé, “bó ti ń ṣe àwọn ẹni rírẹlẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onínúure tí wọ́n sì tún jẹ́ ọmọlúàbí láǹfààní, bẹ́ẹ̀ náà ló tún ń ṣàǹfààní fáwọn èèyàn ńlá tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú tó ń gbé àwọn nǹkan kàǹkàkàǹkà ṣe láwùjọ.”

Ojú Wo Làwọn Èèyàn Fi Ń Wo Ẹ̀sìn Kristẹni?

Ẹ̀sìn Kristẹni wá ńkọ́? Àwọn èèyàn kan sọ pé ó jẹ́ “ọ̀kan lára àṣeyọrí gíga jù lọ tí aráyé ṣe nínú ọ̀ràn ìjọsìn.” Ọ̀gbẹ́ni David Kelso láti Yunifásítì Glasgow ti Caledonia tó wà nílẹ̀ Scotland sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lójú rẹ̀. Ohun tó kọ ni pé: “Láti ẹgbàá [2000] ọdún tí ẹ̀sìn Kristẹni ti wà, ọ̀pọ̀ àṣeyọrí tí kò lẹ́gbẹ́ ló ti mú kó wáyé nínú iṣẹ́ ọnà, ilé kíkọ́, èrò ẹ̀dá, orin, àti àjọṣe láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.”

Àmọ́ ojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn mìíràn fi ń wo ọ̀ràn náà yàtọ̀ pátápátá. Wọ́n gbà pé ohun tí ẹ̀sìn Kristẹni dá lé lórí ni àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi àti ìgbàgbọ́ pé òun ni ọmọ Ọlọ́run. Àmọ́, ohun tínú wọn ò dùn sí ni ìwà àwọn tó pe ara wọn ní ẹlẹ́sìn Kristi.

Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Friedrich Nietzsche, tó jẹ́ onímọ̀ nípa èrò ẹ̀dá ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn ẹlẹ́sìn Kristi yìí, ó sọ pé ẹ̀sìn Kristẹni jẹ́ “àbààwọ́n ayérayé tí ìran èèyàn ní.” Ó kọ̀wé pé, ẹ̀sìn Kristẹni ni “olórí ohun tó ń fa ìpalára jù lọ, ìwà ìbàjẹ́ inú rẹ̀ pọ̀ ó sì burú jáì, . . . kò sí ọ̀nà búburú tàbí ọ̀nà àbòsí èyíkéyìí tí wọn ò lè gbà kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń wá.” Lóòótọ́, irú èrò tí Nietzsche ní yìí kò wọ́pọ̀ rárá, àmọ́ èrò àwọn kan tó jẹ́ olóye èèyàn pàápàá fara jọ èyí. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò sígbà kan rí tí ìwà àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni bá ti Jésù Kristi mu, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó gbilẹ̀ láàárín wọn ni “ìwà ìbàjẹ́, ìwà ọ̀daràn tó burú jáì, àtàwọn ọ̀rọ̀ òdì.”

Ṣé Kristi Ṣì Wà Pẹ̀lú Àwọn Tó Pe Ara Wọn Ní Kristẹni?

Kò sóhun tó burú téèyàn bá béèrè pé, “Ṣé Kristi ṣì wà pẹ̀lú àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ni?” Ojú ẹsẹ̀ làwọn kan a sì dáhùn pé, “Ó wà pẹ̀lú wọn dáadáa! Àbí òun kọ́ ló ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun yóò wà pẹ̀lú wọn ‘títí dé òpin ayé’?” (Mátíù 28:20, Bibeli Mimọ) Lóòótọ́ ni Jésù sọ bẹ́ẹ̀, àmọ́ ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ó máa wà pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti pe ara rẹ̀ ní ọmọlẹ́yìn rẹ̀, láìka ìwà tí onítọ̀hún ń hù sí?

Ẹ rántí pé àwọn aṣáájú ìsìn kan nígbà ayé Jésù gbà pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn lọ́jọ́kọ́jọ́. Ohun táwọn aṣáájú ìsìn náà rò ni pé ohun yòówù táwọn ì báà ṣe, Ọlọ́run ò lè fáwọn sílẹ̀ láé, nítorí pé ó ti yan orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fún ìdí pàtàkì kan. (Míkà 3:11) Àmọ́, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n ṣe àṣerégèé, wọ́n kọ àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run sílẹ̀ pátápátá. Nítorí ohun tí wọ́n ṣe yìí, Jésù Kristi sọ fún wọn kedere pé: “Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mátíù 23:38) Bí gbogbo ètò ìsìn yẹn lódindi ṣe pàdánù ojú rere Ọlọ́run nìyẹn. Ọlọ́run kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pátápátá, ó sì jẹ́ káwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú wọn àti tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni.

Ǹjẹ́ ohun tó fara jọ èyí lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀sìn Kristẹni náà? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù fi kún ìlérí tó ṣe pé òun á wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn òun títí dé “òpin ayé.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2, 3]

Àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi ń ṣe àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn jákèjádò ayé láǹfààní

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́