“Àwa Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso Dípò Àwọn Ènìyàn”
“Ti Jèhófà Ni Ìjà Ogun Náà”
ẸGBẸ́ ológun Ísírẹ́lì àti ti ilẹ̀ Filísínì dúró sí ìhà ìhín àti ìhà ọ̀hún àfonífojì kan, wọ́n ń wo ara wọn lójú. Ogójì ọjọ́ ni jìnnìjìnnì fi bá àwọn jagunjagun Ísírẹ́lì bí wọ́n ṣe ń gbọ́ bí Gòláyátì, olórí ogun ilẹ̀ Filísínì, ṣe ń rọ̀jò èébú lé wọn lórí.—1 Sámúẹ́lì 17:1-4, 16.
Ńṣe ni Gòláyátì ń fi ohùn rara ṣáátá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Á ní: “Ẹ yan ọkùnrin kan fún ara yín, kí ẹ sì jẹ́ kí ó sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ mí wá. Bí ó bá lè bá mi jà, tí ó sì ṣá mi balẹ̀, nígbà náà, àwa yóò di ìránṣẹ́ fún yín. Ṣùgbọ́n bí èmi fúnra mi bá figẹ̀ wọngẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí mo sì ṣá a balẹ̀, ẹ̀yin pẹ̀lú yóò di ìránṣẹ́ fún wa, ẹ ó sì máa sìn wá. . . . Èmi fúnra mi ṣáátá ìlà ogun Ísírẹ́lì lónìí yìí. Ẹ fún mi ní ọkùnrin kan, kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ jà!”—1 Sámúẹ́lì 17:8-10.
Láyé ìgbàanì, àwọn akọni sábà máa ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ogun wọn nínú ìjà, wọ́n á lọ figẹ̀ wọngẹ̀ pẹ̀lú akọni mìíràn. Ẹgbẹ́ ológun tí akọni rẹ̀ bá sì ṣẹ́gun ni wọ́n á gbà pé ó borí. Àmọ́ akọni tó ń ṣáátá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí yàtọ̀ sí gbogbo jagunjagun yòókù. Òmìrán ni ọ̀tá yìí, ṣẹ̀rùbàwọ́n sì tún ni. Àmọ́ ṣá o, ńṣe ni Gòláyátì fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣera ẹ̀ bó ṣe ń pẹ̀gàn ẹgbẹ́ ológun àwọn èèyàn Jèhófà.
Èyí kì í ṣe ìjà àjàmọ̀gá láàárín ẹgbẹ́ ológun méjì o. Ìjà láàárín Jèhófà àtàwọn òrìṣà ilẹ̀ Filísínì ni. Dípò tí Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì ì bá fi fìgboyà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ gbéjà ko àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, ńṣe ni jìnnìjìnnì bò ó.—1 Sámúẹ́lì 17:11.
Ọ̀dọ́kùnrin Kan Gbára Lé Jèhófà
Láàárín àkókò yìí táwọn ẹgbẹ́ ológun méjèèjì fi ń wo ara wọn lójú, ọ̀dọ́kùnrin kan tí wọ́n ti fòróró yàn láti di ọba Ísírẹ́lì wá wo àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù. Dáfídì ni orúkọ rẹ̀. Nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu Gòláyátì, ó béèrè pé: “Ta ni Filísínì aláìdádọ̀dọ́ yìí jẹ́ tí yóò fi máa ṣáátá àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè?” (1 Sámúẹ́lì 17:26) Lójú Dáfídì, àwọn ọmọ Filísínì àtàwọn òrìṣà wọn ni Gòláyátì ń ṣojú fún. Ìdí nìyí tí inú fi bí i lọ́nà òdodo tó wá fẹ́ jà fún orúkọ Jèhófà àti Ísírẹ́lì, kí ó bá òmìrán tó jẹ́ abọ̀rìṣà náà jà. Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù Ọba sọ fún un pé: “Ìwọ kò lè lọ bá Filísínì yìí láti bá a jà, nítorí ọmọdékùnrin lásán-làsàn ni ọ́.”—1 Sámúẹ́lì 17:33.
Ẹ ò rí i pé ojú tí Sọ́ọ̀lù àti Dáfídì fi wo ọ̀rọ̀ náà yàtọ̀ síra! Sọ́ọ̀lù wò ó pé ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn yìí ò lè bá òmìrán tó rorò náà jà rárá àti rárá ni. Àmọ́ lójú Dáfídì, èèyàn lásán-làsàn tó ń ṣàfojúdi sí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni Gòláyátì. Dáfídì ò sì mikàn torí ó mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣáátá orúkọ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀ kò ní lọ láìjìyà. Gòláyátì ń fọ́nnu nípa agbára tó ní, àmọ́ Jèhófà ni Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé ní tiẹ̀, ojú tí Ọlọ́run sì fi ń wo ọ̀ràn náà lòun fi ń wò ó.
“Èmi Ń Bọ̀ Lọ́dọ̀ Rẹ Pẹ̀lú Orúkọ Jèhófà”
Ìdí pàtàkì kan wà tí Dáfídì fi gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Ó rántí pé Ọlọ́run ló ran òun lọ́wọ́ tóun fi gba àgùntàn òun lẹ́nu béárì àti kìnnìún. Èyí ló jẹ́ kó dá ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn yìí lójú pé Jèhófà yóò ran òun lọ́wọ́ lọ́tẹ̀ yìí láti kojú elénìní ọmọ Filísínì tó jẹ́ ṣẹ̀rùbàwọ́n yìí. (1 Sámúẹ́lì 17:34-37) Dáfídì mú kànnàkànnà rẹ̀, ó sì wá òkúta márùn-ún tó jọ̀lọ̀, ó wá lọ pàdé Gòláyátì.
Ìgbẹ́kẹ̀lé tí Dáfídì ní nínú Jèhófà ló mú kó fẹ́ ṣe ohun tó dà bíi pé kò lè ṣeé ṣe yìí. Ó fìgboyà sọ fún òmìrán Filísínì náà pé: “Ìwọ ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ ti ṣáátá. Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ . . . Àwọn ènìyàn gbogbo ilẹ̀ ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà tí ó jẹ́ ti Ísírẹ́lì. Gbogbo ìjọ yìí yóò sì mọ̀ pé kì í ṣe idà tàbí ọ̀kọ̀ ni Jèhófà fi ń gbani là, nítorí pé ti Jèhófà ni ìjà ogun náà.”—1 Sámúẹ́lì 17:45-47.
Kí ni àbájáde ìjà náà? Bíbélì sọ pé: “Dáfídì, pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta, lágbára ju Filísínì náà, ó sì ṣá Filísínì náà balẹ̀, ó sì fi ikú pa á; kò sì sí idà ní ọwọ́ Dáfídì.” (1 Sámúẹ́lì 17:50) Kò sí idà kankan lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run wà lẹ́yìn rẹ̀ gbágbáágbá.a
Ìjà yìí fi hàn gbangba pé ìgbẹ́kẹ̀lé tí Dáfídì ní nínú Jèhófà ò já sásán! Tó bá di pé ká yàn nínú pé ká bẹ̀rù èèyàn tàbí ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó ní agbára láti gbani là, ohun tó yẹ ká ṣe ṣe kedere, ìyẹn ni pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Ìyẹn nìkan kọ́ o, tá a bá ń fi ojú tí Jèhófà Ọlọ́run fi ń wo ìṣòro kan wò ó, yóò ṣeé ṣe fún wa láti fi ojú tó tọ́ wo ohun tó jẹ́ ìṣòro ńlá pàápàá.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo oṣù May àti June nínú kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2006.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
BÁWO NI GÒLÁYÁTÌ ṢE TÓBI TÓ?
Ìwé Sámúẹ́lì kìíní orí kẹtàdínlógún ẹsẹ kẹrin sí ìkeje fi yé wa pé gíga Gòláyátì lé ní ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà, ìyẹn ohun tó lé ní ẹsẹ̀ bàtà mẹ́sàn-án. Tá a bá wo ẹ̀wù tí wọ́n fi àdàrọ irin ṣe tí Filísínì yìí ń wọ̀, a ó mọ bó ṣe tóbi tó àti bó ṣe lágbára tó. Ẹ̀wù náà wúwo ju àpò sìmẹ́ǹtì kan lọ! Ọ̀pá tí wọ́n fi ṣe ọ̀kọ̀ rẹ̀ dà bí ìtì igi àwọn ahunṣọ, ìwọ̀n abẹ ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì tó kílò méje. Áà, àfàìmọ̀ ni ìhámọ́ra Gòláyátì ò wúwo ju Dáfídì alára lọ!