ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 2/15 ojú ìwé 3-4
  • Ṣé Ipa Rere ni Ẹ̀sìn Ń ní Lórí Àwọn Èèyàn ni Àbí Ipa Búburú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ipa Rere ni Ẹ̀sìn Ń ní Lórí Àwọn Èèyàn ni Àbí Ipa Búburú?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ipa Rere Ni Ẹ̀sìn Ń Ní àbí Ipa Búburú?
  • Ṣé Ayé Á Dára Ju Báyìí Lọ Ká Ní Kò Sí Ìsìn?
  • Ṣé Ìsìn Ló Fa Ìṣòro Aráyé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Isin Eyikeyii Ha Dara Tó Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣíṣe Isin Mimọgaara fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jija Àjàbọ́ Kuro Ninu Isin Èké
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 2/15 ojú ìwé 3-4

Ṣé Ipa Rere ni Ẹ̀sìn Ń ní Lórí Àwọn Èèyàn ni Àbí Ipa Búburú?

“ỌPẸ́LỌPẸ́ ìsìn Kristẹni lára mi, ó sì dá mi lójú pé, ọpẹ́lọpẹ́ rẹ̀ lára àwọn tó ń gbé láyé láti ẹgbẹ̀rún ọdún méjì wá.—Ọ̀rọ̀ ìṣáájú ìwé Two Thousand Years—The First Millennium: The Birth of Christianity to the Crusades.

Melvyn Bragg, ìyẹn òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó tún jẹ́ oníròyìn, ló sọ̀rọ̀ rere tó wà lókè yẹn nípa “ìsìn Kristẹni.” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé èrò ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn nínú ayé yọ, ìyẹn àwọn tí wọ́n gbà pé ó yẹ káwọn náà dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ irú ẹ̀sìn kan tàbí òmíràn kí àwọn sì dúró ṣinṣin tì í. Wọ́n gbà pé ẹ̀sìn ní ipa tó dára gan-an lórí ìgbésí ayé àwọn. Bí àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé kan sọ pé ẹ̀sìn Ìsìláàmù “mú ọ̀làjú ńláńlá . . . [tó ti] ṣe gbogbo ayé làǹfààní wá.”

Ṣé Ipa Rere Ni Ẹ̀sìn Ń Ní àbí Ipa Búburú?

Ọ̀rọ̀ tí Bragg sọ tẹ̀ lé e mú ká ṣiyèméjì pé bóyá ipa rere ni ẹ̀sìn lápapọ̀ máa ń ní lórí àwọn èèyàn àbí ipa búburú. Bragg tún sọ pé: “Ìsìn Kristẹni náà ní àlàyé tó gbọ́dọ̀ ṣe fún mi.” Àlàyé lórí kí ni? Ó ní òun ń fẹ́ àlàyé lórí “ìwà àìgba èrò tẹlòmíràn, ìwà ìkà, ìwà òǹrorò àti ìwà mímọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ aláìmọ̀kan tó pọ̀ nínú ‘ìtàn’ ìsìn Kristẹni.”

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ pé jálẹ̀ ìtàn, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ẹ̀sìn ayé ti kún fún ìwà àìgba èrò tẹlòmíràn, ìwà ìkà, ìwà òǹrorò àti ìwà mímọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ aláìmọ̀kan. Ojú tí wọ́n fi wo ọ̀rọ̀ náà ni pé ńṣe ni ẹ̀sìn wulẹ̀ ń ṣe bí olóore aráyé, nígbà tó jẹ́ pé àgàbàgebè àti irọ́ ló wà nídìí ṣíṣe tó ń ṣe bí oníwà funfun àti ẹni mímọ́. (Mát. 23:27, 28) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ A Rationalist Encyclopædia sọ pé, “Gbólóhùn tó wọ́pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé wa ni pé ipa kékeré kọ́ ni ẹ̀sìn kó nínú ọ̀rọ̀ ọ̀làjú.” Ìwé náà sọ síwájú sí i pé, “Tá a bá sì wá wo àwọn ohun tí ìsìn ti ṣe látẹ̀yìnwá, a óò rí i pé irọ́ gbuu ni gbólóhùn náà.”

Kò sí ìwé ìròyìn tó o kà lónìí, tó ò ní í rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n ń wàásù ìfẹ́, àlàáfíà àti ìpamọ́ra, tó sì jẹ́ pé àwọn náà gan-an ló ń gbin ẹ̀mí ìkórìíra sáwọn èèyàn lọ́kàn, tí wọ́n á sì máa dárúkọ Ọlọ́run sí ìwà òkú òǹrorò tí wọ́n ń hù láti fi mú káwọn èèyàn gbà pé nǹkan tó dáa làwọn ń ṣe. Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé ipa tí kò dára ni ẹ̀sìn ń ní lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn!

Ṣé Ayé Á Dára Ju Báyìí Lọ Ká Ní Kò Sí Ìsìn?

Ibi táwọn kan parí èrò sí, gẹ́gẹ́ bíi ti onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, Bertrand Russell, ni pé yóò dára tí “gbogbo onírúurú ẹ̀sìn [bá] wọlẹ̀” láìpẹ́ láìjìnnà. Lójú tiwọn, ọ̀nà kan ṣoṣo tí gbogbo ìṣòro aráyé yóò gbà yanjú ni pé kó máà sí ẹ̀sìn kankan mọ́. Wọ́n lè máà fẹ́ gbà pé bí àwọn tí wọ́n dúró ti ìsìn lẹ́yìn gbágbáágbá ṣe lè gbin ẹ̀mí ìkórìíra àti ìwà mímọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ aláìmọ̀kan sí àwọn èèyàn lọ́kàn náà làwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀. Karen Armstrong, tó jẹ́ òǹkọ̀wé nípa ẹ̀sìn ránni létí pé: “Pípa tí ìjọba Násì pa àwọn Júù àtàwọn mìíràn nípakúpa nígbà Ogun Àgbáyé Kejì fi hàn pé àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn pàápàá [lè] ṣe irú ọṣẹ́ kan náà tí ogun ìsìn èyíkéyìí lè ṣe.”—Ìwé The Battle for God—Fundamentalism in Judaism, Christianity and Islam.

Ṣé ipa rere ni ẹ̀sìn máa ń ní lórí èèyàn àbí òun gan-an ló ń fá ìṣòro aráyé? Ṣé kí gbogbo ẹ̀sìn wọlẹ̀ ló máa tánṣòro yìí ni? Yẹ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn náà wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn. Ìdáhùn náà lè yà ọ́ lẹ́nu?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́