Inú Orílẹ̀-èdè Tí Ọlọ́run Yàn La Bí Wọn Sí
“Ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti yàn láti di ènìyàn rẹ̀.”—DIUTARÓNÓMÌ 7:6.
1, 2. Àwọn ohun ribiribi wo ni Jèhófà ṣe nítorí àwọn èèyàn rẹ̀, àjọṣe wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì wọnú rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run?
LỌ́DÚN 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà mú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé wọnú àjọṣe tuntun kan pẹ̀lú rẹ̀. Lọ́dún yẹn, ó dojú ti agbára ayé kan, ó sì gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú. Ohun tó ṣe yìí ló mú kó di Olùgbàlà wọn àti Olúwa wọn. Kí Ọlọ́run to ṣe ohun tó ṣe yìí, ó sọ fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Èmi ni Jèhófà, èmi yóò sì mú yín jáde dájúdájú kúrò lábẹ́ ẹrù ìnira àwọn ará Íjíbítì, èmi yóò sì dá yín nídè kúrò nínú ìsìnrú wọn, èmi yóò sì tún gbà yín padà ní ti gidi pẹ̀lú apá nínà jáde àti pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ ńlá. Dájúdájú, èmi yóò sì mú yín sọ́dọ̀ ara mi gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run fún yín ní ti tòótọ́.’”—Ẹ́kísódù 6:6, 7; 15:1-7, 11.
2 Kété táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, wọ́n dá májẹ̀mú pé àjọṣe yóò wà láàárín àwọn àti Jèhófà Ọlọ́run. Dípò kí Jèhófà máa bá ẹnì kọ̀ọ̀kan, tàbí ìdílé kọ̀ọ̀kan, tàbí àwùjọ àwọn ìdílé tó bára tan lò, àwọn èèyàn tá a kó jọ, ìyẹn orílẹ̀-èdè kan lórí ilẹ̀ ayé, ló wá ń bá lò látìgbà yẹn lọ. (Ẹ́kísódù 19:5, 6; 24:7) Ó fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní òfin tí yóò máa darí ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́, pàápàá àwọn òfin tí wọ́n á máa lò nínú ìjọsìn wọn. Mósè sọ fún wọn pé: “Orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó wà, tí ó ní àwọn ọlọ́run tí wọ́n sún mọ́ ọn bí Jèhófà Ọlọ́run wa ti ṣe nínú gbogbo kíké tí a ń ké pè é? Orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó sì wà, tí ó ní àwọn ìlànà òdodo àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ bí gbogbo òfin yìí tí mo ń fi sí iwájú yín lónìí?”—Diutarónómì 4:7, 8.
Inú Orílẹ̀-Èdè Àwọn Ẹlẹ́rìí La Bí Wọn Sí
3, 4. Kí nìdí pàtàkì tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi wà?
3 Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Aísáyà rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí ìdí pàtàkì tí orílẹ̀-èdè náà fi wà. Aísáyà sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹlẹ́dàá rẹ, ìwọ Jékọ́bù, àti Aṣẹ̀dá rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì: ‘Má fòyà, nítorí pé mo ti tún ọ rà. Mo ti fi orúkọ rẹ pè ọ́. Tèmi ni ọ́. Nítorí pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tí í ṣe Olùgbàlà rẹ. . . . Mú àwọn ọmọkùnrin mi wá láti ibi jíjìnnàréré, àti àwọn ọmọbìnrin mi láti ìkángun ilẹ̀ ayé, olúkúlùkù ẹni tí a ń fi orúkọ mi pè, tí mo sì dá fún ògo mi, tí mo ṣẹ̀dá, bẹ́ẹ̀ ni, tí mo ṣe. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn, . . . àwọn ènìyàn tí mo ti ṣẹ̀dá fún ara mi, kí wọ́n lè máa ròyìn ìyìn mi lẹ́sẹẹsẹ.’”—Aísáyà 43:1, 3, 6, 7, 10, 21.
4 Gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tá à ń fi orúkọ Jèhófà pè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò máa jẹ́rìí fún àwọn orílẹ̀-èdè pé Ọlọ́run ni ọba aláṣẹ. Wọ́n yóò jẹ́ èèyàn ‘tí a dá fún ògo Jèhófà.’ Wọn yóò máa ‘sọ̀rọ̀ ìyìn Jèhófà,’ wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun ribiribi tó ṣe láti dá wọn nídè, wọ́n á wá tipa báyìí máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀ lógo. Ní ṣókí, wọ́n á jẹ́ orílẹ̀-èdè ẹlẹ́rìí fún Jèhófà.
5. Ọ̀nà wo ni Ísírẹ́lì gbà jẹ́ orílẹ̀-èdè tá a yà sí mímọ́?
5 Ni ọ̀rúndún kọkànlá ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Sólómọ́nì Ọba fi hàn pé Jèhófà ti ṣe Ísírẹ́lì ní orílẹ̀-èdè tó yà sọ́tọ̀. Nínú àdúrà tí Sólómọ́nì gbà sí Jèhófà, ó sọ pé: “Ìwọ fúnra rẹ ni ó yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún ìní rẹ nínú gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé.” (1 Àwọn Ọba 8:53) Ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan tún ní àjọṣe pàtàkì pẹ̀lú Jèhófà. Ṣáájú àkókò yẹn, Mósè ti sọ fún wọn pé: “Ọmọ Jèhófà Ọlọ́run yín ni ẹ jẹ́. . . . Nítorí ènìyàn mímọ́ ni o jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 14:1, 2) Nítorí náà, àwọn ọmọdé tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì kò ní láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Ńṣe la bí wọ́n gẹ́gẹ́ bí ara àwọn èèyàn tí Ọlọ́run ti yà sí mímọ́. (Sáàmù 79:13; 95:7) Gbogbo àwọn ọmọ tí wọ́n ń bí ló gba ìtọ́ni nípa àwọn òfin Jèhófà wọ́n sì ní láti máa pa wọ́n mọ́ nítorí májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ísírẹ́lì dá.—Diutarónómì 11:18, 19.
Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Lómìnira Láti Yan Ohun Tó Wù Ú
6. Ìpinnu wo lọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣe?
6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú orílẹ̀-èdè tá a yà sí mímọ́ ni wọ́n bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní láti pinnu láti sin Ọlọ́run. Kí wọ́n tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè sọ fún wọn pé: “Èmi ń fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí, pé èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn; nítorí òun ni ìyè rẹ àti gígùn ọjọ́ rẹ, kí ìwọ lè máa gbé lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù láti fi fún wọn.” (Diutarónómì 30:19, 20) Nítorí náà, ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan ló ní láti fúnra rẹ̀ pinnu láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, láti fetí sí ohun rẹ̀, àti láti fà mọ́ ọn. Níwọ̀n báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ní òmìnira láti yan ohun tó bá wù wọ́n, àwọn fúnra wọn ló máa kórè ohun tó bá tẹ̀yìn rẹ̀ yọ.—Diutarónómì 30:16-18.
7. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ìran ìgbà ayé Jóṣúà kú tán?
7 Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn Onídàájọ́ ń ṣàkóso ní Ísírẹ́lì jẹ́ ká rí ohun tó máa ń jẹ́ àbájáde ìṣòtítọ́ àti àìṣòtítọ́. Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere Jóṣúà, Jèhófà sì bù kún wọn. “Àwọn ènìyàn náà sì ń bá a lọ láti sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbà ọkùnrin tí ọjọ́ wọ́n gùn ré kọjá ti Jóṣúà, tí wọ́n sì ti rí gbogbo iṣẹ́ ńlá Jèhófà tí ó ṣe fún Ísírẹ́lì.” Àmọ́ o, lẹ́yìn ikú Jóṣúà, “ìran mìíràn sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde lẹ́yìn wọn, tí kò mọ Jèhófà tàbí iṣẹ́ tí ó ti ṣe fún Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣubú sínú ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.” (Onídàájọ́ 2:7, 10, 11) Ó hàn kedere pé, ìran tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà náà kò nírìírí, wọn ò sì fojú iyebíye wo ogún wọn pé ara àwọn èèyàn tá a yà sí mímọ́ ni wọ́n, ìyẹn àwọn èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run ti tìtorí wọn ṣe iṣẹ́ àrà nígbà kan sẹ́yìn.—Sáàmù 78:3-7, 10, 11.
Bí Wọ́n Ṣe Lè Ṣe Ohun Tó Bá Ìyàsímímọ́ Wọn Mu
8, 9. (a) Ìṣètò wo ló fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti fi hàn pé wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà? (b) Kí làwọn tó ń rú ọrẹ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe sí Ọlọ́run jèrè fún ara wọn?
8 Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ láǹfààní láti ṣe ohun tó bá ìyàsímímọ́ wọn mu gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. Bí àpẹẹrẹ, Òfin tó fún wọn ló mú kí wọ́n máa rú àwọn ẹbọ tàbí ọrẹ. Àwọn kan lára àwọn ẹbọ náà jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe, àwọn kan sì jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe. (Hébérù 8:3) Lára irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni, ọrẹ ẹbọ sísún, ọrẹ ẹbọ ọkà àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ tí wọ́n jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe, àwọn wọ̀nyí sì jẹ́ ẹ̀bùn tí wọ́n ń mú wá fún Jèhófà láti jèrè ojú rere rẹ̀ àti láti fi ṣe ìdúpẹ́.—Léfítíkù 7:11-13.
9 Àwọn ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe wọ̀nyẹn máa ń múnú Jèhófà dùn. “Òórùn amáratuni sí Jèhófà” ni wọ́n pe ọrẹ ẹbọ sísún àti ọrẹ ẹbọ ọkà. (Léfítíkù 1:9; 2:2) Nínú ẹbọ ìdàpọ̀, ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá ẹran ni wọ́n fi máa ń rúbọ sí Jèhófà, àwọn àlùfáà àtẹni tó mú ẹran ẹbọ náà wá sì máa ń jẹ àwọn apá kan lára ẹran náà. Ó jẹ́ oúnjẹ ìṣàpẹẹrẹ tó ń fi hàn pé àjọṣe alálàáfíà wà láàárín ẹni náà àti Jèhófà. Òfin náà sọ pé: “Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ rú ẹbọ ìdàpọ̀ sí Jèhófà, kí ẹ rú u láti rí ìtẹ́wọ́gbà fún ara yín.” (Léfítíkù 19:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì la yà sí mímọ́ fún Jèhófà nítorí orílẹ̀-èdè tá a bí wọn sí, àwọn tí wọ́n ṣe ohun tó bá ìyàsímímọ́ wọn mu nípa rírú ọrẹ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe sí Ọlọ́run ‘jèrè ojú rere fún ara wọn’ Ọlọ́run sì bù kún wọn gan-an.—Málákì 3:10.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé ohun táwọn èèyàn ṣe láwọn ọjọ́ Aísáyà àti Málákì kò dùn mọ́ òun nínú?
10 Àmọ́ ṣá o, léraléra ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tá a ti yà sí mímọ́ yìí hùwà àìṣòtítọ́ sí Jèhófà. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Aísáyà sọ fún wọn pé: “Ìwọ kò mú àgùntàn àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun rẹ wá fún mi, o kò sì fi àwọn ẹbọ rẹ yìn mí lógo. Èmi kò ṣe é ní ọ̀ranyàn fún ọ pé kí o fi ẹ̀bùn sìn mí.” (Aísáyà 43:23) Ohun mìíràn tún ni pé, àwọn ọrẹ ẹbọ tá ò fìfẹ́ ṣe tí kò sì tọkàn ẹni wá kò níye lórí lójú Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ọjọ́ Aísáyà, ìyẹn lọ́jọ́ wòlíì Málákì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń fi àwọn ẹran tó lábùkù rúbọ. Nítorí náà, Málákì sọ fún wọn pé: “‘Èmi kò ní inú dídùn sí yín,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘èmi kò sì ní ìdùnnú nínú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn láti ọwọ́ yín.‘ . . . ‘Ẹ ti mú ohun tí a fà ya wá, àti èyí tí ó yarọ, àti aláìsàn; bẹ́ẹ̀ ni, ẹ ti mú un wá bí ẹ̀bùn. Èmi ha lè ní ìdùnnú nínú rẹ̀ ní ọwọ́ yín bí?’ ni Jèhófà wí.”—Málákì 1:10, 13; Ámósì 5:22.
Wọn Kì Í Ṣe Orílẹ̀-Èdè Tí Ọlọ́run Yà Sí Mímọ́ fún Ara Rẹ̀ Mọ́
11. Àǹfààní wo ni Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì?
11 Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè tí Jèhófà yà sí mímọ́ fún ara rẹ̀, ó ṣèlérí fún wọn pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, nítorí pé, gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi. Ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.” (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Àárín wọn ni Mèsáyà tá a ṣèlérí náà yóò ti fara hàn, àwọn ni yóò sì kọ́kọ́ fún láǹfààní láti di ara àwọn tó máa ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18; 49:10; 2 Sámúẹ́lì 7:12, 16; Lúùkù 1:31-33; Róòmù 9:4, 5) Àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ lára orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kò ṣe ohun tó bá ìyàsímímọ́ wọn mu. (Mátíù 22:14) Wọ́n kọ Mèsáyà sílẹ̀ wọ́n sì pa á níkẹyìn.—Ìṣe 7:51-53.
12. Gbólóhùn wo ni Jésù sọ tó fi hàn pé Jèhófà ti kọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, pé kì í ṣe orílẹ̀-èdè tó yà sí mímọ́ fún ara rẹ̀ mọ́?
12 Ní ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú kí Jésù tó kú, ó sọ fáwọn aṣáájú ìsìn Júù pé: “Ṣé ẹ kò tíì kà nínú Ìwé Mímọ́ rí pé, ‘Òkúta tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì ni èyí tí ó ti di olórí òkúta igun ilé. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ohun ìyanu ní ojú wa’? Ìdí nìyí tí mo fi wí fún yín pé, A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mátíù 21:42, 43) Láti fi hàn pé Jèhófà ti kọ orílẹ̀-èdè tó yà sí mímọ́ fún ara rẹ̀ yìí sílẹ̀, Jésù sọ pé: “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, olùpa àwọn wòlíì àti olùsọ àwọn tí a rán sí i lókùúta,—iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀! Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́ ẹ. Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.”—Mátíù 23:37, 38.
Orílẹ̀-Èdè Tuntun Kan Tá A Yà Sí Mímọ́
13. Ọ̀rọ̀ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jèhófà sọ lákòókò Jeremáyà?
13 Lákòókò wòlíì Jeremáyà, Jèhófà sàsọtẹ́lẹ̀ ohun tuntun kan nípa àwọn èèyàn rẹ̀. A kà á pé: “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe èyí tí ó rí bí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo di ọwọ́ wọn mú láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, “májẹ̀mú mi èyí tí àwọn fúnra wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ni ọkọ olówó orí wọn,” ni àsọjáde Jèhófà.’ ‘Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì,’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Ṣe ni èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.’”—Jeremáyà 31:31-33.
14. Ìgbà wo ni Jèhófà dá orílẹ̀-èdè tuntun tó yà sí mímọ́ yẹn sílẹ̀, kí sì nìdí tó fi dá a sílẹ̀? Àwọn wo ni orílẹ̀-èdè tuntun náà.
14 Nígbà tí Jésù kú tó sì gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ fún Bàbá rẹ̀ lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni la fi ìpìlẹ̀ májẹ̀mú tuntun yìí lélẹ̀. (Lúùkù 22:20; Hébérù 9:15, 24-26) Àmọ́ ṣá o, májẹ̀mú tuntun yẹn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà tá a tú ẹ̀mí mímọ́ jáde lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni àti nígbà ìbí orílẹ̀-èdè tuntun kan, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16; Róòmù 2:28, 29; 9:6; 11:25, 26) Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó sọ pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá’ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀. Nítorí ẹ kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run.” (1 Pétérù 2:9, 10) Àjọṣe pàtàkì tó wà láàárín Jèhófà àti Ísírẹ́lì nípa tara ti dópin. Lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ojú rere Jèhófà ti kúrò lára Ísírẹ́lì nípa tara, ó ti wá wà lára Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí, ìyẹn ìjọ Kristẹni, ‘orílẹ̀-èdè tó ń mú èso’ Ìjọba Mèsáyà “jáde.” —Mátíù 21:43.
Ìyàsímímọ́ Tí Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Ṣe
15. Irú ìrìbọmi wo ni Pétérù rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ láti ṣe lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?
15 Lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìyẹn Júù tàbí Kèfèrí, ní láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run kó sì ṣe ìrìbọmi “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.”a (Mátíù 28:19) Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, àpọ́sítélì Pétérù sọ fáwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n lọ́kàn rere pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́.” (Ìṣe 2:38) Àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe wọ̀nyẹn ní láti fi hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi wọn pé, àwọn ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà àwọn sì tún gbà pé Jésù ni ẹni tí Jèhófà ń tipasẹ̀ rẹ̀ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn jì. Wọ́n ní láti gbà pé òun ni Àlùfáà Àgbà tí Jèhófà yàn àti Aṣáájú wọn, ìyẹn Orí ìjọ Kristẹni.—Kólósè 1:13, 14, 18.
16. Báwo làwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tí wọ́n lọ́kàn rere ṣe di ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí nígbà ayé Pọ́ọ̀lù?
16 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ṣùgbọ́n mo ń mú ìhìn iṣẹ́ náà wá fún àwọn tí ń bẹ ní Damásíkù lákọ̀ọ́kọ́ àti àwọn tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù, àti fún gbogbo ilẹ̀ Jùdíà, àti fún àwọn orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí padà sí Ọlọ́run nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.” (Ìṣe 26:20) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti mú un dá àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí lójú pé Jésù ni Kristi, tí í ṣe Mèsáyà, ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ya ara wọn sí mímọ́ kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. (Ìṣe 16:14, 15, 31-33; 17:3, 4; 18:8) Nígbà tí wọ́n yí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun yẹn di ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí.
17. Iṣẹ́ fífi èdìdì di àwọn wo lo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, iṣẹ́ mìíràn wo ló sì ń yára kankan báyìí?
17 Lónìí, fífi èdìdì di àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí tó ṣẹ́ kù ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. Nígbà tí iṣẹ́ náà bá parí, a óò pàṣẹ fún “àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin” tó di afẹ́fẹ́ ìparun ti “ìpọ́njú ńlá” mú pé kí wọ́n tú wọn sílẹ̀. Kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, à ń kó àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” jọ báyìí, ìyẹn àwọn tó ní ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé, iṣẹ́ náà sì ń yára kánkán. “Àwọn àgùntàn mìíràn” wọ̀nyí ń fúnra wọn fínnúfíndọ̀ yàn láti lo ìgbàgbọ́ nínú “ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” wọ́n sì ń ṣèrìbọmi láti fi hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà. (Ìṣípayá 7:1-4, 9-15; 22:17; Jòhánù 10:16; Mátíù 28:19, 20) Ọ̀pọ̀ lára wọn jẹ́ àwọn èwe tí àwọn obí Kristẹni ń tọ́. Bó o bá jẹ́ irú ewé bẹ́ẹ̀, yóò wù ọ́ láti ka àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Àtúnyẹ̀wò
• Kí nìdí tí èwe kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì kò fí ní láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà láyè ọ̀tọ̀?
• Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lè fi hàn pé àwọn ń ṣe ohun tó bá ìyàsímímọ́ wọn mu?
• Kí nìdí tí Jèhófà fi kọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ pé kì í ṣe orílẹ̀-èdè tóun yà sí mímọ́ fún ara òun mọ́, orílẹ̀-èdè wo ló sì wá fi rọ́pò rẹ̀?
• Láti ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni lọ, kí làwọn Júù àtàwọn Kèfèrí ní láti ṣe láti di ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ìgbà tí wọ́n bí àwọn èwe tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n ti di ara orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run yàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan ní láti fúnra rẹ̀ pinnu pé Ọlọ́run lóun máa sìn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọrẹ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti fi ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà hàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run kí wọ́n sì fi èyí hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi