ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 4/15 ojú ìwé 3-4
  • Ẹ̀yin Tọkọtaya Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Jùmọ̀ Sọ̀rọ̀ Dáadáa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Tọkọtaya Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Jùmọ̀ Sọ̀rọ̀ Dáadáa?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bi A Ṣe Lè Mú Ìdè igbeyawo Lókun Sii
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọkọ Tàbí Aya Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Tú Ìgbéyàwó Ká?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 4/15 ojú ìwé 3-4

Ẹ̀yin Tọkọtaya Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Jùmọ̀ Sọ̀rọ̀ Dáadáa?

“LẸ́TÀ Ìfẹ́ tí Ẹni Ọgọ́ta Ọdún Kọ.” Èyí ni àkọlé ìdíje oríire tí báńkì kan ní orílẹ̀-èdè Japan ṣètò rẹ̀ lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn. Báńkì náà rọ àwọn ará Japan tí wọ́n ti lé ní àádọ́ta àti ọgọ́ta ọdún pé kí wọ́n kọ lẹ́tà láti fi sọ “bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn wọn” nípa ọkọ tàbí aya wọn. Ọ̀kan lára àwọn tó kópa nínú ìdíje náà kọ̀wé sí aya rẹ̀ pé: “O lè fi ọ̀rọ̀ mi rẹ́rìn-ín o, àmọ́ mi ò gbọ́dọ̀ má sọ ohun tó wà lọ́kàn mi. Jẹ́ kí n sòótọ́: Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ gan-an pé o fẹ́ mi.”

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé nínú àṣà ìbílẹ̀ wọn, àwọn èèyàn kì í fi gbogbo ẹnu sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn fún ẹlòmíì. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn láwọn ibì kan nílẹ̀ Éṣíà. Síbẹ̀, ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún èèyàn tó kópa nínú ìdíje kíkọ lẹ́tà ìfẹ́ yẹn. Ìdíje yìí gbayì débi pé wọ́n tún ṣètò òmíràn lẹ́yìn rẹ̀, kódà àwọn èèyàn ṣèwé lórí lẹ́tà wọ̀nyẹn. Èyí fi hàn pé ó wu ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn látọkànwá láti sọ bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya wọn ọ̀wọ́n tó. Àmọ́, ẹ ò lè gbọ́ ọ lẹ́nu àwọn míì. Kí nìdí? Ó lè jẹ́ nítorí pé ó nira fún wọn láti sọ, tàbí pé wọn ò mọ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ káwọn ẹlòmíì, irú bí ọkọ tàbí aya wọn, mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn.

Ọ̀gbẹ́ni Hitoshi Kato tó kọ̀wé kan nípa ìfẹ̀yìntì sọ nínú ìwé rẹ̀ pé, lágbo àwọn tọkọtaya tó ti dàgbà nílẹ̀ Japan, àwọn aya ló sábà máa ń jáwèé fún ọkọ wọn nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti ń fi sínú tipẹ́ tó wá di ńlá. Ó tún sọ pé: “Àmọ́ o, ohun mìíràn tó tún lè fa èyí ni pé àwọn tọkọtaya náà kì í sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn gan-an nígbà tí wọ́n bá ní ìṣòro.”

Nígbà míì, kété táwọn ọkọ kan bá fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ni aya wọn máa ń jáwèé fún wọn, ńṣe ni ọ̀rọ̀ náà sì máa ń bá wọn lábo. Ó lè jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún làwọn méjèèjì ò ti fi sọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn wọn fúnra wọn. Kálukú wọn sì ti lè máa gbìyànjú láti sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, àmọ́ kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa ń gba ara wọn sódì. Dípò kí àjọṣe àárín wọn máa dán mọ́rán sí i, ariwo ni ṣáá lójoojúmọ́.

Báwo ni ọkọ àti aya ṣe lè máa fi pẹ̀lẹ́tù yanjú ìṣòro àárín wọn kí wọ́n sì máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò tu ẹnì kejì lára? A fẹ́ kó o mọ̀ pé àwọn ìmọ̀ràn tó máa ran tọkọtaya lọ́wọ́ wà, àmọ́ kì í ṣe inú ìwé tí agbani-nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìdílé kan kọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ló wà, bí kò ṣe inú ìwé àtayébáyé kan táwọn èèyàn mọyì láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, ìyẹn Bíbélì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́